Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Iṣẹ́ Ò Fi Ní Bọ́ Mọ́ Ẹ Lọ́wọ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Iṣẹ́ Ò Fi Ní Bọ́ Mọ́ Ẹ Lọ́wọ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Iṣẹ́ Ò Fi Ní Bọ́ Mọ́ Ẹ Lọ́wọ́

“Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí.”—Òwe 22:29.

BÍ ẸSẸ Bíbélì tó wà lókè yìí ṣe fi hàn, àwọn èèyàn máa ń mọrírì òṣìṣẹ́ tó bá já fáfá gan-an ni. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà táwọn agbanisíṣẹ́ máa ń fẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ wọn ní àtàwọn nǹkan tí wọ́n máa ń fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe? George, olùdarí ẹ̀ka tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] òṣìṣẹ́, sọ fún aṣojú ìwé ìròyìn Jí! pé: “Ohun tó jẹ wá lógún lára òṣìṣẹ́ ni pé kó lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa yé gbogbo èèyàn, kó sì lè bá àwọn ẹlòmíràn ṣiṣẹ́ láìjà láìta.” Bíbélì láwọn ìmọ̀ràn tó yááyì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè báwọn ẹlòmíì ṣe nǹkan pọ̀, àwọn ìmọ̀ràn náà á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ débi tí iṣẹ́ ò fi ní bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

Mọ Béèyàn Ṣeé Sọ̀rọ̀

Jákọ́bù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé kéèyàn tó lanu sọ̀rọ̀ gan-an lèèyàn ti gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe yẹ kó sọ̀rọ̀. Jákọ́bù kọ̀wé pé èèyàn gbọ́dọ̀ “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn yìí fi ṣe pàtàkì? Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” (Òwe 18:13) Òótọ́ sì ni, tó o bá ń fetí sílẹ̀ dáadáa sí ẹni tó gbà ọ́ síṣẹ́ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, èdè àìyedè ò ní máa wáyé kò sì ní jẹ́ kó o máa hùwà tí ò bọ́gbọ́n mu.

Tó o bá fẹ́ sọ̀rọ̀, rántí pé ọ̀nà tó o gbà sọ ọ́ náà ṣe pàtàkì. Tó o bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere tó o sì gbóhùn sókè bó ṣe yẹ, ó ṣeé ṣe kí ohun tó ò ń sọ yé àwọn èèyàn, wọ́n á sì ka ọ̀rọ̀ rẹ sí pàtàkì. Brian, agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ wíwá, tá a mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Á yà ọ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ iye àwọn tí iṣẹ́ ń bọ́ lọ́wọ́ wọn, kìkì nítorí pé wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ wọ́n sì mọṣẹ́ dáadáa.”

Máa Bá Àwọn Ẹlòmíràn Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀

Kò sí àníàní pé wàá mọ àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ dáadáa bá a bá wo ti àkókò tẹ́ ẹ jọ ń lò pa pọ̀. Èyí lè mú kó o fẹ́ máa rojọ́ wọn lẹ́yìn, tí wàá sì máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣìṣe àti àléébù wọn. Àmọ́, ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: ‘Kó o fi ṣe ìfojúsùn rẹ láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, kó o má sì máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.’ (1 Tẹsalóníkà 4:11) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, o ò ní dẹni tí wọ́n mọ̀ bí “olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.” (1 Pétérù 4:15) Bákan náà, o ò ní máa fàkókò ṣòfò, o ò sì ní máa dá rúgúdù sílẹ̀ ṣáá láàárín àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́.

