Ohun Tó Mú Kí Ìgbésí Ayé Mi Nítumọ̀
Ohun Tó Mú Kí Ìgbésí Ayé Mi Nítumọ̀
GẸ́GẸ́ BÍ ERNEST PANDACHUK ṢE SỌ Ọ́
Ilẹ̀ ọ̀dàn ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Saskatchewan, lórílẹ̀-èdè Kánádà ni wọ́n bí mi sí. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, mo lọ sí Áfíríkà, níbi tí mo ti gbé ìgbésí ayé alárinrin gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì fún ọdún márùndínlógójì tó tẹ̀ lé e. Báwo ni mo ṣe wá dẹni tó gbé irú ìgbésí ayé yìí? Kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀. Ẹ gbọ́ làbárè.
ÒPÓ igi, koríko àti amọ̀ ni wọ́n fi kọ́ ilé tí wọ́n bí mi sí. Agbára káká ni ilé náà fi lè dáàbò bo ìdílé wa kúrò lọ́wọ́ otútù nini tó máa ń mú ní ilẹ̀ ọ̀dàn náà. Ní ọdún 1928, kí àwọn òbí wa tó bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwa ọmọ wọn mẹ́sàn-án ni wọ́n ti gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ àlejò kan tó wá sí ilé wa. Nígbà òtútù tó tẹ̀ lé e, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látinú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tó fi máa di àkókò ìrúwé, ó ti dá wọn lójú gbangba pé wọ́n ti rí òtítọ́. Wọ́n sọ nípa òtítọ́ náà fún ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn, àwọn aládùúgbò wọn àti ní pàtàkì jù lọ, àwa ọmọ wọ́n.
Wọ́n bí mi ní ọdún 1931, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi bí àwọn àbúrò mi márùn-ún lé mi. Kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ètò tí ìdílé wa máa ń ṣe déédéé. Inú mi máa ń dùn gan-an bí mo bá rántí àwọn òwúrọ̀ tí a fi máa ń wà pa pọ̀ yẹn. Bàbá ló máa ń múpò iwájú nínú jíjíròrò ẹsẹ Bíbélì kan pẹ̀lú wa, kódà nígbà tá a bá ní àlejò pàápàá. Màmá àti Bàbá àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi, máa ń pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣàlàyé Bíbélì kà láàárín ara wọn. Wọ́n á sì kà á sókè ketekete.
Yàtọ̀ sí kíkọ́ wa ní ìwé kíkà àti ìwé kíkọ, Bàbá tún kọ́ wa bá a ṣe lè ṣèwádìí nípa lílo àwọn atọ́ka Bíbélì. Kò sì pẹ́ tá a fi mọ bá a ṣe lè lo Bíbélì láti ṣàlàyé àwọn ohun tí a gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ìjíròrò alárinrin wọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ láti mọ bí a ti í fèròwérò bí a bá ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tó ṣe, mo wá mọ bí mo ṣe lè lo Bíbélì láti já irọ́ tó wà nídìí àwọn ẹ̀kọ́ èké. Mo lè fi ẹ̀rí Bíbélì tì í lẹ́yìn pé ọkàn máa ń kú, pé kò sí iná ọ̀run àpáàdì àti pé Ọlọ́run àti Jésù kò dọ́gba wọ́n kì í sì í ṣe apá kan Mẹ́talọ́kan.—Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Jòhánù 14:28.
