ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31
Ṣé Ò Ń Retí “Ìlú Tó Ní Ìpìlẹ̀ Tòótọ́”?
“Ó ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́, tí Ọlọ́run ṣètò, tó sì kọ́.”—HÉB. 11:10.
ORIN 22 Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Àwọn nǹkan wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń yááfì lónìí, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
Ọ̀PỌ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ló ń yááfì àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló pinnu pé àwọn ò ní ṣègbéyàwó, àwọn tọkọtaya kan sì pinnu pé àwọn ò ní tíì bímọ. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti jẹ́ káwọn nǹkan díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn. Kí nìdí tí gbogbo wọn fi ṣe ìpinnu tí wọ́n ṣe? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ fi gbogbo okun wọn sin Jèhófà débi tí wọ́n bá lè ṣe é dé. Ọkàn wọn balẹ̀, ó sì dá wọn lójú pé Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Ṣé Jèhófà máa já wọn kulẹ̀? Rárá! Kí ló mú kíyẹn dá wọn lójú? Ìdí kan ni pé Jèhófà bù kún Ábúráhámù tó jẹ́ “baba gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́.”—Róòmù 4:11.
2. (a) Bó ṣe wà nínú Hébérù 11:8-10, 16, kí nìdí tí Ábúráhámù fi kúrò ní Úrì? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Tinútinú ni Ábúráhámù fi fi àwọn nǹkan amáyédẹrùn tó ń gbádùn nílùú Úrì sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ń retí “ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́.” (Ka Hébérù 11:8-10, 16.) “Ìlú” wo nìyẹn? Àwọn ìṣòro wo ni Ábúráhámù kojú bó ṣe ń retí pé kí Ọlọ́run kọ́ ìlú náà parí? Báwo la ṣe lè fara wé Ábúráhámù àtàwọn míì lóde òní tó ṣe bíi tiẹ̀?
ÌLÚ WO NI “ÌLÚ TÓ NÍ ÌPÌLẸ̀ TÒÓTỌ́”?
3. Ìlú wo ni Ábúráhámù ń retí?
3 Ìjọba Ọlọ́run ni ìlú tí Ábúráhámù ń retí, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ló sì para pọ̀ jẹ́ ìlú náà. Pọ́ọ̀lù pe Ìjọba yìí ní “ìlú Ọlọ́run alààyè, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run.” (Héb. 12:22; Ìfi. 5:8-10; 14:1) Ìjọba yìí kan náà ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún nígbà tó gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ ní ayé bíi ti ọ̀run.—Mát. 6:10.
4. Bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 17:1, 2, 6, kí ni Ábúráhámù mọ̀ nípa ìlú tàbí Ìjọba tí Jèhófà ṣèlérí?
4 Ṣé Ábúráhámù mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa rí? Rárá. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fi jẹ́ “àṣírí mímọ́.” (Éfé. 1:8-10; Kól. 1:26, 27) Àmọ́ Ábúráhámù mọ̀ pé àwọn kan lára àtọmọdọ́mọ òun máa di ọba torí pé Jèhófà dìídì sọ bẹ́ẹ̀ fún un. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 17:1, 2, 6.) Ábúráhámù nígbàgbọ́ tó lágbára débi pé ṣe ló dà bíi pé ó ń rí Ẹni Àmì Òróró tàbí Mèsáyà tó máa di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fáwọn Júù ìgbà ayé ẹ̀ pé: “Ábúráhámù bàbá yín yọ̀ gidigidi bó ṣe ń retí láti rí ọjọ́ mi, ó rí i, ó sì yọ̀.” (Jòh. 8:56) Èyí fi hàn pé ó dá Ábúráhámù lójú pé àwọn kan lára àtọmọdọ́mọ òun máa wà nínú Ìjọba tí Jèhófà á fìdí ẹ̀ múlẹ̀, Ábúráhámù sì ṣe tán láti dúró de Ìjọba náà.
5. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìlú tí Ọlọ́run dá sílẹ̀ ni Ábúráhámù ń dúró dè?
5 Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé ìlú tí Ọlọ́run dá sílẹ̀, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run lòun ń dúró dè? Lákọ̀ọ́kọ́, Ábúráhámù ò dara pọ̀ mọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè èyíkéyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń ṣí kiri dípò kó jókòó sójú kan kó sì máa bá àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú wọn ṣèjọba. Yàtọ̀ síyẹn, Ábúráhámù ò gbé ìjọba tiẹ̀ kalẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì ń fi sùúrù dúró de àwọn ìlérí rẹ̀. Ohun tí Ábúráhámù ṣe yìí fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí Ábúráhámù kojú, ká sì wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára ẹ̀.