Bí wọ́n bá gbéṣẹ́ kan fún ọ, fi ìmọ̀ràn pàtàkì tí Jésù fúnni sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá . . . fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mátíù 5:41) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọba ni Jésù ń bá wí níbí yìí, síbẹ̀ ìlànà náà wúlò níbi iṣẹ́. Bí wọ́n bá ti mọ̀ ẹ́ bí ẹni tó ń múra síṣẹ́, ìyẹn ẹni táá ṣe kọjá ohun tí wọ́n ní kó ṣe, bóyá ni iṣẹ́ á fi bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá, ó lójú ohun tí ẹni tó gbà ọ́ síṣẹ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti ní kó o ṣe o. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé a ní láti “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Ìlànà tí Jésù ń fi lélẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ni pé o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn aláṣẹ pinnu fún ọ lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì bí ọ̀ràn sísin Ọlọ́run.

Jẹ́ Olóòótọ́

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórí egbèje [1,400] ilé iṣẹ́ fi hàn pé “àwọn ìwà tó máa ń wu àwọn agbaniṣíṣẹ́ lára àwọn tó ń wáṣẹ́ ni jíjẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin.” Gbogbo wa la mọ̀ pé olóòótọ́ èèyàn ò gbọ́dọ̀ jí owó tàbí àwọn nǹkan míì tó jẹ́ tẹni tó gbà á síṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní máa jalè àkókò. Ìwádìí tí ilé iṣẹ́ abániwáṣẹ́ kan ṣe fi hàn pé ó kéré tán, wákàtí mẹ́rin àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ń jí lọ́sẹ̀. Lára ọ̀nà táwọn tó ń jalè àkókò gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pípẹ́ dé síbi iṣẹ́, fífi ibi iṣẹ́ sílẹ̀ ṣáájú àkókò àti kí wọ́n máa bá àwọn òṣìṣẹ́ míì rojọ́ lásìkò iṣẹ́.

Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.” (Éfésù 4:28) Láfikún sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa múra síṣẹ́ wọn, kódà báwọn aláṣẹ ò bá tiẹ̀ rí wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá yín nípa ti ara, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣe àrójúṣe, gẹ́gẹ́ bí olùwu ènìyàn, ṣùgbọ́n pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn-àyà, pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Kólósè 3:22) Bí wọ́n bá ti mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó ń gbájú mọ́ṣẹ́, kódà nígbà tí ò sẹ́ni tó ń wò ọ́, wọ́n á kà ọ́ sí òṣìṣẹ́ tó ṣeé fọkàn tán.

Máa Gba Bọ̀rọ̀ Bá Ṣe Rí

Gẹ́lẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò wa yìí á le koko, á sì nira láti bá lò, ló ń rí. (2 Tímótì 3:1) Kò sí àníàní pé, rògbòdìyàn ìṣèlú, àìfararọ tó bá mùtúmùwà àti rúkèrúdò tó gba ìlú kan ni kò jẹ́ kí ètò ọrọ̀ ajé dúró sójú kan. (Mátíù 24:3-8) Nítorí náà, ká tiẹ̀ ni èèyàn tẹ̀ lé gbogbo ìmọ̀ràn tá a ti sọ yìí, iṣẹ́ ṣì lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀.

Àmọ́, bá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì, ó lè dín àníyàn tí àìníṣẹ́lọ́wọ́ máa ń fà fún èèyàn kù. Jésù sọ pé: “Wàyí o, bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò ní ọ̀la, òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré? Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ . . . Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—Mátíù 6:30-32.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ Jésù tó wà lókè yẹn. Ericka tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan yẹn wà lára wọn, ó sọ pé: “Mo gbádùn iṣẹ́ tí mò ń ṣe nísinsìnyí gan-an ni. Ṣùgbọ́n ìrírí ti jẹ́ kó yé mi pé nǹkan máa ń yí padà. Síbẹ̀ náà, nípa fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò àti bí mo ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, mo ti mọ ohun tí mo lè ṣe láti dín àníyàn mi kù nígbà tí mi ò bá níṣẹ́ lọ́wọ́, mo sì mọ bí mo ṣe lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ tí mò ń ṣe lọ́wọ́ báyìí.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Tí o kì í bá fọkàn sí ohun tó ń lọ níbi ìpàdé tẹ́ ẹ̀ ń ṣe, iṣẹ́ rẹ lè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́