A tún rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àpẹẹrẹ tí Màmá àti Bàbá fi lélẹ̀, wọ́n sì tún fún wa níṣìírí láti máa mú ìdúró wa fún ohun tí ó tọ́, kódà bí àwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ ní gba tiwa. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í lo tábà, wọ́n sì kìlọ̀ fún wa nípa bó ṣe lè sọni di ẹlẹ́gbin àti bí àwọn tí a jọ ń lọ síléèwé á ṣe máa rọ̀ wá láìdábọ̀
pé ká lò ó. Mo rántí ọ̀rọ̀ tí bàbá mi máa ń sọ pé: “Bó o bá kọ̀ láti mu sìgá, wọ́n lè máa bú ọ pé sùẹ̀gbẹ̀ ni ọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ bi onítọ̀hún pé, ‘Ta ni ká pè ní akọni? Ṣe ẹni tí tábà ń darí ẹ̀ ni àbí ẹni tó ń darí tábà?’”Ohun mìíràn tó tún dán ìgbàgbọ́ mi wò bóyá màá hùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọdé ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá. Nígbà tí mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Ogun Àgbáyé Kejì ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì retí pé kí gbogbo àwọn ọmọdé tó wà nílé ìwé jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfọkànsìn fún àsíá orílẹ̀-èdè. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ látinú Bíbélì jẹ́ kó yé mi pé irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìjọsìn, nítorí náà mo kọ̀ láti jẹ́jẹ̀ẹ́. Bí wọ́n ṣe lé mi kúrò nílé ìwé fún odindi oṣù mẹ́fà nìyẹn.
Àmọ́ ṣá o, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn mo jáde ilé ẹ̀kọ́, nígbà tó sì di March 1947, mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà Ọlọ́run. Ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, mo di aṣáájú-ọ̀nà, olùpòkìkí ìhìn rere náà alákòókò kíkún. Mo kọ́kọ́ sìn ní ìhà gúúsù Saskatchewan, mò ń jẹ́rìí fún àwọn àgbẹ̀ àtàwọn ẹlẹ́ran ọ̀sìn ní ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ gbígbòòrò náà. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ẹṣin ni mo máa ń gùn láti rìnrìn àjò, bó bá sì dìgbà òtútù nini, mo máa ń lo ọkọ̀ àfẹṣinfà tó nílé lórí, èyí tí à ń pè ní caboose. Àdògán tó ń lo èédú ni à ń lò láti mú inú rẹ̀ móoru, nítorí náà mo máa ń ṣọ́ra gan-an kí ọkọ̀ àfẹṣinfà náà má bàa yẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kí àdògán náà sì yí dà nù.
Ọlọ́yàyà làwọn èèyàn tó wà ní ìgbèríko náà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àlejò ṣíṣe. Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ wọn ní ọjọ́rọ̀, wọ́n sábà máa ń rọ̀ mí láti sùn mọ́jú. Mo máa ń gbádùn àwọn ìjíròrò Bíbélì tí ń tani jí tó máa ń wáyé ní irú àkókò bẹ́ẹ̀ gan-an ni! Ìdílé kan tó rí òtítọ́ lẹ́yìn irú ìjíròrò àṣemọ́jú bẹ́ẹ̀ ni ìdílé Peterson. Earl àti ìyá rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí onítara fún Jèhófà.
Sísìn ní Quebec
Ní ọdún 1949, nígbà tí wọ́n ké sí àwọn aṣáájú ọ̀nà láti wá ṣèrànwọ́ nípa wíwàásù láwọn àgbègbè kan ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec, ní orílẹ̀-èdè Kánádà, èmi náà ò gbẹ́yìn. Àwọn aṣáájú ọ̀nà bí igba [200] láti ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Kánádà ló múra àtilọ. Wọ́n gúnlẹ̀ sí ìlú Montreal tó wà ní ìhà gúúsù Quebec ní oṣù September, wọ́n sì múra tán láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ lápá ibikíbi ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec. Lákòókò yìí gan-an ni olórí ìjọba náà, Maurice Duplessis, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti rẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí ní gbogbo ẹkùn ìpínlẹ̀ náà wà lórí àlééfà.
