Ohun Karùn-ún: Ìfòyebánilò
Ohun Karùn-ún: Ìfòyebánilò
“Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.”—Fílípì 4:5.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Nínú ìdílé tó wà níṣọ̀kan, ọkọ àti aya máa ń dárí ji ara wọn bí wọ́n bá ṣe àṣìṣe. (Róòmù 3:23) Wọn kì í le koko mọ́ àwọn ọmọ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í kẹ́ wọn bà jẹ́. Wọ́n máa ń ní ìlànà tí kò pọ̀ jù fún ìdílé láti tẹ̀ lé. Bí ọ̀rọ̀ bá sì la ìbáwí lọ, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Jeremáyà 30:11.
Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Bíbélì sọ pé “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.” (Jákọ́bù 3:17) Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ò retí pé ká ṣe nǹkan lọ́nà pípé, kí wá ló dé tí tọkọtaya á fi máa retí pé káwọn ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà pípé? Bó bá sì jẹ́ gbogbo àṣìṣe tí kò tó nǹkan ni wọ́n á máa sọ̀rọ̀ lé lórí, ìkórìíra ló má dá sílẹ̀ kò ní mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i. Ohun tó dáa jù lọ ni pé ká fara mọ́ òtítọ́ náà pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”—Jákọ́bù 3:2.
Àwọn òbí tó wà ní ìṣọ̀kan máa ń fi òye bá àwọn ọmọ wọn lò. Ìbáwí wọn kì í ré kọjá ààlà, kì í sì í “ṣòro láti tẹ́ [wọn] lọ́rùn.” (1 Pétérù 2:18) Wọ́n máa ń fún àwọn ọmọ wọn tó ti bàlágà tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán ní òmìnira. Wọn kì í darí gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé béèyàn bá ń gbìyànjú láti darí gbogbo apá ìgbésí ayé ọ̀dọ́langba kan ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ń fi gbogbo ara jó ijó àjótàpá torí kí òjò bàa lè rọ̀. Òjò ò kúkú ní rọ̀, ẹni tó ń jó lára máa ro.”
Gbìyànjú èyí wò. Lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti ṣàgbéyẹ̀wò bó o ṣe ń fòye báni lò tó.
◼ Ìgbà wo lo dúpẹ́ lọ́wọ́ ọkọ tàbí aya rẹ kẹ́yìn?
◼ Ìgbà wo lo ṣe àríwísí ọkọ tàbí aya rẹ kẹ́yìn?
Pinnu ohun tó o máa ṣe. Bó bá ṣòro fún ẹ láti dáhùn èyí àkọ́kọ́ lára àwọn ìbéèrè yìí, àmọ́ tí kò ṣòro fún ẹ láti dáhùn èkejì, ronú nípa ohun tó o lè ṣe kó o lè máa fòye bá àwọn ẹlòmíì lò.
O ò ṣe bá ọkọ tàbí aya rẹ jíròrò ohun tí ẹ̀yin méjèèjì lè pinnu láti ṣe?
Ẹ ronú nípa òmìnira tẹ́ ẹ tún lè fún ọmọ yín ọkùnrin tàbí obìnrin tó ti bàlágà bó bá ṣe ń fi hàn pé òun ṣeé fọkàn tán.
Ẹ ò ṣe bá ọmọ yín tó ti bàlágà jíròrò láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n nípa àkókò tẹ́ ẹ fẹ́ kó máa wọlé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí awakọ̀ tó máa ń fún àwọn míì lọ́nà, bẹ́ẹ̀ ni ọkọ, aya, tàbí ọmọ tó ń fòye báni lò ṣe máa ń múra tán láti juwọ́ sílẹ̀