Nǹkan Ò Rọrùn Fáwọn Ọ̀dọ́
Nǹkan Ò Rọrùn Fáwọn Ọ̀dọ́
◼ Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọmọléèwé kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, bẹ̀rẹ̀ sí yìnbọn lu àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, méjì lára wọn kú, àwọn mẹ́tàlá sì ṣèṣe.
◼ Ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ti mutí yó pa ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan nípakúpa wọ́n sì lu bàbá ọmọ náà àti ẹ̀gbọ́n ẹ̀ kan nídìí bàbá ní àlùbolẹ̀.
◼ Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan lu ọmọkùnrin kan tó kéré sí i ó sì gún un yánnayànna. Ohun tó sì sọ fáwọn ọlọ́pàá ni pé: “Kò wù mí kí n pa á, àmọ́ nígbà tí mo rí i tí ẹ̀jẹ̀ ń jáde lára rẹ̀ ni mo bá kúkú ń gún un nìṣó títí tó fi kú.”
ÀWỌN ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń jáni láyà bí èyí máa ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́. Wọ́n kọjá ohun téèyàn lè sọ pé kì í sábàá ṣẹlẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé Professional School Counseling tiẹ̀ sọ pé: “Ìwà ipá táwọn ọ̀dọ́ ń hù ti di ìṣòro ńlá láwùjọ wa.” Àkọsílẹ̀ tó wà lọ́wọ́ nípa iye ìwà ipá tó ti wáyé sì jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ gan an lọ̀rọ̀ rí.
Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ètò Ẹ̀kọ́ ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé ìròyìn ò fi bẹ́ẹ̀ gbé e mọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ ń hùwà ipá nílé ìwé lórílẹ̀-èdè yẹn, “lọ́dún 2001, wọ́n hùwà ipá sáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá sí méjìdínlógún nílé ìwé, wọ́n sì ja àwọn míì lólè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ipá náà ò la ẹ̀mí lọ, ó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ [2,000,000] irú rẹ̀ tó wáyé.” A tún ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ sí i nípa fífòòró ẹni nílé ìwé.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn ọmọ ilé ìwé bíi tiwọn nìkan làwọn ọ̀dọ́ ń hùwà ipá sí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà o. Ibùdó ìsọfúnni nípa ètò ẹ̀kọ́ tún sọ pé, “láàárín ọdún márùn-ún, látọdún 1997 sí ọdún 2001, ìwà ọ̀daràn tí wọ́n hù sáwọn olùkọ́ nílé ìwé tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínláàádọ́rin [1,300,000], bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò la ẹ̀mí lọ. Wọ́n tún jalè nígbà ogójì ọ̀kẹ́ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàásàn-án [817,000], wọ́n sì hùwà ọ̀daràn nígbà ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje [473,000].” Wọ́n tún sọ síwájú sí i pé, “ìdá mẹ́sàn-án nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùkọ́ ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi àti ilé ìwé girama làwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ fẹ́ ṣe léṣe, wọ́n sì lu ìdá mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ní àlùbami.”
Báwo lọ̀ràn náà ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè míì? Ilé iṣẹ́ ìròyìn kan sọ pé: “Lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, ẹgbàá márùndínlógójì ó dín okòólérúgba [69,780] ọ̀dọ́ tó ń hùwà ìpáǹle ló kó sí galagálá àwọn agbófinró lọ́dún 2003. Ìyẹn sì fi nǹkan bí ìdá mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún lé sí iye àwọn tó kó sí akóló wọn lọ́dún 2002.” Ó wá fi kún un pé, “bá a bá fi ìwà ìpáǹle táwọn ọ̀dọ́ ń hù níbẹ̀ dá ọgọ́rùn-ún, ìpín àádọ́rin nínú ẹ̀ ló jẹ́ ìwà ọ̀daràn pọ́ńbélé.” Bákan náà ni ìròyìn kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Japan lọ́dún 2003 sọ
pé àwọn ọ̀dọ́ ló wà nídìí ìdajì lára gbogbo ìwà ọ̀daràn tó ti ń wáyé látọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.Oògùn Olóró Ń Sọ Àwọn Ọ̀dọ́ Dìdàkudà
Èyí tó túbọ̀ wá ń máyé nira sí i fáwọn ọ̀dọ́ ni sísọ tí wọ́n ń sọ àgọ́ ara wọn dìdàkudà. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Lílo Oògùn Olóró sọ pé nǹkan bí ìdajì àwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè yẹn ló ti tọ́ oògùn olóró wò rí kí wọ́n tó jáde ilé ìwé gíga. Ìròyìn náà fi kún un pé: “Mímu ọtí líle kàn ń gbilẹ̀ sí i ṣáá ni láàárín àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí. Á fẹ́ẹ̀ tó mẹ́rin lára gbogbo ọmọ ilé ìwé márùn-ún tá á ti máa mutí (tí wọ́n á ti máa já a sára gan-an ni o) bí wọ́n bá fi máa jáde ilé ìwé gíga; ó sì tó ìdajì lára àwọn ọlọ́dún kẹjọ nílé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti mú un rí.”
