Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Àwọn Òbí Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Àwọn Òbí Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Àwọn Òbí Mi?

Jessica àti àwọn òbí rẹ̀ ń jẹun pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Bí wọ́n tí ń jẹun lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ òbí Jessica sọ fún mọ́mì Jessica pé: “Tiẹ̀ gbọ́ ná, mo mà rí Richard tó ò ń fẹ́ nígbà tá a wà nílé ẹ̀kọ́ gíga.”

Bí fọ́ọ̀kì tí Jessica fi ń jẹun ṣe já bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ nìyẹn. Kò tiẹ̀ rí i gbọ́ pé ẹnikẹ́ni wà tó ń jẹ́ Richard!

“Mọ́mì, àṣé ẹ fẹ́ ẹnì kan kẹ́ ẹ tó fẹ́ Dádì? Ẹ ò tiẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ nípa ẹ̀ rárá!”

BÍI ti Jessica, ǹjẹ́ o ti gbọ́ ohùn kan nípa àwọn òbí ẹ rí tó yà ẹ́ lẹ́nu? Bó bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ó ṣeé ṣe kó o wá máa ronú nípa àwọn nǹkan míì tó ò tíì mọ̀ nípa wọn!

Kí nìdí táwọn nǹkan míì fi wà tó ò mọ̀ nípa àwọn òbí rẹ? Àǹfààní wo ló wà nínú pé kó o mọ̀ wọ́n? Báwo lo sì ṣe lè mọ̀ wọ́n?

Àwọn Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ ṣì Pọ̀

Kí nìdí táwọn nǹkan míì fi wà tó yẹ kó o mọ̀ nípa àwọn òbí rẹ? Nígbà míì, ó lè jẹ́ torí pé ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé jìnnà síra. Jacob a tó ti pé ọmọ ọdún méjìlélógún báyìí sọ pé: “Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni mí nígbà táwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀. Látìgbà yẹn ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni mò ń rí dádì mi lọ́dún. Àwọn nǹkan tó wù mi kí ń mọ̀ nípa wọn pọ̀.”

Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló ti ń báwọn òbí rẹ gbé, kò dájú pé wọ́n á sọ gbogbo nǹkan nípa ara wọn fún ẹ. Kì nìdí? Bó ṣe máa ń rí lára gbogbo wa, àwọn òbí pẹ̀lú máa ń tijú láti sọ àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe. (Róòmù 3:23) Bákan náà, wọ́n lè rò pé báwọn bá sọ àṣìṣe wọn fún ẹ, o lè má bọ̀wọ̀ fáwọn mọ́ tàbí kó o máa rò pé o lè ṣe ohun tó bá wù ẹ́.

Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà torí pé ẹ ò sọ̀rọ̀ débẹ̀ ni wọn ò fi tíì sọ àwọn nǹkan kan fún ẹ nípa ara wọn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Cameron sọ pé: “Ó yani lẹ́nu gan-an pé béèyàn bá tiẹ̀ ti gbé pẹ̀lú àwọn òbí ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, á ṣì ní nǹkan púpọ̀ láti kọ́ nípa wọn!” Ìwọ fúnra rẹ ò ṣe kọ́kọ́ bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀? Gbé àwọn àǹfààní mẹ́rin tó o lè rí nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.

Àǹfààní Kìíní: Ó ṣeé se kí inú àwọn òbí rẹ̀ dùn pé o fẹ́ mọ̀ wọ́n sí i. Ó dájú pé bó o ṣe fi hàn pé ọ̀ràn wọn jẹ ẹ́ lógún máa wú wọn lórí. Èyí lè mú kí wọ́n túbọ̀ máa gba tìẹ rò kí wọ́n sì fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ!Mátíù 7:12.

