Oyin Ẹ̀bùn Iyebíye Fáwa Ẹ̀dá
Oyin Ẹ̀bùn Iyebíye Fáwa Ẹ̀dá
Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Mẹ́síkò
ÓTI rẹ ọmọ ogun Ísírẹ́lì kan báyìí tẹnutẹnu. Bó ṣe rí afárá oyin tó ń ro tótó nínú ẹgàn báyìí, ńṣe ló tẹ orí ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, tó sì tọ́ díẹ̀ lá lára oyin náà. Lójú ẹsẹ̀, “ojú rẹ̀ . . . bẹ̀rẹ̀ sí tàn yanran,” agbára rẹ̀ sì padà di àkọ̀tun. (1 Sámúẹ́lì 14:25-30) Àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí ṣàpèjúwe ọ̀kan lára ọ̀nà tí oyin gbà wúlò tó sì lè gba ṣe ẹ̀dá lóore. Ó tètè máa ń fára lókun, nítorí pé èròjà onítáàṣì ló kó ìdá tó pọ̀ jù lára ẹ̀. Ibi tọ́rọ̀ náà wá dùn sí jù ni pé, kòkòrò tó ń ṣe oyin máa rí agbára gbà nínú oyin tó ń ṣe. Bí oyin bá tó ṣíbí ìmùkọ méjì, kòkòrò yìí lè fi agbára táá rí nínú ẹ̀ fó yíká ayé!
Ṣé àwa èèyàn nìkan ni oyin ń ṣe lóore ni? Ó tì o, oyin yẹn gan-an loúnjẹ tó ń gbẹ́mìí àwọn kòkòrò yẹn fúnra wọn ró. Káwọn kòkòrò yìí má bàa kú nígbà òtútù níbi tí wọ́n máa ń kóra jọ sí, wọ́n á nílò oyin tó tó gálọ́ọ̀nù mẹ́ta sí mẹ́rin. Àmọ́ bójú ọjọ́ bá dáa, àwọn kòkòrò yìí lè ṣe oyin tó tó kìlógíráàmù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ìyẹn nǹkan bíi gálọ́ọ̀nù méje, èyí tó ṣẹ́ kù táwọn kòkòrò náà ò bá lò làwa èèyàn àtàwọn ẹranko bíi béárì àti raccoon, á rí pọ́n lá.
Báwo làwọn kòkòrò yìí ṣe ń ṣe oyin? Báwọn kòkòrò náà ṣe ń fò kiri látorí òdòdó kan sórí ìkejì, wọ́n máa ń fi ahọ́n wọn ṣóṣóró tó a Bí omi tó wà nínú ẹ̀ bá ti dín kù dé nǹkan bí ìdá márùn-ún, àwọn kòkòrò náà á fi ìda oyin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo afárá onígun mẹ́fà-mẹ́fà náà. Oyin tí wọ́n bá bò mọ́nú afárá yìí lè wà bẹ́ẹ̀ títí gbére. Kódà, a tiẹ̀ ti rí oyin tó ṣeé jẹ dáadáa, tọ́jọ́ ẹ̀ ti tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún, nínú ibojì àwọn Fáráò.
níhò nínú fa omi dídùn òdòdó mu. Omi dídùn náà á sì kọjá lọ sínú ikùn tí wọ́n máa ń tọ́jú rẹ̀ sí, lára ikùn méjì tí wọ́n ní. Bí wọ́n bá délé, wọ́n á pọ̀ ọ́ jáde sẹ́nu àwọn kòkòrò yòókù. Àwọn wọ̀nyẹn á “jẹ ẹ́ lẹ́nu” fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, títí tí èròjà protein tó máa ń sun látinú ẹṣẹ́ tó wà lẹ́nu wọ́n á fi dà pọ̀ mọ́ ọn. Àwọn náà á wá pọ̀ ọ́ sínú àwọn afárá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, onígun mẹ́fà tí wọ́n fi ìda oyin ṣe, wọ́n á sì máa fi ìyẹ́ wọn fẹ́ ẹ kí omi tó wà nínú ẹ̀ lè dín kù.Oyin Ṣeé Lò bí Oògùn
Yàtọ̀ sí pé oyin jẹ́ àgbàyanu oúnjẹ, ṣe ló kún fọ́fọ́ fáwọn èròjà fítámì B àti onírúurú èròjà oúnjẹ, kì í sì í jẹ́ kí nǹkan dógùn-ún bọ̀rọ̀, òun ni ọ̀kan lára oògùn tọ́jọ́ ẹ̀ pẹ́ jù lọ táwọn èèyàn ṣì ń lò. b Ọ̀mọ̀wé May Berenbaum, onímọ̀ nípa kòkòrò, nílé ẹ̀kọ́ gíga University of Illinois, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣàlàyé pé: “Látọjọ́mọjọ́ ni wọ́n ti ń lo oyin láti wo àwọn nǹkan bí egbò, ọgbẹ́ iná, ẹbọ́ ojú, ojuju àti ibi téèyàn bá fi pa.”
