Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kókó Iwájú Ìwé

Bí O Ṣe Lè Láyọ̀

Bí O Ṣe Lè Láyọ̀

“Màá láyọ̀ tí mo bá gbéyàwó, tí mo sì bímọ.”

“Màá láyọ̀ tí mo bá kọ́ ilé tèmi.”

“Màá láyọ̀ tí mo bá rí iṣẹ́ yẹn gbà.”

“Màá láyọ̀ tí . . .”

ṢÉ ÌWỌ náà ti ronú bẹ́ẹ̀ rí? Ó dájú pé inú rẹ dùn nígbà tí ọwọ́ rẹ tẹ ohun tó o fẹ́, àmọ́, ṣé ayọ̀ náà pẹ́? Ká sòótọ́, ayọ̀ ẹni máa ń pọ̀ tọ́wọ́ èèyàn bá ba ohun tó ń wá, ṣùgbọ́n irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í pẹ́ pòórá. Ìdí ni pé àwọn nǹkan téèyàn kó jọ tàbí àṣeyọrí téèyàn ṣe kọ́ ló ń mú kéèyàn ní ayọ̀ tó ń bani kalẹ́. Torí náà, béèyàn bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́, ó ní àwọn nǹkan pàtàkì tó gbọ́dọ̀ ṣe.

Ohun kan ni pé, a yàtọ̀ síra wa. Ohun tó ń fún ẹ láyọ̀ lè má jọ ẹlòmíì lójú. Àti pé, bí a ṣe ń dàgbà ni ìrònú wa ń yí pa dà. Síbẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ohun kan wà tó máa mú kéèyàn túbọ̀ láyọ̀ láìka irú ẹni tá a jẹ́ tàbí ọjọ́ orí wa. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá fẹ́ láyọ̀, ó yẹ kó ní ìtẹ́lọ́rùn, kó má ṣe ìlara àwọn míì, kó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, kó sì ní ìfaradà. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

1. NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN

Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan sọ pé ‘owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ Àmọ́, ó fi kún un pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú.” (Oníwàásù 5:10; 7:12) Kí ló fẹ́ fàyọ? Ohun tó fẹ́ fàyọ ni pé, a nílò owó lóòótọ́, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ẹ̀mí ìwọra torí pé àwọn tó bá lẹ́mìí ìwọra kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ ló sọ̀rọ̀ yìí, ìdí tó sì fi lẹ́nu ọ̀rọ̀ ni pé òun fúnra rẹ̀ ti fìgbà kan rí kó owó àti ọrọ̀ jọ láti mọ̀ bóyá ó lè fúnni láyọ̀ tó máa tọ́jọ́. Ó sọ pé: “Ohunkóhun tí ojú mi fẹ́, ni èmi kò fi dù ú; èmi kò sì fi ohun ayọ̀ kan jẹ ara mi níyà.”—Oníwàásù 1:13; 2:10, BÍBÉLÌ MÍMỌ́.

Sólómọ́nì lówó rẹpẹtẹ, ó kọ́ àwọn ilé ńláńlá, ó ṣe àwọn ọgbà tó rẹwà àti adágún omi tó tura, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní. Gbogbo ohun tó bá ṣáà ti wù ú ló ń nawọ́ gán. Kí ló wá gbẹ̀yìn gbogbo rẹ̀? Òun fúnra rẹ̀ sọ nípa àwọn nǹkan yẹn pé: “Asán ni gbogbo rẹ̀ . . . kò sì sí nǹkan kan tí ó ní àǹfààní.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yẹn kọ́kọ́ fún un láyọ̀, àmọ́ ayọ̀ náà kò tọ́jọ́. Èyí mú káyé tojú sú u! (Oníwàásù 2:11, 17, 18) Àbí ẹ̀ rí nǹkan, Sólómọ́nì kẹ́kọ̀ọ́ pé kéèyàn wa ilé ayé mọ́yà nípa kíko nǹkan rẹpẹtẹ jọ kì í fúnni láyọ̀ tó tọ́jọ́. *

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Sólómọ́nì sọ yìí bá ohun táwọn èèyàn sọ lónìí mu? Ìwé náà, Journal of Happiness Studies sọ pé “a kò nílò owó ju ìwọ̀nba tó lè gbẹ́mìí ró, ohun tó bá ti jùyẹn lọ kọ́ ló máa fi kún ayọ̀ wa.” Kódà, ìwádìí ti jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn bá ń kó nǹkan jọ tó wá tìtorí ẹ̀ lọ hùwàkiwà tàbí tó pa ìjọsìn Ọlọ́run tì, ńṣe ni ayọ̀ rẹ̀ máa dínkù.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”Hébérù 13:5.