Àǹfààní Kejì: Wàá lóye ojú táwọn òbí rẹ fi ń wo nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ìgbà kan wà táwọn òbí ẹ ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́? Bóyá ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń ṣọ́wó ná, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ò rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Bó o bá mọ ìdí táwọn òbí rẹ fi ń ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, á jẹ́ kó o lè lóye wọn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Cody sọ pé: “Bí mo ṣe lóye bí àwọn òbí mi ṣe ń ronú máa ń jẹ́ kí n ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ.”—Òwe 15:23.

Àǹfààní Kẹta: Ó lè túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti máa sọ ọ̀rọ̀ ara ẹ fún wọn. Bridgette tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún sọ pé: Ó ṣòro fún mi láti sọ fún Dádì pé mo nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin kan. Àmọ́, nígbà tí mo jàjà sọ fún Dádì, wọ́n wá sọ fún mi bó ṣe rí lára àwọn nígbà tí ìfẹ́ ọmọbìnrin kan kọ́kọ́ kó sí àwọn lórí. Wọ́n tiẹ̀ tún sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ tí wọ́n fi ọmọ tí wọ́n ń fẹ́ sílẹ̀ àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe dùn wọ́n gan-an. Èyí ló mú kí ń máa sọ gbogbo bọ́ràn tèmi náà ṣe rí fún wọn.”

Àǹfààní Kẹrin: O lè rí nǹkan kọ́. Ìrírí táwọn òbí rẹ ti ní lè jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa bójú tó àwọn ìṣòro tó o bá ní. Joshua ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Mo fẹ́ mọ ọgbọ́n táwọn òbí mi ń dá tí wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé wa tó jẹ́ ẹlẹ́ni púpọ̀, tí ohun tá a nílò nípa tara, ti ìmí ẹ̀dùn àti nípa tẹ̀mí ti pọ̀ gan-an. Mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè ṣe mí láǹfààní ni màá rí kọ́ lára wọn.” Bíbélì béèrè pé: “Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́?”—Jóòbù 12:12.

Sapá Láti Mọ̀ Wọ́n

Bó bá wù ẹ́ láti túbọ̀ mọ àwọn òbí rẹ, báwo lo ṣe lè ṣe e? Àwọn àbá kan rèé.

Bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tó wọ̀. Kò pọn dandan kó o máa pè wọ́n jókòó, ó lè jẹ́ ìgbà tẹ́ ẹ kàn ń ṣeré ni wàá sọ̀rọ̀ débẹ̀. Ó lè jẹ́ ìgbà tẹ́ ẹ jọ ń ṣeré ọwọ́dilẹ̀, tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ kan, tẹ́ ẹ jọ ń gbafẹ́, tàbí kó jẹ́ nígbà tẹ́ ẹ jọ wà nínú ọkọ̀. Cody tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo ti ní ìjíròrò tó lárinrin pẹ̀lú àwọn òbí mi nígbà tá a jọ ń rìnrìn àjò. Lóòótọ́, ó rọrùn láti ki ohun tí wọ́n fi ń gbọ́ orín bọ etí tàbí kí n kàn sùn lọ ní tèmi, àmọ́ mo ti kíyè sí i pé àǹfààní pọ̀ níbẹ̀ bí mo bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀!”

Máa béèrè ọ̀rọ̀. Ó dájú pé, bó bá tiẹ̀ jẹ́ ìgbà tó wọ̀ náà lẹ jọ ń sọ̀rọ̀, mọ́mì ẹ ò ní ṣàdédé sọ fún ẹ nípa ọkùnrin tóun kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ sí, dádì ẹ náà ò sì ní ṣàdédé pìtàn bóun ṣe fi ọkọ̀ ìdílé ní jàǹbá tó sì bà jẹ́ pátápátá. Àmọ́, tó o bá bi àwọn òbí rẹ, wọ́n lè sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún ẹ!—Tó o bá fẹ́ mọ irú àwọn ìbéèrè tó o lè bi wọ́n, wo  àpótí tó wà ní ojú ìwé 12.

