Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Owó

Owó

Ṣé owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo?

“Ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo.”​—1 Tímótì 6:10, Bibeli Mimọ.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ìfẹ́ owó” ni gbòǹgbò “ohun búburú gbogbo,” kì í ṣe owó fúnra rẹ̀. Nínú Bíbélì, Sólómọ́nì Ọba tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ sọ ohun búburú mẹ́ta tí ojú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó sábà máa ń rí. Ìdààmú: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.” (Oníwàásù 5:12) Àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníwàásù 5:10) Ìwàkiwà: “Ẹni tí ó bá ń ṣe kánkán láti jèrè ọrọ̀ kì yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.” —Òwe 28:20.

Kí ni owó wà fún?

‘Owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’​—Oníwàásù 7:12.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Owó ló ń fúnni ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní pé owó ló ń fúnni ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ jẹ́ ara “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” (Máàkù 4:19) Síbẹ̀, “owó ní ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.” (Oníwàásù 10:19) Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè fi owó ra àwọn nǹkan tó lè gbé ẹ̀mí ró, irú bí oúnjẹ àti oògùn.—2 Tẹsalóníkà 3:12

Èèyàn tún lè fi owó tọ́jú ìdílé. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 5:8.

Báwo lo ṣe lè fi ọgbọ́n náwó?

‘Kọ́kọ́ jókòó, kí o sì gbéṣirò lé ìnáwó náà.’​—Lúùkù 14:28.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Lo owó lọ́nà tí inú Ọlọ́run dùn sí. (Lúùkù 16:9) Kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu kéèyàn kàn máa ra gbogbo nǹkan tó bá ṣáà ti wù ú, ó sì yẹ kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. (Hébérù 13:18) Kó o má bàa kó ara ẹ sí wàhálà torí pé ò ń ná kọjá owó tó ń wọlé fún ẹ, jẹ́ “kí ọ̀nà ìgbésí ayé [rẹ] wà láìsí ìfẹ́ owó.” —Hébérù 13:8

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ pé ó burú kéèyàn yá owó, ó kìlọ̀ pé: ‘Ajigbèsè ni ìránṣẹ́ onígbèsè.’ (Òwe 22:7, Bibeli Mimọ) Fara balẹ̀ ronú dáadáa kó o tó ra nǹkan, torí pé “àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Ńṣe ni kó o “ya ohun kan sọ́tọ̀ gédégbé ní ìpamọ́,” kó o sì tọ́jú owó láti fi ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí ẹ.—1 Kọ́ríńtì 16:2.

Bíbélì sọ pé kí á “sọ fífúnni dàṣà.” (Lúùkù 6:38) Ó yẹ káwọn tó bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn jẹ́ ọ̀làwọ́, torí pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Torí náà, “má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.”—Hébérù 13:16.