Jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run Tí Ń Fúnni Ní Òmìnira
“Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” —2 KỌ́R. 3:17.
1, 2. (a) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ òmìnira fi gba àwọn èèyàn lọ́kàn nígbà ayé Pọ́ọ̀lù? (b) Ta ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó lè fúnni ní òmìnira tòótọ́?
ÀWỌN ará Róòmù ìgbàanì gbà pé ọ̀gá làwọn tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe ìdájọ́ òdodo, ká gbèjà òmìnira, ká sì lo òfin bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ibẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ Kristẹni ìgbà yẹn ń gbé. Síbẹ̀, iṣẹ́ àṣekúdórógbó táwọn ẹrú ṣe ló mú kí ilẹ̀ Róòmù gbayì kó sì lágbára. Ìgbà kan wà tó tiẹ̀ jẹ́ pé tá a bá kó èèyàn mẹ́wàá jọ, àá rí ẹrú mẹ́ta nínú wọn. Abájọ tí ọ̀rọ̀ bí gbogbo èèyàn ṣe máa wà lómìnira ṣe gba àwọn èèyàn lọ́kàn, títí kan àwọn Kristẹni.
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ gan-an nípa òmìnira nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. Àmọ́ kì í ṣe òmìnira táwọn èèyàn ń jà fún ló ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí táwọn olóṣèlú ṣèlérí. Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti àǹfààní tá à ń rí nínú ẹbọ ìràpadà Kristi ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ ń polongo fáwọn èèyàn, kì í ṣe bí àwọn olóṣèlú ṣe máa mú òmìnira wá. Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ káwọn Kristẹni mọ Ẹni tó ń fúnni ní òmìnira tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Jèhófà 2 Kọ́r. 3:17.
ni Ẹ̀mí náà; níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.”—3, 4. (a) Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 3:17? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè gbádùn òmìnira tí Jèhófà ń fúnni?
3 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó ti kọ́kọ́ sọ nípa ìgbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ lórí Òkè Sínáì tí ògo Jèhófà sì ń tàn lójú rẹ̀ lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Jèhófà bá a sọ̀rọ̀. Nígbà táwọn èèyàn rí Mósè, ẹ̀rù bà wọ́n débi pé Mósè ní láti fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. (Ẹ́kís. 34:29, 30, 33; 2 Kọ́r. 3:7, 13) Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé pé: “Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá yíjú sí Jèhófà, ìbòjú náà a ká kúrò.” (2 Kọ́r. 3:16) Kí lohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí túmọ̀ sí?
4 Bá a ṣe ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo nìkan ló ní òmìnira ní gbogbo ọ̀nà tí kò sì sí ẹnikẹ́ni tó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé níbi tí Jèhófà bá wà tàbí ‘níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá wà,’ òmìnira wà níbẹ̀. Torí náà, tá a bá máa jadùn òmìnira yìí, a gbọ́dọ̀ “yíjú sí Jèhófà,” ìyẹn ni pé, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àárín àwa àti Jèhófà gún régé. Dípò káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé Mósè ronú nípa àǹfààní tí wọ́n ní láti jọ́sìn Jèhófà, àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní Íjíbítì ló gbà wọ́n lọ́kàn. Ṣe ló dà bíi pé ìbòjú bo ọkàn wọn àti èrò orí wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, ọkàn wọn sì yigbì débi pé kò sóhun míì tí wọ́n ń rò kọjá nǹkan tara.—Héb. 3:8-10.
