Ta Ló Ń forí Fá Àtúbọ̀tán Ṣíṣàfọwọ́rá?
Ta Ló Ń forí Fá Àtúbọ̀tán Ṣíṣàfọwọ́rá?
NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ Japan, ọwọ́ oníṣòwò kan tẹ ọmọkùnrin kan tó jà á lólè, ló bá ké sí àwọn ọlọ́pàá. Báwọn ọlọ́pàá yẹn ṣe dé lọmọ náà fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Àwọn ọlọ́pàá náà bá gbá tẹ̀ lé e. Bí ọmọkùnrin yẹn ṣe ní kóun sọdá ojú ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin kan báyìí, ṣe ni ọkọ̀ ojú irin tó ń bọ̀ kọ lù ú, bó ṣe kú nìyẹn.
Bí gbogbo èèyàn ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà báyìí, ṣe ni wọ́n ń dá oníṣòwò náà lẹ́bi torí pé ó ké sí àwọn ọlọ́pàá. Kò ṣí ilé ìtajà rẹ̀ títí dìgbà tí afẹ́fẹ́ ti fẹ́ sórí ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tó jàjà wá ṣí ilé ìtajà náà ńkọ́, ọwọ́ táwọn aláfọwọ́rá fi tún ya dé kọjá àfẹnusọ. Ṣùgbọ́n nítorí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ẹ̀rù ń bà á láti tún yẹ àwọn olè náà lọ́wọ́ wò. Wọ́n ti wá mọ ilé ìtajà rẹ̀ sí ibi téèyàn lè wọ̀ kó sì jí ohun tó bá wù ú láìsí wàhálà. Kò pẹ́ tó fi ti ilé ìtajà ọ̀hún pa pátápátá.
Lóòótọ́, irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú tó báyìí ò wọ́pọ̀, síbẹ̀ ó jẹ́ ká mọ òkodoro òtítọ́ pàtàkì kan nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Láìmọye ọ̀nà, àdánù ńlá gbáà ni àfọwọ́rá jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ẹ wá jẹ́ ká tú iṣu òfò tó ń bá aráyé látàrí ìwà ọ̀daràn yìí dé ìsàlẹ̀ ìkòkò.
Ipa Tó Ń Ní Lórí Àwọn Oníṣòwò
Lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye bílíọ̀nù dọ́là làwọn aláfọwọ́rá ń mú káwọn oníṣòwò pàdánù. Àwọn kan fojú bù ú pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, òfò yẹn ju ogójì bílíọ̀nù dọ́là lọ. Oníṣòwò mélòó ló lè pàdánù adúrú owó yẹn láìní kógbá sílé? Ọ̀pọ̀ oníṣòwò lọ̀rọ̀ ọ̀hún ti sú. Nígbà táwọn olè bá ya bo ilé ìtajà kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí òpin ṣe máa dé bá gbogbo làálàá tí oníṣòwò náà ti fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe nìyẹn.
Oníṣòwò kan tó ń jẹ́ Luke nílùú New York City sọ pé, “Àfọwọ́rá kì í ṣe ohun téèyàn lè fọwọ́ lẹ́rán sí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ìbára-ẹni-díje tó tún wà nídìí ṣíṣòwò ọ̀hún. Èmi ò mọ ibi tá a máa bá yàrá òwò yìí já o.” Kò lágbára láti ra ẹ̀rọ̀ abánáṣiṣẹ́ tó máa ń táṣìírí olè. Nígbà tó ń sọ nípa àwọn olè yẹn, ó ní: “Mi ò lè sọ pé ẹni báyìí ni, kódà àwọn oníbàárà mi pàápàá lè ṣe é.”
Àwọn kan gbà pé èyí tí Luke kà sí ìṣòro yẹn kò lè tó bẹ́ẹ̀. Ohun táwọn kan máa ń sọ ni pé: “Jabíjabí owó làwọn oníṣòwò máa ń pa, torí náà kò sóhun táwọn lè jí tó lè ní kóníṣòwò kan máà dé ibi tó máa dé.” Ṣé lóòótọ́ lèrè jaburata kan wà lórí káràkátà?