Àkókò amóríyá tí ọwọ́ wa dí fún iṣẹ́ tá a sì ń dojú kọ ìpèníjà ni àwọn àkókò wọ̀nyẹn jẹ́. Lára àwọn ìpèníjà tí a dojú kọ ni kíkọ́ èdè Faransé, ìfàṣẹ ọba múni àti dídà tí àwọn jàǹdùkú ń da àpéjọ Kristẹni wa rú. Àmọ́ ṣá o, irú ìwà àìfẹ́-rímí-ẹni-láàtàn bẹ́ẹ̀ yẹn ò tu irun kankan lára mi o, kò sì mú kí n ṣiyè méjì nípa iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn òbí mi ti gbin ìfẹ́ fún ohun tó tọ́ sí mi lọ́kàn, wọ́n sì ti jẹ́ kó dá mi lójú pé iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí láìka àtakò sí.—Mátíù 24:9, 14.
Ní àkókò tí mo fi wà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec, mo bá Emily Hawrysh pàdé, aṣáájú ọ̀nà kan tí kò kẹ̀rẹ̀ ni, ó wá láti ẹkùn ìpínlẹ̀ Saskatchewan. Látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó ní January 27, 1951 ni Emily ti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ tó ṣeé gbára lé àti alábàákẹ́gbẹ́
tó ń fún mi ní ìṣírí. Nítorí pé góńgó wa ni láti kópa ní kíkún sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a kọ̀wé béèrè fún àǹfààní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, èyí tó ń pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mélòó kan fún àwọn òjíṣẹ́ kí wọ́n bàa lè tóótun fún iṣẹ́ ìsìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, wọ́n sì ké sí wa. A kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì ogún ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ní February 1953.Kó tó di pé a rí ìwé àṣẹ láti wọ Áfíríkà gbà, a ké sí wa láti máa ran ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Alberta àti Ontario, ní orílẹ̀-èdè Kánádà lọ́wọ́. Láyé ìgbà yẹn, ọkọ̀ là ń wọ̀ láti ìjọ kan dé òmíràn. Nítorí náà, a kọ́ láti ní ẹrù níwọ̀nba, inú àpótí ẹrù kan la sì ń di àwọn nǹkan tá a bá nílò sí. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, nígbà tí wọ́n rí ìwé ìrìnnà àti ìwé àṣẹ ìwọ̀lú wa gbà, a mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí ìhà Gúúsù Rhodesia, tí wọ́n ń pè ní Zimbabwe báyìí.
Mímú Ara Wa Bá Ìgbésí Ayé ní Áfíríkà Mu
Láàárín oṣù márùn-ún àkọ́kọ́ tí a lò ní Áfíríkà, wọ́n yàn wá láti máa bẹ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò ní Zimbabwe àti Botswana títí tó fi dé àwọn apá ìhà gúúsù Àríwá Rhodesia (tí à ń pè ní Zambia báyìí). Wọ́n ti gbà wá níyànjú ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì pé ká má ṣe fi ibi tí wọ́n yàn wá sí ní ilẹ̀ òkèèrè wé ìlú ìbílẹ̀ tiwa, ká sì máa rántí pé inú ipò yòówù ká bá ara wa, a lè rí ohun kan kọ́ látinú àwọn ìrírí wa. Irú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ló ń tọ́ èrò wa sọ́nà. Títí dòní olónìí, àṣàyàn ọ̀rọ̀ kan tí èmi àti Emily ò jẹ́ gbàgbé ni pé, “Má ṣe jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí tó o bá ní lọ lófo; o lè ṣaláì rí irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ mọ́ láé.”
