Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33

Ìrètí Àjíǹde Jẹ́ Ká Rí I Pé Jèhófà Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́, Ọlọ́gbọ́n àti Onísùúrù

Ìrètí Àjíǹde Jẹ́ Ká Rí I Pé Jèhófà Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́, Ọlọ́gbọ́n àti Onísùúrù

“Àjíǹde . . . yóò wà.”​—ÌṢE 24:15.

ORIN 151 Òun Yóò Pè

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá àwọn nǹkan tó wà láyé àti lọ́run?

ÌGBÀ kan wà tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló wà, àmọ́ kò ṣe é bíi pé òun dá wà. Ìdí sì ni pé Jèhófà ò nílò kí ẹnikẹ́ni wà pẹ̀lú òun kó tó lè láyọ̀. Síbẹ̀, ó fẹ́ káwọn míì wà kí wọ́n sì láyọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan.​—Sm. 36:9; 1 Jòh. 4:19.

2. Báwo ló ṣe rí lára Jésù àtàwọn áńgẹ́lì nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan?

2 Ẹni tí Jèhófà kọ́kọ́ dá ni Jésù Ọmọ rẹ̀. Ó wá tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ “dá gbogbo ohun mìíràn” títí kan gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run. (Kól. 1:16) Inú Jésù dùn gan-an pé òun bá Bàbá òun ṣiṣẹ́. (Òwe 8:30) Inú àwọn áńgẹ́lì náà dùn bí wọ́n ṣe ń wo Jèhófà tó ń dá àwọn nǹkan. Ìṣojú wọn ni Jèhófà àti Jésù tó jẹ́ Àgbà Òṣìṣẹ́ ṣe dá ayé àti ọ̀run. Kí làwọn áńgẹ́lì ṣe nígbà tí Jèhófà ń dá àwọn nǹkan? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà dá ayé, Bíbélì sọ pé wọ́n ń ‘hó yèè, wọ́n sì ń yin’ Jèhófà. Ohun kan náà ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbà tí Jèhófà dá àwọn nǹkan tó kù láyé títí kan àwa èèyàn tó dá kẹ́yìn. (Jóòbù 38:7; Òwe 8:​31, àlàyé ìsàlẹ̀) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá ló fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni, ó sì nífẹ̀ẹ́.​—Sm. 104:24; Róòmù 1:20.

3. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:​21, 22, kí ni ìràpadà Jésù mú kó ṣeé ṣe?

3 Nígbà tí Jèhófà dá ayé, ohun tó fẹ́ ni pé kí gbogbo ayé jẹ́ Párádísè káwa èèyàn sì máa gbé nínú ẹ̀ títí láé. Àmọ́ nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Baba wọn ọ̀run, àwọn àtàwọn ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kú. (Róòmù 5:12) Kí wá ni Jèhófà ṣe? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà sọ bó ṣe máa dá aráyé nídè. (Jẹ́n. 3:15) Jèhófà ṣèlérí pé òun máa pèsè ìràpadà táá jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìyẹn lá mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yàn bóyá àwọn máa sin Jèhófà káwọn sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun àbí àwọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.​—Jòh. 3:16; Róòmù 6:23; ka 1 Kọ́ríńtì 15:​21, 22.

4. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ó ṣeé ṣe ká láwọn ìbéèrè kan nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni àjíǹde yẹn ṣe máa wáyé? Ṣé a máa dá àwọn èèyàn wa mọ̀ nígbà tí Jèhófà bá jí wọn dìde? Kí ló máa mú kí àjíǹde yẹn fún wa láyọ̀? Tá a bá ń ronú nípa àjíǹde, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká mọyì ìfẹ́, ọgbọ́n àti sùúrù tí Jèhófà ní? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.

BÁWO NI ÀJÍǸDE ṢE MÁA WÁYÉ?