Àwọn oníṣòwò kan máa ń fi ìdá ọgbọ̀n, ogójì, tàbí àádọ́ta lé iye tí wọ́n bá ra ọjà náà, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo iye tí wọ́n fi lé e yẹn lèrè wọn o. Wọ́n ṣì máa ń yọ àwọn owó kan nínú iye tí wọ́n fi lé owó ọjà náà. Àwọn owó ọ̀hún ni owó ṣọ́ọ̀bù, owó orí, owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ àtowó àjẹmọ́nú míì fáwọn òṣìṣẹ́, owó tí wọ́n bá ná sórí àtúnṣe ṣọ́ọ̀bù, owó tí wọ́n fi ń tún ohun èlò ṣe, owó iná, owó omi, owó epo, owó tẹlifóònù, àtowó ètò ààbò gbogbo. Ìgbà tí wọ́n bá fi máa yọ gbogbo owó yẹn tán, èrè wọn lè má ju ìdá méjì tàbí mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ. Nítorí náà, bí ẹnì kan bá wá lọ ń ja oníṣòwò kan lólè, ṣe ni olè náà ń sọ pé bí ebi bá lè pa oníṣòwò kan kú, kó pa á kú.
Fífẹ́wọ́ Ńkọ́?
Nígbà tí ìyá kan àti ọmọkùnrin rẹ̀ wà nínú ilé ìtajà kan, ọmọkùnrin yẹn kúrò lọ́dọ̀ ìyá ẹ̀, ó sì lọ síbi tí wọ́n pàtẹ súìtì sí. Ó ṣí páálí kan, ó mú súìtì ó sì jù ú sápò. Ǹjẹ́ irú àfọwọ́rá tí ò tó nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kí oníṣòwò kan kógbá sílé?
Àjọ Tó Ń Bójú Tó Òwò Alábọ́ọ́dé Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ nínú ìwé kan tí wọ́n pè ní Curtailing Crime—Inside and Out, pé: “Fífẹ́wọ́ lè má dà bí ìwà ọ̀daràn lójú ọmọkọ́mọ kan tí ò mọ̀ ju kó jí bírò níbí, kó jí ẹ̀rọ̀ ìṣírò kékeré lọ́hùn-ún. Àmọ́ lójú oníṣòwò tó jẹ́ pé bí òwò rẹ̀ ṣe máa fìdí múlẹ̀ ló ń wá, bí ìgbà téèyàn dọ̀bẹ dé e lọ́rùn ni téèyàn bá ń jí ọjà rẹ̀.” Nítorí pé èrè tí wọ́n ń jẹ kò tó nǹkan, kí oníṣòwò kan tó lè rí ẹgbẹ̀rún kan dọ́là tó jẹ́ iye owó ọjà táwọn aláfọwọ́rá máa ń jí lọ́dún kan, ó gbọ́dọ̀ máa ta ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án súìtì tàbí ọ̀rìn-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [380] agolo ọbẹ̀ lójoojúmọ́.
Nítorí náà, òfò ńlá ló jẹ́ fáwọn oníṣòwò táwọn ọmọ kéékèèké bá ń jí súìtì. Ibi tí ìṣòro ọ̀hún wà gan-an lẹ rí yẹn o.Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, lọ́mọdé àti lágbà, olówó àti tálákà látinú gbogbo ẹ̀yà àti ìran ló máa ń jalè lọ́jà àti láwọn ṣọ́ọ̀bù. Kí ni àbájáde ẹ̀? Ìgbìmọ̀ Tó Ń Dènà Ìwà Ọ̀daràn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn oníṣòwò tó wà ní orílẹ̀-èdè náà làwọn aláfọwọ́rá ti fẹ́ sún débi tí wọ́n ti máa kógbá sílé. Kò sí iyèméjì pé ohun táwọn oníṣòwò láwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń fara gbá náà nìyẹn.
Bí Àwọn Oníbàárà Ṣe Ń Sanwó Ohun Tí Wọn Ò Rà
Ńṣe lọjà máa ń gbówó lórí sí i báwọn èèyàn bá ti ń jalè nílé ìtajà. Nípa bẹ́ẹ̀, láwọn àdúgbò kan, àwọn oníbàárà máa ń san tó ọ̀ọ́dúnrún dọ́là lọ́dún lórí owó ọjà tó lé sí i láti lè dí ohun táwọn aláfọwọ́rá jí. Èyí túmọ̀ sí pé tó o bá ń gba ọgọ́ta dọ́là lóòjọ́, iṣẹ́ tó o bá ṣe lódidi ọ̀sẹ̀ kan lọ́dún lo máa fi dí ohun táwọn ẹlòmíràn jí. Ṣé ìyẹn ò ní ga ọ́ lára ṣá? Bí ẹni ṣòfò gbogbo dúkìá ni pípàdánù odindi owó iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kan máa jẹ́ fáwọn tó ti fẹ̀yìn tì, tó jẹ́ pé owó ìfẹ̀yìntì wọn ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé tàbí fáwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ tó jẹ́ pé ekukáká lọwọ́ wọn fi ń tẹ́nu. Àdánù yẹn ò mọ síbẹ̀ o.