Bá a bá ń rìnrìn àjò láti ibì kan lọ sí ibòmíràn a máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin, bọ́ọ̀sì tàbí ọkọ̀ akẹ́rù. A sì tún máa ń gun kẹ̀kẹ́ tàbí ohunkóhun tó bá ṣáà ti lè gbé wa débi táà ń lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìrìn-àjò náà ò rọrùn, àwọn ipò mìíràn tún wà tó ń dán ìpinnu wa láti ‘má ṣe jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí tá a bá ní lọ lófo’ wò. Lọ́dún méjì àkọ́kọ́, òfin kò gba Emily láyè láti ba mi lọ sí àgbègbè ibi táwọn ọmọ onílẹ̀ ń gbé. Nítorí èyí, ìyàwó tí mo gbé lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn máa ń dúró dè mí láwọn ìlú tó wà nítòsí ibi tí ojú irin parí sí, níbi tó jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà kì í sí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn. Kì í ṣe pé ìgbàgbọ́, ìgboyà àti ìdúróṣinṣin Emily jọ mi lójú tó sì tún mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìkan ni o, àmọ́ ó tún mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà sèso rere ní àwọn àdúgbò tó ti ń wàásù.
Ní gbàrà tí Emily bá ti rí ibi tó lè wọ̀ sí lọ́dọ̀ ọ̀kan lára àwọn aráàlú náà, ó máa ń wàásù nítòsí ibẹ̀ títí tí màá fi dé láti àgbègbè ibi táwọn ọmọ onílẹ̀ wà. Nígbà míì, ó máa ń dá ṣiṣẹ́ fún odindi oṣù kan gbáko. Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú ọwọ́ agbára ńlá Jèhófà ló fún un ní okun àti ààbò, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sì sèso rere. Àpẹẹrẹ kan ni ti Rita Hancock tó wá sínú òtítọ́ tí ọkọ rẹ̀ náà sì dara pọ̀ mọ́ ọn. Ó di olùṣòtítọ́ ó sì sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà títí tó fi kú. Lónìí, àwọn ìjọ tó ń gbèrú ti wà ní díẹ̀ lára àwọn ìlú tí Emily ti fúnrúgbìn òtítọ́ Bíbélì.
Ìfẹ́ Àlejò àti Ìdánúṣe Àwọn Ará Áfíríkà
Ní gbogbo àkókò tí mo fi ṣiṣẹ́ ní àgbègbè ibi tí àwọn ọmọ onílẹ̀ ń gbé, àgbàyanu ìṣírí gbáà ni ìmọrírì jíjinlẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí ará Áfíríkà ní fún ètò àjọ Jèhófà àti àwọn aṣojú arìnrìn-àjò rẹ̀ jẹ́ fún mi. Àwọn Kristẹni arákùnrin tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ yìí bójú tó mi dáadáa. Lọ́jọọjọ́ọ Monday ni mo máa ń gbéra láti ibi àpéjọ kan lọ sí ibi àpéjọ mìíràn. Inú ahéré tí wọ́n fi ewéko kọ́ ni wọn máa ń fi mi wọ̀ sí, ìyẹn sì máa ń rán mi létí ilé wa ní Saskatchewan. Ìdì koríko tí kò ga púpọ̀, tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀ẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì da aṣọ bò ni ibùsùn mi.
Inú igbó, lágbègbè ibi táwọn ọmọ onílẹ̀ ń gbé, la ti ń ṣe àpéjọ. Àwọn tó bá wá sí àpéjọ náà ni wọ́n máa ń ṣán igbó tó wà láyìíká, wọ́n á sì fi àwọn igi tó léwé lórí dáadáa sílẹ̀ fún ìbòòji. Ìdì koríko tí wọ́n dì pinpin, tí wọ́n sì tò nigín-nigín, ni wọ́n fi ṣe ìjókòó. Lẹ́yìn èyí, wọ́n wá fi koríko ṣe ọgbà yí ibi tí wọ́n ro náà ká. Láàárín igbó yìí, ohùn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Áfíríkà tó máa ń dùn yéye máa ń wọ̀ mí ní akínyẹmí ara nígbà tí wọ́n bá ń kọrin ìyìn sí Jèhófà tí gbogbo rẹ̀ sì ń bára mu wẹ́kú. Èyí jẹ́ ohun kan tí kò rọrùn láti gbàgbé.
