Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Awọ Ejò

Awọ Ejò

NÍTORÍ pé ejò kò ní apá àti ẹsẹ̀, awọ ara wọn gbọ́dọ̀ yi dáadáa kó sì lágbára kó má bàa máa bó tí wọ́n bá ń fà. Àwọn ejò kan wà tí wọ́n máa ń fà lára àwọn igi tí ara wọn rí ṣákaṣàka, àwọn míì sì wà tí wọ́n máa ń fà lórí ilẹ̀ olókùúta tó rí gbágungbàgun. Kí ló mú kí awọ ejò yi tó bẹ́ẹ̀?

Rò ó wò ná: Oríṣiríṣi ejò ló wà, awọ wọn sì yi jura lọ. Àmọ́ ohun kan wà tó jọra nínú gbogbo awọ ejò: Ó yi níta, ó sì ń rọ̀ bó ṣe ń dé ọwọ́ inú. Kí nìdí tí èyí fi ṣàǹfààní gan-an? Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Marie-Christin Klein sọ pé: “Àwọn ohun tó bá le lọ́wọ́ ìta, tó sì wá ń rọ̀ bó ṣe ń dé ọwọ́ inú máa ń dúró dáadáa lórí ibi tó bá fẹ̀, láìsí pé ibi kan tẹ̀ wọnú ju ibi kan lọ.” Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa awọ ejò yìí ló mú kí ara wọ́n lè di ilẹ̀ mú dáadáa, ìyẹn sì ló mú kí wọ́n lè máa fà lórí ilẹ̀. Bákan náà, tí wọ́n bá ń fà lórí ilẹ̀ olókùúta tó rí gbágungbàgun, bí ara wọ́n ṣe rí yìí ló máa ń mú kí wọ́n lè dúró déédéé lórí ilẹ̀ débi pé òkúta ò ní fi bẹ́ẹ̀ ya awọ ara wọn. Ohun tó tún mú kó ṣe pàtàkì pé kí awọ ejò yi dáadáa ni pé ẹ̀yìn oṣù méjì-méjì sí oṣù mẹ́ta-mẹ́ta ni wọ́n máa ń tó bọ́ awọ ara wọn.

Wọ́n lè lo àpapọ̀ èròjà tó wà nínú awọ ejò nínú ìmọ̀ ìṣègùn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi ṣe ìsàlẹ̀ àwọn bàtá tí kì í jẹ́ kéèyàn yọ̀ ṣubú, wọ́n sì lè fi ṣe àwọn ẹ̀yà ara àtọwọ́dá tó máa lálòpẹ́. Bákan náà, tí wọ́n bá fi àpapọ̀ èròjà tó wà nínú awọ ejò ṣe àwọn bẹ́líìtì tó máa ń wà nínú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbé ẹrù, ìwọ̀nba epo tàbí gíríìsì ni wọ́n á máa fi sí i, èyí sì ṣàǹfààní torí pé òórùn epo náà máa ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́.

Kí lèrò rẹ? Ṣé bí awọ ejò ṣe rí yìí kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni àbí ẹnì kan ló dá a?