Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àṣàrò

Àṣàrò

Kí ni àṣàrò?

“Èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—Sáàmù 77:12.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni èèyàn lè gbà ṣe àṣàrò, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀nà yìí ló jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Ìlà Oòrùn àtijọ́ ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá. Nígbà tí òǹkọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa àṣàrò, ó sọ pé, “Téèyàn bá fẹ́ ríran kedere, kò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun tó ń fi ọpọlọ rò.” Ohun tí òǹkọ̀wé yìí sọ fi èrò táwọn kan ní hàn pé, tí èèyàn ò bá fi ọpọlọ ro ohunkóhun tó sì wá tẹjú mọ́ ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán kan, ó máa ń mú kí àlàáfíà jọba lọ́kàn ẹni, kí ìrònú èèyàn já geere, ó sì tún ń mú kéèyàn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kéèyàn máa ṣàṣàrò. (1 Tímótì 4:15) Àmọ́, irú àṣàrò tí Bíbélì sọ pé ká máa ṣe kò gba pé kéèyàn má ṣe fi ọpọlọ ro ohunkóhun tàbí kéèyàn máa tún ọ̀rọ̀ kan sọ léraléra, èyí tí àwọn kan máa ń pè ní mantra. Dípò ìyẹn, ohun tí àṣàrò tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fara balẹ̀ ronú lórí àwọn nǹkan rere, bí irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, àwọn ìlànà rẹ̀ àtàwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ọkùnrin olóòótọ́ kan sọ nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.” (Sáàmù 143:5) Ó tún sọ pé: “Nígbà tí mo rántí rẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi, mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru.”—Sáàmù 63:6.

Àǹfààní wo ni àṣàrò lè ṣe fún ẹ?

“Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.”Òwe 15:28.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tó dára, á mú kí ìwà wa dára sí i, á mú ká túbọ̀ máa kó ara wa níjàánu, á sì jẹ́ ká lè máa sá fún àwọn ìwà tí kò dára. Gbogbo nǹkan yìí ló ń mú ká máa ronú jinlẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀ àti ká tó hùwà. (Òwe 16:23) Torí náà, irú àwọn àṣàrò yìí wà lára ohun tó máa ń mú kéèyàn láyọ̀, kí ìgbésí ayé èèyàn sì nítumọ̀. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó máa ń ṣàṣàrò déédéé nípa Ọlọ́run, ó ní: “Òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:3.

Àṣàrò tún máa ń mú kí nǹkan tètè yéni, ó sì ń mú kéèyàn túbọ̀ máa rántí nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ̀dá tàbí à ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ni la máa ń kọ́. Tá a bá wá ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá a kọ́ yẹn, a máa rí bí wọ́n ṣe tan mọ́ra àti bí wọ́n ṣe tan mọ́ àwọn nǹkan tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Nípa báyìí, bó ṣe jẹ́ pé káfíńtà kan máa ń to igi jọ táá sì fi kọ́ ilé tó jojú ní gbèsè, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ṣíṣe àṣàrò máa ń mú kéèyàn lè “ṣàkójọ” àwọn nǹkan téèyàn ti kẹ́kọ̀ọ́, kéèyàn sì sọ wọn di odindi.

Ǹjẹ́ ó yẹ kéèyàn máa ṣèkáwọ́ ọkàn rẹ̀ bó ṣe ń ṣàṣàrò?

‘Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, o sì burú jáì! Ta ni o lè mọ̀ ọ́n?’—Jeremáyà 17:9, Bíbélì Mímọ́.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

‘Láti inú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn, ni àwọn èrò tí ń ṣeni léṣe ti ń jáde wá: àgbèrè, olè jíjà, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, ojúkòkòrò, àwọn iṣẹ́ ìwà burúkú, ẹ̀tàn, ìwà àìníjàánu, ojú tí ń ṣe ìlara àti àìlọ́gbọ́n-nínú.’ (Máàkù 7:21, 22) Ńṣe ni àṣàrò dà bí iná tó ń jó, ó yẹ kéèyàn máa ṣèkáwọ́ rẹ̀! Bá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, èrò tí kò tọ́ lè mú kéèyàn gbé nǹkan burúkú sọ́kàn, ó sì lè burú débi tí èèyàn á fi hùwà burúkú.—Jákọ́bù 1:14, 15.

Bákan náà, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan ‘tí ó jẹ́ òótọ́, tí ó jẹ́ òdodo, tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, tí ó dára ní fífẹ́, tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tí ó jẹ́ ìwà funfun àti ohun tí ó bá yẹ fún ìyìn.’ (Fílípì 4:8, 9) Tá a bá gbin irú àwọn nǹkan yìí sínú ọpọlọ wa, a máa ká àwọn èsò rere bí, àwọn ìwà àtàtà, a ó máa sọ ọ̀rọ̀ tó ní oore ọ̀fẹ́ nínú, àá sì máa ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn.—Kólósè 4:6.