Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Mi Tòótọ́?

Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Mi Tòótọ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Mi Tòótọ́?

“Ọ̀rẹ́ mi tó ń jẹ́ Cori ti jẹ́ kí ojú mi là sí ọ̀pọ̀ nǹkan tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tí mo bá wà pẹ̀lú rẹ̀, mo máa ń mọ àwọn èèyàn sí i, mo máa ń gbìyànjú àwọn nǹkan tí mi ò ṣe rí, a sì máa ń gbádùn ara wa dáadáa. Àjọṣe èmi àti Cori ti yí ìgbésí ayé mi pa dà ní ti gidi!”—Tara. a

Ǹjẹ́ o rò pé kò ṣeé ṣe láti rí irú ọ̀rẹ́ yìí? Tó bá jẹ́ pé èrò rẹ nìyẹn, fọkàn balẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó o mọ̀ ló jẹ́ pé ẹ ṣì lè wá di ọ̀rẹ́ gidi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bó o ṣe lè rí irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀.

‘MO MỌ ọ̀pọ̀ èèyàn lóòótọ́, àmọ́ kò sí èyí tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi nínú wọn.’ Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shayna ló sọ ọ̀rọ̀ yìí, nígbà tó ń ṣàlàyé bó ṣe máa ń rí lára rẹ̀ láti wà láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn àmọ́ tí kò sún mọ́ èyíkéyìí lára wọn. Àwọn tó ṣeé ṣe kí irú nǹkan báyìí máa ṣẹlẹ̀ sí jù lọ ni àwọn tó máa ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọmọ ọdún méjìlélógún [22] kan tó ń jẹ́ Serena sọ pé: “O lè ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àmọ́ ká sòótọ́, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo kàn kó orúkọ jọ lásán tí kò sì wúlò fún nǹkan kan.” b

Èwo ló wù ẹ́ nínú nǹkan méjì yìí, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ orúkọ àwọn ọ̀rẹ́, àbí àwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀ tí wọ́n jẹ ọ̀rẹ́ tòótọ́? Òótọ́ ni pé méjèèjì ló ní àǹfààní tiẹ̀, àmọ́, ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa dúró tì ẹ́ nígbà ìṣòro, ó sì tún lè fún ẹ níṣìírí tó máa jẹ́ kí ìwà rẹ dára sí i. (1 Kọ́ríńtì 16:17, 18) Ronú nípa àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ àwọn tó ní ìwà téèyàn fi ń mọ ọ̀rẹ́ tòótọ́ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́ ṢEÉ FỌKÀN TÁN

“Ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí rẹ̀ fún mi, nítorí èyí, mo ronú pé èmi náà lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí tèmi náà fún un. Torí náà, lọ́jọ́ kan, mo sọ fún un pé ọmọkùnrin kàn wà tí ìfẹ́ rẹ̀ kó sí mi lórí. Mo wá rí i pé àṣìṣe ńlá ni mo ṣe pẹ̀lú bí mo ṣe sọ̀rọ̀ yìí fún un! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ti lọ sọ̀rọ̀ náà fáwọn èèyàn.”—Beverly.

“Kò sí ọ̀rọ̀ náà láyé yìí tí mi ò lè sọ fún ọ̀rẹ́ mi Alan, torí mo mọ̀ pé kò ní máa sọ̀rọ̀ náà káàkiri.”—Calvin.

Èwo nínú àwọn ọ̀dọ́ méjèèjì yìí lo lè sọ pé ó ní ọ̀rẹ́ tòótọ́? Èwo nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lo lè sọ̀rọ̀ àṣírí fún? c Bíbélì sọ pé, “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà.”—Òwe 17:17.

Kọ orúkọ ọ̀rẹ́ rẹ méjì tó o rí i pé wọ́n ṣeé fọkàn tán sórí ìlà yìí.

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́ MÁA Ń YÁÁFÌ NǸKAN

“Láàárín ọ̀rẹ́ méjì, ìgbà kan máa ń wà tó jẹ́ pé ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá ẹnì kan, nígbà tí ara ẹnì kejì á sì yá gágá. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń mọ̀ tí ara ìwọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò bá yá gágá, ó sì máa tètè wá nǹkan ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó sì dá onítọ̀hún lójú pé ìwọ náà á ran òun lọ́wọ́ nígbà tí òun bá wà nínú ìṣòro.”—Kellie.

“Nígbà tí mọ́mì mi kú, mo ní ọ̀rẹ́ tuntun kan. Lákòókò yẹn, a ò tíì fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra dáadáa, àmọ́, a ti sọ pé a jọ máa lọ síbi ìgbéyàwó kan. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ọjọ́ ìgbéyàwó yẹn náà ni ọjọ́ ìsìnkú mọ́mì mi. Ó yà mí lẹ́nu láti rí i pé ọ̀rẹ́ mi ò lọ síbi ìgbéyàwó náà, ńṣe ló wá síbi ìsìnkú mọ́mì mi. Ohun tó ṣe yẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni!”—Lena.

