Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Mọ Bí Wàá Ṣe Di Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà

O Lè Mọ Bí Wàá Ṣe Di Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà

O Lè Mọ Bí Wàá Ṣe Di Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà

BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé wọ́n lè bí èrò tí kò tọ́ mọ́ wa, àwọn tó ń hù ìwà ipá sábà máa ń kọ́ ọ ni. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí téèyàn bá fẹ́ di ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Torí náà, ta ló lè kọ́ wa bá a ṣe lè di ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa ni, ẹni tí àṣẹ rẹ̀ ga jù lọ, tí ọgbọ́n rẹ̀ kò sì láàlà. Jẹ́ ká gbé àwọn kókó márùn ún tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò àtàwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó bá a mu látinú Bíbélì.

1 “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá.” (Òwe 3:31) Fi sọ́kàn pé ohun tó ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ alágbára lóòótọ́ ni àwọn ìwà bí ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìwà tútù. Ó ṣe tán, ìwé Òwe 16:32 sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.” Bí ògiri ńlá tó ń dá omi dúró, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú máa fọwọ́ wọ́nú tí wọ́n bá ṣe ohun tó lè mú un bínú. Kódà, tí inú bá tiẹ̀ ń bí i, ṣe ló máa dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, èyí á sì “yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) Àmọ́, ẹni tó bá ń yára bínú máa ń tètè gbaná jẹ kódà tí ohun tó bá mú un bínú kò bá tó nǹkan.—Òwe 25:28.

2 Fi ọgbọ́n yan ọ̀rẹ́ rẹ. Ìwé Òwe 16:29 sọ pé: “Ènìyàn tí ń hu ìwà ipá yóò sún ọmọnìkejì rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.” Àmọ́ “ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Òótọ́ ni, tá a bá ń bá àwọn tó lẹ́mìí àlàáfíà ṣọ̀rẹ́, tí wọ́n máa ń kó ara wọn níjàánu, tí wọ́n sì ń hùwà pẹ̀lẹ́, àwa náà á fẹ́ máa hùwà bíi tiwọn.

3 Mọ bí èèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì dénú. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:4-7 ṣe àlàyé tó dáa jù lọ nípa ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí gan-an. Díẹ̀ nínú ohun tó sọ ni pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. . . . A kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. . . . A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, . . . a máa fara da ohun gbogbo.” Jésù sọ pé títẹ̀lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run tún gba pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa pàápàá.—Mátíù 5:44, 45.

4 Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tí wọ́n bá hùwà ìkà sí ẹ. “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, . . . nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:17-19) Tá a bá gba Ọlọ́run gbọ́ àti àwọn ìlérí tó ṣe, á jẹ́ ká ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn táwọn èèyàn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ kò lè ní.—Sáàmù 7:14-16; Fílípì 4:6, 7.

5 Máa retí ìjọba Ọlọ́run tó máa mú àlàáfíà tòótọ́ wá sórí ilẹ̀ ayé. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba ọ̀run tó máa fòpin sí gbogbo ìwà búburú, tó sì máa ṣàkóso gbogbo ayé láìpẹ́. (Sáàmù 37:8-11; Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ Ìjọba yẹn, “olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́.”—Sáàmù 72:7.

Irú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì báyìí ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti di ẹlẹ́mìí àlàáfíà, títí kan àwọn tó máa ń hu ìwà ipá.