Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Ibo Ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Yìí Ti Wáyé?
1. Ìlú wo ní ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé?
AMỌ̀NÀ: Ka Ìṣe 2:1-13.
Fa ilà yípo ìdáhùn rẹ nínú àwòrán ilẹ̀.
Áténì
Jerúsálẹ́mù
Bábílónì
◼ Ibo lọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti wá?
․․․․․
◼ Kí nìdí táwọn kan fi fàwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣẹlẹ́yà?
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àtèyí tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9, báwo ni wọ́n sì ṣe jọra?
Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 14 Kí làwọn kan tó ní ìtara fún Ọlọ́run ò ní? Róòmù 10:․․․
OJÚ ÌWÉ 15 Ta ló yẹ ká ṣègbọràn sí? Ìṣe 5:․․․
Kí Lo Mọ̀ Nípa Ótíníẹ́lì Onídàájọ́?
Ka Àwọn Onídàájọ́ 3:7-11. Wá dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí.
2. ․․․․․
Ẹ̀yà wo ló ti wá?
AMỌ̀NÀ: Ka Jóṣúà 15:17, 20.
3. ․․․․․
Ọwọ́ alákòóso wo ló ti dá Ísírẹ́lì nídè?
4. ․․․․․
Bẹ́ẹ̀ ni tàbí rárá? Ó gbé láyé ṣáájú Mósè.
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Àpẹẹrẹ rere wo ni Kálébù tó jẹ́ èèyàn òbí Ótíníẹ́lì fi lélẹ̀?
AMỌ̀NÀ: Ka Númérì 14:6-9. Kọ orúkọ ìbátan ẹ kan tó o gba tìẹ sílẹ̀, kó o sì ṣàlàyé nǹkan tó wú ẹ lórí nípa ẹ̀.
ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1. Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 2:5.
◼ Gálílì.—Ìṣe 2:7.
◼ Wọ́n rò pé wọ́n ti mutí yó.—Ìṣe 2:13.
2. Júdà.—Jóṣúà 15:17, 20.
3. Kuṣani-ríṣátáímù.—Àwọn Onídàájọ́ 3:8.
4. Rárá.