5. (a) Irú òmìnira wo ni ẹ̀mí Jèhófà ń fúnni? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé téèyàn bá tiẹ̀ wà lẹ́wọ̀n ó ṣì lè gbádùn òmìnira tí Jèhófà ń fúnni? (d) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
5 Òmìnira tí ẹ̀mí Jèhófà ń fúnni kọjá òmìnira èyíkéyìí téèyàn lè fúnni. Ẹ̀mí Jèhófà máa mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, yàtọ̀ síyẹn, ó ń mú ká bọ́ lọ́wọ́ ìsìn èké àtàwọn àṣà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, kò sì sẹ́ni tó lè dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn nǹkan yìí. (Róòmù 6:23; 8:2) Ó dájú pé òmìnira tí kò lẹ́gbẹ́ lèyí jẹ́! Èèyàn lè jadùn òmìnira yìí kódà bó tiẹ̀ wà lẹ́wọ̀n tàbí tó jẹ́ ẹrú. (Jẹ́n. 39:20-23) Àpẹẹrẹ kan ni ti Arábìnrin Nancy Yuen àti Arákùnrin Harold King, tí wọ́n lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. Ìrírí wọn wà lórí Tẹlifíṣọ̀n JW. (Wo abẹ́ ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ ÀTI ÌRÍRÍ > BÍ A ṢE Ń FARA DA ÀDÁNWÒ.) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó méjì yìí. Àkọ́kọ́, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì òmìnira tí Jèhófà ń fún wa? Ìkejì, kí la lè ṣe tá ò fi ní ṣi òmìnira wa lò?
MỌYÌ ÒMÌNIRA TÓ O NÍ
6. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé wọn ò mọyì òmìnira tí Jèhófà fún wọn?
6 Tá a bá mọyì ẹ̀bùn iyebíye tẹ́nì kan fún wa, a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọyì òmìnira tí Jèhófà fi jíǹkí wọn lẹ́yìn tó dá wọn nídè kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Láàárín oṣù mélòó kan péré tí wọ́n kúrò níbẹ̀, ṣe lọkàn wọn ń fà sí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní Íjíbítì, wọ́n sì ń ráhùn nípa ìpèsè Jèhófà. Kódà, wọ́n ronú láti pa dà sí Íjíbítì. Àbí ẹ ò rí nǹkan, ‘ẹja, apálá, bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti aáyù’ lásánlàsàn ni wọ́n kà sí pàtàkì ju òmìnira tí wọ́n ní láti sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́! Abájọ tí Jèhófà fi bínú sí wọn. (Núm. 11:5, 6, 10; 14:3, 4) Ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn jẹ́ fún wa lónìí!
7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmọ̀ràn tó gba àwọn míì nínú 2 Kọ́ríńtì 6:1 sílò? Báwo làwa náà ṣe lè fara wé e?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé ká má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú òmìnira 2 Kọ́ríńtì 6:1.) Ẹ rántí bó ṣe ká Pọ́ọ̀lù lára tó, tí inú rẹ̀ sì bà jẹ́ pé òun jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé kò sóhun tí òun lè ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ ikú. Síbẹ̀, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” Kí nìdí tó fi ń dúpẹ́? Ó sọ pé: “Nítorí òfin ẹ̀mí yẹn, èyí tí ń fúnni ní ìyè ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù ti dá [yín] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.” (Róòmù 7:24, 25; 8:2) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ káwa náà mọyì bí Jèhófà ṣe dá wa nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ká sì máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.—Sm. 40:8.
tí Jèhófà fún wa nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. (Ka8, 9. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Pétérù fún wa nípa bó ṣe yẹ ká lo òmìnira wa? (b) Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún lónìí?
8 Ó yẹ ká mọyì òmìnira tá a ní, àmọ́ ó tún yẹ ká kíyè sára ká má lọ ṣi òmìnira náà lò. Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ pé ká má ṣe lo òmìnira wa bíi bojúbojú láti lé àwọn nǹkan tara. (Ka 1 Pétérù 2:16.) Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ yẹn ò rán wa létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù? Ká fi sọ́kàn pé àsìkò tiwa yìí burú ju tiwọn lọ, tá ò bá sì ṣọ́ra, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà. Bí àpẹẹrẹ, onírúurú nǹkan ni ayé Sátánì fi ń tan àwọn èèyàn jẹ, bí aṣọ, ìmúra, oúnjẹ, ohun mímu, eré ìnàjú, ìgbafẹ́ àtàwọn nǹkan míì. Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń lo àwọn tó rẹwà kí wọ́n lè fọgbọ́n tan àwọn èèyàn láti ra ohun tí wọn ò nílò. Ẹ ò rí i pé tá ò bá ṣọ́ra, ó rọrùn gan-an láti ṣi òmìnira wa lò.