ÀWỌN ÌṢÒRO WO NI ÁBÚRÁHÁMÙ KOJÚ?
6. Báwo ni ìlú Úrì ṣe rí?
6 Ìlú ọ̀làjú ni ìlú Úrì tí Ábúráhámù fi sílẹ̀, àwọn èèyàn ibẹ̀ kàwé, wọ́n rí jájẹ, ọkàn wọn sì balẹ̀. Ìlú náà ní ààbò torí pé àwọn odi gìrìwò ló yí i ká, kódà wọ́n gbẹ́ àwọn kòtò omi ńlá yí ìlú náà ká. Àwọn èèyàn ìlú náà mọ ìṣirò gan-an, wọ́n sì
mọ̀wé kọ. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ìlú náà jẹ́ ojúkò ìṣòwò torí pé ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ táwọn oníṣòwò kọ làwọn awalẹ̀pìtàn rí níbẹ̀. Bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé àdáni tó wà nílùú náà, wọ́n rẹ́ àwọn ilé náà wọ́n sì fi ẹfun kùn wọ́n. Kódà àwọn ilé míì ní yàrá mẹ́tàlá (13) sí mẹ́rìnlá (14) pẹ̀lú àgbàlá tí wọ́n fi òkúta tẹ́.7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí Ábúráhámù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bo òun àti ìdílé òun?
7 Ó ṣe pàtàkì pé kí Ábúráhámù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bo òun àti ìdílé òun. Kí nìdí? Ẹ rántí pé inú ilé tó ní ààbò ni Ábúráhámù àti Sérà fi sílẹ̀ tó sì wá ń gbé nínú àgọ́ láàárín pápá gbalasa nílẹ̀ Kénáánì. Kò sí odi gìrìwò tàbí àwọn kòtò omi ńlá tó máa dáàbò bo òun àti ìdílé rẹ̀, torí náà ìgbàkigbà làwọn ọ̀tá lè gbógun jà wọ́n.
8. Ìṣòro wo ni Ábúráhámù kojú nígbà kan?
8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni Ábúráhámù ń ṣe, ìgbà kan wà tí àtijẹ àtimu ṣòro fún òun àti ìdílé rẹ̀. Ohun tó sì fà á ni pé ìyàn mú gan-an ní ilẹ̀ tí Jèhófà ní kó lọ. Ìyàn náà mú débi pé Ábúráhámù ní láti kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Íjíbítì fúngbà díẹ̀. Àmọ́ nígbà tó máa dé ilẹ̀ Íjíbítì, ńṣe ni Fáráò ọba Íjíbítì gba ìyàwó rẹ̀. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe máa rí lára Ábúráhámù kó tó di pé Jèhófà sọ fún Fáráò pé kó dá ìyàwó rẹ̀ pa dà fún un.—Jẹ́n. 12:10-19.
9. Àwọn ìṣòro wo ni Ábúráhámù kojú nínú ìdílé rẹ̀?
9 Nǹkan ò rọrùn nínú ìdílé Ábúráhámù torí pé Sérà ìyàwó rẹ̀ kò rọ́mọ bí. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi ń retí tí wọn ò gbọ́ pá tí wọn ò sì gbọ́ po. Nígbà tó yá, Sérà fún ọkọ rẹ̀ ní Hágárì ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ kó lè bímọ fún wọn. Àmọ́ gbàrà tí Hágárì lóyún Íṣímáẹ́lì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn Sérà. Ọ̀rọ̀ náà le débi pé ṣe ni Sérà lé Hágárì kúrò nílé.—Jẹ́n. 16:1-6.
10. Kí ni Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe fún Íṣímáẹ́lì àti Ísákì tó dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò?
10 Nígbà tó yá Sérà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí Ábúráhámù pè ní Ísákì. Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì yìí. Àmọ́ torí pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́, Ábúráhámù ní láti lé òun àti ìyá rẹ̀ kúrò nílé. (Jẹ́n. 21:9-14) Nígbà tó yá, Jèhófà tún ní kí Ábúráhámù fi Ísákì rúbọ. (Jẹ́n. 22:1, 2; Héb. 11:17-19) Nínú ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí, Ábúráhámù ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa mú àwọn ìlérí tó ṣe nípa àwọn ọmọ náà ṣẹ.
