O Lè Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ojú Ìwòye Bíbélì
O Lè Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run
BÓ TI ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore kó tó lè ní ìlera tó jí pépé, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run rí. Àmọ́, tó bá dọ̀ràn oúnjẹ, oríṣiríṣi oúnjẹ tó ń gbẹ́mìí ró ló wà téèyàn lè yan èyí tó wù ú níbẹ̀. Ṣé bọ́rọ̀ àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn? Ọ̀kẹ́ àìmọye àṣà àti ààtò ìsìn làwọn èèyàn sọ pé ó lè jẹ́ kí èèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé béèyàn bá ṣáà ti ń ṣe nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn, ohun yòówù kéèyàn gbà gbọ́ tàbí ọ̀nà yòówù kéèyàn máa gbà jọ́sìn kò já mọ́ nǹkan kan. Kí lèrò tìẹ? Ṣé ọ̀nà tó bá wù ẹ́ lo lè gbà jọ́sìn Ọlọ́run láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀? Kí ni Bíbélì sọ?
Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ní Jẹ́nẹ́sísì 1:27, Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó mú kó máa wù wá láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, ó ní: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti jẹ́ ẹ̀mí, kì í ṣe ìrísí wa la fi jẹ́ àwòrán rẹ̀, bí kò ṣe pé a ní àwọn ànímọ́ tó ní. Bíi ti Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Ádámù tó jẹ́ èèyàn àkọ́kọ́ lè fi àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan, inú rere, ìyọ́nú, ìdájọ́ òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn, kó sì tún mọ bí àwọn ànímọ́ yìí ti ṣe pàtàkì tó. Ó tún ní ẹ̀rí ọkàn, ìyẹn ọlọ́pàá inú, tó ń tọ́ ọ sọ́nà kó lè lo òmìnira rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run. Àwọn ànímọ́ yìí ló jẹ́ kó yàtọ̀ sí àwọn ẹranko, tó fi jẹ́ pé nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá èèyàn nìkan ló lè ṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá fẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Róòmù 2:14.
Bíbélì ṣàlàyé ohun pàtàkì kan tá a gbọ́dọ̀ ṣe 1 Kọ́ríńtì 2:12-15, a rí i pé èèyàn tẹ̀mí, ìyẹn ẹni tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ni ẹni tó gba ẹ̀mí tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni ẹ̀mí yìí, ó sì pọn dandan kéèyàn ní in kó tó lè lóye àwọn nǹkan tẹ̀mí. Èyí á mú kéèyàn lè ṣàyẹ̀wò nǹkan kó sì fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Àmọ́, ẹni tara kò ní ẹ̀mí Ọlọ́run, ohun tí kò bọ́gbọ́n mu ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ka ohun tẹ̀mí sí. Torí náà, ìpinnu wọn kì í kọjá ibi tí ọgbọ́n ẹ̀dá èèyàn mọ.
ká bàa lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. NíBó tiẹ̀ jẹ́ pé nítorí Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀ ló ṣe ń wù wá láti ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀, kì í ṣe kíka ara ẹni sí pàtàkì, ọgbọ́n orí ẹ̀dá tàbí àwọn àṣeyọrí wa ló ń mú ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó pọn dandan pé ká ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ tiẹ̀ fi hàn pé aláìnífẹ̀ẹ́ nǹkan tẹ̀mí ni àwọn tí kò gbà kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wọn, àmọ́ tí wọ́n yàn láti máa lépa ìfẹ́ ọkàn ara wọn àti àwọn nǹkan tí kò bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu. Ìfẹ́ ti ara àti èrò ti ara ló ń darí wọn.—1 Kọ́ríńtì 2:14; Júúdà 18, 19.
Bó O Ṣe Lè Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ẹni tó bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti pé òun ni orísun ìwàláàyè wa. (Ìṣípayá 4:11) A mọ̀ pé àfi ká ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí ìgbésí ayé wa tó lè ní ìtumọ̀. (Sáàmù 115:1) Tá a bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó tún jẹ́ ohun pàtàkì tó ń jẹ́ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ jíjẹ́ ti ṣe pàtàkì fún wa. Ìdí nìyẹn tí Jésù, ẹni táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run fi lè sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 4:34) Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fún Jésù lókun, ó tù ú lára, ó sì jẹ́ kó ní ìtẹ́lọ́rùn.
Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ bíi ti Ọlọ́run. (Kólósè 3:10) Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa hùwà tó lè kó àbààwọ́n bá wa tàbí èyí tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn míì jẹ́. (Éfésù 4:24-32) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ìgbé ayé wa á máa sunwọ̀n sí i, á tún jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ dáadáa, torí pé ẹ̀rí ọkàn wa kò ní máa dá wa lẹ́bi.—Róòmù 2:15.
Jésù tún sọ ohun pàtàkì míì tá a lè ṣe ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) A gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò bí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe rí nígbà gbogbo. Nínú Bíbélì, Jèhófà dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ìgbésí ayé, ìyẹn àwọn ìbéèrè tó ń jẹ gbogbo aráyé lọ́kàn.—2 Tímótì 3:16, 17.
Orísun Ayọ̀ Tòótọ́
Ẹnì kan lè jẹ pàrùpárù oúnjẹ nígbà tí ebi bá ń pa á. Bákan náà, èèyàn lè máa lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò kan tàbí kó máa gba ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó dà bíi pé ó ń múni sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ bí pàrùpárù oúnjẹ ṣe máa ń fa àìjẹunrekánú, àrùn tàbí ohun tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, lọ́nà kan náà, ìpalára ló máa já sí bá ò bá ṣe ohun tó yẹ ká ṣe láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Àmọ́, tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, tá à ń sapá láti ṣe ohun tó fẹ́, tá a sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, a ó rí i pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ, pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Kí nìdí tó fi máa ń wu èèyàn láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run?—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.
◼ Tá a bá fi dídàá tiwa nìkan, ṣé a lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run?—1 Kọ́ríńtì 2:12-15.
◼ Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run?—Mátíù 4:4; Jòhánù 4:34; Kólósè 3:10.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Ìpalára ló máa já sí bá ò bá ṣe ohun tó yẹ ká ṣe láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run