9 Ìkìlọ̀ Pétérù tún kan àwọn apá míì tó tún ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Ó kan béèyàn ṣe máa kàwé tó, irú iṣẹ́ tó máa ṣe àtohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń rọ àwọn ọ̀dọ́ tó wà nílé ìwé pé kí wọ́n lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó lóókọ. Wọ́n máa ń sọ fún wọn pé tí wọ́n bá kàwé dójú àmì, wọ́n á rí iṣẹ́ gidi tó ń mówó gọbọi wọlé. Kódà, wọ́n máa ń tọ́ka sáwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga máa ń rí towó ṣe ju àwọn tí kò lọ. Èyí ti mú káwọn ọ̀dọ́ kan ronú pé á dáa káwọn lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga káwọn lè rọ́wọ́ mú. Àmọ́ kí ló yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn òbí wọn fi sọ́kàn?
10. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa ṣe?
10 Àwọn kan lè ronú pé ìpinnu ara ẹni làwọn nǹkan yìí, torí náà ohun tó bá wu kálukú ló lè ṣe tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ti gbà á. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n tọ́ka sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ, pé: “Èé ṣe tí ó fi ní láti jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ní ń ṣèdájọ́ òmìnira mi?” (1 Kọ́r. 10:29) Lóòótọ́, kálukú ló máa pinnu ohun tó máa ṣe tó bá kan ọ̀rọ̀ lílọ sí ilé ìwé àtohun téèyàn máa fayé ẹ̀ ṣe. Síbẹ̀, ó yẹ ká rántí pé ó níbi tí òmìnira wa mọ àti pé kò sí ìpinnu téèyàn ṣe tí kì í lérè. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ ṣáájú pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró.” (1 Kọ́r. 10:23) Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lómìnira láti pinnu ohun tá a máa ṣe, àwọn nǹkan pàtàkì míì wà tó yẹ ká ronú lé.
LO ÒMÌNIRA RẸ LÁTI SIN ỌLỌ́RUN
11. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sílẹ̀ lómìnira?
11 Nígbà tí Pétérù ń kìlọ̀ pé ká má ṣi òmìnira wa lò, ó sọ bó ṣe yẹ ká lo òmìnira
wa. Ó rọ̀ wá pé ká lo òmìnira wa “gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run.” Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi tipasẹ̀ Jésù dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni pé ó fẹ́ ká fayé wa sin òun.12. Àpẹẹrẹ wo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi lélẹ̀ fún wa?
12 Tá ò bá fẹ́ ṣi òmìnira wa lò, tá ò sì fẹ́ káyé sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká jẹ́ kọ́wọ́ wa dí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Gál. 5:16) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Nóà àti ìdílé rẹ̀. Àárín àwọn èèyàn tó ń hùwà ipá tí wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe ni wọ́n gbé. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn náà kéèràn ràn wọ́n. Ọgbọ́n wo ni wọ́n dá sí i? Wọ́n jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí nínú iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Bí wọ́n ṣe ń kan ọkọ̀ áàkì náà ni wọ́n ń ṣètò oúnjẹ táwọn àti àwọn ẹranko máa jẹ, wọ́n sì tún ń wàásù ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Bíbélì sọ pé: ‘Nóà ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.’ (Jẹ́n. 6:22) Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Nóà àti ìdílé rẹ̀ la ìparun ayé búburú yẹn já.—Héb. 11:7.
13. Iṣẹ́ wo ni Jésù gbà tó sì tún gbé fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
13 Kí ni Jèhófà pa láṣẹ pé káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe lónìí? Torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, a mọ iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká máa ṣe. (Ka Lúùkù 4:18, 19.) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn lónìí ni Sátánì ti fọ́ lójú nípa tẹ̀mí, wọn ò sì mọ̀ pé ìsìn àti òṣèlú ti mú àwọn lẹ́rú, àti pé ṣe làwọn ń sìnrú torí àwọn nǹkan tara. (2 Kọ́r. 4:4) Ojúṣe àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì wá jọ́sìn rẹ̀ torí pé Jèhófà ló ń fúnni lómìnira. (Mát. 28:19, 20) Iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yìí torí pé a máa kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ kan, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, àwọn míì tiẹ̀ kórìíra wa. Àmọ́ torí pé Jèhófà ló pàṣẹ pé ká máa wàásù, ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè lo òmìnira tí mo ní kí n lè túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?’
