Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 2 Torí Pé Ìrànlọ́wọ́ Wà fún Ẹ

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 2 Torí Pé Ìrànlọ́wọ́ Wà fún Ẹ

‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé Ọlọ́run, nítorí ó bìkítà fún ẹ.’​—1 PÉTÉRÙ 5:7.

Bí ìṣòro tó lágbára bá ń bá ẹ fínra tó o sì rò pé kò sọ́nà àbáyọ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o kú. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wa tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Àdúrà. Àdúrà kì í kàn ṣe oògùn amáratuni lásán. Bákan náà, kì í ṣe ìgbà tí ìṣòro bá pinni lẹ́mìí nìkan léèyàn ń gbàdúrà. Àmọ́, ó jẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gidi pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí kò fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣeré rárá. Jèhófà fẹ́ kó o sọ ìṣòro rẹ fún òun. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22.

O ò ṣe gbàdúrà sí Ọlọ́run lónìí. Pe orúkọ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà, kó o sì gbàdúrà tọkàntọkàn. (Sáàmù 62:8) Jèhófà fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun. (Aísáyà 55:6; Jákọ́bù 2:23) Àdúrà jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbàkigbà àti níbikíbi.

Àjọ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe lè dènà àṣà ṣíṣekú para ẹni lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn American Foundation for Suicide Prevention sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìwádìí fi hàn pé ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára awọn tó ń fọwọ́ ara wọn para wọn ló jẹ́ pé wọ́n ní àìsàn ọpọlọ nígbà tí wọ́n fi máa kú. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, wọn ò tiẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní irú àìsàn bẹ́ẹ̀ débi tí wọ́n á fi lọ ṣàyẹ̀wò tàbí kí wọ́n lọ tọ́jú ara wọn dáadáa

Àwọn èèyàn tí kò fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣeré. Àwọn kan wà tí wọ́n fẹ́ràn ẹ, lára wọn ni àwọn ìdílé rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ àwọn lógún. Àwọn míì tún wà tí wọ́n fẹ́ràn ẹ àmọ́ tó ṣeé ṣe kó o má mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń wàásù wọ́n máa ń pàdé àwọn tí ìbánújẹ́ dorí wọn kodò, tí wọ́n sì sọ pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ ti lè gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé ti mú kí wọ́n lè ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ Jésù làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn fi jẹ wọ́n lógún. Ọ̀rọ̀ tìẹ náà sì jẹ wọ́n lógún.—Jòhánù 13:35.

Àwọn dókítà. Ohun tó sábà máa ń mú kéèyàn máa ronú àtipara ẹ̀ ni ìmọ̀lára àti ìṣesí tó ń yí pa dà bìrí, irú bí ìsoríkọ́ tó lágbára gan-an. Kì í ṣe ohun ìtìjú rárá tó o bá ní ìsoríkọ́, bó ṣe jẹ́ pé o kì í tijú tí ara rẹ ò bá yá. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ìsoríkọ́ jẹ́ “àìsàn tó lè ṣe ọpọlọ nígbàkigbà.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló lè ní in, kì í sì í ṣe àìsàn tí kò gbóògùn. a

MÁA RÁNTÍ PÉ: Ńṣe ni ìsoríkọ́ dà bí ìgbà tó o wà nínú kòtò jíjìn kan, o ò lè dá jáde níbẹ̀. Àmọ́, tẹ́nì kan bá ràn ẹ́ lọ́wọ́, o bọ́ nínú ẹ̀.

OHUN TÓ O LÈ ṢE LÓNÌÍ: Lọ rí dókítà kan tó máa ń tọ́jú àwọn tí ìmọ̀lára àti ìṣesí wọn máa ń yí pa dà bìrí, irú bí àwọn tó ní ìsoríkọ́.

a Tó bá ń ṣe ẹ́ ní gbogbo ìgbà bíi pé kó o pa ara rẹ, wádìí nípa ibi tó o ti lè gba ìrànlọ́wọ́, o lè pe fóònù ilé ìwòsàn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó fẹ́ pa ara wọn. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti wà ní sẹpẹ́ níbẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.