Má ṣe rin kinkin. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí wọ́n ṣe ń dáhùn ìbéèrè kan wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan míì tó ṣẹlẹ̀. Ó lè máa ṣe ẹ́ bí i pé kó o dá wọn pa dà sórí ohun tẹ́ ẹ̀ ń bá bọ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ má ṣe bẹ́ẹ̀! Rántí pé, kì í kan ṣe pé o fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, ṣùgbọ́n ṣe lo fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó jẹ wọ́n lógún.Fílípì 2:4.

Lo ìfòyemọ̀. “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yoo fà á jáde.” (Òwe 20:5) O gbọ́dọ̀ lo ìfòyemọ̀ tó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ sọ ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wù ẹ́ gan-an láti mọ àwọn àṣìṣe tó ń tini lójú táwọn òbí rẹ ṣe nígbà tí wọ́n wà ní kékeré bíi tìẹ àti ohun tí wọ́n máa fẹ́ láti ṣe báyìí ká sọ pé irú ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀. Àmọ́, kó o tó dẹ́nu lé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, o lè kọ́kọ́ bi wọ́n pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ṣé mo lè bi yín nípa . . . ”

Máa fọgbọ́n ṣe é. Tí àwọn òbí rẹ bá ń sọ fún ẹ nípa ara wọn, ṣe ni kó o “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Rí i dájú pé o kò fi àwọn òbí rẹ ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kó o kàn wọ́n lábùkù torí ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún ẹ. Ṣọ́ra, kò ní dá a kó o sọ pé: “Ábà! Mi ò mọ̀ pé ẹ lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn!” tàbí “Àṣé ohun tó fà á tẹ́ ẹ fi máa ń le koko mọ́ mi nìyẹn!” Irú èsì bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí wọ́n sọ nǹkan míì fún ẹ mọ́. Kò sì yẹ kó o sọ ohun tí wọ́n bá sọ fún ẹ fáwọn míì tí kò sí nínú ìdílé yín.

Kò Tíì Pẹ́ Jù!

Àwọn àbá tó wà lókè yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ àwọn òbí rẹ nígbà tó o ṣì wà nílé pẹ̀lú wọn. Àmọ́ ká sọ pé ẹ ò jọ gbé mọ́ ńkọ́? O ṣì lè lo àwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí láti túbọ̀ sún mọ́ àwọn òbí rẹ tàbí láti túbọ̀ mọ èyí tó ò tíì mọ̀ dáadáa lára àwọn òbí rẹ méjèèjì. Jacob tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ti rí i pé bọ́ràn náà ṣe rí gan-an nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń dá gbé báyìí, ó sọ pé: “Mo túbọ̀ wá ń mọ irú ẹni tí dádì mi jẹ́ sí i ni, ó sì ń múnú mi dùn gan-an.”

Torí náà, yálà o ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ tàbí o ti ń dá gbé, kò tíì pẹ́ jù láti túbọ̀ mọ̀ wọ́n. O ò ṣe gbìyànjú láti lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀?

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Èwo lára àwọn kókó tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí ni wàá fẹ́ bi àwọn òbí rẹ?

◼ Bó o bá túbọ̀ mọ àwọn òbí rẹ, báwo ló ṣe máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ara rẹ?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

  Lára àwọn ìbéèrè tó o lè bi àwọn òbí rẹ rèé:

ÌGBÉYÀWÓ: Báwo ni ẹ̀yin àti Mọ́mì (tàbí Dádì) ṣe pàdé? Kí ló kọ́kọ́ fà yín mọ́ra nígbà tẹ́ ẹ rí wọn? Ibo lẹ gbé lẹ́yìn tẹ́ ẹ ṣègbéyàwó?

ÌGBÀ Ọ̀DỌ́: Ibo ni wọ́n bí i yín sí? Báwo ni àárín ẹ̀yin àti àwọn ẹ̀gbọ̀n àti àbúrò yín ṣe rí? Ṣé àwọn òbí yin le mọ́ ọn yín àbí wọ́n máa ń fàyè gbà yín?

