Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹni Ọ̀wọ́n Kan
Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹni Ọ̀wọ́n Kan
Òǹkàwé kan láti ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ńṣe ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà dà bíi lẹ́tà kan tí ẹni ọ̀wọ́n kan kọ síni, ó ṣàlàyé pé: “Àkòrí kọ̀ọ̀kan ń runi lọ́kàn sókè gan-an ni, ó sì ń jẹ́ kí ìfẹ́ téèyàn ní fún Jèhófà pọ̀ sí i.” Ó fi kún un pé: “Ní báyìí tí mo ti ka gbogbo ìwé náà tán, mo tún ti ń hára gàgà láti tún kà á lẹ́ẹ̀kan sí i, gẹ́gẹ́ béèyàn ṣe máa ń ka lẹ́tà tí ẹni ọ̀wọ́n kan bá kọ síni ní àkàtúnkà.” Kíyè sí ohun tí àwọn mìíràn sọ nípa ìwé náà.
Òǹkàwé kan ní ìpínlẹ̀ Kansas sọ pé: “Mo nímọ̀lára pé mo túbọ̀ ń sún mọ́ Baba mi ọ̀run sí i. Ńṣe ni ìfẹ́ fún Jèhófà túbọ̀ ń kún inú ọkàn mi ṣáá . . . Mo máa ń wọ̀nà láti ka púpọ̀ sí i láràárọ̀, màá sì rí i pé mo ka ìwé náà ní àkàtúnkà.”
Obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ Maine kọ̀wé pé: “Ó ti jẹ́ kí n túbọ̀ lóye irú ẹni tí Jèhófà jẹ́! Gbólóhùn tó wà lójú ìwé 74 mà ń tuni lára o, èyí tó sọ pé: ‘Ní ti àwọn tó bá kú, kò tún sí abẹ́ ààbò téèyàn lè wà tó ju pé kí Ọlọ́run fini sí ìrántí rẹ̀.’” Òǹkọ̀wé kan ní ìpínlẹ̀ Alaska náà gbà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an débi pé ńṣe ni mò ń sunkún ṣáá.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó dájú pé, àkàtúnkà ni màá máa kà á, màá sì máa lo ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ látìgbàdégbà.”
A gbà pé bọ́rọ̀ á ṣe rí lára ìwọ náà nìyí bó o bá ka ìwé yìí. Lẹ́yìn àwọn àkòrí mẹ́ta tó ṣáájú, a pín ìwé náà sí ìsọ̀rí mẹ́rin, ìyẹn ni: “Ó ‘Ní Agbára Ńlá’,” “Olùfẹ́ Ìdájọ́ Òdodo,” “Ọlọ́gbọ́n ní Ọkàn-Àyà,” àti “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́.” Àkòrí tó gbẹ̀yìn nínú ìwé náà ni, “Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò sì Sún Mọ́ Yín.”
Bó o bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 320 yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.