Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Tete Tita

Tete Tita

Àwọn kan máa ń wo tẹ́tẹ́ títa bí eré ọwọ́ lásán, àmọ́ àwọn míì kà á sí àṣà tó léwu.

Ṣé ó burú láti ta tẹ́tẹ́?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ò rí nǹkan tó burú nínú títa tẹ́tẹ́, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé èyí tó bófin mu ni wọ́n ta. Irú àwọn tẹ́tẹ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ èyí tí ìjọba fọwọ́ sí, tí wọ́n sì fi ń pa owó tí wọ́n á fi ṣe àwọn nǹkan tó máa ṣe àwọn aráàlú láǹfààní.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò mẹ́nu kan tẹ́tẹ́ títa ní tààràtà. Síbẹ̀, ó fún wa ní àwọn ìlànà tó máa jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó.

Ohun tó wà nínú tẹ́tẹ́ ni pé kéèyàn ṣáà ti jẹ owó láìka bóyá ẹlòmíì pàdánù owó tirẹ̀. Èrò yìí ta ko ìkìlọ̀ tí Bíbélì fún wa pé ká “ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò [tàbí ìwọra].” (Lúùkù 12:15) Ìwọra ló máa ń sún èèyàn sídìí tẹ́tẹ́. Àwọn iléeṣẹ́ tẹ́tẹ́ máa ń polówó pé èèyàn máa jẹ owó rẹpẹtẹ, àmọ́ wọn kì í sọ bó ṣe máa ṣòro tó láti jẹ irú owó bẹ́ẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé táwọn èèyàn bá ń ronú nípa owó tí wọ́n máa jẹ, èyí á mú kí wọ́n fi owó púpọ̀ ta tẹ́tẹ́ náà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tẹ́tẹ́ kì í mú kéèyàn yẹra fún ìwọra, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń mú kí èèyàn máa wá owó òjijì.

Tẹ́tẹ́ títa máa ń sọ àwọn èèyàn di onímọtara-ẹni-nìkan torí pé, béèyàn ṣe máa jẹ owó àwọn ẹlòmíì ni á máa rò. Àmọ́, Bíbélì gbà wá níyànjú pé, “kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Kódà, ọ̀kan nínú àwọn Òfin Mẹ́wàá sọ pé: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ . . . ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:17) Tí ẹni tó ta tẹ́tẹ́ bá ń ronú nípa bó ṣe máa jẹ owó, ńṣe ló ń wá káwọn míì pàdánù owó wọn, kí gbogbo owó náà lè jẹ́ tirẹ̀.

Bíbélì tún dẹ́bi fún wíwá oríire, ìyẹn ohun kan bí agbára àràmàǹdà tí àwọn kan gbà pé ó ń sọni di olówó. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í “tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire.” Ǹjẹ́ Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba jíjọ́sìn “ọlọ́run Oríire?” Rárá o, torí ó sọ fún wọn pé: “Ẹ sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi, ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn.”—Aísáyà 65:11, 12.

Òótọ́ ni pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, owó tí ìjọba bá rí nídìí tẹ́tẹ́ tí wọ́n gbé kalẹ̀ ni wọ́n fi ń bójú tó ìmọ̀ ẹ̀kọ́, wọ́n fi ń tún ìlú ṣe, wọ́n sì fi ń ṣe àwọn ètò míì táá ṣe àwọn aráàlú láǹfààní. Àmọ́, ohun tí wọ́n ń fi owó náà ṣe kọ́ ló jà jù, bí kò ṣe ibi tí wọ́n ti rí owó náà, ìyẹn nídìí àwọn àṣà tó ń gbé ìwà ìwọra àti ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan lárugẹ, tó sì ń mú káwọn èèyàn máa wá bí wọ́n á ṣe sọ ogún di ogójì.

“Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ . . . ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.”Ẹ́kísódù 20:17.

Àwọn ìṣòro wo ni àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń kó sí??

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kìlọ̀ pé “àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tímótì 6:9) Ìwọra ló ń mú kéèyàn ta tẹ́tẹ́, ìwọra sì burú gan-an débi pé Bíbélì ka “ìwọra” mọ́ àwọn ìwà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún.—Éfésù 5:3.

Tẹ́tẹ́ títa máa ń gbé ìfẹ́ owó lárugẹ torí ó máa ń mú kéèyàn fẹ́ di olówó òjijì. Bíbélì sì sọ pé ìfẹ́ owó ni “gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” Ìfẹ́ owó lè tètè jọba lọ́kan ẹni, kó sì di pé ọ̀rọ̀ àtidolówó lẹni náà á máa lépa débi tí àníyàn á fi gbà á lọ́kàn, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run á sì yingin. Bíbélì lo àpèjúwe kan táá jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí fún àwọn tí ìfẹ́ owó ti dẹkùn mú, ó ní wọ́n máa ń “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.

Ìwọra kì í jẹ́ kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn, owó tẹ́ni tó bá lẹ́mìí ìwọra bá ní kì í tó o, kò sì ní láyọ̀. Bíbélì sọ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”—Oníwàásù 5:10.

Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ ni tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún. Kárí ayé sì ni ìṣòro yìí wà. Wọ́n fojú bù ú pé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ni tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún.

Òwe kan sọ pé: “Ogún ni a ń fi ìwọra kó jọ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún.” (Òwe 20:21) Ìyẹn ni pé téèyàn bá fi ìwọra kó nǹkan ìní jọ, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í da. Tẹ́tẹ́ títa ti sọ àwọn kan di onígbèsè, ó sì ti jẹ́ kí ilé iṣẹ́ àwọn míì dẹnu kọlẹ̀ tàbí kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ó tún máa ń mú kí ìdílé túká tàbí kí àwọn ọ̀rẹ́ jáni jù sílẹ̀. Ẹni tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì kò ní kó sí àwọn ìṣòro tí àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń kó sí, á sì máa láyọ̀.

“Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.”1 Tímótì 6:9.