Ṣíṣe Ìṣekúṣe
Láyé tí àrùn éèdì ti gbòde kan yìí, kò sí àníàní pé ṣíṣe ìṣekúṣe léwu gan-an ni. Síbẹ̀, erémọdé lọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ka ìbálòpọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, báwọn ọ̀dọ́ kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà bá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan lóru mọ́jú, ṣe ni wọ́n máa ń sọ pé àwọn “jọ gbádùn ara àwọn ni,” ìyẹn àdàpè ọ̀rọ̀ tó dà bíi pé kò burú. Bí wọ́n bá sì fẹ́ sọ pé àwọn lẹ́nì kan táwọn máa ń bá lòpọ̀ nígbàkigbà tó bá wu àwọn, wọ́n á ní àwọn “jọ ń ṣeré ìfẹ́” ni.
Òǹkọ̀wé Scott Walter tiẹ̀ ṣàpèjúwe báwọn ọ̀dọ́ kan láwọn ìgbèríko ṣe máa ń pe àpèjẹ tí wọ́n á ti máa bara wọn lò pọ̀ fàlàlà lẹ́yìn táwọn òbí wọn bá ti gba ibi iṣẹ́ lọ. Nígbà tí irú àpèjẹ kan bẹ́ẹ̀ ń lọ lọ́wọ́, ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ ní etígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn pé gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n wà níbẹ̀ pátá ni wọ́n máa bá òun lòpọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, “àwọn ọmọdé tí wọn ò ju ọmọ ọdún méjìlá lọ wà níbi àpèjẹ náà.”
Bóyá o rò pé irú ìyẹn ò ṣeé gbọ́ sétí. Àmọ́, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ò jẹ́ tuntun létí àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ tí wọ́n ti ṣèwádìí báwọn ọ̀dọ́ ṣe máa ń ṣe tó bá dọ̀ràn ìbálòpọ̀. Dókítà Andrea Pennington kọ̀wé pé: “Láti ogún ọdún sẹ́yìn, àwọn ọmọ kéékèèké ló wá kù tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ takọtabo báyìí. Kò tún jẹ́ tuntun mọ́ pé káwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin tí wọn ò ju ọmọ ọdún méjìlá lọ ti bẹ̀rẹ̀ sí bára wọn lò pọ̀.”
Èyí tó tiẹ̀ bani lọ́kàn jẹ́ jù ni ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn USA Today, tó kà pé: “Ńṣe làwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn kéré jù lọ lórílẹ̀-èdè wa yìí, . . . tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ nípa fífẹnu pa ẹ̀yà ìbímọ ara wọn, túbọ̀ ń pọ̀ sí i. . . . Àwọn ọ̀dọ́ ti gbà láàárín ara wọn pé ‘ìyẹn kì í ṣe ohun téèyàn lè pè ní ìbálòpọ̀.’” Nínú ìwádìí kan tó dá lórí ẹgbàárùn-ún [10,000] ọmọdébìnrin, “ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn sọ pé wúńdíá làwọn, àmọ́ ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ló ti fẹnu pa ẹ̀yà ìbímọ rí. A sì rí ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn tó sọ pé ‘eré ìfẹ́ lásán ni kéèyàn àti bọ̀bọ́ téèyàn bá gba tiẹ̀ jọ máa ṣe é.’”
Àwọn kan náà tún ti ń fi irú ojú yẹn wo ìbálòpọ̀ níbòmíràn. Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ [UNESCO] sọ pé: “Àfàìmọ̀ káwọn ọ̀dọ́ nílẹ̀ Éṣíà máà kárùn éèdì nítorí pé àtikékeré ni wọ́n ti máa ń ka ìbálòpọ̀ sí ìgbádùn.” Àjọ UNESCO wá fi kún un pé: “Ńṣe lọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ túbọ̀ ń dá ṣíọ̀ ojúlówó ‘àṣà ilẹ̀ Éṣíà’ tí wọ́n bá lọ́wọ́ àwọn òbí wọn. Ìyẹn ni wọ́n fi ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú tajá tẹran, láìgbéyàwó.”
Ǹjẹ́ àwọn nǹkan míì tún wà tó ń kó àwọn ọ̀dọ́ sí ìjàngbọ̀n? Ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Kánádà náà, Women’s Health Weekly, sọ pé: “Ìdá mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sí mọ́kàndínlógún ni wọ́n máa ní àárẹ̀ ọkàn tó burú jáì.” Àmọ́ ṣá o, tọkùnrin tobìnrin ló máa ń ní àárẹ̀ ọkàn. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report, tiẹ̀ sọ pé ó máa ń tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tó ń para wọn lọ́dọọdún. Àmọ́, nítorí àwọn ìdí kan ṣá, “àwọn ọkùnrin máa ń para wọn nígbà mẹ́fà ju àwọn obìnrin lọ” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ṣe sọ.
Láìsí àníàní, ìṣòro àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí pọ̀ gan-an ni. Kí ló ń fa àwọn ìṣòro náà?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
STR/AFP/Getty Images