Ìrírí Mánigbàgbé
Mo pàdé Gideon Zenda, ọ̀gá olùbẹ̀wò tó ń bẹ àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà wò, lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Ṣọ́ọ̀ṣì yìí ni igi lẹ́yìn ọgbà fún ẹ̀kọ́ ìwé tí Gideon gbà, àwọn náà ló sì rán an lọ sí yunifásítì. Àmọ́ ṣá o, kò tíì rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn gbà sí àwọn ìbéèrè Bíbélì tó ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀. Nítorí náà, ó ní kí ń wá bá òun àtàwọn
kan lára àwọn ẹlẹgbẹ́ òun sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè náà. Nǹkan bí àádọ́ta èèyàn ló pésẹ̀ síbi ìjíròrò náà, tó fi mọ́ àwọn olùbẹ̀wò ilé ẹ̀kọ́, àwọn ọ̀gá ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àtàwọn olùkọ́. Gideon ló ṣalága ìpàdé náà. Lẹ́sọ̀lẹsọ̀ la rọra ń lọ látorí kókó kan dé èkejì. Nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo fi sọ̀rọ̀ lórí kókó kọ̀ọ̀kan tí mo sì dáhùn àwọn ìbéèrè wọn lẹ́yìn náà. Ìjíròrò náà gba wákàtí bíi mélòó kan.Àbájáde ìpàdé tí irú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n yìí ni pé Gideon, ìdílé rẹ̀ àti púpọ̀ lára àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Èyí ló mú kí bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Áńgílíkà fòpin sí iṣẹ́ wọn lábẹ́ ètò ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì. Síbẹ̀, wọn ò fòyà, gbogbo wọn ló sì dúró ṣinṣin nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kódà àwọn kan lára wọn tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.
Àwọn Èèyàn Ń Rọ́ Wá Wo Sinimá Kan Tó Pabanbarì
Ní ọdún 1954, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé sinimá náà, The New World Society in Action jáde. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n mú ìkálọ́wọ́kò tí kò gba ìyàwó láyè láti bá ọkọ lọ sí àgbègbè ibi táwọn ọmọ onílẹ̀ ń gbé kúrò. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún Emily láti máa tẹ̀lé mi lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní àgbègbè ibi táwọn ọmọ onílẹ̀ ń gbé. Lákòókò yẹn, wọ́n ti gbé ọkọ̀, ẹ̀rọ amúnáwá àti ẹ̀rọ agbáwòrányọ fún wa láti máa fi sinimá náà hàn jákèjádò àgbègbè ibi táwọn ọmọ onílẹ̀ ń gbé. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà ò tíì rí sinimá rí, nítorí náà yíya ni wọ́n ń ya wá wò ó. Sinimá náà jẹ́ káwọn èèyàn rí bí wọ́n ṣe ń ṣe Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé ní ilé ìtẹ̀wé wa títóbi tó wà ní Brooklyn, New York.
Nínú sinimá náà èèyàn lè rí ẹgbẹ́ ará ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé tí wọ́n jùmọ̀ ń jọ́sìn ní Pápá Ìṣeré Yankee, ní ìlú New York, lọ́dún 1953. Àwọn ará Áfíríkà wọ̀nyí ò tíì rí i kí àwọn tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn síra wọn lọ́nà yẹn rí. Sinimá yìí sún ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé tó jẹ́ ará Zimbabwe láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tún sún wọ́n láti máa dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí. Jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni ìwé ẹ-wá-fi-sinimá-hàn-wá ti ń rọ́ wọlé látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀gá ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n mọyì ẹ̀kọ́ gbígbámúṣé tí irú àwòrán bẹ́ẹ̀ lè kọ́ àwọn ọmọléèwé wọn.
Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan báyìí, àwọn ará gan-an ni wọ́n wá jí mi lójú oorun pé ó yá kí n wá fi sinimá náà hàn. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo wá mọ̀ pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn ló ti rìnrìn àjò wákàtí bíi mélòó kan láti wá wò ó. Wọ́n gbọ́ pé mò ń fi han àwọn kan lágbègbè náà. Nígbà táwọn èrò náà fi máa tú ká, àwọn ọ̀ọ́dúnrún [300] èèyàn míì tún ti dé. Bí mo ṣe fi sinimá náà hàn lẹ́ẹ̀kan sí i nìyẹn o. Agogo mẹ́ta òru làwọn tó wo sinimá náà gbẹ̀yìn sì tó lọ! Ní orílẹ̀-èdè Zambia nìkan, ó ju mílíọ̀nù kan èèyàn lọ tó wo sinimá àwòyanu yẹn láàárín ọdún mẹ́tàdínlógún!
Wọ́n Yanṣẹ́ Míì fún Wa ní Áfíríkà
Lẹ́yìn tí a ti sìn fún ohun tó lé ní ọdún márùn-ún àti ààbọ̀ ní Zimbabwe, wọ́n gbé wa lọ sí Gúúsù Áfíríkà. Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti kọ́ èdè Afrikaans. Nígbà tó yá a tún kọ́ èdè Sesotho àti Súlù. Mímọ báa ṣe lè fi àwọn èdè mìíràn kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká túbọ̀ já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ó sì ń mú ká láyọ̀ pé a ṣàṣeyọrí.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1960, wọ́n yàn wá sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní ìhà gúúsù Áfíríkà. Fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e, a rìnrìn àjò jákèjádò orílẹ̀-èdè Lesotho, Nàmíbíà, Gúúsù Áfíríkà àti Swaziland títí tó fi dé erékùṣù Ascension àti erékùṣù St. Helena tó wà ní Gúúsù Òkun Àtìláńtíìkì. Lápapọ̀, a rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà, bí a ti ń ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Ọ̀nà tí wọ́n gbà fi ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣiṣin wọn hàn lábẹ́ àwọn ipò tí kò bára dé ti fún wa níṣìírí gidigidi láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé.
Bí àpẹẹrẹ, mo fojú ara mi rí àwọn Ẹlẹ́rìí ará Swaziland tí wọn ò fi ìgbàgbọ́ wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́ nígbà tí Ọba Sobhuza Kejì kú. Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti kópa nínú ààtò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tó máa ń wáyé nígbà tí irú èèyàn pàtàkì bẹ́ẹ̀ bá kú, wọ́n lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n sì fi ẹ̀tọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ onílẹ̀ dù wọ́n. Láìka ọ̀pọ̀ ọdún ìfẹ̀tọ́duni àti ìnira sí, wọn ò juwọ́ sílẹ̀. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ gbáà ló jẹ́ pé a mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rere wọ̀nyí a sì bá wọn sọ̀rọ̀ lójúkoojú. Nígbà gbogbo
ni màá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní náà.A ò sì tún lè gbàgbé Philemon Mafereka, aṣáájú ọ̀nà kan tó wà ní abúlé Mokhotlong ní orílẹ̀-èdè Lesotho. Téńté orí òkè tó ga tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] mítà ni abúlé náà wà. Níwọ̀n bí kò ti sí mọ́tò, òun àti ìyàwó rẹ̀ ọ̀wọ́n, àwọn ọmọ wọn méjì àtàwọn mẹ́rin tí wọ́n fẹ́ ṣèrìbọmi rin ìrìn-àjò tó lé ní ọgọ́rùn-ún kìlómítà lọ sí àpéjọ kan tó wáyé lórí òkè tó ga tó ẹgbẹ̀fà [1,200] mítà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibì kan tí wọn ò ti gba gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òke kọjá. Bí wọ́n ṣe ń pọ́nkè ni wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ gba àwọn ibi pàlàpálá òkúta, wọ́n sì la ọ̀pọ̀ odò ńlá àti odò kékeré kọjá.