Ẹ̀KỌ́: Iṣẹ́ wo lẹ fẹ́ràn jù nígbà tẹ́ ẹ wà nílé ẹ̀kọ́? Iṣẹ́ wo lẹ ò fẹ́ràn rárá? Ṣé ẹ ní olùkọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ràn jù lọ? Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa olùkọ́ yẹn?

IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́: Iṣẹ́ wo lẹ kọ́kọ́ ṣe? Ǹjẹ́ ẹ tiẹ̀ gbádùn ẹ̀? Bẹ́ ẹ bá ní láti ṣe iṣẹ́ míì, irú iṣẹ́ wo lẹ máa yàn?

OHUN TÓ WÙ WỌ́N: Bẹ́ ẹ bá láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò síbikíbi lágbàáyé, ibo lẹ máa fẹ́ lọ? Kí ló máa ń wù yín láti ṣe tàbí kí ló máa wù yín láti kọ́?

IPÒ TẸ̀MÍ: Ṣé Kristẹni làwọn òbí yín? Bí wọ́n kì í bá ṣe Kristẹni, kí ló mú kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì? Àwọn ìṣòro wo lẹ kojú kẹ́ ẹ tó lè máa fi ìlànà Bíbélì ṣèwà hù?

OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ: Àwọn nǹkan wo lẹ rò pé ó ṣe pàtàkì jù kéèyàn lè ní ọ̀rẹ́ tó jíire? kéèyàn lè láyọ̀? kí tọkọtaya àtàwọn ọmọ lè wà ní ìṣọ̀kan? Èwo ló dára jù lọ nínú gbogbo ìmọ̀ràn tẹ́ ẹ ti rí gbà?

Fi èyí dánra wò: Mú díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí kó o sì gbìyànjú láti ronú kan bó o ṣe rò pé àwọn òbí rẹ̀ máa dáhùn rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kó o wá bi wọ́n ní ìbéèrè náà kó o sì fi ìdáhùn wọn wé ohun tó o rò pé wọ́n á sọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Ìwọ, ọkọ rẹ, ọmọbìnrin rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ yín kan jọ ń jẹun. Bí ẹ ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọ̀rẹ́ rẹ sọ nípa ẹnì kan tó o fẹ́ nígbà kan, àmọ́ tẹ́ ẹ tún fira yín sílẹ̀, kó tó di pé o wá pàdé ọkọ rẹ. O ò sọ ìtàn yìí fún ọmọbìnrin rẹ rí. Ní báyìí, ó wá fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀. Kí lo máa ṣe?

Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó dáa ni pé kó o dáhùn ìbéèrè tí ọmọ rẹ bi ẹ́. Ó ṣe tán, ìgbàkigbà tó o bá ń dáhùn ìbéèrè tó bi ẹ́, ẹ̀ ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nìyẹn, ọ̀pọ̀ òbí ló sì máa ń fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.

Báwo ni ohun tó o máa sọ fún ọmọ rẹ nípa ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn ṣe yẹ kó pọ̀ tó? Òótọ́ ni pé o ò ní fẹ́ mẹ́nu kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lè kó ìtìjú bá ẹ. Síbẹ̀, tó bá ṣeé ṣe, bó o bá jẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ mọ àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe àti àwọn ìṣòro tó o ti ní, ó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Lọ́nà wo?

Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Nígbà kan, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi. . . . Èmi abòṣì ènìyàn!” (Róòmù 7:​21-24) Jèhófà Ọlọ́run ló mí sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, òun ló sì jẹ́ kí wọ́n kọ ọ́ sínú Bíbélì fún àǹfààní wa. (2 Tímótì 3:16) Ó sì dájú pé gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, àbí èwo nínú wa ní ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn kì í ṣẹlẹ̀ sí?