Èwo nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ló máa ń yááfì nǹkan tó ṣe pàtàkì nítorí tìrẹ? Ọ̀rẹ́ tòótọ́ kì í “wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

Kọ orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjì tí wọ́n lè yááfì nǹkan tó ṣe pàtàkì sí wọn nítorí tìrẹ sórí ìlà yìí.

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́ Á RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́ KÍ ÌWÀ RẸ LÈ DÁRA SÍ I

“Àwọn kan máa ń fẹ́ kí n dúró ti àwọn tàbí kí n fara mọ́ èrò wọn, bó bá tiẹ̀ gba pé kí n pa àwọn ìwà tí mo kà sí pàtàkì tì, tàbí kí n ṣe nǹkan tó máa da ẹ̀rí ọkàn mi láàmù. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọ̀rẹ́ gidi.”—Nadeine.

“Àǹtí mi ni ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ mi jù lọ. Ó máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé mo lè borí àwọn ìṣòro kan tí mo rò pé mi ò lè borí, ó tún jẹ́ kí ara mi yá mọ́ àwọn èèyàn. Ó máa ń bá mi sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé inú mi kò dùn sí i.”—Amy.

“Bí mo bá ní ìṣòro, àwọn ọ̀rẹ́ gidi kì í wulẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ tó dùn fún mi; ńṣe ni wọ́n máa ń fún mi ní ìmọ̀ràn tòótọ́. Ṣùgbọ́n ńṣe ni àwọn tó kù máa ń dá mi dá ìṣòro mi tàbí kí wọ́n kàn sọ pé kí n gbà gbé ẹ̀. Wọn ò rí ohun tó ń ṣe mí gẹ́gẹ́ bí ìṣòro rárá.”—Miki.

“Ọ̀rẹ́ mi mọ àwọn nǹkan tí mo lè ṣe ju bí ẹnikẹ́ni ṣe mọ̀ ọ́n lọ, ó sì máa ń fún mi ní ìṣírí kí ọwọ́ mi lè tẹ àwọn àfojúsùn mi. Ó máa ń bá mi sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nígbàkigbà tó bá yẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà lè gbòdì lára mi, àmọ́ mo fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀!”—Elaine.

Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lo àwọn ẹ̀bùn tó o ní, àbí ńṣe lo máa ń pa àwọn ìwà rere tó o ní tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan káwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè gba tìẹ? Òwe 13:20 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”

Kọ orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjì tí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ìwà rẹ fi dára sí i sórí ìlà yìí.

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Wo àwọn orúkọ tó o kọ sí ibi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lókè yìí. Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan wà tí orúkọ rẹ̀ wà ní ibi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, á jẹ́ pé ọ̀rẹ́ gidi nìyẹn! Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ó ṣòro fún ẹ láti ronú nípa èyíkéyìí lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó kúnjú ìwọ̀n ohun tá a sọ yìí, fọkàn balẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn míì tó o mọ̀ wá di ọ̀rẹ́ rẹ tòótọ́ tó bá yá. Ó kàn lè gba àkókò díẹ̀ ni. d Ní báyìí ná, ìwọ ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ogún ọdún kan tó ń jẹ́ Elena sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti dúró ti àwọn ọ̀rẹ́ mi nígbà gbogbo. Tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nǹkan, mo máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Tí wọ́n bá fẹ́ sọ̀rọ̀, mo máa ń fetí sílẹ̀. Tí nǹkan kan bá bà wọ́n nínú jẹ́, mo máa ń tù wọ́n nínú.”

Òótọ́ ni pé o lè mọ ọ̀pọ̀ èèyàn, ìyẹn sì dára ju pé kí o kó ìwọ̀nba ọ̀rẹ́ jọ kó o sì wá pa àwọn míì tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. (2 Kọ́ríńtì 6:13) Àmọ́, ṣé o kò ní fẹ́ ní ìwọ̀nba ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí a “bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà”? (Òwe 17:17) Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ogún ọdún kan tó ń jẹ́ Jean sọ pé: “Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn mọ àwọn èèyàn púpọ̀, àmọ́ ńṣe ni ìyẹn dà bí ìgbà tí aṣọ kún inú ibi tí wọ́n máa ń fi aṣọ kọ́ sí, tó jẹ́ pé gbogbo wọn ló dára lórí ìkọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn ló dáa lára. Àwọn aṣọ tó o bá rí i pé wọ́n dáa lára rẹ nìkan ni wàá máa wọ̀. Ohun tó yẹ kó o ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ẹ náà nìyẹn.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ̀ Béèrè Pé,” ojú ìwé 16 sí 19 àti ojú ìwé 26 sí 29 nínú ìwé ìròyìn yìí.

