ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17
Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Borí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
“A ní ìjà kan . . . pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.”—ÉFÉ. 6:12.
ORIN 55 Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Bó ṣe wà nínú Éfésù 6:10-13, kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́? Ṣàlàyé.
JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ń gbà fìfẹ́ hàn ni bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ọ̀tá wa. Olórí ọ̀tá wa ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún wọn, ó sì tún sọ bá a ṣe lè bá wọn jà, ká sì borí wọn. (Ka Éfésù 6:10-13.) Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, tá a sì gbára lé e pátápátá, àá borí Sátánì Èṣù. Àwa náà lè nírú ìdánilójú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ pé: “Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?”—Róòmù 8:31.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ló gba àwa Kristẹni tòótọ́ lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa túbọ̀ mọ Jèhófà ká sì máa jọ́sìn rẹ̀ nìṣó. (Sm. 25:5) Bó ti wù kó rí, ó ṣe pàtàkì ká mọ àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ò fẹ́ kó fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ tàn wá jẹ. (2 Kọ́r. 2:11; àlàyé ìsàlẹ̀) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ọ̀nà kan gbòógì tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. A tún máa sọ bá a ṣe lè bá wọn jà, ká sì borí wọn.
BÍ ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ ṢE Ń ṢI ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́NÀ
3-4. (a) Kí ni ìbẹ́mìílò? (b) Báwo ni àṣà ìbẹ́mìílò ṣe gbilẹ̀ tó?
3 Ọ̀nà kan gbòógì tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ni ìbẹ́mìílò. Àwọn abẹ́mìílò gbà pé *
àwọn mọ ohun táwọn míì ò mọ̀, àwọn sì lágbára àrà ọ̀tọ̀ láti darí àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àtàwọn awòràwọ̀ gbà pé àwọn lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn míì máa ń ṣe bíi pé àwọn ń bá òkú sọ̀rọ̀. Àwọn kan gbà pé àjẹ́ làwọn, àwọn míì sì ń pidán, wọ́n máa ń gbìyànjú láti fi èèdì di àwọn èèyàn tàbí láti tú wọn sílẹ̀.4 Báwo ni àṣà ìbẹ́mìílò àti ìgbàgbọ́ nínú agbára abàmì ṣe gbilẹ̀ tó? Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè méjìdínlógún (18) ní Latin America àtàwọn erékùṣù Caribbean, wọ́n rí i pé ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn ibẹ̀ ló gbà gbọ́ nínú idán pípa, iṣẹ́ àjẹ́ tàbí iṣẹ́ oṣó, wọ́n sì tún gbà pé ó ṣeé ṣe láti bá òkú sọ̀rọ̀. Wọ́n tún ṣe irú ìwádìí kan náà láwọn orílẹ̀-èdè méjìdínlógún (18) nílẹ̀ Áfíríkà. Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn tó ju ìdajì ló gbà gbọ́ pé àwọn àjẹ́ wà. Kókó ibẹ̀ ni pé, ibi yòówù ká máa gbé, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò. Ó ṣe tán, ohun tí Sátánì ń wá ni bó ṣe máa ṣi “gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.”—Ìfi. 12:9.
5. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò?
5 “Ọlọ́run òtítọ́” ni Jèhófà. (Sm. 31:5) Torí náà, ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò? Ó kórìíra ẹ̀ tẹ̀gàntẹ̀gàn! Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná, kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, kò gbọ́dọ̀ pidán, kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, kò gbọ́dọ̀ di oṣó, kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́, kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú. Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.” (Diu. 18:10-12) Òótọ́ ni pé àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. Síbẹ̀, ohun tó dájú ni pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò kò yí pa dà.—Mál. 3:6.
6. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń lo ìbẹ́mìílò láti fa àkóbá fáwọn èèyàn? (b) Bó ṣe wà nínú Oníwàásù 9:5, ipò wo làwọn òkú wà?
6 Jèhófà kìlọ̀ pé ká má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò torí pé ó máa ń fa àkóbá. Sátánì ń tipasẹ̀ ìbẹ́mìílò tan irọ́ kálẹ̀ pé àwọn òkú máa ń lọ gbé níbòmíì. (Ka Oníwàásù 9:5.) Ó tún máa ń lo ìbẹ́mìílò láti dẹ́rù ba àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa sin Jèhófà. Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé káwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò máa wá ìrànwọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù dípò Jèhófà.
BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ
7. Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀?
7 Bá a ṣe sọ lókè, Jèhófà sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká mọ̀ fún wa ká má bàa kó sínú pańpẹ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìgbésẹ̀ pàtó tá a lè gbé láti bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jà ká sì borí wọn.
8. (a) Kí ni ọ̀nà tó lágbára jù lọ tá a lè gbà borí àwọn ẹ̀mí èṣù? (b) Báwo ni Sáàmù 146:4 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé irọ́ ni Sátánì pa nípa ipò táwọn òkú wà?
8 Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o sì máa ṣàṣàrò nípa ohun tó o kà. Ọ̀nà tó lágbára jù lọ tó o lè gbà já irọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ nìyí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí idà tó mú, ó sì lágbára láti já irọ́ Sátánì. (Éfé. 6:17) Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ ká mọ̀ pé kò ṣeé ṣe fún ẹni tó wà láàyè láti bá òkú sọ̀rọ̀. (Ka Sáàmù 146:4) Ó tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà nìkan ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tí kò sì ní tàsé. (Àìsá. 45:21; 46:10) Torí náà, tá a bá ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀ déédéé, a ò ní gba Sátánì gbọ́, kódà àá kórìíra gbogbo irọ́ táwọn ẹ̀mí èṣù ń pa.
9. Àwọn àṣà tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò wo ló yẹ ká sá fún?
9 Má ṣe lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Torí pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, a kì í lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Bí àpẹẹrẹ, a kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn abẹ́mìílò èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ la ò kì í wá bá a ṣe máa bá òkú sọ̀rọ̀ lọ́nàkọnà. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a kì í lọ́wọ́ nínú àṣà ìsìnkú tó ń fi hàn pé àwọn òkú ṣì wà láàyè níbì kan. Bákan náà, a kì í jẹ́ káwọn awòràwọ̀ àtàwọn woṣẹ́woṣẹ́ sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la fún wa. (Àìsá. 8:19) A mọ̀ dáadáa pé gbogbo àwọn àṣà yìí léwu gan-an, wọ́n sì lè mú kéèyàn ní àjọṣe pẹ̀lú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.
10-11. (a) Kí làwọn kan ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (b) Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:21, kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Kó gbogbo nǹkan tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò jù nù. Àwọn kan tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nílùú Éfésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ti máa ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò tẹ́lẹ̀. Àmọ́ nígbà tí wọ́n lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ akin. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń pidán kó àwọn ìwé wọn jọ, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo èèyàn.” (Ìṣe 19:19) Àwọn tá à ń sọ yìí mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn yọwọ́yọsẹ̀ nínú ìbẹ́mìílò. Owóbówó làwọn ìwé idán yẹn. Síbẹ̀, ńṣe ni wọ́n dáná sun àwọn ìwé náà, wọn ò fún ẹlòmíì, wọn ò sì tà wọ́n. Bí wọ́n ṣe máa múnú Jèhófà dùn ló jẹ wọ́n lógún, kì í ṣe iye tí wọ́n máa rí ká sọ pé wọ́n ta àwọn ìwé náà.
11 Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká kó gbogbo nǹkan tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò jù nù. Lára wọn ni ìfúnpá, bàǹtẹ́, ìgbàdí, àlùwó, ońdè, òkígbẹ́, ìwé idán àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn máa ń lò láti fi dáàbò bo ara wọn.—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:21.
12. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa nípa eré ìnàjú tá à ń gbádùn?
