Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14

Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?

Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?

“Máa wàásù ìhìn rere náà, ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láìkù síbì kan.”​—2 TÍM. 4:5, àlàyé ìsàlẹ̀.

ORIN 57 Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ‘lọ, kí wọ́n sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ (Wo ìpínrọ̀ 1)

1. Kí ló máa ń wu gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ṣe, kí sì nìdí? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

JÉSÙ KRISTI pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Ó máa ń wu gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé ká mọ bá a ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa “láìkù síbì kan.” (2 Tím. 4:5) Ó ṣe tán, kò sí iṣẹ́ míì tó ṣe pàtàkì, tó ń fúnni láyọ̀, tó sì tún jẹ́ kánjúkánjú bí iṣẹ́ ìwàásù. Bó ti wù kó rí, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ náà bá a ṣe fẹ́.

2. Àwọn nǹkan wo ló ń mú kó ṣòro láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú?

2 Àwọn ojúṣe pàtàkì míì wà tó máa ń gba àkókò àti okun wa. Bí àpẹẹrẹ, ká lè bójú tó ara wa àti ìdílé wa, ó di dandan pé ká ṣiṣẹ́, èyí sì lè gba ọ̀pọ̀ wákàtí lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, bùkátà táwọn míì ń gbé nínú ìdílé kọjá kèrémí, àwọn kan ń ṣàìsàn, ìrẹ̀wẹ̀sì nìṣòro àwọn míì, nígbà táwọn àgbàlagbà ń bá hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó fà á. Báwo la ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú bí nǹkan ò tiẹ̀ fara rọ fún wa?

3. Kí ló ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Mátíù 13:23?

3 Ká má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra kò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bó ṣe wù wá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Jésù mọ̀ pé ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run á yàtọ̀ síra. (Ka Mátíù 13:23.) Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé gbogbo ohun tágbára wa gbé la ṣe. (Héb. 6:10-12) Àmọ́, a lè ronú pé ó yẹ káwa náà lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbawájú láyé wa. Yàtọ̀ síyẹn, àá rí bá a ṣe lè jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn àti bá a ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan tàbí láṣeyanjú?

4. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan?

4 Tá a bá sọ pé ẹnì kan ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Àmọ́, ó kọjá kéèyàn lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ìdí ni pé kì í ṣe bí àkókò tá a lò ṣe pọ̀ tó ni Jèhófà ń wò, bí kò ṣe ìdí tá a fi ń ṣe é. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa ló ń mú ká máa lo ara wa tọkàntọkàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. * (Máàkù 12:30, 31; Kól. 3:23) Ẹni tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn kì í fọwọ́ hẹ iṣẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń fi gbogbo okun àti agbára rẹ̀ ṣe iṣẹ́ Jèhófà. Tá a bá mọyì àǹfààní tá a ní láti wàásù, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.

5-6. Ṣàpèjúwe bí ẹnì kan tí ọwọ́ ẹ̀ máa ń dí gan-an ṣe lè fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sípò àkọ́kọ́.

5 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́kùnrin kan tó fẹ́ràn àtimáa ta gìtá. Inú ẹ̀ máa ń dùn táwọn èèyàn bá pè é láti wá kọrin. Nígbà tó yá, wọ́n ní kó wá máa ta gìtá fáwọn èèyàn nílé oúnjẹ kan láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Àmọ́ owó tó ń wọlé fún un kò lè gbọ́ bùkátà rẹ̀. Torí náà, ó ń bá ẹnì kan tajà nínú ṣọ́ọ̀bù látọjọ́ Monday sí Friday. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìtajà yẹn ló máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà, orin kíkọ ló gbà á lọ́kàn jù. Ó wù ú pé kóun túbọ̀ já fáfá, kóun lè di olórin. Bó ti wù kó rí, ó ṣì gbádùn kó máa kọrin nígbàkigbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ bó tiẹ̀ jẹ́ fún ìwọ̀nba àkókò díẹ̀.