5. Kí nìdí tá a fi gbà pé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni àjíǹde máa wáyé?

5 Nígbà tí Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ bá máa jí àwọn òkú dìde, a lè gbà pé kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan náà ni gbogbo wọn máa jíǹde. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tí gbogbo òkú bá jíǹde lẹ́ẹ̀kan náà, èrò á ti pọ̀ jù láyé, nǹkan á sì rí rúdurùdu. A sì mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe nǹkan rúdurùdu. Ó mọ̀ pé táwa èèyàn bá máa gbé ní àlàáfíà, nǹkan gbọ́dọ̀ wà létòlétò. (1 Kọ́r. 14:33) Jèhófà lo ọgbọ́n, ó sì mú sùúrù nígbà tóun àti Jésù ń dá àwọn nǹkan sáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé kó tó wá dá àwa èèyàn. Tó bá dìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa lo ọgbọ́n àti sùúrù bó ṣe ń darí àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já láti múra ilẹ̀ ayé sílẹ̀ de àwọn tó máa jíǹde.

Àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já máa kọ́ àwọn tó jíǹde nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìlànà Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 6) *

6. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 24:​15, àwọn míì wo ni Jèhófà máa jí dìde yàtọ̀ sáwọn olódodo?

6 Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já máa kọ́ àwọn tó jíǹde nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìlànà Jèhófà. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “àwọn aláìṣòdodo” ló máa pọ̀ jù lára àwọn tí Jèhófà máa jí dìde. (Ka Ìṣe 24:15.) Ọ̀pọ̀ ìyípadà ni wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù. Iṣẹ́ ńlá ló máa jẹ́ láti kọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí kò mọ ohunkóhun nípa Jèhófà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ṣé a máa kọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónìí? Ṣé wọ́n máa yàn wọ́n sí ìjọ táwọn náà á sì wá máa kọ́ àwọn míì tó jíǹde lẹ́yìn wọn? Àfi ká dúró dìgbà yẹn. Àmọ́ ohun kan wà tó dá wa lójú, nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá máa fi parí, “ìmọ̀ Jèhófà [ti] máa bo ayé.” (Àìsá. 11:9) Ó dájú pé ọwọ́ wa máa dí gan-an, inú wa sì máa dùn nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn!

7. Kí nìdí táwa èèyàn Jèhófà fi máa gba tàwọn tó jíǹde rò nígbà tá a bá ń kọ́ wọn?

7 Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà láyé la máa ṣe àwọn àtúnṣe táá jẹ́ ká múnú Jèhófà dùn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Torí náà, ó di dandan ká gba tàwọn tó ṣẹ̀sẹ̀ jíǹde rò bí wọ́n ṣe ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn tí wọ́n sì ń fi ìlànà Jèhófà sílò. (1 Pét. 3:8) Kò sí àní-àní pé àwọn tó jíǹde yẹn máa nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn Jèhófà tá à ń fìrẹ̀lẹ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ báwa náà ṣe ń “ṣiṣẹ́ ìgbàlà [wa] yọrí.”​—Fílí. 2:12.

ṢÉ A MÁA DÁ ÀWỌN TÓ JÍǸDE MỌ̀?

8. Kí ló mú ká gbà pé a máa dá àwọn èèyàn wa mọ̀ nígbà tí wọ́n bá jíǹde?

8 Àwọn ìdí kan wà tó jẹ́ ká gbà pé a máa dá àwọn èèyàn wa mọ̀ nígbà tí wọ́n bá jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àwọn tó jíǹde, ó jọ pé ṣe ni Jèhófà máa fún àwọn tó máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú ní ara tuntun tó jọ èyí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀, wọ́n á máa sọ̀rọ̀, wọ́n á sì máa ronú bí wọ́n ṣe ń ṣe kí wọ́n tó kú. Ẹ rántí pé Jésù fi ikú wé oorun, ó sì fi àjíǹde wé ìgbà téèyàn jí lójú oorun. (Mát. 9:​18, 24; Jòh. 11:​11-13) Táwọn èèyàn bá jí lójú oorun, ojú wọn, ohùn wọn àti èrò wọn kì í yàtọ̀ sí bó ṣe rí kí wọ́n tó sùn, kódà wọ́n máa ń rántí ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lọ sùn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Lásárù. Odindi ọjọ́ mẹ́rin ni Lásárù fi wà nínú ibojì, ara ẹ̀ sì ti ń jẹrà. Síbẹ̀, nígbà tí Jésù jí i dìde, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn arábìnrin rẹ̀ dá a mọ̀, òun náà sì rántí wọn.​—Jòh. 11:​38-44; 12:​1, 2.

9. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn tó jíǹde máa dẹni pípé?

9 Jèhófà ṣèlérí pé kò sẹ́ni tó ń gbé lábẹ́ àkóso Kristi tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.” (Àìsá. 33:24; Róòmù 6:7) Torí náà, ara tó jí pépé ni Jèhófà máa fún àwọn táá jí dìde. Àmọ́ kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n máa dẹni pípé. Torí pé tí wọ́n bá di pípé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn èèyàn wọn lè má dá wọn mọ̀. Ó jọ pé díẹ̀díẹ̀ ni aráyé máa di pípé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Lẹ́yìn tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá parí, Jésù máa dá Ìjọba pa dà fún Baba rẹ̀. Nígbà yẹn, gbogbo ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ni Ìjọba náà á ti ṣe, títí kan sísọ àwa èèyàn di pípé.​—1 Kọ́r. 15:​24-28; Ìfi. 20:​1-3.

KÍ LÓ MÁA MÚ KÍ ÀJÍǸDE FÚN WA LÁYỌ̀?

10. Báwo ni àjíǹde àwọn òkú ṣe máa rí lára ẹ?

10 Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa tá a bá ń kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀! Ṣé inú ẹ tó dùn máa mú kó o bú sẹ́kún tàbí ṣe ni wàá máa rẹ́rìn-ín? Ṣó máa mú kó o bú sórin ayọ̀ sí Jèhófà? Èyí ó wù ó jẹ́, ó dájú pé inú gbogbo wa máa dùn torí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa bí wọ́n ṣe jí àwọn òkú dìde.

11. Bí Jésù ṣe sọ nínú Jòhánù 5:​28, 29, kí ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn tó bá fi ìlànà rẹ̀ sílò nínú ayé tuntun?

11 Ẹ wo bí inú àwọn tó jíǹde ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ìwà àtijọ́ wọn tì, tí wọ́n sì ń fi ìlànà Jèhófà sílò. Àwọn tó bá ṣe àwọn àyípadà yìí máa rí àjíǹde sí ìyè. Àmọ́ Jèhófà ò ní fàyè gba àwọn tó bá ṣọ̀tẹ̀ láti máa wà láàyè nìṣó nínú Párádísè.​—Àìsá. 65:20; ka Jòhánù 5:​28, 29.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe máa bù kún àwọn tó máa wà láyé nígbà yẹn?

12 Nínú ayé tuntun, gbogbo èèyàn máa rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 10:22 tó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa mú káwọn èèyàn Ọlọ́run dẹni tẹ̀mí ní ti pé wọ́n á túbọ̀ máa hùwà bíi ti Kristi bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ìjẹ́pípé. (Jòh. 13:​15-17; Éfé. 4:​23, 24) Ojoojúmọ́ ni ara wọn á máa jí pépé sí i tí wọ́n á sì máa sunwọ̀n sí i. Ẹ wo bí ìgbésí ayé ṣe máa dùn tó nígbà yẹn! (Jóòbù 33:25) Àmọ́ àǹfààní wo lo máa rí báyìí tó o bá ń ronú nípa àjíǹde?

