Kí Ló Máa Ń Mú Mi Ronú Pé Kò Yẹ Kí N Ṣe Àṣìṣe Kankan?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Máa Ń Mú Mi Ronú Pé Kò Yẹ Kí N Ṣe Àṣìṣe Kankan?
“Nítorí pé bàbá mi ti jẹ́ olùkọ́, ńṣe ni gbogbo èèyàn ń retí pé kí n máa gbé ipò kìíní nínú gbogbo iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́. Nígbà míì, mo máa ń sunkún títí mo fi máa sùn.”—Leah. a
“Mo jẹ́ ẹni tó máa ń fẹ́ ṣe nǹkan láìsí àṣìṣe kankan. Mo máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí mo bá ṣe ló máa dáa jù tàbí kí n ṣe é lọ́nà tó máa yàtọ̀ pátápátá sí ti gbogbo àwọn ẹlòmíràn, láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ mi ò ní dáwọ́ lé irú ohun bẹ́ẹ̀ rárá.”—Caleb.
ǸJẸ́ O máa ń fẹ́ kí gbogbo ohun tó o bá ń ṣe jẹ́ èyí tí kò ní ní àṣìṣe kankan nínú? Ǹjẹ́ o máa ń sábàá ṣàníyàn pé, láìka bó o ṣe lè gbìyànjú tó, ohun tó o ṣe kì í tẹ́ ọ lọ́rùn? Ṣé ó máa ń ṣòro fún ọ láti gbà tẹ́nì kan bá sọ fún ọ pé ohun tó o ṣe kò dójú ìlà? Nígbà tí nǹkan ò bá rí bó o ṣe fẹ́ kó rí, ǹjẹ́ o máa ń dá ara rẹ lẹ́bi, tí wàá sì máa ka ara rẹ sí aláìmọ̀kan tàbí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan? Ǹjẹ́ o máa ń wò ó pé bó o bá fẹ́ pé kí nǹkan dára, àfi kó o ṣe é fúnra rẹ? Nígbà míì, ǹjẹ́ o máa ń bẹ̀rù pé o lè fìdí rẹmi débi pé ńṣe lo máa ń fi nǹkan falẹ̀ tàbí kó o má tiẹ̀ dáwọ́ lé e rárá?
Àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ńkọ́? Ṣé àwọn èèyàn kì í rójú rẹ nílẹ̀ torí pé kò sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n ṣe tó lójú rẹ? Ǹjẹ́ àṣìṣe àti ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ẹlòmíràn máa ń bí ọ nínú? Bí ìdáhùn rẹ sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, nígbà náà, á jẹ́ pé o ní ìṣòro ṣíṣe nǹkan láìfẹ́ ṣàṣìṣe rara. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan lo ní irú ìṣòro yìí o. Ìṣòro yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́—pàápàá àwọn ọ̀dọ́ tó mọ̀wé gan-an àtàwọn tó máa ń gbégbá orókè. b
Kí ló ń fa kéèyàn máà fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan? Ńṣe làwọn olùṣèwádìí kàn ń dábàá lásán, wọn ò lè sọ ohun tó ń fà á gan-an. Ìwé náà, Perfectionism—What’s Bad About Being Too Good? dábàá pé: “Ẹ̀mí ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan kì í ṣe àrùn, torí pé o ò kó o lára ẹnì kankan. Kì í ṣe àjogúnbá, torí pé àwọn òbí rẹ kò bí i mọ́ ọ. Nígbà náà, báwo lo ṣe di ẹni tó máa ń fẹ́ ṣe nǹkan láìkù síbì kan? Àwọn ògbógi kan sọ pé ìgbà ọmọdé ni ìwà yìí ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí ló máa ń sún ẹnì kan sí híhu irú ìwà bẹ́ẹ̀: Kí ìdílé ẹni máa fínná mọ́ni láti gbégbá orókè lọ́nàkọnà, kéèyàn máa kóra rẹ̀ sí àníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, kéèyàn máa fẹ́ fara wé àwọn tó ń bá rìn, kéèyàn máa tẹ̀ lé ohun táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń sọ nípa jíjẹ́ aláṣeyọrí tí kò lẹ́gbẹ́, àti kéèyàn máa fi àwọn tí kò ṣeé ṣe fún un láti fara wé ṣe ẹni àwòkọ́ṣe. Àwọn kókó wọ̀nyí ló ń jẹ́ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn ṣàníyàn ṣáá, tí wọ́n á máa dá ara wọn lẹ́bi ṣáá, tí wọ́n á sì máa fìgbà gbogbo ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó.”