11. Kí ló mú kí Ábúráhámù fi sùúrù dúró de Jèhófà?
11 Ní gbogbo àsìkò yẹn, Ábúráhámù ní láti mú sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ó ṣeé ṣe kó ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ fi ìlú Úrì sílẹ̀. (Jẹ́n. 11:31–12:4) Fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ló sì fi ń ṣí kiri nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ábúráhámù kú nígbà tó pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án (175). (Jẹ́n. 25:7) Síbẹ̀, kò rí ìmúṣẹ ìlérí tí Jèhófà ṣe pé àwọn àtọmọdọ́mọ òun máa jogún ilẹ̀ Kénáánì. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣojú ẹ̀ nígbà tí Jèhófà fìdí Ìjọba tó ṣèlérí múlẹ̀. Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé Ábúráhámù “darúgbó, ayé rẹ̀ sì dára” kó tó kú. (Jẹ́n. 25:8) Láìka àwọn ìṣòro tí Ábúráhámù kojú sí, ó nígbàgbọ́ tó lágbára, ó sì fi sùúrù dúró de Jèhófà. Kí ló mú kó lè fara dà á? Ìdí ni pé jálẹ̀ ìgbésí ayé Ábúráhámù, Jèhófà dáàbò bò ó, ó sì mú un lọ́rẹ̀ẹ́.—Jẹ́n. 15:1; Àìsá. 41:8; Jém. 2:22, 23.
12. Kí làwa náà ń retí, kí la sì máa jíròrò báyìí?
12 Bíi ti Ábúráhámù, àwa náà ń retí ìlú Ìfi. 12:7-10) Ohun tó kù ni pé kí Ìjọba náà nasẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ dórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, àwa náà lè kojú àwọn ìṣòro kan bíi ti Ábúráhámù àti Sérà. Ṣé a rí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan lóde òní tó fara wé Ábúráhámù? Ìtàn ìgbésí ayé àwọn ará wa kan tí wọ́n gbé jáde nínú Ilé Ìṣọ́ fi hàn pé àwọn náà nígbàgbọ́, wọ́n sì ní sùúrù bíi ti Ábúráhámù àti Sérà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìtàn yìí, ká sì wo àwọn nǹkan tá a lè rí kọ́.
tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́. Àmọ́, a ò retí pé kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ torí pé Jèhófà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ lọ́dún 1914, ó sì ti ń ṣàkóso lọ́run. (WỌ́N FARA WÉ ÁBÚRÁHÁMÙ
13. Kí lo rí kọ́ látinú ìtàn Arákùnrin Walden?
13 Múra tán láti yááfì àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí ẹ. Tá a bá máa fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé wa, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan bíi ti Ábúráhámù. (Mát. 6:33; Máàkù 10:28-30) Ẹ jẹ́ ka wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Bill Walden. * Ìgbà tó kù díẹ̀ kó gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kó sì di ẹnjiníà tó ń yàwòrán ilé ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1942. Kódà, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rẹ̀ ti ṣètò iṣẹ́ tó máa ṣe lẹ́yìn tó bá gboyè jáde, àmọ́ Bill kò gbà láti ṣe iṣẹ́ náà. Ó sọ fún olùkọ́ náà pé iṣẹ́ Jèhófà lòun fẹ́ fi ìgbésí ayé òun ṣe. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjọba sọ pé kó wá wọṣẹ́ ológun. Ó fìrẹ̀lẹ̀ ṣàlàyé fún wọn pé òun ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọ́n bá bu owó ìtanràn lé e, wọ́n ní kó san ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là ($10,000), wọ́n sì tún jù ú sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, wọ́n dá a sílẹ̀. Nígbà tó yá, ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ó sì di míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà. Nígbà tó yá, Bill fẹ́ Eva, wọ́n sì ń báṣẹ́ wọn lọ nílẹ̀ Áfíríkà, èyí tó gba pé kí wọ́n yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan. Nígbà tó tún yá, wọ́n ní láti pa dà sí Amẹ́ríkà kí wọ́n lè tọ́jú ìyá Bill. Nígbà tó ń sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀, ó ní: “Omijé ayọ̀ máa ń dà lójú mi tí mo bá ti rántí àwọn iṣẹ́ bàǹtàbanta tí Ọlọ́run ti lò mí fún láti nǹkan bí àádọ́rin (70) ọdún sẹ́yìn. Mo sábà máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún bó ṣe ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fi ayé mi ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.” Ṣéwọ náà lè pinnu pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni wàá fi ìgbésí ayé rẹ ṣe?
14-15. Kí lo rí kọ́ látinú ìtàn Arákùnrin àti Arábìnrin Apostolidis?
