ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Bí O Ṣe Lè Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Ọkọ tàbí aya rẹ sọ fún ẹ pé, “O ò gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ!” Àmọ́ lójú tìẹ gbogbo ohun tó sọ lo gbọ́. A jẹ́ pé ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé kì í ṣe ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ sọ lo gbọ́. Ìyẹn sì tún máa dá àríyànjiyàn míì sílẹ̀.
Ohun tó o lè ṣe wà kí àríyànjiyàn yìí má bàa wáyé. Àmọ́ ó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ ohun tó lè fà á tí o kò fi gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ tí ọkọ tàbí aya rẹ ń sọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o rò pé ò ń gbọ́ ohun tó ń sọ.
OHUN TÓ FÀ Á
O kò pọkàn pọ̀, ó ti rẹ̀ ẹ́ tàbí kó jẹ́ méjèèjì. Àwọn ọmọ rẹ lè máa pariwo nínú ilé, ohùn tẹlifíṣọ̀n lè lọ sókè jù tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ló ń ronú nípa ìṣòro kan tó o ní níbi iṣẹ́. Ó lè wá jẹ́ ìgbà yẹn gan-an ni ìyàwó rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹ sọ̀rọ̀, bóyá kó máa sọ fún ẹ nípa àlejò kan tó fẹ́ wá kí yín lálẹ́. O mi orí pé o ti gbọ́, àmọ́ ǹjẹ́ o gbọ́ ohun tó sọ báyìí? Kò dájú pé o gbọ́.
O ronú pé o mọ ohun tó wà lọ́kàn ọkọ tàbí aya rẹ. Ó ronú pé nǹkan kan wà tí ọkọ tàbí aya rẹ ní lọ́kàn tó fi sọ ohun tó sọ, nígbà tó sì jẹ́ pé o ti ronú kọjá bó ṣe yẹ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ sọ pé: “Àfikún iṣẹ́ tó o ṣe lọ́sẹ̀ yìí pọ̀, ó sì jẹ́ kó o máa pẹ́ dé láti ibi iṣẹ́.” Àmọ́ ìwọ rò pé ṣe ló fẹ́ dá ẹ lẹ́bi, o wá sọ pé: “Ẹ̀bi mi kọ́! Mo gbọ́dọ̀ ṣe àfikún iṣẹ́ torí iye tíwọ nìkan ń ná kò kéré.” Ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ bá jágbe mọ́ ẹ pé, “Mi ò sọ pé ohun tó o ṣe burú!” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ló kàn wò ó pé bóyá ẹ lè jọ lọ lo òpin ọ̀sẹ̀ níbì kan kẹ́ ẹ lè ráyè sinmi dáadáa.
Bó o ṣe máa yanjú ìṣòro ló ká ẹ lára jù. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Tọ́pẹ́ a sọ pé, “Nígbà míì, mo kàn fẹ́ sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn mi fún ọkọ mi, àmọ́ ṣe lọkọ mi máa ń fẹ́ sọ fún mi bí mo ṣe máa yanjú ìṣòro náà. Ìyẹn sì kọ́ lohun tó bá èmi. Mo kàn fẹ́ kó mọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn mi ni.” Kí ló fa ìṣòro yìí? Bí òkè ìṣòro ṣe máa di pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ọkọ Tọ́pẹ́ máa ń wà ní tiẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó máà gbọ́ àwọn nǹkan kan lára ohun tí ìyàwó rẹ bá sọ tàbí kó máà tiẹ̀ gbọ́ rárá.
Ohun yòówù kó fa ìṣòro náà, báwo lo ṣe lè máa fara balẹ̀ fetí sí aya tàbí ọkọ rẹ?
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun gbà ẹ́ lọ́kàn. Ọkọ tàbí aya rẹ ní ohun pàtàkì kan tó fẹ́ sọ fún ẹ, àmọ́ ṣé o ṣe tán láti gbọ́ ọ? Kò dájú pé o ṣe tán láti gbọ́ ọ tó bá jẹ́ pé ò ń ro nǹkan míì nígbà yẹn. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má ṣe díbọ́n pé ò ń gbọ́ ọ. Tó bá ṣeé ṣe, pa ohun tó ò ń ṣe tì, kó o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí ọkọ tàbí aya ẹ ń sọ, tàbí kó o sọ fún un pé kó ní sùúrù ná, kó o fi parí ohun tó ò ń ṣe.—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 1:19.
Ẹ fún ara yín lọ́rọ̀ sọ. Tó bá jẹ́ pé ọkọ tàbí aya rẹ ló ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu tàbí kó o ta kò ó. Ìwọ náà ṣì máa sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ. Àmọ́ ní báyìí ná, tẹ́tí sílẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 18:13.
Béèrè ìbéèrè. Èyí máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ń sọ. Tọ́pẹ́ tá a sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Inú mi máa ń dùn tí ọkọ mi bá béèrè ohun tí kò yé e nínú ọ̀rọ̀ mi. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ń fọkàn bá ohun tí mò ń sọ lọ.”
Ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ fẹ́ sọ ni kó o fọkàn sí má ṣe máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Bí ọkọ tàbí aya rẹ ṣe ń fara ṣàpèjúwe, ojú rẹ̀ àti ohùn rẹ̀ máa jẹ́ kó o lóye ohun tó ń sọ. Nígbà míì, ẹnì kan lè sọ pé “ìyẹn náà dáa,” àmọ́ kó jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé “kò dáa rárá,” ó sinmi lórí bí onítọ̀hún bá ṣe sọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ tàbí ìyàwó kan lè sọ pé, “O kì í ràn mí lọ́wọ́,” ó lè jẹ́ pé ohun tó sì ń sọ ni pé, “Ó ń ṣe mí bíi pé mi ò ṣe pàtàkì sí ẹ.” Gbìyànjú láti lóye ohun tí ọkọ tàbí aya ẹ ń sọ, kódà tí kò bá tiẹ̀ sọ gbogbo ẹ̀ jáde. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara yín jiyàn lórí ohun tẹ́ ẹ sọ dípò kẹ́ ẹ lóye ohun tó ní lọ́kàn.
Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa tẹ́tí gbọ́ ọkọ tàbí aya rẹ. Má ṣe rìn kúrò níwájú ọkọ tàbí aya rẹ tàbí kó o máa fi pe igi, kódà kó jẹ́ pé ohun tó ń sọ ò bá ẹ lára mu. Ká sọ pé ọkọ tàbí aya ẹ ń dá ẹ lẹ́bi lórí nǹkan kan ńkọ́? Ìmọ̀ràn Gregory tó ti lé lọ́gọ́ta [60] ọdún tó ti fẹ́yàwó ni pé, “Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa tẹ́tí gbọ́ ọ. Fi tọkàntọkàn gbé ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ń sọ yẹ̀ wò. Ó gba pé kéèyàn láròjinlẹ̀ o, àmọ́ àǹfààní ẹ̀ pọ̀.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 18:15.
Nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ dénú. Tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí aya rẹ, ṣe ló fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú, kì í wulẹ̀ ṣe pé o jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ balẹ̀. Wàá rí i pé kò ní nira rárá láti máa fetí sílẹ̀ tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn lo fi fẹ́ gbọ́ ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ń bá ẹ sọ. Ìyẹn á sì jẹ́ kó o máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ má máa mojútó nǹkan ti ara yín nìkan, ṣugbọn kí ẹ máa mojútó nǹkan àwọn ẹlomiran.”—Fílípì 2:4, Ìròyìn Ayọ̀.
a A ti yí àwọn orúkọ pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.