Kókó Iwájú Ìwé
Nje Bibeli Wulo Fun Wa Lonii?
‘Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí màá láyọ̀ láyé mi.’
Ọ̀GBẸ́NI kan tó ń jẹ́ Hilton gbádùn eré àwọn tó máa ń kan ẹ̀ṣẹ́, àtìgbà tó sì ti wà ní ọmọ ọdún méje ló ti n kan ẹ̀ṣẹ́ kiri! Nígbà tó wà níléèwé gíga, ńṣe lòun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń rìn kiri inú ọgbà láti wá ẹni tí wọ́n máa lù. Hilton sọ pé nígbà yẹn, “mo máa ń jalè, mò ń ta tẹ́tẹ́, mò ń wo ìwòkuwò, mo máa ń fòòró àwọn obìnrin, mo tún máa ń bú àwọn òbí mi. Ìwà mi burú débi pé àwọn òbí mi ò rò pé mo lè yíwà pa dà mọ́ láé. Nígbà tí mo jáde iléèwé, mo kúrò nílé.”
Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí Hilton pa dà wálé, àwọn òbí rẹ̀ ṣì í mọ̀, ńṣe ló ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kò fa wàhálà mọ́, ó sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Kí ló ran Hilton lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà yìí? Nígbà tó kúrò nílé lọ́dún náà lọ́hùn-ún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Ó wá ṣàyẹ̀wò Bíbélì kó lè rí ìrànlọ́wọ́ tó máa mú kó yíwà pa dà. Hilton sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tí mò ń kọ́ sílò, èyí gba pé kí n jáwọ́ nínú àwọn ìwà mi àtijọ́, kí n sì máa tẹ̀ lé àṣẹ tó wà nínú ìwé Éfésù 6:2, 3 tó ni ká bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wa. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí mo ṣe ohun tó múnú àwọn òbí mi dùn, tó sì fún èmi náà láyọ̀!”
Ìtàn ráńpẹ́ tá a sọ nípa Hilton yìí fi hàn pé Bíbélì máa ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe. (Hébérù 4:12) Bíbélì lè mú ká ní àwọn ìwà rere bíi jíjẹ́ olóòótọ́, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́ láàárín tọkọtaya. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn nǹkan yìí ṣe lè mú kí ayé wa dára sí i.