Lọ́nà kan náà, báwọn ọmọ rẹ bá gbọ́ nípa àwọn ìpinnu tó lọ́gbọ́n nínú tó o ṣe àti àwọn àṣìṣe rẹ, èyí lè mú kí wọ́n túbọ̀ lè sọ tinú wọn jáde fún ẹ. Lóòótọ́, bí nǹkan ṣe rí nígbà tó o wà lọ́mọdé kọ́ ló ṣe rí lónìí. Bí nǹkan tiẹ̀ ti yí pa dà, bí nǹkan ṣe ń rí lára èèyàn kò tíì yí pa dà; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kò tíì yí pa dà. (Sáàmù 119:144) Bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó o dojú kọ àti bó o ṣe yanjú wọn, lè jẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà mọ báwọn ṣe máa bójú tó ìṣòro tiwọn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Cameron sọ pé: Nígbà tó o bá wá mọ̀ pé àwọn òbí rẹ náà ti kojú irú àwọn ìṣòro tó ò ń ní báyìí, ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ rí i pé aláìpé bíi tiẹ̀ làwọn òbí rẹ.” Ó tún sọ pé: “Bó o bá ní ìṣòro míì, kíá ló máa sọ sí ẹ lọ́kàn pé ó ṣeé ṣe káwọn òbí rẹ̀ ti ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí.”

Àkíyèsí: Kò pọn dandan kó o máa bá wọn wí lẹ́yìn gbogbo ìtàn tó o bá ti sọ fún wọn. Lóòótọ́, o lè máa ronú pé ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà lè máà lóye ohun tí ò ń sọ tàbí kó wá lọ rò pé kò burú tóun náà bá ṣe irú àṣìṣe kan náà. Kàkà tí wàá fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ kọ́mọ rẹ kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ jọ sọ (bóyá kó o sọ pé, “Ìdí nìyẹn tí o kò fi gbọ́dọ̀ ṣe báyìí báyìí”), ì bá sàn kó o sọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ṣe rí lára rẹ. (O lè sọ pé, “Àmọ́ ó dùn mí pé mo ṣe báyìí báyìí”) Nípa báyìí ọmọ rẹ á lè kẹ́kọ̀ọ́ tó máa ṣe é láǹfààní látinú ìrírí rẹ, tí kò sì ní máa ronú pé ńṣe lo kan dá òun jókòó kó o lè bá òun wí.—Éfésù 6:⁠4.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

“Lọ́jọ́ kan, mo sọ fún mọ́mì mi pé ara máa ń tù mi kí ń wà pẹ̀lú àwọn ojúgbà mi níléèwé ju kí n wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Lọ́jọ́ kejì, mo rí lẹ́tà kan tí Mọ́mì kọ sí mi lórí tábìlì mi. Nínú lẹ́tà náà wọ́n sọ báwọn náà ṣe rò pé kò sí ẹni téèyàn lè mú lọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Wọ́n wá rán mi létí àwọn kan nínú Bíbélì tí wọ́n sin Ọlọ́run nígbà tí kò sẹ́nì kankan tó lè máa fún wọn níṣìírí. Wọ́n tún wá gbóríyìn fún mi torí bí mo ṣe ń sapá láti ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi. Ó yà mi lẹ́nu nígbà tí mo wá mọ̀ pé èmi nìkan kọ́ ló ní irú ìṣòro yìí. Ó ti ṣe mọ́mì mi bẹ́ẹ̀ rí, èyí sì mú kí inú mi dùn gan-an débi pé mo sunkún. Ohun tí Mọ́mì sọ fún mi yìí fún mi níṣìírí gan-an, ó sì jẹ́ kí lókun láti ṣe ohun tó tọ́.”—Junko, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, láti orílẹ̀-èdè Japan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ní kí àwọn òbí rẹ fi fọ́tò tàbí àwọn nǹkan míì tó lè jẹ́ kó o mọ ohun tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn hàn ẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ṣeé ṣe kí èyí mú kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó gbámúṣé