6 Lọ́nà kan náà, iṣẹ́ tó ò ń ṣe lè mú kó ṣòro fún ẹ láti lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ ìwàásù lo fẹ́ràn jù. Fún ìdí yìí, o máa ń sapá kó o lè sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí ọ̀rọ̀ rẹ sì lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ rẹ máa ń dí, o lè máa ronú pé ọgbọ́n wo ni wàá dá kó o lè túbọ̀ máa wàásù.

BÓ O ṢE LÈ FI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

7-8. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

7 Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù Kristi tó bá di pé ká fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bó ṣe máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ló kà sí pàtàkì jù nígbà tó wà láyé. (Jòh. 4:34, 35) Ó máa ń fẹsẹ̀ rìn lọ síbi tó jìnnà gan-an kó lè wàásù fáwọn èèyàn. Kò síbi tó ti bá àwọn èèyàn pàdé tí kì í bá wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ì báà jẹ́ ní gbangba tàbí nínú ilé. Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìwàásù ló gbawájú nígbèésí ayé Jésù.

8 A lè fara wé Jésù tá a bá ń wọ́nà láti wàásù fáwọn èèyàn níbikíbi tá a bá wà. Ó yẹ ká ṣe tán láti fàwọn nǹkan du ara wa ká lè túbọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Máàkù 6:31-34; 1 Pét. 2:21) Àwọn ará wa kan ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míì sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí olùrànlọ́wọ́. Àwọn kan ti kọ́ èdè míì, àwọn míì sì ti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Àmọ́, àwọn akéde ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, síbẹ̀ wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn. Ohun kan ni pé, Jèhófà ò retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. Ó fẹ́ ká máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ mímọ́ yìí bá a ṣe ń kéde “ìhìn rere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀.”​—1 Tím. 1:11; Diu. 30:11.

9. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù ló gbawájú láyé òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ní láti ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́? (b) Kí ni Ìṣe 28:16, 30, 31 jẹ́ ká mọ̀ nípa ọwọ́ tí Pọ́ọ̀lù fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ ní ti pé iṣẹ́ ìwàásù ló fi ṣe àkọ́múṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì nílùú Kọ́ríńtì, kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí iṣẹ́ yẹn dí òun lọ́wọ́. Ó ṣe iṣẹ́ náà kó lè fi bójú tó ara rẹ̀ kó bàa lè wàásù fún àwọn ará Kọ́ríńtì “lọ́fẹ̀ẹ́.” (2 Kọ́r. 11:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kò fi iṣẹ́ ìwàásù jáfara, kódà gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ló máa ń wàásù. Lẹ́yìn tí nǹkan yí pa dà díẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù, ó wá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Bíbélì sọ pé: “Ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Kristi náà.” (Ìṣe 18:3-5; 2 Kọ́r. 11:9) Nígbà tó yá, wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé fún ọdún méjì nílùú Róòmù, síbẹ̀ ó máa ń wàásù fáwọn tó bá wá kí i, ó sì máa ń kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ. (Ka Ìṣe 28:16, 30, 31.) Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ó sọ pé: ‘Torí pé a rí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí gbà, a kò juwọ́ sílẹ̀.’ (2 Kọ́r. 4:1) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa bá tiẹ̀ ń gbà wá lákòókò, a ṣì lè rí i dájú pé iṣẹ́ ìwàásù ló gbawájú nígbèésí ayé wa.

Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú (Wo ìpínrọ̀ 10-11)

10-11. Báwo la ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yanjú tá a bá tiẹ̀ ń ṣàìsàn?

