A Wá Ilé Míì fún Ológoṣẹ́ Tó Fara Pa
A Wá Ilé Míì fún Ológoṣẹ́ Tó Fara Pa
“ASÌ ti rí iṣẹ́ tá a ó máa ṣe nìyẹn, àbí?” Ohun tí mo kọ́kọ́ sọ nìyẹn nígbà tí ìyàwó mi mú ẹyẹ ológoṣẹ́ kékeré kan tó jábọ́ láti inú ìtẹ́ rẹ̀ wálé. Àmọ́, nígbà tí mo wo ẹyẹ yìí dáadáa, tí mo rí i tó ń gbọ̀n jolojolo, àánú ẹ̀ ṣe mí. Síbẹ̀, mo rò ó pé báwo ni ẹyẹ tó ti fẹ́ kú yìí ṣe máa yè é. a
Lákọ̀ọ́kọ́, ṣe là ń dọ́gbọ́n fi oúnjẹ tá a ti lọ̀ bọ́ ẹyẹ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà sílé yìí. Àmọ́, lọ́jọ́ kejì, ológoṣẹ́ kékeré yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí ké ṣíoṣío, ó ń sunkún oúnjẹ. Kódà à ń gbọ́ igbe ẹ̀ nínú yàrá wa láti abẹ́ àtẹ̀gùn, tá a sì ti pa gbogbo ilẹ̀kùn dé!
Ìyẹ́ apá ológoṣẹ́ yẹn la fi mọ̀ pé abo ni. Nígbà tó yá, ara ẹ̀ ti mókun débi tó fi lè máa fò. Ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo ọgbọ́n tá a dá láti dá a padà síta níbi tó ti wá já sí! A rò pé ‘bóyá ẹ̀rù ń bà á láti fi ilé wa sílẹ̀ ni.’ La bá ra kéèjì ẹyẹ kan, a sì bẹ̀rẹ̀ sí sin ológoṣẹ́ kékeré yìí. Orúkọ àpèkẹ́ tá a sọ ọ́ ni “Spatzi” tó túmọ̀ sí “ológoṣẹ́” lédè Jámánì.
Lọ́jọ́ kan, a se ìrẹsì, tó dà bí ọ̀kan lára oúnjẹ tí Spatzi fẹ́ràn jù lọ. Nítorí pé ó ṣì gbóná, ìyàwó mi bu díẹ̀ sọ́tọ̀ ó sì da hóró mélòó kan sílẹ̀ fún Spatzi. Kí ni ẹyẹ wa kékeré yìí ṣe o? Ṣe ló yí orí ẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìkó ẹnu ẹ̀ ti hóró ìrẹsì wọ̀nyẹn lọ sí ẹ̀gbẹ́ tábìlì! Èmi àtìyàwó mi ò rẹ́ni bá wa rẹ́rìn-ín, ó yà wá lẹ́nu gan-an ni. La bá yáa gbé ìrẹsì kékeré díẹ̀ tó ti tutù síwájú Spatzi, ó sì dà bíi pé ìyẹn tẹ́ ẹ lọ́rùn!
Bá a ṣe ń tọ́jú ẹyẹ kékeré tá a fẹ́ràn bí ojú yìí jẹ́ ká rántí ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.” Jésù wá fi kún un fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29-31.
Ó mà dùn mọ́ni nínú o, pé Jèhófà ń rí gbogbo ìnira wa kò sì gbàgbé ìfaradà wa. (Aísáyà 63:9; Hébérù 6:10) Dájúdájú, ìyọ́nú tá a ní fún ẹyẹ kékeré yìí kò tó nǹkan lára ìfẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní fún gbogbo àwọn tó ń sìn ín!—Ẹnì kan ló kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà míì, èèyàn lè kárùn téèyàn bá ń tọ́jú ẹyẹ tára ẹ̀ ò yá tàbí tó ṣèṣe, ó sì lè máà bá òfin àdúgbò yẹn mu.