Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Ń Ṣe Àwọn Aráàlú Láǹfààní

Wọ́n Ń Ṣe Àwọn Aráàlú Láǹfààní

Wọ́n Ń Ṣe Àwọn Aráàlú Láǹfààní

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ

LÁTI ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn làwọn aláṣẹ ìlú ní ilẹ̀ Sípéènì ti máa ń fún àwọn aráàlú ní ilẹ̀ láti fi kọ́ àwọn ibi ìjọsìn. Àwọn ìjọba ìlú nígbàgbọ́ pé ìsìn yóò ṣe àwọn èèyàn wọn láǹfààní. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀sìn Kátólíìkì ni ẹ̀sìn orílẹ̀-èdè náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nìkan ni wọ́n máa ń fún ní àwọn ilẹ̀ tó jẹ́ ti ìlú látọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn. Àmọ́, ìyẹn ti di ọ̀rọ̀ àtijọ́ báyìí o.

Lọ́dún 1980, òfin ilẹ̀ Sípéènì kan tó fàyè gba òmìnira ìsìn sọ pé “kò sí ẹ̀sìn kan tó máa jẹ́ ẹ̀sìn orílẹ̀-èdè.” Èyí ti wá mú kí àwọn aláṣẹ ìlú kan sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti fi ẹ̀rí èyí hàn, wọ́n ti fún wa ní ilẹ̀ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Àwọn aláṣẹ ní oríṣiríṣi ẹ̀ka ìjọba ìlú ti sọ èrò wọn jáde nípa èyí. Wọ́n sọ pé fífún tí wọ́n ń fún àwa Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ jẹ́ ohun tó tọ́ sí wa gan-an nítorí “iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí [àwa Ẹlẹ́rìí] ń ṣe,” àti láfikún sí i, nítorí “àwọn àǹfààní tí irú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú bá àwọn aráàlú.” Àwọn aláṣẹ ìjọba mìíràn náà tún sọ nípa “bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ṣe pàtàkì tó fún ìlú” àti “bí a kò ṣe ń ṣe iṣẹ́ wa nítorí owó.”

Ọ̀pọ̀ lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ló jẹ́ pé ọjọ́ méjì péré ni àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tí wọ́n jẹ́ kọ́lékọ́lé fi kọ́ wọn, nípa lílo ọ̀nà ìkọ́lé kan tó jẹ́ àkànṣe. Olórí ìlú La Línea, níhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sípéènì, sọ pé: “Ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni náà wú mi lórí gan-an, mo sì lérò pé ó yẹ ká ṣètìlẹ́yìn fún wọn. A nílò irú ẹ̀mí yìí gan-an nínú ayé tó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí.” Ohun tó pe Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà ni “ọwọ̀n tó dúró fún ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀.”

Àwọn ará àdúgbò pàápàá kíyè sí ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan wọn yìí. Nígbà tí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba alákọ̀ọ́pọ̀ kan ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Vitoria, níhà àríwá ilẹ̀ Sípéènì, ohun tí Marian tó ń gbé nítòsí ibẹ̀ sọ nìyí: “Bí gbogbo èèyàn bá lè máa fi irú ìfẹ́ yìí hàn ni, kò ní sí àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra lónìí.” Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan tó jẹ́ ayàwòrán ilé ládùúgbò náà rí bí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó sọ pé: “Màá fẹ́ láti di ọ̀kan lára ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí n lè ní irú ayọ̀ tí ẹ̀ ń ní!”

Ní ìlú Zaragoza, níhà àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Sípéènì, àwọn aláṣẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ kan tó fẹ̀ ní ẹgbẹ̀ta mítà níìbú àti lóòró láìgba kọ́bọ̀. Nígbà tí ìwé ìròyìn kan ní àdúgbò náà ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ti wáyé, ó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà dà bí “ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèrà tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan.” Tọ̀yàyàtọ̀yàyà làwọn ará àdúgbò fi tẹ́wọ́ gba àwọn òṣìṣẹ́ náà. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Àwọn àlùfáà ti mú kí n pàdánù ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run, àmọ́ ẹ ti jẹ́ kí n rí i padà.”

Àwa Ẹlẹ́rìí mọrírì ìrànwọ́ tí àwọn ará àdúgbò àtàwọn aláṣẹ pèsè gan-an nínú kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn wa. A pinnu láti máa lo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa náà fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó máa ṣe aráàlú láǹfààní jù lọ, ìyẹn ni wíwàásù àti kíkọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

La Línea, Cadiz, Sípéènì