KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ìkànnì Kan Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
-
KA Bíbélì ní èdè tí ó tó àádọ́ta [50]. Àwọn ìsọfúnni tá a gbé ka Bíbélì tó wà níbẹ̀ ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èdè lọ.
-
WO fídíò ní èdè àwọn adití tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rin [70].
-
WÀ Á RÍ ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè lórí ìkànnì náà.
-
GBỌ́ àwọn ìtàn tó dá lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú Bíbélì.
-
WO àwọn àwòrán tó ń mú kí àwọn ìtàn inú Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere kó sì dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
-
WO àwọn eré àti fídíò tó dá lórí àwọn ìtàn inú Bíbélì, èyí tó máa ràn ẹ́ lówọ́ kó o lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé.
-
WA àwọn fáìlì jáde lórí ìkànnì wa, irú bí èyí tó wà lórí PDF, EPUB, àwọn àpilẹ̀kọ nínú ìwé ìròyìn wa, àwọn ìtàn inú Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀fẹ́ ni gbogbo wọn.
-
ṢÈWÁDÌÍ nípa oríṣiríṣi àwọn kókó pàtàkì nípa lílo ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni ló wà níbẹ̀, ní iye tó ju ọgọ́rùn-ún [100] èdè lọ.
FÚN ÀWỌN TỌKỌTAYA
“Mo fẹ́ kí ilé wa tòrò. Èmi àtìyàwó mi ní àwọn ìṣòro kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àmọ́ ńṣe ni ìṣòro ọ̀hún tún wá pọ̀ sí i nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. A nílò ìrànlọ́wọ́ o”
BÍBÉLÌ SỌ PÉ:
“Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—Òwe 24:3.
APÁ TÓ LÈ RAN ÀWỌN TỌKỌTAYA LỌ́WỌ́ LÓRÍ ÌKÀNNÌ NÁÀ
Wo apá tá a pè ní “Tọkọtaya Àtàwọn Òbí.” Níbẹ̀, o lè ka àwọn àpilẹ̀kọ tó máa jẹ́ kó o mọ:
-
Bó o ṣe lè borí àwọn ìṣòro tó máa ń wáyé ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbéyàwó
-
Bó o ṣe lè yanjú ìṣòro àárín ìwọ àti àna rẹ
-
Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa ọmọ títọ́
-
Bí ẹ ṣe lè jáwọ́ nínú bíbá ara yín jiyàn
-
Bí ẹ ṣe lè yanjú ìṣòro owó
(Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > TỌKỌTAYA ÀTÀWỌN ÒBÍ)
Ìwé kan wà tó ń jẹ́ Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ìwé yìí sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìdílé. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan téèyàn lè máa ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó, títí kan béèyàn ṣe lè máa bójú tó àwọn òbí tó ti darúgbó.
(Ó tún wà lórí ìkànnì www.dan124.com. Wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ)
FÚN ÀWỌN ÒBÍ
“Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ mi jẹ mí lógún gan-an ni. Mo fẹ́ kí wọ́n dàgbà di ọmọ àmúyangàn”
BÍBÉLÌ SỌ PÉ:
“Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.
APÁ TÓ LÈ RAN ÀWỌN ÒBÍ LỌ́WỌ́ LÓRÍ ÌKÀNNÌ NÁÀ
Wo apá tá a pè ní “Àwọn Ọmọ.” Àwọn àwòrán lóríṣiríṣi wà níbẹ̀ tá a fi ṣàlàyé ìtàn Bíbélì, àwọn fídíò, àwọn àwòrán téèyàn lè fi ṣeré ọwọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè . . .
-
jẹ́ onígbọràn
-
máa ṣoore
-
máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn
-
máa sọ pé “o ṣeun,” tẹ́nì kan bá ṣòore fún wọn
(Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN ỌMỌDÉ)
Ìwé Ìtàn Bíbélì àti Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náa dára púpọ̀. Oríṣiríṣi àwòrán mèremère ló wà níbẹ̀. O lè máa kà á pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.
(Ó tún wà lórí ìkànnì jw.org. Wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ)
FÚN ÀWỌN Ọ̀DỌ́
“Mo fẹ́ ìmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ iléèwé, àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn òbí mi, àwọn ọ̀rẹ́ mi àti ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti obìnrin. Mi ò kì í ṣọmọdé mọ́, torí náà mi ò fẹ́ kẹ́nì kan máa sọ fún mi pé kí n ṣe tibí kí n ṣe tọ̀hún”
BÍBÉLÌ SỌ PÉ:
“Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ.”—Oníwàásù 11:9.
APÁ TÓ LÈ RAN ÀWỌN Ọ̀DỌ́ LỌ́WỌ́ LÓRÍ ÌKÀNNÌ NÁÀ
Wo apá tá a pè ní “Àwọn Ọ̀dọ́.” Àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò kan wà níbẹ̀ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ . . .
-
tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá nìkan wà
-
tó o bá ní ìṣòro níléèwé
-
tó o bá ṣe ohun táwọn òbí rẹ sọ pé o kò gbọ́dọ̀ ṣe
-
tẹ́nì kan bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ tàbí tó ń fẹ́ kó o bá òun ṣèṣekúṣe
(Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́)
Ìwé kan wà tó ń jẹ́ Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní àti Apá Kejì. Ìwé yìí dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77] táwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń béèrè.
(Ó tún wà lórí ìkànnì jw.org. Wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ)
FÚN ÀWỌN TÓ BÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
“Ó wù mí kí n mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Kí ni mo lè ṣe?”
BÍBÉLÌ SỌ PÉ:
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.”—2 Tímótì 3:16.
APÁ TÓ LÈ RAN ÀWỌN TÓ BÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÓRÍ ÌKÀNNÌ NÁÀ
A túmọ̀ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lọ́nà tó péye, ó sì rọrùn láti kà.
(Wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > BÍBÉLÌ)
Wo apá tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ.” Ibẹ̀ la ti dáhùn àwọn ìbéèrè bíi “Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?” “Ìgbà wo ni wọ́n bí Jésù?”
(Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ)
Apá kan wà níbẹ̀ tá a pè ní “Béèrè Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́fẹ̀ẹ́.” Ibẹ̀ lo ti máa rí bó o ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ tá à ń kọ́ àwọn èeyàn.
(Lọ sí ìlujá tá a pè ní “Béèrè Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” ní ojúde ìkànnì náà)
“Mo ti gbìyànjú nígbà kan láti máa ka Bíbélì, ìgbà tí kò yé mi ni mo pa á tì. Àmọ́ látìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé ‘Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?’ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo ti rí i pé ó rọrùn láti kà, ó sì ń yéni yékéyéké.” —Christina.
Lójoojúmọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700,000] èèyàn ló máa ń lọ sórí ìkànnì jw.org. A rọ̀ ọ́ pé kíwọ náà lọ síbẹ̀.