Mo Jẹ́ Aláàbọ̀ Ara, Síbẹ̀ Mi Ò Juwọ́ Sílẹ̀
Mo Jẹ́ Aláàbọ̀ Ara, Síbẹ̀ Mi Ò Juwọ́ Sílẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí Kouamé NʹGuessan ṣe sọ ọ́
Èmi àti ẹnì kejì mi ń tiraka láti ti kẹ̀kẹ́ wa gorí òkè míì. Ìyẹn sì jẹ́ nínú oṣù November, ọdún 2002 nígbà tí ogun abẹ́lé ṣì ń jà lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Ivory Coast, nílẹ̀ Áfíríkà. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ewu ló wà lójú ọ̀nà àdádó yìí. Àwọn ọlọ́pàá tó ń yẹ èrò tó ń lọ tó ń bọ̀ wò sì tún wà níwájú níbi tá a máa gbà kọjá. Kí ló fà á gan-an tó jẹ́ pé àkókò rògbòdìyàn yìí ni mò ń rin irú ìrìn àjò tó léwu bẹ́ẹ̀ yẹn ná?
ỌDÚN 1978 ni wọ́n bí mi, mo sì ní àìlera kan tó jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ló ń lágbára sí i. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé mi ò gbọ́ràn dáadáa, ẹsẹ̀ mi méjèèjì sì máa ń ro mí goorogo. Bí mo ti ń dàgbà, àwọn èèyàn mi ò fi bẹ́ẹ̀ kà mí kún, wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ pé ẹsẹ̀ mi ò wúlò, ìdọ̀tí sì ti rọ dí mi létí. Àwọn àgbà máa ń wò mí tìkà-tẹ̀gbin, àwọn ọmọdé sì máa ń hó lé mi lórí pé arọ àti agésẹ̀ ni mí.
Mo bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, kí sì ni mo bẹ̀rẹ̀ sí báyìí, ńṣe làwọn tá a jọ wà ní kíláàsì àtàwọn olùkọ́ bẹ̀rẹ̀ sí bú mọ́ mi. Nígbà míì, á ṣe mí bíi pé kí ilẹ̀ lanu kó gbé mi mì. Báwọn èèyàn bá sì ti rí i pé ẹ̀rù ń bà mí báyìí, ńṣe ni wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Ìgbà tí mo bá ń relé ìwé nìkan ṣoṣo ni mo máa ń kúrò nílé.
Ìbéèrè tí mo máa ń bi ara mi ni pé, ‘Kí ló fa àìlera yìí o?’ Màmá mi sọ pé oògùn tẹ́nì kan sà sí mi ló kó àìlera náà ràn mí. Nígbà míì, tí mo bá ráwọn tó ní àìlera bíi tèmi, mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣó wá túmọ̀ sí pé wọ́n ń sà sí òun náà ni?’
Lọ́dún 1992, ìgúnpá mi méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí ro mí goorogo. Lẹ́yìn tí ìrora náà mọ́wọ́ dúró, apá mi méjèèjì ò ṣeé nà mọ́. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ojú mi òsì ò ríran mọ́. Àwọn òbí mi gbé mi káàkiri ọ̀dọ̀ àwọn adáhunṣe, àmọ́ a ò rójútùú ọ̀rọ̀ náà. Àìlera náà ṣáà ń pọ̀ sí i ni ṣáá, mo sì ní láti fi ilé ìwé sílẹ̀ nítorí ẹ̀.
Mò Ń Wá Bí Ìṣòro Mi Á Ṣe Yanjú
Ọmọ kíláàsì wa kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni kí n bóun ká lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn. Abọgibọ̀pẹ̀ ni wá nílé tiwa; àmọ́, fún odindi ọdún kan ni mo fi ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. a Mi ò rí ohun tó pọ̀ kọ́ nípa Bíbélì, nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí kọminú pé bóyá ni ètò ẹ̀sìn lóore kankan tó lè ṣèèyàn.
Àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn kan wà tó máa ń já mi láyà, pàápàá ẹ̀kọ́ iná ọ̀rún àpáàdì. Mi ò rò pé mo burú débi tí Ọlọ́run á fi máa dá mi lóró títí ayérayé. Bẹ́ẹ̀ sì tún rèé, mi ò ronú pé mo dáa débi tí màá fi lè lọ máa gbé títí ayérayé lọ́run.
Níwọ̀n bí mi ò ti rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn sáwọn ìbéèrè mí, ẹ̀sìn ò fi bẹ́ẹ̀ wù mí mọ́.Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ní kí n wá síbi ìpàdé wò-ó-sàn kan ní ìlú Abíjan tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè Ivory Coast, tó fi nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà jìn sí abúlé wa, ìyẹn Vavoua. Ká tó gbéra, mo sọ fáwọn mélòó kan tó jẹ́ igi-lẹ́yìn-ọgbà ṣọ́ọ̀ṣì pé owó tí mo ní lọ́wọ́ ò tó owó ìwọlé kò sì ní tó mi jẹun. Wọ́n dá mi lọ́kàn le pé àwọn èèyàn á bójú tó mi ní Abíjan, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò mà rí bí wọ́n ṣe wí o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó tó ọ̀kẹ́ méjì [40,000] sí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] ló yí mi ká, síbẹ̀ kò yàtọ̀ sí pé mo dá wà, mo sì wá rẹ̀wẹ̀sì. Kò tiẹ̀ sẹ́ni tó sú já mi.
Ìgbà tí mo fi máa padà dé abúlé Vavoua, àìlera mi ti pọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, mi ò sì tún wá mọ èwo gan-an ni ṣíṣe mọ́. Àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ládùúgbò sọ fún mi pé nítorí pé mi ò nígbàgbọ́ ni Ọlọ́run ò ṣe wò mí sàn. Lẹ́yìn ìyẹn ni mo jáwọ́ pátápátá kúrò nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn.
Mo Rí Ìtùnú Gbà Látinú Ìwé Mímọ́
Lọ́dún 1996, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì bá Ẹlẹ́rìí kankan sọ̀rọ̀ rí, mò ń fetí kọ́ ìjíròrò àtọkànwá tó ń wáyé láàárín òun àti bùrọ̀dá mi. Ẹ̀gbọ́n mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ń sọ, àmọ́ èmi nífẹ̀ẹ́ sí i. Gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tí Ẹlẹ́rìí yẹn ń sọ kàn ń wọ̀ mí lákínyẹmí ara ni.
Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé àìgbọràn ọkùnrin àkọ́kọ́ ló kó ẹ̀ṣẹ̀ ran aráyé. Ìwà ọ̀tẹ̀ yẹn ló yọrí sí àìpé àti ikú fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn. Àmọ́, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ bí ìràpadà ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà ká sì lè gbádùn ìyè ayérayé. (Róòmù 3:23; 5:12, 17-19) Síwájú sí i, Ẹlẹ́rìí náà fi hàn látinú Bíbélì pé Jèhófà Ọlọ́run máa tó tipasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè á sì mú ẹ̀ṣẹ̀ àti làásìgbò tó ń fà kúrò.—Aísáyà 33:24; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:3, 4.
Ẹ̀kọ́ tó lọ́gbọ́n nínú tí Bíbélì fi kọ́ni wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. Ẹlẹ́rìí ọ̀hún, tí mo wá mọ̀ sí Robert, ṣètò láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Láàárín oṣù díẹ̀, ẹ̀kọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ látinú Bíbélì mú kí èmi náà tóótun láti máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Kì í wá ṣe ohun tó rọrùn fún mi ṣá o, níwọ̀n bí mo ti ní láti borí ẹ̀rù tó máa ń bà mí bí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn.