MỌYÌ ÌFẸ́ TÍ JÈHÓFÀ NÍ SÍ WA

13. Kí ni Sáàmù 139:​1-4 sọ nípa bí Jèhófà ṣe mọ̀ wá tó, báwo sì ni àjíǹde ṣe fi hàn pé òótọ́ ni?

13 Bá a ṣe sọ ṣáájú, nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn òkú dìde ó máa mú kí wọ́n rántí ohun tí wọ́n ṣe sẹ́yìn, ojú wọn, ohùn wọn àti èrò wọn á sì rí bíi ti tẹ́lẹ̀. Ẹ wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ débi pé ó ń kíyè sí ẹ, ó mọ ohun tó ò ń rò báyìí, ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ, bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ àtàwọn nǹkan tó ò ń ṣe. Torí náà, tó bá di pé kó jí ẹ dìde, kò ní ṣòro fún un láti mú kó o rántí ohun tó o ṣe sẹ́yìn, á sì mú kí ojú rẹ, ohùn rẹ àti èrò rẹ rí bíi ti tẹ́lẹ̀. Ọba Dáfídì náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ̀ wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Ka Sáàmù 139:​1-4.) Báwo ló ṣe rí lára wa pé Jèhófà mọ̀ wá gan-an?

14. Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe mọ̀ wá tó, báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa?

14 Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe mọ̀ wá tó, kò yẹ káyà wa máa já pé ṣe ló ń ṣọ́ wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Kí nìdí? Ká rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì fọ̀rọ̀ wa ṣeré. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jèhófà kà sí, ó sì mọyì wa. Ó mọ̀ wá dunjú, ó mọ nǹkan tá à ń ṣe, ó sì mọ àwọn nǹkan tó jẹ́ ká yàtọ̀ sáwọn míì. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Torí náà, ká máa rántí pé a ò dá wà. Gbogbo ìgbà ni ojú Jèhófà wà lára wa, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́.​—2 Kíró. 16:9.

MỌYÌ ỌGBỌ́N JÈHÓFÀ

15. Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n?

15 Àyà àwọn èèyàn máa ń já gan-an tí wọ́n bá fi ikú halẹ̀ mọ́ wọn. Àwọn tí Sátánì ń darí máa ń fi ikú halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè dalẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn tàbí kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé wọn ò fẹ́ ṣe. Àmọ́ bí wọ́n bá tiẹ̀ halẹ̀ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà, wọn ò lè fipá mú wa ṣe ohun tá a mọ̀ pé kò tọ́. A mọ̀ pé táwọn ọ̀tá bá pa wá, Jèhófà máa jí wa dìde. (Ìfi. 2:10) Ó dá wa lójú pé kò sóhun tí wọ́n lè ṣe táá mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Róòmù 8:​35-39) Ẹ ò rí i pé ìrètí àjíǹde yìí jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n! Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù ò bà wá táwọn èèyàn Sátánì bá ń fi ikú halẹ̀ mọ́ wa torí pé a ò ṣe nǹkan tí wọ́n fẹ́ ká ṣe. Bákan náà, ìrètí àjíǹde yìí mú ká nígboyà, ká sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.

Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè àwọn ohun tí mo nílò? (Wo ìpínrọ̀ 16) *

16. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ, báwo ni ìdáhùn rẹ ṣe máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

16 Táwọn ọ̀tá Jèhófà bá fi ikú halẹ̀ mọ́ ẹ, ṣé wàá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà pẹ̀lú ìdánilójú pé á jí ẹ dìde? Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá wàá jẹ́ adúróṣinṣin? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o bi ara ẹ pé, ‘Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?’ (Lúùkù 16:10) Ìbéèrè míì tó o lè bi ara ẹ ni pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo gbà pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tí mo nílò tí mo bá ń fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́?’ (Mát. 6:​31-33) Tí ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ó fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti pé o ti ṣe tán láti kojú àdánwò èyíkéyìí.​—Òwe 3:​5, 6.

MỌYÌ SÙÚRÙ JÈHÓFÀ

17. (a) Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe fi hàn pé Jèhófà ní sùúrù? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì sùúrù Jèhófà?

