Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ BÍBÉLÌ WÚLÒ FÚN WA LÓNÌÍ

Isotito Laaarin Tokotaya

Isotito Laaarin Tokotaya

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.”Hébérù 13:4.

ÈRÈ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Àwọn kan rò pé ọ̀rọ̀ Bíbélì yẹn ò bóde mu mọ́. Àmọ́ èrò wọn ò tọ̀nà rárá! Àìṣòótọ́ ò dáa, ohun tí ò dáa ò sì lórúkọ méjì. Àti pé ìbànújẹ́ tó máa ń fà kọjá àfẹnusọ.—Òwe 6:34, 35.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jessie tó ti gbéyàwó tó sì ti bímọ sọ pé: “Torí pé mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi dénú, mi ò lójú míì síta, èyí tí mú kí okùn ìfẹ́ wa lágbára sí i. Mo rí i pé ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí tọkọtaya máa bá ara wọn sọ òótọ́. Àìṣòótọ́ máa ń da àárín tọkọtaya rú” ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ipa tó máa ní lórí àwọn ọmọ!

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ligaya * gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ da ìgbéyàwó rẹ̀ rú. Ligaya sọ pé: “Ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ ló fa ìṣòro mi, mo máa ń bá wọn lọ sí àríyá alaalẹ́ tá a ti máa ń ṣe ìranù, ibẹ̀ ni mo ti ṣe àṣemáṣe tó mú kí n dalẹ̀ ọkọ mi.” Ohun tó ṣe yìí ba ayọ̀ rẹ̀ jẹ́, òun àti ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn fà á, gbogbo nǹkan wá tojú sú u. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo rí gbogbo wàhálà tí mo kó ara mi sí, mo wá rí i pé òótọ́ ni gbogbo ohun táwọn òbí mi ti máa ń sọ fún mi pé, ‘ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.’”—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Ligaya ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àmọ́ kí nǹkan tó bà jẹ́ jìnnà, mo pinnu láti jáwọ́ nínú gbogbo ìranù yẹn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo sapá gan-an láti fi ohun tí mò ń kọ́ sílò.” Ìgbà yẹn ni àárín òun àti ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gún. Ó wá sọ nígbẹ̀yìn pé: “Bí Ọlọ́run ṣe bá mi tún ìgbéyàwó mi tò nìyẹn o. Bíbélì ti tún ayé mi ṣe, mi ò sì kábàámọ̀ pé mo jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú àtàwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́.”

^ ìpínrọ̀ 6 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.