KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ BÍBÉLÌ WÚLÒ FÚN WA LÓNÌÍ
Ikora-Eni-Nijaanu
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.”—Òwe 29:11.
“Ńṣe ló dà bíi pé mo ti kú tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá jí mi dìde!”
ÈRÈ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Tá a bá ní ká máa kọ àwọn èrè tó wà nínú kéèyàn máa kó ara rẹ̀ níjàánu, ilẹ̀ á kún! Ó kéré tán, ẹni bá lẹ́mìí ìkóra-ẹni-níjàánu máa ní ìlera tó dáa. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè.” Ó tún sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” (Òwe 14:30; 17:22) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí torí ìwádìí fi hàn pé àìsàn kì í jìnnà sáwọn tó máa ń bínú, pàápàá àìsàn ọkàn. Àmọ́ ṣá, èrè tó wà nínú kéèyàn máa kó ara rẹ̀ níjàánu ju kéèyàn ní ìlera tó dáa.
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Cassius tó ti lé ní ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún sọ pé: “Onígbòónára àti oníbìínú èèyàn ni mí tẹ́lẹ̀, mo sì máa ń wájà àwọn èèyàn. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ ka ara mi sí, àmọ́ mo yíwà mi pa dà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Mo kọ́ béèyàn ṣe ń kó ara rẹ̀ níjàánu àti béèyàn ṣe ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀ kó sì máa dárí jini. Ká ní kì í ṣe àwọn ìlànà Bíbélì tí mo fi sílò ni, ẹ̀wọ̀n ni mi ò bá wà. Ńṣe ló dà bíi pé mo ti kú tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá jí mi dìde!”