Nígbà tí wọ́n ń darí lọ sílé lẹ́yìn àpéjọ náà, wọ́n gbé ọgọ́rùn-ún ẹ̀dà ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye dání. Nítorí àwọn tó wà lábúlé ni Mokhotlong ni wọ́n ṣe kó àwọn ìwé náà dání. Àmọ́, nítorí pé wọ́n bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàdé lọ́nà, gbogbo ìwé náà ló tán kí wọ́n tó délé. Àǹfààní mánigbàgbé gbáà ló jẹ́ fún èmi àti Emily láti fojú ara wa rí ìtara àti ìfọkànsìn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa bíi Philemon àti ìyàwó rẹ̀.
Nígbà míì, a máa ń dojú kọ ewu àwọn ejò olóró bíi sèbé, a sì tún máa ń dojú kọ ewu àgbàrá òjò àtàwọn ìjàǹbá mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìrírí wọ̀nyí máa ń bani lẹ́rù nígbà yẹn, a kìí pẹ́ gbàgbé wọn nígbà tí a bá fi wọ́n wéra pẹ̀lú èrè àti ayọ̀ tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. A ti rí i kedere kèdèrè pé kò jẹ́ kọ àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀ láé.
Nígbà tí àìsàn ńlá kan kọ lu Emily, Jèhófà fún wa ní ọgbọ́n tí a fi lè kojú ipò náà lọ́nà tó tọ́. Yíyí oúnjẹ tó ń jẹ padà àti ètò ìmọ́tótó tó sunwọ̀n sí i ṣèrànwọ́ láti mú kí ara rẹ̀ tètè mókun. A ṣe ilé àgbérìn kan mọ́ ara ọkọ̀ akẹ́rù kékeré. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Emily láti wà ní àyíká kan tí kò gbóná jù tí kò sì tutù jù bí a ti ń rìnrìn àjò káàkiri, kò sì pẹ́ tí ara rẹ̀ fi yá.
A Padà sí Kánádà
Ní ọdún 1988, lẹ́yìn ọdún márùndínlógójì tí a fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ Áfíríkà fífanimọ́ra, wọ́n dá wa padà sí Kánádà. Nígbà tó sì di ọdún 1991, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Ní ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, àrùn rọpárọsẹ̀ kọ lù mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí mo lè ṣe ti dín kù gidigidi láti ìgbà náà wá, mo ṣì ń rí ìdùnnú nínú sísìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní ìlú London ní Ontario.
Lónìí, ńṣe ni ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bí mo bá ń ronú nípa ìgbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gun ẹṣin ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní gúúsù Saskatchewan ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta sẹ́yìn. Mo mà dúpẹ́ o, pé Bàbá ò jáwọ́ nínú kíkọ́ wa nípa bí a ṣe lè máa ronú gẹ́gẹ́ bí ẹni tẹ̀mí, tí kò jẹ́ bẹ̀rù láé láti gbèjà òtítọ́ àti òdodo! Òun ló kọ́ mi ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó mú kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀. Ogún tó sì gbé lé mi lọ́wọ́ yìí ò fi mí sílẹ̀ nígbà kan rí. N ò jẹ́ fi ohunkóhun nínú ayé ògbólógbòó yìí ṣe pàṣípààrọ̀ iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn òbí mi àti àwa ọmọ wọn mẹ́sàn-án rèé ní ọdún 1949, àbígbẹ̀yìn wa ni Màmá gbé dání. Èmi ni mo dúró sẹ́yìn Màmá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Mo kan ọkọ̀ “caboose” yìí kí n lè máa lò ó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn obìnrin tí wọ́n fàṣẹ ọba mú ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec nítorí pé wọ́n ń wàásù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Mo kópa nínú kíkọ́ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wọ̀nyí lẹ́kọ̀ọ́ ní Zimbabwe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
A kan ilé àgbérìn yìí kí ara Emily bàa lè tètè mókun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Fọ́tò tí èmi àti Emily yà láìpẹ́ yìí