Nígbà tí ilé iṣẹ́ ìròyìn CNN ń ṣàlàyé lórí báwọn èèyàn ṣe wá ń kúndùn oyin nítorí ìwúlò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí egbòogi, ó sọ pé: “Ìgbà tí wọ́n ṣàwárí oògùn apakòkòrò láti máa fi wẹ egbò nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ló di pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lo oyin mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe àti bí àwọn kòkòrò àrùn tí oògùn apakòkòrò kò lè pa ṣe ń pọ̀ sí i, ti mú kí oògùn àbáláyé yìí padà sójú ọpọ́n lágbo àwọn oògùn tí wọ́n fi ń wo àìsàn.” Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ohun tí ìwádìí dá lé lórí ni bí wọ́n ṣe lè máa tọ́jú ẹni tí iná bá jó. Wọ́n ti kíyè sí i pé bó bá jẹ́ pé oyin ni wọ́n fi sójú ọgbẹ́ náà, ó máa ń jẹ́ kó tètè jẹ bò, ó máa ń dín ìrora kù àti pé àpá ọgbẹ́ náà kì í fi bẹ́ẹ̀ hàn.
Ìwádìí fi hàn pé nítorí èròjà protein táwọn kòkòrò yìí máa ń dà mọ́ omi dídùn òdòdó, oyin máa ń ní àwọn èròjà rírọjú tó lè kápá àwọn kòkòrò àrùn tó bá bá ojú ọgbẹ́ wọlé. Nínú èròjà protein yìí ni èròjà míì tún wà tí kì í jẹ́ kí egbò dómùkẹ̀, tó sì máa ń pa àwọn kòkòrò tó lè ṣèpalára. c Ní àfikún, bí wọ́n bá tọ́ oyin sí ojú ibi téèyàn fi pa, kò ní jẹ́ kó wú, á sì jẹ́ kí ojú ọgbẹ́ náà tètè san. Ìdí nìyẹn tí onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àti egbòogi, Dókítà Peter Molan tó wà nílẹ̀ New Zealand fi sọ pé: “Oyin ti wá di ohun táwọn tó ń fi tewé tegbò tọ́jú àìsàn lọ́nà ti ìgbàlódé gbà gẹ́gẹ́ bí egbòogi ìwòsàn tó lóókọ tó sì múná dóko.” Kódà, àwọn olówò egbòogi kan nílẹ̀ Ọsirélíà, tí wọ́n ń pè ní Australian Therapeutic Goods Administration, ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa lo oyin gẹ́gẹ́ bí egbòogi, oyin téèyàn lè máa fi wẹ ọgbẹ́ tàbí egbò sì ti wà lórí àtẹ káàkiri orílẹ̀-èdè yẹn báyìí.
Oúnjẹ mélòó míì wo lo mọ̀ tó ń ṣara lóore dáadáa, tó dùn yùngbà yungba, síbẹ̀ náà tó ṣeé lò nílò egbòogi? Abájọ tó fi jẹ́ pé látijọ́, wọ́n gbé àwọn òfin pàtó kalẹ̀ nítorí àtidáàbò bo àwọn kòkòrò tó ń ṣe oyin àtàwọn tó ń sìn wọ́n! Bí ẹnì kan bá wó igi táwọn kòkòrò yìí ṣe afárá sí tàbí tó ba ilé wọn jẹ́ pẹ́nrẹ́n, ọ̀ràn ńlá tó lè la ikú lọ ló dá, wọ́n sì lè dá owó ìtanràn tó pọ̀ lé ẹni náà nítorí ẹ̀. Lóòótọ́, ẹ̀bùn iyebíye ni oyin jẹ́ fáwa ẹ̀dà, ó sì yẹ ká fọpẹ́ fún Ẹlẹ́dàá nítorí ẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Látinú àkànṣe ẹṣẹ́ tó wà lára wọn ni wọ́n ti máa ń rí ìda tí wọ́n fi ń ṣe afárá. Igun mẹ́fà tí afárá náà ní ló máa ń mú kó lè gbé ohun tó wúwo jù ú lọ nígbà ọgbọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ̀ rí fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà nípọn ju bébà lọ. Àgbàyanu ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ mà ni ọ̀rọ̀ afárá oyin yìí.
b Oyin kì í ṣe oúnjẹ tó dáa fáwọn ọmọdé nítorí pé ó lè mú kí wọ́n ní àrùn tó máa ń sọ ara di ahẹrẹpẹ.
c Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ooru àti ìmọ́lẹ̀ máa ń ba omi dídùn òdòdó jẹ́, oyin tí wọn ò tíì sè ni wọ́n máa ń lò bí oògùn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Fífi Oyin Se Oúnjẹ
Oyin dùn ju ṣúgà lọ. Nítorí náà, bó o bá fẹ́ fi oyin se oúnjẹ dípò ṣúgà, jẹ́ kí èyí tó o máa lò tó ìdajì tàbí ìdáta ṣúgà tó yẹ kó o lò. Àti pé, níwọ̀n bí omi ti kó nǹkan bí ìdá márùn-ún nínú oyin, ṣe ni kó o dín omi tó o bá máa lò kù. Bó ò bá sì ní lo omi rárá, a jẹ́ pé o lè máa fi ìyẹ̀fun ṣíbí ìmùkọ méjì-méjì kún ife oyin kọ̀ọ̀kan tó o bá lò. Bó bá sì jẹ́ nǹkan bíi búrẹ́dì lo fẹ́ ṣe, fi ìyẹ̀fun inú agolo bíi ṣíbí tíì kan àtààbọ̀ kún ife oyin kọ̀ọ̀kan tó o bá lò, kó o sì dín gbígbóná àdògán rẹ̀ kú ní ìwọ̀n mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
[Credit Line]
National Honey Board
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Kòkòrò tó ń ṣe oyin ń wá omi dídùn òdòdó kiri
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Afárá oyin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ibi táwọn kòkòrò tó ń ṣe oyin kóra jọ sí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹni tó ń sin oyin ń yẹ ọ̀kan wò lára pátákó tí wọ́n fi ṣe ilé kòkòrò náà