Gbogbo àwọn tó ń gbé ládùúgbò kan lè jìyà ẹ̀ tí ilé ìtajà tó sún mọ́ wọn bá kógbá sílé. Ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé oníṣòwò tó ń ta òògùn ládùúgbò kan tó sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní láti ti ilé ìtajà náà pa nígbà táwọn aláfọwọ́rá ò jẹ́ kó rímú mí. Ó wá di pé kẹ́ni tó bá fẹ́ ra oògùn, kódà kí ẹni náà jẹ́ àgbàlagbà tàbí aláìlera, wá bó ṣe máa dé ṣọ́ọ̀bù míì tí wọ́n ti ń ta òògùn tó wà ní nǹkan bí kílòmítà méjì àbọ̀ sí àdúgbò yẹn. Ọkùnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba sọ pé, “Ìwọ gbé kẹ̀kẹ́ arọ lọ wò, kó o wá rí bó ṣe nira to.”
Báwọn Òbí Ṣe Ń Forí Fá A
Ọkùnrin tí kò gba gbẹ̀rẹ́ ni Bruce tó bá dọ̀ràn ìwà híhù, ó máa ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ láti jẹ́ olóòótọ. Lọ́jọ́ kan, wọ́n mú ọmọbìnrin ẹ̀ níbi tó ti ń jalè. Bruce sọ pé, “Jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé mi lọ́wọ́. Rò ó wò ná, kí wọ́n tẹ̀ ọ́ láago pé ọwọ́ ti tẹ ọmọbìnrin ẹ níbi tó ti ń ṣàfọwọ́rá. Látọdún tá a ti ń tọ́ ọmọbìnrin wa yìí bọ̀ torí kó lè ṣeé mú yangàn, ẹ ò wá rójú ayé lóde. A ò rò ó rí pé ó lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láé.”
Ìrònú dorí Bruce kodò nípa bí ọjọ́ ọ̀la ọmọbìnrin ẹ̀ ṣe máa rí. Síwájú sí i, ó kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tó yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti máa kọ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́fẹ̀ẹ́. Ó ní: “Ojú wo láwọn ará ìjọ á fi máa wò mí bí mo bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle? Ṣé ẹnu mi á lè gbà á láti máa fún ìjọ ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe tọ́ àwọn ọmọ wọn? Mi ò rò pé ẹnu mi á gbà á.” Kò
dà bíi pé ọmọbìnrin ẹ̀ mọ̀ pé bóun bá dáràn, ipa kékeré kọ́ ló máa ní lórí baba òun.Báwọn Aláfọwọ́rá Ṣe Ń Jèrè Iṣẹ́ Ọwọ́ Wọn
Bọ́wọ́ àwọn tó ni ilé ìtajà bá tẹ aláfọwọ́rá nígbà kan rí, ṣe ni wọ́n máa kì í nílọ̀ tí wọ́n á sì jẹ́ kí olè náà máa lọ. Lóde òní, àwọn oníṣòwò kì í jẹ́ kí aláfọwọ́rá tọ́wọ́ bá tẹ̀ lọ kódà kó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tó máa ṣe é nìyẹn. Ìyẹn làwọn tó ń ṣàfọwọ́rá pàápàá fi mọ̀ pé tọ́wọ́ pálábá àwọn bá ségi, ìyà ńlá ló ń dúró de àwọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Natalie nìyẹn.
Natalie ní: “Bí mo ṣe ń pẹ́ sí i lẹ́nu olè jíjà ni mò ń láyà sí i. Mo fojú bù ú pé kódà bọ́wọ́ bá tiẹ̀ tẹ̀ mí, owó tí màá fi gba agbẹjọ́rò àtèyí tí màá san nílé ẹjọ́ ò lè tó owó tí ǹ bá fi ra àwọn aṣọ tó nẹgba tí mo jí kó yẹn.” Àṣé Natalie ń tan ara ẹ̀ ni.