14, 15. Irú ọwọ́ wo làwọn èèyàn Jèhófà fi ń mú iṣẹ́ ìwàásù lónìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
14 Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti rí i pé ayé yìí máa tó pa run, torí náà wọ́n ti pinnu láti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. (1 Kọ́r. 9:19, 23) Àwọn kan ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà lágbègbè wọn, àwọn kan sì ti lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ní ọdún márùn-ún tó kọjá, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì lọ́nà igba àti ààbọ̀ [250,000] ló di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn sì ti mú kí iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé lé ní mílíọ̀nù kan báyìí. Àbí ẹ ò rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ torí pé wọ́n ń lo òmìnira wọn láti sìn ín ní kíkún!—Sm. 110:3.
15 Kí ló ran àwọn ará yìí lọ́wọ́ láti lo òmìnira wọn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó ti sìn lónírúurú orílẹ̀-èdè fún ọgbọ̀n [30] ọdún. John àti Judith lorúkọ wọn. Wọ́n sọ pé nígbà tí ètò Ọlọ́run dá Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà sílẹ̀ lọ́dún 1977, wọ́n rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Kí John àti Judith náà lè ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni John ní láti pààrọ̀ iṣẹ́ tó ń ṣe kí wọ́n lè gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. Nígbà tó yá, wọ́n kó lọ sórílẹ̀-èdè míì níbi tí àìní gbé pọ̀. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, kò rọrùn fún wọn láti kọ́ èdè àti àṣà ibẹ̀, ojú ọjọ́ ibẹ̀ ò sì tètè mọ́ wọn lára. Àmọ́, àdúrà àtọkànwá àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́, kò sì pẹ́ tí ara wọn fi mọlé. Báwo ni iṣẹ́ tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe yìí ṣe rí lára wọn? John sọ pé: “Mo gbà pé ohun tó dáa jù ni mo fi ìgbésí ayé mi ṣe. Ṣe ni Jèhófà wá dà bí bàbá tí mò ń rí lójoojúmọ́, ó sì ń fìfẹ́ hàn sí mi bí bàbá ṣe ń ṣe sáwọn ọmọ rẹ̀. Mo ti wá túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú Jákọ́bù 4:8 tó sọ pé: ‘Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.’ Ọkàn mi balẹ̀, mo ní ìtẹ́lọ́rùn, ohun tí mo sì fẹ́ gan-an nìyẹn.”
16. Báwo làwọn tí ipò wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbà wọ́n láyè ṣe lo òmìnira wọn?
16 Ipò àwọn kan ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bíi ti John àti Judith, síbẹ̀ àwọn náà ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún fúngbà díẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tí ètò Ọlọ́run ń ṣe kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] ló lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, New York. Àwọn kan lára wọn lo ọ̀sẹ̀ méjì nígbà táwọn míì sì lò tó ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà, ọ̀pọ̀ wọn ló filé fọ̀nà sílẹ̀, àwọn míì tiẹ̀ fiṣẹ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ká sòótọ́, àwọn tá a sọ yìí lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn lọ́nà tó dáa torí pé wọ́n mú ìyìn àti ògo wá fún Jèhófà. Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fáwa náà.
17. Ìbùkún wo làwọn tó ń fi ọgbọ́n lo òmìnira wọn máa rí lọ́jọ́ iwájú?
17 A dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá pé a mọ Jèhófà, a sì ń gbádùn òmìnira tí ìsìn tòótọ́ ń fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe àwọn ìpinnu tó fi hàn pé a mọyì òmìnira wa. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣi òmìnira náà lò, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ ká máa lo ara wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa gbádùn àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.