Àwọn Ìṣòro Wo Ló Ń Bá Àwọn Ọ̀dọ́ Fínra?
Àwọn Ìṣòro Wo Ló Ń Bá Àwọn Ọ̀dọ́ Fínra?
Ṣé ìṣòro tó ń bá àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí fínra le ju tàwọn ọ̀dọ́ àtijọ́ lọ? Kí lèrò ẹ? Bó o bá gbà pé ìṣòro àwọn ọ̀dọ́ àtijọ́ ló le jù, o lè máa ronú pé àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí ń jẹ̀gbádùn ju àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ èyíkéyìí tó tíì gbé ayé yìí rí.
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n ti ní oògùn tí wọ́n lè fi wo ọ̀pọ̀ àrùn tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀rí ó lè sọ àwọn ọ̀dọ́ di aláàbọ̀ ara kó sì tún pa wọ́n. Nítorí ìtẹ̀síwájú tó ti bá ìmọ̀ iṣẹ́ èrọ, àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ àtàwọn ohun ìṣeré ọmọdé téèyàn ò jẹ́ ronú kàn tẹ́lẹ̀, ti wà báyìí. Àtúntò ètò ọrọ̀ ajé ti sọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìdílé tó tòṣì di ọlọ́rọ̀. Kódà, àìlóǹkà àwọn òbí tí àtijẹ àtimu nira fún, tí wọn ò sì reléèwé, ń ṣiṣẹ́ kára kí ọ̀ràn àwọn ọmọ wọn má bàa rí bíi tiwọn.
Ó dájú nígbà náà pé, ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí ní. Àmọ́ àwọn ìṣòro gígadabú kan wà táwọn náà ń fojú winá rẹ̀. Ọ̀kan lára ohun tó fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé aráyé ti ń gbé ní àkókò kan tí Bíbélì pè ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Jésù Kristi sọ lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé jákèjádò ayé, ipò nǹkan máa ṣàdédé yí pa dà lágbo òṣèlú, láwùjọ àti nínú ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gbé ìgbé ayé wọn. (Mátíù 24:7, 8) Bíbélì tún pe àkókò yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó sì ṣàlàyé pé àwọn nǹkan tá máa ṣẹlẹ̀ láwùjọ á mú kí àkókò yìí jẹ́ èyí tó “nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìṣòro gígadabú tó ń bá àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí fínra.
Ìṣòro Àkọ́kọ́
Wọ́n Túbọ̀ Ń Dá Wà
Àwọn ilé iṣẹ́ fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn ìwé ìròyìn máa ń mú kó dà bíi pé àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń wà lágbo àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ṣe kékeré, tí wọ́n jọ kàwé yọrí, tí àjọṣe wọn sì ń bá a nìṣó títí tí wọ́n fi dàgbà. Àmọ́, ọ̀rọ̀ kì í sábàá rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn.
Àwọn olùṣèwádìí, Barbara Schneider àti David Stevenson, tí wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀
wá wọn lẹ́nu wò, rí i pé “ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ làwọn ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ àtàwọn alábàáṣeré wọn míì jọ wà pẹ́.” Bí Schneider àti Stevenson ṣe sọ, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ “ò mọ béèyàn ṣe máa ń báni dọ́rẹ̀ẹ́, torí náà wọn ò ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó máa rọrùn fún wọn láti sọ ìṣòro wọn fún tàbí tí wọ́n á jọ máa fọ̀rọ̀ wérọ̀.”Ó sì jọ pé àwọn ọ̀dọ́ tó mọ béèyàn ṣe ń báni dọ́rẹ̀ẹ́, kì í lè lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìwádìí délé dóko kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé bá a bá dá àkókò tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún máa ń lò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn sí ọ̀nà mẹ́wàá, ìdá kan lára ẹ̀ làwọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn fi ń ríra sójú, àmọ́ nǹkan bí ìdá méjì lára ẹ̀ ni wọ́n fi ń dá wà. Èyí fi hàn pé àkókò tí wọ́n fi ń dá wà ju èyí tí wọ́n fi ń wà pẹ̀lú ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ. Wọ́n ń dá jẹun, wọ́n ń dá rìnrìn-àjò, wọ́n ń dá gbádùn ara wọn.
Àwọn ohun ìṣeré tó ń lo iná tàbí bátìrì tún wà lára ohun tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ máa dá wà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2006, ìwé ìròyìn Time sọ pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́jọ sí méjìdínlógún, ń lo nǹkan bíi wákàtí mẹ́fà ààbọ̀ lóòjọ́ nídìí tẹlifíṣọ̀n, wọ́n á ki ohun tí wọ́n fi ń gbọ́ orin bọ etí, tàbí kí ọwọ́ wọn máa jó lọ jó bọ̀ lórí bọ́tìnnì tí wọ́n fi ń gbá géèmù tàbí kí wọ́n wà nídìí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. a
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣàwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí lá kọ́kọ́ máa lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti gbádùn orin tàbí kí wọ́n ṣeré. (Mátíù 11:16, 17) Síbẹ̀, ewu ńlá ló wà nínú ọ̀pọ̀ àkókò táwọn ọ̀dọ́ fi ń dá wà nídìí àwọn ohun ìṣeré tó ń lo iná tàbí bátìrì dípò tí wọn ì bá fi máa ní ìfararora pẹ̀lú àwọn míì nínú ìdílé. Àwọn olùṣèwádìí, Schneider àti Stevenson, sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣàròyé pé àwọn ò dá ara àwọn lójú, àwọn kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, ohun táwọn ń ṣe kì í fi bẹ́ẹ̀ dùn mọ́ àwọn, àti pé nǹkan máa ń sú àwọn bí àwọn bá dá wà.”
Ìṣòro Kejì
Wọ́n Ń Fi Ìbálòpọ̀ Lọ̀ Wọ́n
Wọ́n máa ń fi ìbálòpọ̀ lọ àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ogún ọdún àtàwọn tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Nathan, ọ̀dọ́ kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí mo mọ̀ níléèwé ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìbálòpọ̀ látìgbà tí wọ́n ti wà láàárín ọmọ ọdún méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.” Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Vinbay, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, sọ pé ó wọ́pọ̀ níléèwé pé káwọn ọ̀dọ́ máa bá ẹni tó bá ṣáà ti wù wọ́n sùn. Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣàjèjì sí wọn bí ẹnì kan bá sọ pé òun ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.” Ana, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ojúgbà mi pé kí wọ́n máa bá ẹni tó bá wù wọ́n sùn, bó o bá sì sọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo pé o ò ṣe, ìyẹn ò ní kí wọ́n fi ẹ́ sílẹ̀. Wọ́n á máa fi lọ̀ ẹ́ ṣáá, àfi kó o máa sọ fún wọn pé o kò ṣe.”
Àwọn olùṣèwádìí kan lórílẹ̀-èdè United Kingdom fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹgbẹ̀rún kan àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọmọ ọdún méjìlá sí ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, tí wọ́n wá láti ibi tó yàtọ̀ síra. Wọ́n rí i pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára wọn tó máa ń lọ́wọ́ nínú oríṣi irú ìbálòpọ̀ kan déédéé. Bá a bá sì dá àwọn ọmọ tó ń bára wọn lò pọ̀ yìí sọ́nà mẹ́wàá, ó ju méjì lọ nínú wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá péré! Dókítà
Dylan Griffiths, tó ṣe kòkáárí ìwádìí náà sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ilé, ẹ̀kọ́ Ẹ̀sìn àti ìtọ́ni láwọn ibòmíì táwọn ọ̀dọ́ ti lè gbẹ̀kọ́ tí ì bá gbà wọ́n lọ́wọ́ ìṣòro yìí ò sí mọ́, ìyà ẹ̀ sì ń jẹ wọ́n.”Ṣóòótọ́ ni pé àwọn ọ̀dọ́ tó ń ní ìbálòpọ̀ ń ‘jìyà’ ẹ̀? Nínú ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde lọ́dún 2003, àwọn olùṣèwádìí, Rector, Noyes àti Johnson rí i pé ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ ló ń fa ìsoríkọ́, èyí tó mú káwọn ọ̀dọ́ tó ń pọ̀ sí i máa fẹ́ láti gbẹ̀mí ara wọn. Wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, tí gbogbo wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ààbọ̀ [6,500], wọ́n sì rí i pé “ó ṣeé ṣe káwọn ọmọbìnrin tó ń ní ìbálòpọ̀ máa ní ìsoríkọ́ ní ìlọ́po mẹ́ta ju àwọn ọmọbìnrin tí kì í ní ìbálòpọ̀.” Ní tàwọn ọmọkùnrin sì rèé, “ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ máa ní ìsoríkọ́ ní ìlọ́po méjì ju àwọn tí kì í ní ìbálòpọ̀.”