Ìṣòro Ń Yọjú
Kò tẹ́ àwọn èèyàn mi lọ́rùn pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ẹ̀gbọ́n mi bàa lè mú mi bínú, á wá sí yàrá mi lálẹ́ á sì máa mu sìgá níbẹ̀. Bí ilẹ̀ bá mọ́, orí á máa fọ́ mi, á sì ṣe bí ẹní pó fẹ́ rẹ̀ mí. Ìṣòro míì tún ni ti oúnjẹ tá a máa ń jẹ. Ògbójú ọdẹ ni bàbá mi, ẹran ìgbẹ́ tó ń pa wálé sì sábà máa ń wà nínú oúnjẹ wa. Mo ṣàlàyé fún un pé Bíbélì ní ká má máa jẹ ẹran tí wọn kò dúńbú. (Ìṣe 15:28, 29) Síbẹ̀, ó kọ̀ láti máa dúńbú ẹran tó bá pa. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àsán ìrẹsì ni màmá máa ń bù fún mi, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ni n kì í róúnjẹ tó tó jẹ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òdì kejì ìlú lọ́hùn-ún ni Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Vavoua wà, mi ò jẹ́ kí ọ̀nà tó jìn tàbí ojú ọjọ́ tí ò dáa dí mi lọ́wọ́ àtimáa lọ sípàdé. Mo ṣèrìbọmi lóṣù September, ọdún 1997, ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tó wáyé lórílẹ̀-èdè Ivory Coast. Nígbà tó ṣe, mo túbọ̀ ń kópa sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni débi tí mo fi lè di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn orúkọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún tó wà láàárín wa.
Àwọn Ìṣòro Míì Tún Yọjú
Rúkèrúdò ìṣèlú tó wáyé yọrí sí ogun abẹ́lé nígbà tó di oṣù September, ọdún 2002. Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan, àwọn ọmọ ogun ìjọba ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ìlú Vavoua. Ẹ̀rù ikú ń ba àwọn èèyàn kan, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí náà wọ́n fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Lọ́jọ́ márùn-ún lẹ́yìn yẹn, àwọn sójà gba ìlú, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sì fòfin de gbogbo wọlé wọ̀de tó ń lọ láàárín ìlú. Ìyẹn gan-an ló kúkú wá fà á tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ṣẹ́ kù nílùú Vavoua fi wábi sá gbà, tó fi mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó kù.
Níwọ̀n bí kò sì ti sí ọkọ̀ kankan nígboro, ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ làwọn èèyàn máa ń rìn kí wọ́n tó lè dé àwọn ìlú tó múlé gbè wọ́n. Mi ò lè rin
ìrìn tó jìn tóyẹn, nítorí náà èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó kù ní ìlú Vavoua. Mò ń báṣẹ́ ìwàásù nìṣó, mò ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ, a sì rí lára àwọn ará àdúgbò náà tó ń wá sípàdé.Àpéjọ Kan Tí Mo Sapá Láti Lọ
Ètò ti wà nílẹ̀ láti ṣe àpéjọ àkànṣe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú oṣù November, ní ìlú Daloa. Mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì sọ fún un pé màá fẹ́ láti lọ sí àpéjọ náà. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé Ẹlẹ́rìí kan tó ti sá kúrò nílùú tẹ́lẹ̀ ṣàdédé padà wálé. Mo bi í bóyá ó máa lè fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ gbé mi lọ sí àpéjọ náà, èyí tó jìn tó nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà. Ó gbà láìjanpata, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun náà ní àìlera àra tó le gan-an.
Ìlú kan gógó, nítorí náà, kò dà bíi pé irú ìgbà yẹn ló yẹ kéèyàn lọ sí ìrìn àjò bẹ́ẹ̀. Kò sí ọkọ̀ kankan tó gbọ́dọ̀ ná ìlú Vavoua sí ìlú Daloa. Àwọn sójà tó ń bára wọn jagun lè fura sí arìnrìn-àjò tí wọn ò mọ̀ rí, kí wọ́n sì fìbọn arọ̀jò ọta pa á bí wọ́n bá rò pé ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n ń bá jagun ni. Láìkọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí, lówùúrọ̀ ọjọ́ Sátidé, November 9, 2002, a gbéra nílùú Vavoua, a sì mórí lé ìlú Daloa, à ń gun kẹ̀kẹ́ lọ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí.
