Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Mi Ti Rí Ìwà Ìrẹ́jẹ Tó Kọjá Àfẹnusọ

Ojú Mi Ti Rí Ìwà Ìrẹ́jẹ Tó Kọjá Àfẹnusọ

WỌ́N bí mi ní ọdún 1965 ní orílẹ̀-èdè Northern Ireland. Tálákà làwọn òbí mi. Àgbègbè Derry ni mo gbé dàgbà, lákòókò tàwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ń bá ara wọn fa wàhálà. Ó sì lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún kí rògbòdìyàn náà tó parí. Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tí wọn kò tó nǹkan wò ó pé àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n pọ̀ ju àwọn lọ ń rẹ́ àwọn jẹ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìdìbò, iṣẹ́, ilé gbígbé àtàwọn òfin máṣu-mátọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀.

Mo rí àìsí ìdájọ́ òdodo àti ìwà ìrẹ́nijẹ ní gbogbo ibi tí mo bá yíjú sí. Àìmọye ìgbà ni àwọn sójà tàbí àwọn ọlọ́pàá nà mí, tí wọ́n wọ́ mi jáde nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì gbé ìbọn sí mi lórí tàbí kí wọ́n máa da ìbéèrè bò mí, tí wọ́n á sì máa tú ara mi tàbí ẹrù mi. Wọ́n mú ayé sú mi débi pé mo ronú pé, ‘mo gbọ́dọ̀ yan ọ̀kan nínú kí n gba kámú tàbí kí n gbara mi sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn!’

Mo wà lára àwọn tó ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ́dọọdún ní ìrántí àwọn mẹ́rìnlá kan táwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìnbọn pa lọ́dún 1972. Mo tún wà lára àwọn tó ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní ìrántí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ń jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn, tí wọ́n fi ebi pa ara wọn lọ́dún 1981 títí tí wọ́n fi kú. Mo máa ń gbé àsíá orílẹ̀-èdè Northern Ireland kọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé àsíá náà, mo sì máa ń kọ oríṣiríṣi nǹkan tó fi hàn pé mo kórìíra ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí gbogbo ibi tí mo bá ti rí. Ṣe ló dà bíi pé kò sígbà tí ọ̀ràn ńlá kan kì í ṣẹlẹ̀ tàbí tí wọn kì í pa ọmọ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan tíyẹn sì tún máa ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀. Kì í pẹ́ tí ìwọ́de wọ́ọ́rọ́wọ́ táwọn èèyàn ń ṣe fi máa ń di ìjà ìgboro.

Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé tó máa ń ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn fún ohun tí kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn. Nígbà tó yá, mo kó lọ sí ìlú London, mo sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ìlú, a sì máa ń wọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba lórí àwọn òfin tó dẹ àwọn olówó lọ́rùn, àmọ́ tó ń ni àwọn mẹ̀kúnnù lára. Mo wà lára ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó jà fún bí wọ́n ṣe ń fi owó orí fá àwọn òṣìṣẹ́ lórí, mo sì wà lára àwọn tó wọ́de lọ́dún 1990 fún ẹ̀tọ́ owó orí. Gbàgede kan tó ń jẹ́ Trafalgar Square sì bà jẹ́ gan-an látàrí ìwọ́de náà.

Àmọ́ nígbà tó yá, ojú mi wá là pé nǹkan ò rí bí mo ṣe rò. Dípò kí ìwọ́de mú kọ́wọ́ èèyàn tẹ ohun tó fẹ́, ṣe ló túbọ̀ ń mú kí ìkórìíra máa pọ̀ sí i.

Ẹ̀dá èèyàn kò lè mú ìrẹ́jẹ àti ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kúrò, láìka bó ṣe wu ẹnì kan tó láti ṣe bẹ́ẹ̀

Àkókò yìí ni ọ̀rẹ́ mi kan mú mi mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n fi hàn mí látinú Bíbélì pé kò wu Ọlọ́run pé ká máa jìyà àti pé ó máa ṣe àtúnṣe sí gbogbo ìbàjẹ́ tí ẹ̀dá èèyàn ti ṣe. (Aísáyà 65:17; Ìṣípayá 21:3, 4) Ẹ̀dá èèyàn kò lè mú ìrẹ́jẹ àti ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kúrò, láìka bó ṣe wu ẹnì kan tó láti ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí pé a nílò kí Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà, òun nìkan ló tún lè bá wa borí àwọn ẹ̀mí àìrí tó wà nídìí ìṣòro tó ń bá ayé fínra.—Jeremáyà 10:23; Éfésù 6:12.

Ní báyìí, mo rí i pé ńṣe ni ìwọ́de tí mò ń ṣe torí kí ìdájọ́ òdodo lè wà dà bí ìgbà tí mò ń fi ọ̀dà kun ilé tó ti ń wó lọ. Ó tuni lára pẹ̀sẹ̀ láti wá mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ìwà ìrẹ́jẹ mọ́ láyé yìí, nígbà yẹn kò ní sí ẹnì kan tó ṣe pàtàkì ju ẹlòmíì lọ.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo” ni Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 37:28) Ìdí kan nìyí tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò pátápátá, èyí táwọn ìjọba èèyàn ò lè ṣe láéláé. (Dáníẹ́lì 2:44) Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àgbègbè rẹ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn www.dan124.com/yo.