Wọ́n mú un níbi tó ti ń jí aṣọ, àwọn ọlọ́pàá bá kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́, wọ́n sì mú un lọ. Ní àgọ́ àwọn ọlọ́pàá, wọ́n ní kó tẹ̀ka, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n wá tì í mọ́lé pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn mìíràn. Ọ̀pọ̀ wákàtí ló fi wà níbẹ̀ káwọn òbí ẹ̀ tó wá gba ìdúró ẹ̀.
Nígbà tó ń fún gbogbo ẹni tó bá ń gbèrò àtijalè ní ìmọ̀ràn, ó ní: “Tèmi ò ju pé, ó sàn kò o ra aṣọ tó wọ̀ ẹ́ lójú yẹn ju pé kó o jí i lọ.” Natalie wá sọ pé: “Bó o bá wá pinnu pé ṣe lo fẹ́ jalè, wàá géka àbámọ̀ jẹ kẹ́yìn ni.”
Ọ̀kan lára àbámọ̀ náà ni pé kí orúkọ èèyàn wọ̀wé tí wọ́n ń kọ orúkọ àwọn ọ̀daràn sí. Ó lè ya àwọn aláfọwọ́rá tórúkọ wọn ti wọ̀wé tí wọ́n fi ń kọrúkọ àwọn ọ̀daràn sí lẹ́nu pé àwọn èèyàn ò ní yé fi ojú ọ̀daràn wò wọ́n, kódà, kí ìwà ọ̀daràn kan tó ṣẹlẹ̀ tán ni wọ́n á ti dárúkọ wọn, bí epo lára aṣọ fúnfún ni. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní kẹ́ni tó ti jẹ̀bi ẹ̀sùn àfọwọ́rá nígbà kan rí kọ ọ́ sínú ìwé ìwọlé sí yunifásítì kí wọ́n tó gbà á wọlé. Ó lè nira fún un kí wọ́n tó lè gbà á sáwọn iṣẹ́ kan, bí iṣẹ́ ìṣègùn, iṣẹ́ ìtọ́jú eyín tàbí iṣẹ́ àwọn tó ń yàwòrán ilé. Àwọn ilé iṣẹ́ lè ní láti rò ó lẹ́ẹ̀mejì kí wọ́n tó gbà á síṣẹ́. Èyí tó burú níbẹ̀ ni pé ẹ̀yìn ìgbà tó bá ti san owó ìtanràn nílé ẹjọ́, tó sì ti kiwọ́ olè jíjà bọlẹ̀, àwọn ìṣòro yẹn tún ṣì lè máa yọjú.
Kódà, bọ́wọ́ ṣìnkún àwọn ọlọ́pàá ò bá tiẹ̀ tẹ aláfọwọ́rá kan, kò sí ni kí ọ̀rọ̀ ọ̀hún máà lẹ́yìn. Bó ṣe rí fún Hector tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí nìyẹn. Ó sọ pé: “Kò bu mí lọ́wọ́ rí látọjọ́ tí mo ti ń jalè.” Síbẹ̀, ó pàpà lẹ́yìn. Ó níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Mo ronú pé ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ mọ nǹkan kan dájú, ìyẹn ni pé: Ohun tó o bá gbìn lo máa ká. Àní, bọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá ò bá tiẹ̀ tíì tó ẹ, ohun tó máa mú ẹ, á mú ẹ.
Ẹnì kan ló ṣáà máa fara gbá ṣiṣàfọwọ́rá, bákan náà aláfọwọ́rá ò sì ní mú un jẹ. Ohun tó yẹ ni pé kí ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣàfọwọ́rá lọ kiwọ́ ìwà yẹn bọlẹ̀ pátápátá. Ṣùgbọ́n, báwo lẹnì kan tó ń ṣàfọwọ́rá ṣe lè ṣíwọ́ pátápátá? Ǹjẹ́ irú ìwà ọ̀daràn yìí tiẹ̀ lè tán láyé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ṣíṣàfọwọ́rá máa ń mú kí oníṣòwò kógbá sílé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Gbogbo èèyàn ló ń forí fá àtúbọ̀tán ṣísàfọwọ́rá
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ṣíṣàfọwọ́rá lè kó bá ọ lọ́jọ́ iwájú
[Credit Line]
Ìtẹ̀ka: © Fọ́tò tí Morocco Flowers/ Index Stock Imagery yà