12 Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú eré ìnàjú tó ò ń lọ́wọ́ sí. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn ìwé tí mò ń kà tàbí àwọn nǹkan tí mò ń kà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kò ní ọ̀rọ̀ awo nínú? Ṣé àwọn orin tí mò ń gbọ́, àwọn fíìmù àti eré orí tẹlifíṣọ̀n tí mò ń wò, títí kan géèmù tí mò ń gbá kò ní ìbẹ́mìílò nínú? Ṣé àwọn nǹkan míì tí mo fi ń najú kò ní ohun tó jẹ́ ìbẹ́mìílò nínú? Bí àpẹẹrẹ, ṣé kò ní àwọn oṣó, ẹlẹyẹ, iwin, àǹjọ̀nú, ṣẹranko-ṣènìyàn, àwọn mùjẹ̀mùjẹ̀, babaláwo àtàwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn míì nínú? Ṣé kò ní idán pípa, àwọn tó ń fi èèdì di àwọn míì tàbí àwọn tó ń sa oògùn nínú, tí wọ́n sì ń ṣe é bíi pé kò sóhun tó burú ńbẹ̀?’ Àmọ́ o, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo ìtàn àròsọ tàbí eré ìnàjú ló ní ìbẹ́mìílò nínú. Síbẹ̀, nígbàkigbà tó o bá fẹ́ yan eré ìnàjú, rí i dájú pé o yan èyí táá jẹ́ kó o jìnnà pátápátá sóhun tí Jèhófà kórìíra. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti rí i pé ‘ẹ̀rí ọkàn wa mọ́’ níwájú Jèhófà.—Ìṣe 24:16. *
13. Kí ni kò yẹ ká máa ṣe?
1 Pét. 2:21) Kí Jésù tó wá sáyé, kò sóhun tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń ṣe tí kò mọ̀. Àmọ́ kì í ṣe ìròyìn nípa wọn ló ń sọ fáwọn èèyàn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Jésù, kì í ṣe agbẹnusọ fún Sátánì. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara wé Jésù, ká má ṣe máa ròyìn ohun táwọn ẹ̀mí èṣù ń ṣe. Ṣe ló yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa fi hàn pé ‘ohun rere ló ń gbé wa lọ́kàn,’ ìyẹn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Sm. 45:1.
13 Má ṣe máa ròyìn ohun táwọn ẹ̀mí èṣù ń ṣe. Àpẹẹrẹ Jésù ló yẹ ká tẹ̀ lé nínú ọ̀rọ̀ yìí. (14-15. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ lónìí?
14 Má ṣe bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Nínú ayé burúkú yìí, kò sí kí nǹkan burúkú má ṣẹlẹ̀. Ìjàǹbá, àìsàn àti ikú lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, àmọ́ kò yẹ ká máa ronú pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló fà á. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. (Oníw. 9:11) Bákan náà, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà lágbára ju àwọn ẹ̀mí èṣù lọ fíìfíì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà kò jẹ́ kí Sátánì pa Jóòbù. (Jóòbù 2:6) Nígbà tí Mósè wà láyé, Jèhófà fi hàn pé òun lágbára ju àwọn àlùfáà onídán ilẹ̀ Íjíbítì lọ. (Ẹ́kís. 8:18; 9:11) Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà, Jésù tí Ọlọ́run ṣe lógo fi agbára rẹ̀ hàn nígbà tó lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, tó sì jù wọ́n sí ayé. Lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà, ó máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níbi tí wọn ò ti ní lè ṣèpalára fún ẹnikẹ́ni mọ́.—Ìfi. 12:9; 20:2, 3.
15 Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé Jèhófà ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ lónìí. Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ibi gbogbo láyé la ti ń wàásù tá a sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 28:19, 20) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń tú àṣírí Sátánì, a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni ibi ni. Ó dájú pé ká ní Sátánì lágbára ẹ̀ ni, ì bá ti dá iṣẹ́ náà dúró, àmọ́ kò lágbára ẹ̀. Torí náà, kò sídìí pé à ń bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. A mọ̀ pé “ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.” (2 Kíró. 16:9) Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àwọn ẹ̀mí èṣù kò ní lè ṣe ìpalára ayérayé fún wa.
JÈHÓFÀ MÁA BÙ KÚN ÀWỌN TÓ BÁ GBA ÌRÀNLỌ́WỌ́ RẸ̀
16-17. Sọ àpẹẹrẹ ẹnì kan tó fìgboyà kojú àwọn ẹ̀mí èṣù.