Ohun yòówù kó fà á, ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe lè ṣàkóbá fún ìgbésí ayé rẹ. Jẹ́ ká túbọ̀ ṣàyẹ̀wò ìwà yìí àti ìdí tó fi lè ṣèpalára fún ọ.
Kí Ni Ìtumọ̀ Kéèyàn Máà Fẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan?
Ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan kì í kàn ṣe kéèyàn máa sapá láti ṣiṣẹ́ lọ́nà tó dára gan-an tàbí kéèyàn láyọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ ẹni. Ó ṣe tán, ní Òwe 22:29, Bíbélì gbóríyìn fún ọkùnrin tó “jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀.” Bíbélì tún kan sáárá sí àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú àwọn iṣẹ́ ọnà kan. (1 Sámúẹ́lì 16:18; 1 Àwọn Ọba 7:13, 14) Nítorí náà, ó dára kéèyàn sapá láti ṣiṣẹ́ dójú àmì, kéèyàn sì gbé àwọn góńgó tó dára kalẹ̀, àmọ́ kó jẹ́ èyí tó ṣeé lé bá. Nípa bẹ́ẹ̀, èèyàn á lè “jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”—Oníwàásù 2:24.
Àmọ́, ẹni tí kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan kì í ní irú ìtẹ́lọ́rùn bẹ́ẹ̀. Èrò tó ní nípa ṣíṣe nǹkan ní àṣeyọrí kò dára rárá. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ògbógi kan sọ, àwọn tí kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan “kì í lé góńgó wọn bá (ìyẹn ni ṣíṣe nǹkan láìsí àṣìṣe èyíkéyìí), wọn kì í sì í ní ìtẹ́lọ́rùn kankan, láìka bí ohun tí wọ́n ṣe ṣe lè dára tó.” Látàrí èyí, ńṣe ni àwọn tí kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan “máa ń ní ìbànújẹ́ ọkàn ṣáá, tí wọ́n á máa ronú pé àwọn ò lè ṣàṣeyọrí láé.” Ìdí nìyẹn tí ìwé kan fi túmọ̀ irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí “níní èrò tí kò bọ́gbọ́n mu pé ìwọ àti gbogbo ẹni tó bá wà láyìíká rẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe èyíkéyìí.” Ó jẹ́ “èrò kan tó máa ń gbani lọ́kàn ṣáá, pé ohunkóhun téèyàn bá dáwọ́ lé ní ìgbésí ayé kò gbọ́dọ̀ ní àṣìṣe, àléébù, tàbí ìkùdíẹ̀-káàtó èyíkéyìí.”
Àmọ́, ǹjẹ́ Jésù ò ti irú ìwà yìí lẹ́yìn nígbà tó sọ pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé”? (Mátíù 5:48) Rárá o, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Kí wá lohun tí Jésù ní lọ́kàn? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “pípé” túmọ̀ sí pípé pérépéré. (Mátíù 19:21) Nígbà tí Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ pípé, ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ló ń jíròrò, ó sì ń rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti túbọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ wọn pé pérépéré. Lọ́nà wo? Nípa mímú kí ìfẹ́ wọn gbòòrò sí i, kódà sí àwọn ọ̀tá wọn pàápàá. Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Lúùkù, ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.”—Lúùkù 6:36.