10 Tí ara tó ń dara àgbà tàbí àìsàn kò bá tiẹ̀ jẹ́ ká lè máa wàásù láti ilé dé ilé, a ṣì lè lọ́wọ́ nínú àwọn apá míì tí iṣẹ́ ìwàásù pín sí. Bíbélì fi hàn pé ibi gbogbo táwọn èèyàn wà ni àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ti máa ń wàásù fún wọn. Wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn láti ilé dé ilé, níbi térò pọ̀ sí àti láìjẹ́ bí àṣà, àní sẹ́ fún gbogbo “àwọn tó bá wà ní àrọ́wọ́tó.” (Ìṣe 17:17; 20:20) Torí náà, tí o kò bá lè rìn púpọ̀, o lè wá ibì kan jókòó sí níbi táwọn èèyàn ń gbà kọjá kó o lè wàásù fún wọn. O sì lè wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, o lè kọ lẹ́tà tàbí kó o wàásù lórí fóònù. Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ní àìlera tàbí tí ara wọn ti dara àgbà ló ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn apá míì tí iṣẹ́ ìwàásù pín sí.

11 Ohun yòówù kó mú kó nira fún ẹ, o ṣì lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú. Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Ó sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílí. 4:13) Pọ́ọ̀lù nílò okun látọ̀dọ̀ Jèhófà torí pé ó ṣàìsàn nígbà kan tó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì. Ó sọ fún àwọn ará ní Gálátíà pé: “Àìsàn tó ṣe mí ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ láǹfààní láti kéde ìhìn rere fún yín.” (Gál. 4:13) Lọ́nà kan náà, àìlera rẹ lè mú kó o làǹfààní láti wàásù fáwọn dókítà, àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn míì tó ń tọ́jú rẹ. Má gbàgbé pé ibiṣẹ́ lọ̀pọ̀ wọn máa ń wà nígbà táwọn ará bá wàásù dé ilé wọn.

BÁ A ṢE LÈ JẸ́ KÍ OHUN ÌNÍ DÍẸ̀ TẸ́ WA LỌ́RÙN

12. Kí ló túmọ̀ sí pé kí ojú wa “mú ọ̀nà kan”?

12 Jésù sọ pé: “Ojú ni fìtílà ara. Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan [tàbí “ríran kedere,”àlàyé ìsàlẹ̀], gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò.” (Mát. 6:22) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ohun tó ń sọ ni pé ó yẹ ká jẹ́ kí nǹkan ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, ká má ṣe máa lé tibí tọ̀hún, ká sì rí i pé a pọkàn pọ̀ sórí nǹkan tẹ̀mí. Jésù fúnra ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti pé ó pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni kó gbawájú láyé wọn. Ẹ jẹ́ ká fara wé Jésù, ká pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká máa “wá Ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.”​—Mát. 6:33.

13. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

13 Ká lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, á dáa ká dín àkókò tá à ń lò fáwọn nǹkan míì kù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní àkókò tó pọ̀ sí i láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì wá jọ́sìn rẹ̀. * Bí àpẹẹrẹ, ṣé a lè dín àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa kù ká lè túbọ̀ máa kópa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láàárín ọ̀sẹ̀? Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká dín àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú kù.

14. Àtúnṣe wo ni tọkọtaya kan ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ máa kópa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

14 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Elias sọ ohun tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe. Ó ní: “Níbẹ̀rẹ̀, a ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, síbẹ̀ a gbà pé ibì kan la gbọ́dọ̀ ti bẹ̀rẹ̀. A bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ táá jẹ́ ká lè túbọ̀ máa lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, a dín ìnáwó wa kù, a dín àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú kù, a sì bẹ àwọn ọ̀gá wa pé kí wọ́n jẹ́ ká dín iṣẹ́ wa kù. Àwọn nǹkan tá a ṣe yìí mú ká lè máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ó jẹ́ ká lè máa darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti máa jáde òde ẹ̀rí àárín ọ̀sẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù. Gbogbo èyí múnú wa dùn gan-an ni!”