17 Jèhófà ti yan ọjọ́ àti wákàtí tó máa pa ayé búburú yìí run. (Mát. 24:36) Àmọ́ kò ní fi ìkánjú ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn. Ó wù ú gan-an pé kó jí àwọn tó ti kú dìde, síbẹ̀ ó ń mú sùúrù. (Jóòbù 14:​14, 15) Ó ń dúró de àsìkò tó tọ́ láti jí wọn dìde. (Jòh. 5:28) Torí náà, ó yẹ ká mọyì sùúrù Jèhófà. Rò ó wò ná: Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà mú sùúrù, ṣé á ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan ìwọ náà láti “ronú pìwà dà”? (2 Pét. 3:9) Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun tó bá ṣeé ṣe. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì sùúrù Jèhófà. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi taratara wá “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.” Ẹ jẹ́ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì wá sìn ín. (Ìṣe 13:48) Èyí á mú káwọn náà jàǹfààní sùúrù Jèhófà bíi tiwa.

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa mú sùúrù fáwọn míì?

18 Jèhófà máa mú sùúrù fún wa dìgbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí ká tó di pípé. Títí dìgbà yẹn, Jèhófà á máa gbójú fo àwọn àṣìṣe wa. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwa náà máa wo ibi táwọn míì dáa sí, ká sì máa mú sùúrù fún wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tí ọkọ ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́kàn sókè láìnídìí débi pé kò wá sípàdé mọ́. Arábìnrin náà sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn fún mi rárá torí pé ṣe ni gbogbo ohun tá a fẹ́ ṣe nínú ìdílé wa dojú rú pátápátá.” Láìka gbogbo ìyẹn sí, arábìnrin náà ń mú sùúrù fún ọkọ ẹ̀, ó sì ń fìfẹ́ hàn sí i. Ó gbára lé Jèhófà pátápátá, kò sì jẹ́ kó sú òun. Bíi ti Jèhófà, ibi tí ọkọ ẹ̀ dáa sí ló gbájú mọ́, kì í ṣe ìṣòro tó ń bá yí. Ó sọ pé: “Èèyàn dáadáa lọkọ mi, ó sì ń sapá kó lè borí ìṣòro tó ní díẹ̀díẹ̀.” Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa mú sùúrù fáwọn tó wà nínú ìdílé wa àtàwọn tá a jọ wà nínú ìjọ bí wọ́n ṣe ń sapá láti borí àwọn ìṣòro tí wọ́n ní!

19. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

19 Inú Jésù àtàwọn áńgẹ́lì dùn nígbà tí Jèhófà dá ayé. Ẹ wá wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó nígbà tó bá di pé àwọn èèyàn pípé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ nìkan ló wà láyé. Ẹ tún wo bí inú àwọn tó lọ jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń rí i tí aráyé ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ wọn. (Ìfi. 4:​4, 9-11; 5:​9, 10) Wo bó ṣe máa rí lára ẹ nígbà táwọn èèyàn bá ń yọ̀ dípò kí wọ́n máa sunkún, tí àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú sì ti pòórá títí láé. (Ìfi. 21:4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, pinnu pé wàá máa fìfẹ́ hàn, wàá máa fọgbọ́n hùwà, wàá sì máa mú sùúrù fáwọn míì bíi ti Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀ láìka ìṣòro èyíkéyìí tó ò ń kojú sí. (Jém. 1:​2-4) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ṣèlérí pé “àjíǹde . . . yóò wà”!​—Ìṣe 24:15.

ORIN 141 Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́

^ ìpínrọ̀ 5 Ọlọ́gbọ́n, onífẹ̀ẹ́ àti onísùúrù ni Jèhófà Baba wa. Èyí hàn nínú bó ṣe dá gbogbo nǹkan àti nínú ìlérí tó ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe ká ní nípa àjíǹde, a sì máa sọ bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́, ọgbọ́n àti sùúrù Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Ọkùnrin kan tó jẹ́ Amerindian tó ti kú lọ́pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn jíǹde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Arákùnrin kan tó la Amágẹ́dọ́nì já ń kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ ohun tó máa ṣe láti jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń sọ fún ọ̀gá ẹ̀ pé àwọn ọjọ́ kan wà láàárín ọ̀sẹ̀ tóun ò ní lè máa ṣe àfikún iṣẹ́. Ó sọ fún un pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà lòun máa ń ṣe láwọn ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Àmọ́ tí wọ́n bá nílò òun lójú méjèèjì láwọn ọjọ́ míì, òun ṣe tán.