Àmọ́ o, èrò òdì làwọn tí kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan máa ń ní pé, ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti ṣe nǹkan láìsí àṣìṣe kankan rárá. Nípa báyìí, wọ́n lè máa retí pé kí àwọn ẹlòmíràn ṣe ju agbára wọn lọ. Ìwé náà, Never Good Enough—Freeing Yourself From the Chains of Perfectionism sọ pé, àwọn ẹlẹ́mìí ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan ni “àwọn èèyàn tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ń ṣe iṣẹ́ wọn . . . Lójú wọn, àwọn èèyàn tó wà nítòsí wọn kì í fọwọ́ dan-indan-in mú iṣẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi iṣẹ́ wọn yangàn.”
Bí àpẹẹrẹ, akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé gan-an ni Carly, èyí ló jẹ́ kí wọ́n gbà á sí ilé ẹ̀kọ́ kan tó wà fún àwọn tó mọ̀wé gan-an. Àmọ́ o, ìṣòro rẹ̀ ni pé kò lè bá àwọn ẹlòmíràn gbé ní ìrẹ́pọ̀. Nítorí pé kì í fẹ́ láti rí àléébù kankan, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti fi í sílẹ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń wò ó pé wọn ò kúnjú ìwọ̀n rárá.”
Àwọn mìíràn sì máa ń lépa ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe èyíkéyìí, kì í ṣe látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, bí kò ṣe látọ̀dọ̀ ara àwọn fúnra wọn. Ìwé Never Good Enough ṣàlàyé pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń rò pé “àwọn fúnra wọn tàbí ohun tí wọ́n ń ṣe kò dára tó . . . , bákan náà, [wọ́n] tún máa ń ṣàníyàn gan-an nípa ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń rò nípa wọn.”
Ìṣòro Tó Wà Nínú Ṣíṣàì Fẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan
Nítorí náà, dípò tí ẹ̀mí ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan ì bá fi jẹ́ ohun dáradára tó lè ṣeni láǹfààní, ńṣe ló máa ń ṣàkóbá fúnni, ó sì lè pani lára. Yàtọ̀ síyẹn, dípò kó jẹ́ kéèyàn máa ṣiṣẹ́ lọ́nà tó dára gan-an, ńṣe ni irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ kéèyàn kùnà. Kristẹni kan tó ń jẹ́ Daniel sọ pé òún ṣiṣẹ́ àṣekára fún ọ̀pọ̀ wákàtí Òwe 19:20) Ṣùgbọ́n, èyí tí Daniel ì bá fi tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tó lè jẹ́ kó ṣe dáadáa sí i, ńṣe ló kà á sí pé òun ò mọ̀ ọ́n ṣe rárá. Ó sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé kí ilẹ̀ lanu kó gbé mi mì.” Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni kò fi lè sùn lóru.
láti múra sílẹ̀ fún ọ̀rọ̀ tí wọ́n yàn fún òun láti sọ nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tó máa ń wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti àdúgbò rẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ náà ló gbóríyìn fún un pé ó ṣe dáradára gan-an. Lẹ́yìn náà, ẹni tó ń fúnni nítọ̀ọ́ni wá rọra fún un ní àwọn àbá kan tó lè mú kó tẹ̀ síwájú. Bíbélì rọ̀ wá láti “fetí sí ìmọ̀ràn kí [a] sì gba ìbáwí.” (Nítorí náà, ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan lè ṣèdíwọ́ fún ẹ̀kọ́ kíkọ́. Nínú àpilẹ̀kọ kan tó fara hàn ní ibi téèyàn ti lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ọ̀dọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga, mo pinnu láti sapá gidigidi. Ipò kìíní ni mo sábà máa ń gbé nínú gbogbo iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, mi ò sì rí ìdí tí máàkì mi fi ní láti lọ sílẹ̀.” Àmọ́, kò pẹ́ tí Rachel fi rí i pé òún ní ìṣòro pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìṣirò nígbà tó gbé ipò kejì nínú iṣẹ́ náà, tó sì kà á sí pé ó ti “rẹlẹ̀ jù” sí máàkì tó yẹ kí òun gbà. Rachel sọ pé: “Lójú gbogbo èèyàn, kò sóhun tó burú nínú ipò kejì tí mo gbé yìí, àmọ́ ní tèmi . . . nǹkan ìtìjú gbáà ló jẹ́. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí dààmú nípa rẹ̀ ṣáá . . . Ẹ̀rù ń bà mí láti sọ fún olùkọ́ wa pé kó la iṣẹ́ náà yé mi, torí mò ń ronú pé bí mo bá sọ fún un pé kó ràn mí lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ àṣetiléwá mi, ńṣe ló máa túmọ̀ sí pé kò yé mi. . . . Nígbà míì, mo máa ń rò ó pé ó sàn kí n kú ju kí n máa fìdí rẹmi lọ.”