BÓ O ṢE LÈ TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ÀTI KÍKỌ́NI

Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fún wa nípàdé àárín ọ̀sẹ̀ sílò, àá túbọ̀ máa sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa (Wo ìpínrọ̀ 15-16) *

15-16. Bó ṣe wà nínú 1 Tímótì 4:13, 15, kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (Wo àpótí náà, “ Àwọn Nǹkan Táá Mú Kí N Lè Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Mi Láṣeyanjú.”)

15 Ohun míì táá mú ká ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú ni pé ká túbọ̀ máa sunwọ̀n sí i nínú bá a ṣe ń wàásù. Bí àpẹẹrẹ, láwọn iléeṣẹ́ kan, wọ́n sábà máa ń dá àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye iṣẹ́ wọn kí wọ́n sì túbọ̀ já fáfá. Bí ọ̀rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi kún òye wa ká lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.​—Òwe 1:5; ka 1 Tímótì 4:13, 15.

16 Kí la lè ṣe táá mú ká túbọ̀ sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ó ṣe pàtàkì ká máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn ìtọ́ni tá à ń gbà ní Ìpàdé Ìgbésí Ayé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wọ́n máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípàdé yìí ká lè sunwọ̀n sí i, ká sì túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí alága ìpàdé bá ń fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ nímọ̀ràn, ó yẹ káwa náà máa ronú bá a ṣe lè fi ìmọ̀ràn náà sílò lóde ẹ̀rí. Kódà, a lè pinnu pé àá fi ìmọ̀ràn náà sílò kété lẹ́yìn ìpàdé ọjọ́ náà. A lè bá alábòójútó àwùjọ wa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí akéde ògbóṣáṣá míì, a sì lè bá aṣáájú-ọ̀nà tàbí alábòójútó àyíká ṣiṣẹ́. Bá a ṣe túbọ̀ ń dojúlùmọ̀ ohun tá a pè ní Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe.

17. Èrè wo lo máa rí tó o bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú?

17 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fún wa láǹfààní pé ká jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́” òun! (1 Kọ́r. 3:9) Tó o bá “wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” tó o sì jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbawájú nígbèésí ayé rẹ, ó dájú pé wàá máa “fi ayọ̀ sin Jèhófà.” (Fílí. 1:10; Sm. 100:2) Láìka ipò rẹ sí, torí pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ẹ́, o ò ní ṣiyèméjì pé Jèhófà máa fún ẹ lágbára tó o nílò láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú. (2 Kọ́r. 4:1, 7; 6:4) Yálà ipò rẹ fún ẹ láyè láti ṣe púpọ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, wàá “láyọ̀” tó o bá ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ yìí. (Gál. 6:4) Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láṣeyanjú tàbí láìkù síbì kan, ṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, “wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.”​—1 Tím. 4:16.

ORIN 58 À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà

^ ìpínrọ̀ 5 Jésù gbéṣẹ́ fún wa pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú bí nǹkan ò tiẹ̀ fara rọ fún wa. Àá tún sọ àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí ayọ̀ wa sì túbọ̀ pọ̀ sí i.

^ ìpínrọ̀ 4 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Onírúurú ọ̀nà ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí, lára ẹ̀ ni iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, iṣẹ́ ìkọ́lé àti àtúnṣe àwọn ibi tá à ń lò fún ìjọsìn wa, títí kan bá a ṣe ń pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá.​—2 Kọ́r. 5:18, 19; 8:4.

^ ìpínrọ̀ 13 Wo àwọn nǹkan méje tó o lè ṣe nínú àpótí tá a pè ní “Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ohun Ìní Díẹ̀ Tẹ́ Ẹ Lọ́rùn” nínú Ilé Ìṣọ́ July 2016, ojú ìwé 10.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń ṣe àṣefihàn ìpadàbẹ̀wò ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ṣàkọsílẹ̀ ìmọ̀ràn tí alága ìpàdé náà fún un sínú ìwé Kíkọ́ni rẹ̀. Lópin ọ̀sẹ̀ yẹn, arábìnrin náà fi ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un nípàdé sílò lóde ẹ̀rí.