2. MÁ ṢE ÌLARA ÀWỌN MÍÌ

Ìlara túmọ̀ sí “kéèyàn máa bínú ẹnì kan torí àǹfààní tó ní, kó sì máa ṣèèyàn bíi pé kí ohun tónítọ̀hún ní di tiwa.” Díẹ̀díẹ̀ ni ẹ̀mí burúkú yìí máa ń wọni lára títí tó máa fi jọba lọ́kàn ẹni, téèyàn ò bá sì ṣọ́ra, ó lè mú kí ìbànújẹ́ dorí ẹni kodò. Kí ló ń fa ìlara? Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá à ń ṣe ìlara àwọn míì? Báwo la ṣe lè fà ẹ̀mí yìí tu kúrò lọ́kàn wa?

Ìwé Encyclopedia of Social Psychology sọ pé àwọn èèyàn sábà máa ń ṣè ìlara àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ kan náà tàbí tí ipò wọn jọra. Bí àpẹẹrẹ, kò dájú pé ẹni tó ń tajà lè máa ṣe ìlara gbajúgbajà òṣèré, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó máa ṣe ìlara ẹlòmíì tí ọjà tirẹ̀ ń tà wàràwàrà.

Irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìjòyè kan ní ìlú Páṣíà ìgbàanì nìyẹn. Àwọn ìjòyè yìí kò ṣe ìlara ọba àmọ́ wọ́n ń ṣe ìlara Dáníẹ́lì ìyẹn ìjòyè míì tó gbọ́n jù wọ́n lọ. Ìgbà tó yá wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bínú Dáníẹ́lì débi pé wọ́n gbìmọ̀ láti pa á! Àmọ́ pàbó ni ètekéte wọn já sí. (Dáníẹ́lì 6:1-24) Ìwé tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó yẹ ká kíyè sára torí pé ìlara máa ń mú ká gbèrò ibi sáwọn ẹlòmíì. Àìmọye ìwà ibi làwọn èèyàn ti hù sẹ́yìn nítorí ẹ̀mí burúkú yìí.” *

Onílara kì í rí ohun tó dáa lára ẹlòmíì

Báwo la ṣe lè mọ̀ pé à ń ṣe ìlara ẹnì kan? Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó máa ń dùn mọ́ mi tí mo bá gbọ́ pé ẹgbẹ́ mi kan ṣàṣeyọrí àbí inú mi máa ń bà jẹ́? Tí ẹ̀gbọ́n mi tàbí àbúrò mi tàbí ọmọ kíláàsì mi tàbí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá ní ìjákulẹ̀, ṣé ó máa ń dùn mí fún un àbí ó máa dùn mọ́ mi?’ Tó bá jẹ pé àṣeyọrí ẹnì kan máa ń bà ẹ́ nínú jẹ́, a jẹ́ pé o ní ẹ̀mí ìlara nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 26:12-14) Ìwé yẹn ṣojú abẹ níkòó, ó ní: “Onílara kì í rí ohun tó dáa lára ẹlòmíì, kì í sì mọyì àwọn àǹfààní tí òun fúnra rẹ̀ ní. . . . Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀.”

Kí la lè ṣe láti mú ẹ̀mí ìlara kúrò lọ́kàn wa? A gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. Àwọn ànímọ́ yìí ló máa jẹ́ ká mọyì ohun táwọn míì lè ṣe, kí inú wá sì dùn sí àṣeyọrí wọn. Bíbélì wá gbà wá nímọ̀ràn pé: ‘Ẹ má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.’—Fílípì 2:3.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”Gálátíà 5:26.

3. NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN DÉNÚ

Ìwé Social Psychology sọ pé: “Ayọ̀ àti ìfọkànbalẹ̀ tá a máa ń ní táwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn sí wa ju èyí tí iṣẹ́, owó, ibi téèyàn ń gbé tàbí ìlera wa pàápàá ń fún wa.” Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ká tó lè láyọ̀, a gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wa. Ọ̀kan nínú àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: ‘Tí èmi kò bá ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.’—1 Kọ́ríńtì 13:2.

Àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Vanessa jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ a máa tún ayé ẹni ṣe. Ọ̀mùtí ni bàbá Vanessa, ó sì máa ń lu Vanessa nílùkulù. Nígbà tí Vanessa pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], ó sá kúrò nílé lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀ kan. Kò pẹ́ tó tún fi kúrò níbẹ̀ tó sì lọ ń sun ilé àwọn ọmọ aláìníbaba. Nígbà tó wà níbẹ̀, ó máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó ṣàánú òun. Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ̀, ó sì fi ìdílé kan kẹ́ ẹ, ìdílé yìí mọyì àwọn ìlànà Bíbélì pàápàá èyí tó sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú, ohun tí òun fúnra rẹ̀ kọ́ nínú Bíbélì sì mú kó borí ìbànújẹ́ àti ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn rẹ̀. Vanessa sọ pé “Èmi tí mo ti máa ń fìdí rẹmi tẹ́lẹ̀ níléèwé wá dẹni tó ń fakọyọ.”

Ìgbésí ayé tí Vanessa gbé látẹ̀yìnwá ṣì máa ń bà á nínú jẹ́. Síbẹ̀, ó ń láyọ̀ báyìí nínú ìdílé tirẹ̀, ó sì ti bí ọmọbìnrin méjì.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”Kólósè 3:14.

4. LẸ́MÌÍ ÌFARADÀ

Kò sẹ́ni tí kò níṣòro láyé yìí. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “ìgbà sísunkún” wà, “ìgbà pípohùnréré ẹkún” náà sì wà. (Oníwàásù 3:4) Àmọ́, ìfaradà máa ń jẹ́ ká lè fàyà rán ìṣòro kó má baà mu wá lómi. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn obìnrin méjì kan tó ń jẹ Carol àti Mildred.

Àìsàn tó ń ṣe Carol ti ba eegun ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́, ó tún ní àrùn àtọ̀gbẹ, kì í mí dáadáa tó bá ń sùn, àìsàn burúkú kan sì ti fọ́ ojú òsì rẹ̀. Carol sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bò mí mọ́lẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àánú ara mi máa ń ṣe mí. Àmọ́, mo tètè máa ń gbé ìrònú yẹn kúrò lọ́kàn, mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìwọ̀nba tí mo lè ṣe pàápàá fún àwọn ẹlòmíì.”

Mildred náà ní oríṣiríṣi àìsàn títí kan àìsàn oríkèé ríro, jẹjẹrẹ inú ọmú àti àrùn àtọ̀gbẹ. Àmọ́ bíi ti Carol, òun náà kì í gbọ́kàn sórí àwọn ìṣòro rẹ̀. Mildred sọ pé: “Mo máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń ṣàárẹ̀, mo sì máa ń tù wọ́n nínú, èyí sì máa ń ràn mí lọ́wọ́. Mo rí i pé bí mo ṣe ń tu àwọn míì nínú kò jẹ́ kí n gbé ìṣòro tèmi sọ́kàn.”

Inú Carol àti Mildred máa ń dùn tí wọ́n bá ń tu àwọn míì nínú

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin méjèèjì yìí ṣì ń wá ìtọ́jú fún àìsàn wọn, síbẹ̀ wọ́n ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àìlera mu wọ́n lómi, wọ́n ṣì ń sapá láti fi àkókò wọn ran àwọn míì lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ ìfaradà wọn máa ń tu ọ̀pọ̀ àwọn tó níṣòro nínú, àwọn èèyàn sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Gbogbo èyí máa ń mú kí wọ́n láyọ̀ láìka ìṣòro wọn sí.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè.”Jákọ́bù 1:12.

Ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa ń “jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀” kìkì tí wọ́n bá ń fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. (Òwe 3:13-18) O ò ṣe wádìí òótọ́ yìí fúnra rẹ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí o lè rí ọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀? Ó ṣe tán, Òǹṣèwé Bíbélì jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì fẹ́ kí ìwọ náà láyọ̀.—1 Tímótì 1:11.

^ ìpínrọ̀ 11 Ìrírí Sólómọ́nì yìí wà nínú ìwé Oníwàásù 2:1-11.

^ ìpínrọ̀ 17 Àpẹẹrẹ míì ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù Kristi. Ìwé Máàkù 15:10 sọ pé ‘ìlara ló mú kí àwọn olórí àlùfáà’ fa Jésù lé àwọn tó máa pa á lọ́wọ́.