Àní, àwọn ọ̀dọ́ kan ti gbèrò láti pa ara wọn torí pé wọn kò fẹ́ láti fìdí rẹmi. Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kì í ronú láti gbé irú ìgbésẹ̀ bíburú jáì bẹ́ẹ̀. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí tí Sylvia Rimm, tó jẹ́ ògbógi nípa ìlera ọpọlọ ṣe, wọ́n lè torí ìbẹ̀rù kí wọ́n má bàa fìdí rẹmi kí wọ́n máà kúkú ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn rárá. Ọ̀gbẹ́ni Rimm sọ pé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe “kì í mú iṣẹ́ àṣetiléwá wọn fún olùkọ́, iṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe kì í tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n máa ń gbàgbé láti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn, wọ́n sì máa ń ṣe àwáwí.”
Àmọ́ ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tún wà tí wọ́n lè máa ṣe àṣejù nípa mímú un dá ara wọn lójú pé àwọn ní láti ṣàṣeyọrí lọ́nàkọnà. Daniel sọ pé: “Mo máa ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọ ọ̀gànjọ́ òru kí n ṣáà lè rí i pé mi ò ṣe àṣìṣe kankan.” Ìṣòro ibẹ̀ ni pé, títi àṣejù bọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn kì í ṣeni láǹfààní lọ́pọ̀ ìgbà. Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń sùn ní kíláàsì kò ní lè dojú kọ iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe yẹ.
Abájọ nígbà náà, tí àwọn ògbógi fi sọ pé ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan máa ń fa onírúurú ìṣòro, irú bí bíbínú rangbandan, ríronú pé èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan, dídá ara ẹni lẹ́bi, ríronú pé èèyàn ò lè ṣe nǹkan láṣeyọrí, ìṣòro àìjẹun bó ṣe yẹ, àti ìdààmú ọkàn. Àmọ́ o, èyí tó tiẹ̀ wá burú jù lọ ni pé, ó lè ṣèpalára fúnni nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì pa á láṣẹ fún àwọn Kristẹni láti máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. (Róòmù 10:10; Hébérù 10:24, 25) Àmọ́, ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Vivian kì í fẹ́ láti sọ̀rọ̀ ní ìpàdé Kristẹni torí pé ó ń bẹ̀rù pé òún lè máà sọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kó rí gan-an. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Leah náà máa ń bẹ̀rù bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Bí ìdáhùn mi kò bá tọ̀nà, ńṣe làwọn ẹlòmíràn á máa fi ojú aláìmọ̀kan wò mí. Nítorí náà, ńṣe ni mo máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ láìsọ̀rọ̀.”
Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan jẹ́ ohun tó lè pani lára, tí kò sì lè ṣeni láǹfààní rárá. Nítorí náà, bó o bá ní ọ̀kan lára àwọn àṣà tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí, o lè rí i pé ó yẹ kó o yí èrò rẹ padà. Àpilẹ̀kọ kan tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú yóò jíròrò bó o ṣe lè ṣe èyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, nǹkan bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan ló jẹ́ ẹlẹ́mìí ṣe-é-kó-má-kù-síbì-kan.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bíbẹ̀rù pé àwọ́n lè ṣe àṣìṣe ni kì í jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ kan parí iṣẹ́ àṣetiléwá wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ṣíṣàì fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan máa ń fa ìdààmú ọkàn, ó sì máa ń mú kéèyàn ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan