Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Di Ọwọ́ Ọ̀tún Ọlọ́run Mú Ṣinṣin

Mo Di Ọwọ́ Ọ̀tún Ọlọ́run Mú Ṣinṣin

Mo Di Ọwọ́ Ọ̀tún Ọlọ́run Mú Ṣinṣin

◼ Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni wọ́n bí Jezreel sí. Ó ní àrùn awọ ara, irú èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀, tí wọ́n ń pè ní congenital lamellar ichthyoses. Àrùn yìí máa ń jẹ́ kí awọ ara rẹ̀ máa bó èépá, kó máa ṣí láwẹ́láwẹ́, kó sì máa dápàáàdì. Jezreel sọ pé: “Èyí máa ń jẹ́ kí ìrísí mi kóni nírìíra, àmọ́ kì í ṣe àrùn tó máa ń ranni.”

Láti kékeré ni Jezreel ti ń gba ìtọ́jú lóríṣiríṣi ilé ìwòsàn. Nígbà tó pé ọmọ ọdún méjì, wọ́n gbé òun nìkan síbi tó pa mọ́ nílé ìwòsàn náà kí kòkòrò àrùn má bàa wọ̀ ọ́ lára. Àmọ́, ìyẹn ò mú kí awọ ara ẹ̀ sunwọ̀n sí i. Wọ́n fún un ní ìtọ́jú tó máa jẹ́ kí ọpọlọ ẹ̀ silé, kó má bàa ka ara ẹ̀ sí ẹni tí kò wúlò.

Àwọn kan rò pé àrùn tó ń ṣe Jezreel lè ran àwọn, torí náà wọ́n máa ń sá fún un. Ìṣòro gbáà lèyí jẹ́ fún un, pàápàá nígbà tó wà lọ́mọdé, tó sì ń fẹ́ láti máa bá àwọn ọmọ míì ṣeré. Ó sọ pé, “Wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì máa ń pè mí láwọn orúkọ bí ‘òkú’ àti ‘àkúdàáyà,’ èyí sì máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́.”

Síbẹ̀, àrùn akónisíta tó ń yọ Jezreel lẹ́nu yìí ti fún un láǹfààní láti sọ fáwọn ẹlòmíì nípa ohun tí Bíbélì sọ pé ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn èèyàn sábà máa ń bí i pé ṣe iná ló jó o lára. Bó bá dáhùn pé kì í ṣe iná, wọ́n á wá bi í pé kí ló fà á tára ẹ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Á ṣàlàyé pé àrùn ló ba awọ ara òun jẹ́, á sì sọ fún wọn pé kò tíì sí oògùn ẹ̀ báyìí.

Lẹ́yìn náà lá wá sọ pé, “Kò sí ìrètí tó dára tó èyí tí mo ní torí pé Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn tó bá ṣègbọràn sí òfin rẹ̀ máa gbé nínú ayé tuntun, níbi tí kò ti ní sí àìsàn àti ìrora.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Bí Jezreel ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣe é yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó sì ń láyọ̀ torí pé lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ti di olùjọsìn Ọlọ́run bíi tiẹ̀.

Jezreel sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé wọ́n bí mi sínú ìdílé Kristẹni, àti pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Kò séyìí tó ń sá fún mi nínú wọn nítorí bí ara mi ṣe rí. Mo ṣèrìbọmi nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], látìgbà náà títí di báyìí, mo ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti sin Ẹlẹ́dàá wa fún ọdún mẹ́rìnlá [14] gbáko.”

Jezreel kò gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà tó ń fúnni níṣìírí, èyí tó wà nínú Aísáyà 41:10, 13, tó kà pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. . . . Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́. Nítorí pé èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”

Bí Jezreel ṣe di ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà mú ṣinṣin kì í jẹ́ kó dààmú nítorí ohun táwọn èèyàn lè máa rò nípa àìlera rẹ̀, ó sì ti ṣeé ṣe fún un láti fara da àwọn ìṣòro tó ń bá àìsàn náà rìn. Òun àti àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn mìíràn ń dúró de ìgbà tí ìlérí àgbàyanu Ọlọ́run máa nímùúṣẹ.