Ìṣòro Kẹta
Àwọn Ìdílé Tó Ń Pínyà
Ńṣe ni ipò táwọn ọ̀dọ́ bára wọn nínú ìdílé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ń yára yí pa dà, ìwà ọmọlúwàbí sì ń dàwátì. Ìwé kan tó sọ nípa àwọn ọ̀dọ́ tí kò ní alábàáwí, ìyẹn The Ambitious Generation—America’s Teenagers, Motivated but Directionless, sọ pé: “Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, àwọn ìyípadà mélòó kan ti wà nínú báwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i, èyí sì ti nípa lórí ìgbé ayé àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Amẹ́ríkà ò bímọ púpọ̀ mọ́, torí náà, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà kì í ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tó pọ̀. Bí iye àwọn tó ń kọra wọn sílẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i, ó wá di pé kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ máa lo apá kan lára ìgbà ọmọdé wọn lọ́dọ̀ bàbá tàbí màmá wọn nìkan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àwọn màmá tọ́mọ wọn ò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún ló ń ṣiṣẹ́, torí náà, agbára káká ni àgbàlagbà tó lè bójú tó ọmọ fi máa ń wà nílé.”
Yálà àwọn ọmọ ń gbé pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn òbí wọn tàbí wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn méjèèjì, ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń rí ara wọn bí àjèjì sírú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ wọn jù lọ. Ìwádìí ọlọ́dún mélòó kan tó dá lórí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] àwọn ọmọ tó ti lé lọ́dún mẹ́tàlá fi hàn pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ló gbà
pé àwọn òbí àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn, wọ́n sì kó àwọn mọ́ra. Síbẹ̀, “ìdámẹ́ta péré lára wọn ló gbà pé ọ̀ràn àwọn jẹ àwọn òbí yìí lógún, wọ́n sì máa ń ran àwọn lọ́wọ́ nígbà táwọn bá níṣòro.” Ìròyìn náà ń bá a nìṣó pé: “Fún ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, ohun tí wọ́n rí bí ìṣòro ni pé kí òbí má lè dá sí ìṣòro àwọn kó sì ran àwọn lọ́wọ́.”Lórílẹ̀-èdè Japan táwọn ìdílé ti máa ń wà pa pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀ tẹ́lẹ̀, ìlépa ọrọ̀ ti ń pín ìdílé níyà. Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Yuko Kawanishi, sọ pé: “Ìgbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í dáṣà bíbímọ rẹpẹtẹ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì ni wọ́n bí ìran ọ̀pọ̀ lára àwọn tó jẹ́ òbí fáwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún lóde òní. Kí wọ́n máa lépa ọrọ̀ àti bí wọ́n á ṣe jèrè rẹpẹtẹ ni wọ́n sì lajú sí nígbà yẹn.” Kí làwọn òbí náà wá rí fi kọ́ àwọn ọmọ wọn? Kawanishi sọ pé: “Ohun tó jẹ ọ̀pọ̀ òbí lógún jù lọ lóde òní ni báwọn ọmọ wọn á ṣe yege nínú ẹ̀kọ́ wọn.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Báwọn ọmọ wọn bá ṣáà ti kàwé, ipò kejì ni wọ́n fi ohun gbogbo tó kù nínú ilé sí, tàbí kó má tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan lójú wọn.”
Báwo ni bí àwọn òbí ṣe ki àṣejù bọ ojú tí wọ́n fi ń wo ọrọ̀ àti àṣeyọrí nínú ẹ̀kọ́ ìwé ṣe lè nípa lórí àwọn ọ̀dọ́? Lórílẹ̀-èdè Japan, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa kireru, gbólóhùn kan tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ máa ń gbà fara ya nígbà tí iṣẹ́ bá pá wọn lórí. Kawanishi sọ pé: “Bí àwọn ọmọ bá fárígá, ó lè jẹ́ torí pé wọ́n wòye pé ìdílé àwọn ò fìwà ọmọlúwàbí kọ́ àwọn.”
Nǹkan Ń Bọ̀ Wá Dáa
Ó dájú pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1) Àmọ́, yàtọ̀ sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pé àwọn tó ń gbé ní àkókò yìí á máa dojú kọ ìṣòro tí ń pọ̀ sí i, ó tún sọ ọ̀pọ̀ ohun mìíràn fún wa.
Bíbélì pèsè ìmọ̀ràn tó wúlò nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú kí ìgbé ayé wọn sunwọ̀n sí i. Ó wu Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Òǹkọ̀wé Bíbélì, gan-an pé kó kọ́ àwọn ọ̀dọ́ ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà kojú àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra. (Òwe 2:1-6) Ó fẹ́ kí wọ́n gbádùn ìgbésí ayé tó dáa. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lè fún “àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà,” kó sì fún “ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.” (Òwe 1:4) Ṣàgbéyẹ̀wò báwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní báyìí, ó ti wọ́pọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè Japan pé káwọn ọ̀dọ́ máa dá wà nínú yàrá wọn débi tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní hikikomori tó túmọ̀ sí adéjúmọ́lé. Àwọn kan fojú bù ú pé àwọn hikikomori tó wà lórílẹ̀-èdè Japan báyìí á tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] sí àádọ́ta ọ̀kẹ́ [1,000,000].
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe sọ, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọbìnrin tó ń ní ìbálòpọ̀ máa ní ìsoríkọ́ ní ìlọ́po mẹ́ta ju àwọn ọmọbìnrin tí kì í ní ìbálòpọ̀
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Dídọ́gbẹ́ Síra Ẹni Lára
Ìròyìn kan tí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbé jáde lọ́dún 2006 fi hàn pé láàárín ọdún kan ṣoṣo, àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kànlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n ń lo oògùn olóró ti di ìlọ́po méjì. Ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [65,000] làwọn ọ̀dọ́ tó sọ pé àwọn ti lo oògùn olóró rí. Ní orílẹ̀-èdè Netherlands, ó ju méjì lọ nínú àwọn ọ̀dọ́ mẹ́wàá tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìndínlógún sí mẹ́rìnlélógún tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n máà mutí tàbí tí àìsàn tó jẹ mọ́ ọtí mímu ń yọ lẹ́nu.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tún ń fi ẹ̀hónú wọn hàn lọ́nà míì tó pabanbarì. Wọ́n á fi nǹkan géra wọn, wọ́n á bu ara wọn jẹ, tàbí kí wọ́n fi iná jó ara wọn. Àwọn olùṣèwádìí, Len Austin àti Julie Kortum, sọ pé: “Wọ́n fojú bù ú pé mílíọ̀nù mẹ́ta àwọn ará Amẹ́ríkà ló ń ṣera wọn léṣe, bá a bá sì kó igba [200] ọ̀dọ́ jọ, ọ̀kan nínú wọn ló ń dọ́gbẹ́ tó kàmàmà síra ẹ̀ lára.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kò ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n lè finú hàn