16 Ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè dúró lórí ìpinnu tó ṣe pé òun ò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run, pàápàá lójú àtakò látọ̀dọ̀ mọ̀lẹ́bí. Bó ti wù kó rí, Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá dúró lórí ìpinnu wọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arábìnrin Erica tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Gánà. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ará. Torí pé aláwo ni bàbá rẹ̀, wọ́n fẹ́ kó máa bá wọn lọ́wọ́ sí àwọn ààtò kan tí wọ́n máa ń ṣe, bíi jíjẹ ẹran tí wọ́n fi rúbọ sí òòṣà ìdílé wọn. Àmọ́ ó kọ̀ láti jẹ ẹran náà, làwọn ìdílé rẹ̀ bá fárígá, wọ́n sọ pé ó tàbùkù sí òòṣà wọn. Wọ́n gbà pé àwọn òòṣà náà máa fi àìsàn kọ lu àwọn, wọ́n á sì mú káwọn ya wèrè.
17 Àwọn ẹbí Erica fúngun mọ́ ọn pé àfi dandan kó lọ́wọ́ sí ààtò náà, àmọ́ kò gbà, wọ́n sì tìtorí ẹ̀ lé e jáde nílé. Bó ṣe dẹni tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ará nìyẹn. Ẹ ò rí bí Jèhófà ṣe bù kún Erica, ó fi ìdílé míì jíǹkí rẹ̀, ìyẹn àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n dà bí ọmọ ìyá rẹ̀. (Máàkù 10:29, 30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹbí rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì dáná sun gbogbo ẹrù ẹ̀, síbẹ̀ Erica ò yé sin Jèhófà. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí. Ó ṣe kedere pé Erica ò bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìdílé rẹ̀, Erica ní, “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́, kí wọ́n lè bọ́ lábẹ́ àjàgà àwọn ẹ̀mí èṣù.”
18. Ìbùkún wo la máa rí gbà tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
18 Kì í ṣe gbogbo wa la máa dojú kọ irú àdánwò tí Erica kojú. Àmọ́, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ kọjú ìjà sáwọn ẹ̀mí èṣù, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí gbà, Sátánì ò sì ní lè fi irọ́ burúkú rẹ̀ ṣì wá lọ́nà. Bákan náà, a ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, okùn àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ lágbára. Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; àmọ́ ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, ó sì máa sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.”—Jém. 4:7, 8.
ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
^ ìpínrọ̀ 5 Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún àwọn ẹ̀mí èṣù, ó sì sọ àkóbá tí wọ́n máa ń fà. Báwo làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe máa ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sí wọn lọ́wọ́? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa kó sí pańpẹ́ wọn.
^ ìpínrọ̀ 3 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ìbẹ́mìílò ni àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tó jẹ mọ́ tàwọn ẹ̀mí èṣù. Lára ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ pé ohun kan wà lára èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn téèyàn bá kú tàbí pé ó ṣeé ṣe láti bá òkú sọ̀rọ̀ bóyá nípasẹ̀ ẹnì kan tó jẹ́ abẹ́mìílò. Yàtọ̀ síyẹn, ìbẹ́mìílò ni téèyàn bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àjẹ́ tàbí iṣẹ́ wíwò. Bá a ṣe lò ó nínú àpilẹ̀kọ yìí, idán pípa wà lára iṣẹ́ awo àti lílo agbára abàmì. Ohun kan náà ni kéèyàn máa sà sí ẹlòmíì, kó fi èèdì dì í tàbí kó tú u sílẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe ìbẹ́mìílò téèyàn bá kàn ń fi ọwọ́ ṣe awúrúju kó lè pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín.
^ ìpínrọ̀ 12 Àwọn alàgbà kò láṣẹ láti ṣòfin nípa irú eré ìnàjú tó yẹ káwọn ará máa wò tàbí lọ́wọ́ sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ láti pinnu ìwé tó máa kà, orin tó máa tẹ́tí sí, fíìmù tó máa wò àtàwọn eré ìnàjú míì tó máa gbádùn. Àwọn olórí ìdílé tó gbọ́n máa ń rí i dájú pé eré ìnàjú tí ìdílé wọn ń gbádùn bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu.—Wo àpilẹ̀kọ yìí lórí jw.org®, “Ṣé Ó Láwọn Fíìmù, Ìwé Tàbí Orin Tẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ò Gbọ́dọ̀ Gbádùn?” lábẹ́ abala NÍPA WA > ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ.
^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Jésù tó jẹ́ Ọba alágbára ló wà nínú àwòrán yìí bó ṣe ń ṣáájú ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì. Ìtẹ́ Jèhófà sì wà lókè téńté wọn.