Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àìkanisí

Àìkanisí

Àìkanisí

“Ní ọdún àkọ́kọ́ tí mo lò níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Sípéènì, ńṣe làwọn ọmọléèwé wa ń wẹ ẹnu sí mi lára, torí pé èmi ni mo kúrú jù láàárín wọn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mò ń sunkún relé.” —Jennifer, ọmọbìnrin kan táwọn òbí rẹ̀ wá láti erékùṣù Philippines.

“Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ilé ìwé wa, àwọn ọmọ aláwọ̀ funfun tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Mo mọ̀ pé wọ́n fẹ́ tọ́ mi níjà ni. Mi ò ṣáà dá sí wọn, àmọ́ yẹ̀yẹ́ yẹn ń dùn mí gan-an, mo sì wá dà bí aláìlárá.”—Timothy, ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Ọmọ ọdún méje ni mí nígbà tí ìjà fi wáyé láàárín àwọn Íbò àtàwọn Haúsá. Ìyẹn mú kí n kórìíra àwọn Haúsá. Mo sì ń fi ọmọ Haúsá kan tá a jọ wà ní kíláàsì ṣe yẹ̀yẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rẹ́ ni wá tẹ́lẹ̀.”—John, ọmọ Íbò.

“Nígbà témi àti èkejì mi tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn aládùúgbò wa, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ládùúgbò náà ní káwọn ọmọdé máa tẹ̀ lé wa kí wọ́n sì máa sọ wá lókùúta, torí pé ó fẹ́ ká kúrò nílùú náà.”—Olga.

ṢÉ Ẹ̀TANÚ ti mú káwọn tí kì í fẹ́ báni lò lọ́gbọọgba fàbùkù kàn ẹ́ rí? Bóyá nítorí pé àwọ̀ rẹ yàtọ̀ sí tiwọn, tí ẹ̀sìn yín ò sì pa pọ̀. Tàbí nítorí pé o kò rí já jẹ bíi tiwọn, o kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn, ọjọ́ orí yín sì yàtọ̀ síra. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀rù máa ń ba àwọn tí ẹ̀tanú ń mú kí wọ́n dẹ́yẹ sí pé wọ́n á tún hùwà àìbánilò-lọ́gbọọgba míì sáwọn. Bí wọ́n bá ń kọjá níbi táwọn èèyàn wà, bí wọ́n bá lọ sílé ìtajà, bí wọ́n bá lọ kàwé níbòmíì, tàbí tí wọ́n bá lọ síbi àpèjẹ, ọkàn wọn kì í balẹ̀.

Ní àfikún sí ìyẹn, ó lè ṣòro fáwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú sí tí wọn ò sì bá lò lọ́gbọọgba láti ríṣẹ́, tàbí kí wọ́n máà rí ìtọ́jú tàbí ẹ̀kọ́ ìwé tó jíire gbà, kí wọ́n máà rọ́wọ́ mú láwùjọ, kí wọ́n sì máa fẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. Báwọn aláṣẹ ò bá sì ṣe nǹkan kan nípa àìbánilò-lọ́gbọọgba, ó lè yọrí sí ìpẹ̀yàrun. Irú ìpẹ̀yàrun kan bẹ́ẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ wáyé nínú ìwé Ẹ́sítérì tó wà nínú Bíbélì. Wàá rí ọṣẹ́ tí ìkórìíra àti ẹ̀tanú máa ń ṣe nínú ìwé Bíbélì yìí.—Ẹ́sítérì 3:5, 6.

Bí òfin ò bá tiẹ̀ fàyè gba àìbánilò-lọ́gbọọgba, ẹ̀tanú ṣì lè máa bá a nìṣó. Ẹnì kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ Ọ̀gá Àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn sọ pé: “Ní ọgọ́ta [60] ọdún lẹ́yìn ìfilọ́lẹ̀ Ìkéde Kárí Ayé fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn . . . , kò tiẹ̀ tíì jọ pé aráyé á lè fi ìlànà àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ àti ìbánilò-lọ́gbọọgba ṣèwà hù.” Ìyẹn ò fini lọ́kàn balẹ̀ torí pé báwọn èèyàn ṣe ń lọ gbé nílùú míì táwọn tó ń wá ibi ìsádi sì ń wábi tí wọ́n máa forí pa mọ́ sí ti mú kí iye àwọn tó ń gbé lọ́pọ̀ ilẹ̀ máa búrẹ́kẹ́ sí i.

Ṣó máa ṣeé ṣe fún aráyé láti ṣera wọn lọ́kan? Ṣé aráyé lè yanjú ọ̀ràn ẹ̀tanú àti àìbánilò-lọ́gbọọgba? Àpilẹ̀kọ tó kàn á dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.