Kò sì pẹ́ tá a fi dé ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ibi táwọn sójà ti ń yẹ àwọn èèyàn tó ń lọ tó ń bọ̀ wò. Wọ́n yẹ̀ wá wò látòkè délẹ̀, kí wọ́n tó jẹ́ ká máa lọ. Ọ̀nà tá à ń wí yìí jìn, ìrìn àjò náà sì nira. Nígbà míì, a óò kọ́kọ́ ti kẹ̀kẹ́ lọ sí téńté orí òkè, bá a bá ti débẹ̀ tán, àwa méjèèjì á jókòó sórí ẹ̀ a ó sì máa da fíríì bọ̀ nísàlẹ̀.
Nígbà tó ṣe, a rí ẹnì kan tóun náà ń gun kẹ̀kẹ́, tó sọ pé òun á ràn wá lọ́wọ́. Ẹ̀yìn kẹ̀kẹ́ onítọ̀hún ni mo jókòó sí. Bí ọ̀rẹ́ wa tó jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú yìí ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, mo kúkú lo àǹfààní yẹn láti bá a sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Mo ṣàlàyé pé ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run wà àti pé ó máa tó mú àlàáfíà tí kò lópin wá sórí ilẹ̀ ayé. Kàyééfì gbáà lohun tí mo sọ fún un jẹ́, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí da ìbéèrè bò mí. Nígbà tá a dé ìlú Daloa, ó ra oúnjẹ fún wa ó sì ṣèlérí pé òun á wá sí àpéjọ àkanṣe náà láàárọ̀ ọjọ́ kejì.
Ilẹ̀ ti ń ṣú lọ ká tó wọ ìlú Daloa, ó ti rẹ̀ wá ṣùgbọ́n inú wa dùn pé a ti débi à ń rè. Ìrìn-àjò wákàtí mẹ́sàn-án tá a rìn náà ò rọrùn fún wa rárá. Ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó ń gbé níbẹ̀ fọ̀yàyà kí wa káàbọ̀, wọ́n sì dábàá pé ká dúró sọ́dọ̀ àwọn títí tí rúkèrúdò àwọn olóṣèlú á fi rọlẹ̀ díẹ̀. Ó dùn wá pé, wọ́n ní láti wọ́gi lé àpéjọ náà nítorí rúkèrúdò ìṣèlú. Àmọ́ ṣá o, ìrìn àjò náà ò já sásán. Ó mú kí n ní àǹfààní sí i láti máa sin àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ní ìlú Daloa.
Mò Ń Gbádùn Ìbùkún Tó Pọ̀ Nítorí Mi Ò Juwọ́ Sílẹ̀
Àǹfààní tí mo ní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí ìranṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún ń mú kí ọwọ́ mi dí fúnṣẹ́ nínú ìjọ kan nílùú Daloa. Mo tún máa ń bójú tó àwọn nǹkan tó bá ń fẹ́ àtúnṣe ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Daloa. Kí n bàa lè gbọ́ bùkátà àtijẹ àtimu, mo máa ń figi gbẹ́ labalábá téèyàn lè lò bí ohun ọ̀ṣọ́ mo sì tún máa ń báwọn èèyàn fi ọ̀dà kọ nǹkan.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún ló jẹ́ pé àtilọ sílé ìwé nìkan ló máa ń gbé mi kúrò nílé, àmọ́ látìgbà yẹn wá, mo ti rin ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ níbi tí mo ti ń wá àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ fún òtítọ́, tí wọ́n fẹ́ mọ ìdí tá a fi ń ṣàìsàn tá a sì ń jìyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi náà ń dúró de ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run á mú gbogbo àìlera kúrò pátápátá, mò ń bá a nìṣó láti máa wàásù ìhìn rere tó ń tuni nínú fáwọn ará Ivory Coast, nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lára ohun táwọn abọgibọ̀pẹ̀ gbà gbọ́ ni pé báwọn ẹranko ṣe lẹ́mìí, bẹ́ẹ̀ náà lẹ̀mí wà nínú àwọn ewéko, àtàwọn ìṣẹ̀dá míì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìgbà tá à ń lọ sí àpéjọ nílùú Daloa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Mò ń bójú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ nílùú Daloa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí n lè rówó gbọ́ bùkátà àtijẹ àtimu, mo máa ń figi gbẹ́ labalábá téèyàn lè ló bí ohun ọ̀ṣọ́