Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Fún Ojú
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Fún Ojú
● Iṣẹ́ ọnà tó ga lọ́lá ni ojú èèyàn jẹ́. Yàtọ̀ sí pé ó lẹ́wà, iṣẹ́ rẹ̀ tún pọ̀ gan-an. Ìwé náà, Visual Impact, Visual Teaching sọ pé: “Ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn iṣan tín-ínrín tó so kọ́ra, tó wá láti inú ọpọlọ ló so mọ́ apá inú lọ́hùn-ún nínú ojú, ìyẹn retina.”
Òótọ́ lọ̀rọ̀ Jésù Kristi tó sọ pé ojú ni “fìtílà ara.” Nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan [tí kì í tanni jẹ, tó ń wo ohun tó dára], gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú, gbogbo ara rẹ yóò ṣókùnkùn.” (Mátíù 6:22,23) Jésù lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí láti jẹ́ ká mọ bí ojú ṣe lágbára tó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, pé ó lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun kan, kéèyàn ní ìmọ̀lára nípa ohun kan, ó sì lé mú kéèyàn gbé ìgbésẹ̀ nípa ohun náà. Èrò rere máa ń múnú ẹni dùn, ṣùgbọ́n èrò búburú máa ń bani lọ́kàn jẹ́.
Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 5:28, 29: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde [lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ].” Kí ló ní lọ́kàn? Ojú tó ń wo tibí wo tọ̀hún máa ń mú kí ọkàn ro èròkerò débi pé tí àǹfààní bá yọ, onítọ̀hún á ṣèṣekúṣe, á sì pàdánù ojú rere Ọlọ́run.—Jákọ́bù 1:14, 15.
Ẹ ò rí bó ṣe dára tó pé kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu, àní bí ìyẹn bá tiẹ̀ máa dà bí ìgbà téèyàn yọ ojú ẹni jáde! Ó ṣe tán, ṣé ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun torí ìgbádùn ojú ẹsẹ̀?
Ohun tá à ń fojú wa wò lè mú ká ṣe ojúkòkòrò. Torí náà, Bíbélì kì wá nílọ̀ pé ìfẹ́ onímọtara ẹni nìkan bí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú . . . kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ńṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:16, 17.
Ǹjẹ́ àwọn ìlànà Bíbélì kò ṣòro jù láti tẹ̀ lé báyìí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ńṣe ni ẹni tó bá kóyán ìlànà Bíbélì kéré fẹ́ fa wàhálà fún ara rẹ̀, kò sì ní láyọ̀. (Gálátíà 6:7, 8) Tá a bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, títí kan ọ̀rọ̀ ọgbọ́n nípa bó ṣe yẹ ká máa lo ojú wa, a máa láyọ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́.” (Lúùkù 11:28) Yàtọ̀ sí ìyẹn, wọ́n tún nírètí láti máa gbé ayé títí láé, nígbà tó jẹ́ pé àwọn tí ojú wọn kò gbé ibì kan tàbí tí wọ́n lójú kòkòrò kò ní láyọ̀, wọn kò sì ní rí ìyè.