c Àwọn ìgbà míì wà tí kò bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn fi ọ̀rọ̀ pa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ọ̀rẹ́ rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan, tó bá ń gbèrò láti pa ara rẹ̀, tàbí tó bá ń ṣe àwọn nǹkan tó lè ṣe ìpalára fún un. Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Jí! January–March 2009, ojú ìwé 19 sí 21, àti July–September 2008, ojú ìwé 16 sí 19.

d Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Jí! April–June 2009, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Ó Yẹ Kí N Ní Ọ̀rẹ́ Míì?”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

BÍ O ṢE LÈ NÍ Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́

1. Àwọn ọ̀rẹ́ gidi ni kó o wá, má kàn kó èrò jọ. “Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn mọ àwọn èèyàn tó pọ̀, àmọ́ bó o bá tiẹ̀ wà láàárín èèyàn púpọ̀, àwọn èèyàn díẹ̀ kan sábà máa ń wà tí ara máa tù ẹ́ láti wà pẹ̀lú wọn, tí wàá sì sún mọ́ jù lọ.”—Karen.

2. Jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́. “Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé káwọn ọ̀rẹ́ mi dúró tì mí, kí wọ́n sì fọkàn tán mi, ohun tí èmi náà sì máa ń ṣe fún wọn nìyẹn.”—Evelyn.

3. Máa fi hàn pé o mọyì àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. “Bí mo bá rí i pé mo gbádùn bí mo ṣe ń bá ẹnìkan ṣọ̀rẹ́, mo máa ń jẹ́ kí onítọ̀hún mọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa fífi káàdì tàbí ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí i.”—Kellie.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Kí lẹ lè sọ nípa àwọn ọ̀rẹ́ yín, nígbà tẹ́ ẹ wà ní ọ̀dọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rẹ́ kan hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí yín rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ wo lẹ rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Àwọn ọ̀rẹ́ adúrótini wo lẹ ní, báwo lẹ sì ṣe rí wọ́n?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

OHUN TÓ YẸ KÓ JẸ́ ÌPÌLẸ̀

Ohun tó yẹ kó jẹ́ ìpìlẹ̀ yíyan ọ̀rẹ́ gidi ni pé kí wọ́n jọ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rere kan náà. Ohun tí ìyẹn sì túmọ̀ sí ni pé, ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ á jọ máa sin Ọlọ́run, ẹ ó jọ máa hu ìwà rere, ẹ ó jọ fara mọ́ àwọn ìwà tó bójú mu.

Ohun míì ni pé kò pọn dandan pé kẹ́ ẹ ní àwọn ànímọ́ kan náà.

Bákan náà, kò pọn dandan kó jẹ́ pé ohun kan náà ló máa ń wù yín ṣe. Ó ṣe tán, ọ̀rẹ́ rẹ lè jẹ́ ẹnì kan tí ohun tó máa ń ṣe nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá dilẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ, àwọn ẹ̀bùn tó ní sì lè yàtọ̀ sí tìẹ.

Ìkìlọ̀: Ó yẹ kó o ṣọ́ra tó bá jẹ́ pé ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹnì kan wọ̀ kò ju pé àwọn ohun kan náà lẹ jọ nífẹ̀ẹ́ sí. Bí onítọ̀hún kò bá fara mọ́ àwọn ìlànà rere tí ò ń tẹ̀ lé, kò ní pẹ́ rárá tẹ́ ẹ máa fi tú ká, tàbí kó tiẹ̀ kó ẹ sí wàhálà.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Tó o bá lọ ṣe àwọn òfin má-ṣe-tibí má-ṣe-tọ̀hún, o kò ní lọ́rẹ̀ẹ́ kankan, torí pé ohun tí wàá máa retí látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn á ti pọ̀ jù. Tó bá sì wá tún lọ jẹ́ pé gbogbo nǹkan lo máa ń gbà mọ́ra, a jẹ́ pé tajá tẹran lo lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́ nìyẹn, ìyẹn náà ò tún bọ́gbọ́n mu.”

“Ohun tó ṣe pàtàkì sí àwọn kan tí wọ́n máa ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni bí wọ́n ṣe máa ní ọ̀pọ̀ orúkọ ọ̀rẹ́, wọ́n kì í sábà ronú nípa àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín àwọn tí wọ́n ń bá ṣọ̀rẹ́. Tó bá di ọ̀rọ̀ yíyan ọ̀rẹ́, ó dáa kéèyàn yan àwọn ọ̀rẹ́ gidi ju kéèyàn kàn kó èrò jọ lásán.”

“Bí ẹnì kan bá wá ṣe òfófó fún mi nípa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó kù, ìyẹn máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé bí onítọ̀hún á ṣe máa sọ̀rọ̀ tèmi náà fáwọn ẹlòmíì nìyẹn. Mi ò fẹ́ irú ìwà yẹn rárá. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ kì í ṣe òfófó.”

[Àwọn Àwòrán]

Dominique

Lianne

Brieanne