14 Má ronú pé o ò ní níṣòro torí pé ò ń sin Jèhófà. Àpẹẹrẹ Ábúráhámù fi hàn pé àwọn tó ń fi gbogbo ayé wọn sin Jèhófà náà máa ń níṣòro. (Jém. 1:2; 1 Pét. 5:9) Ìrírí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Aristotelis Apostolidis * fi hàn pé bó ṣe máa ń rí nígbà míì nìyẹn. Ọdún 1946 ló ṣèrìbọmi lórílẹ̀-èdè Greece, nígbà tó sì dọdún 1952, òun àti arábìnrin kan tó nítara bíi tiẹ̀ tó ń jẹ́ Eleni bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn sọ́nà. Àmọ́ nígbà tó yá Eleni ṣàìsàn, àwọn dókítà sì sọ pé kókó kan wà nínú ọpọlọ rẹ̀. Wọ́n yọ kókó náà, àmọ́ ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, kókó náà tún yọjú. Àwọn dókítà wá ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, àmọ́ nígbà tí wọ́n máa ṣe tán apá kan ara Eleni ti rọ látòkèdélẹ̀, kò sì lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣàìsàn tó lágbára gan-an, tí ìjọba sì tún fòfin de iṣẹ́ wa, Eleni ṣì ń fìtara wàásù ní gbogbo àsìkò yẹn.
15 Odindi ọgbọ̀n (30) ọdún gbáko ni Eleni fi wà nípò yìí, síbẹ̀ ṣe ni Aristotelis ń tọ́jú ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Ní gbogbo àsìkò yẹn, alàgbà ni, ó wà lára ìgbìmọ̀ àpéjọ agbègbè fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sì tún wà lára àwọn tó kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan. Nígbà tó tún dọdún 1987, ilẹ̀kùn irin ńlá kan gbá Eleni látẹ̀yìn, ó sì ṣe é léṣe gan-an débi pé odindi ọdún mẹ́ta ló fi dákú lọ gbári kó tó wá kú lọ́dún 1990. Nígbà tí Arákùnrin Aristotelis ń sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Ní gbogbo ọdún wọ̀nyí, àwọn ipò lílekoko, àwọn ìṣòro tí ń kóni láyà sókè, àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rò tẹ́lẹ̀ ti jẹ́ kó di dandan pé kí n mọwọ́ yí pa dà, kí n sì ní ìforítì. Síbẹ̀, ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń fún mi Sm. 94:18, 19) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ń fi taratara sìn ín láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú sí!
lókun tí mo nílò láti lè borí ìṣòro wọ̀nyí.” (16. Ìmọ̀ràn àtàtà wo ni Arákùnrin Knorr fún ìyàwó ẹ̀?
16 Máa ronú nípa èrè ọjọ́ iwájú. Èrè tí Jèhófà fẹ́ fún Ábúráhámù ló tẹjú mọ́, ìyẹn ló sì mú kó fara da àwọn ìṣòro tó kojú. Ohun tí Arábìnrin Audrey Hyde náà ṣe nìyẹn. Ìgbà gbogbo ló máa ń ronú nípa èrè ọjọ́ iwájú bó tiẹ̀ jẹ́ pé àrùn jẹjẹrẹ ló pa Arákùnrin Nathan H. Knorr tó kọ́kọ́ fẹ́, tí Glenn Hyde ọkọ rẹ̀ kejì náà sì tún ní àìsàn tó máa ń mú kí arúgbó ṣarán. * Ó sọ pé ohun tí Arákùnrin Knorr sọ fún òun ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ kó tó kú ló ran òun lọ́wọ́. Ó ní: “Nathan rán mi létí pé: ‘Lẹ́yìn ikú, ìrètí wa dájú, a ò sì ní jẹ̀rora mọ́ láé.’ Lẹ́yìn náà, ó wá rọ̀ mí pé: ‘Máa wo ọjọ́ iwájú, nítorí pé èrè rẹ ń bẹ lọ́jọ́ iwájú.’ . . . Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: ‘Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí, máa ṣoore fáwọn èèyàn. Èyí yóò mú kó o rí ayọ̀.’ ” Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn tó dáa nìyẹn pé ká máa ṣoore fáwọn míì ká sì ‘jẹ́ kí ìrètí tá a ní máa fún wa láyọ̀!’—Róòmù 12:12.
17. (a) Kí nìdí tá a fi ní láti tẹjú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú? (b) Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Míkà 7:7 ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú?
17 Lónìí, ọ̀pọ̀ ìdí la ní tó fi yẹ ká tẹjú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ti jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé apá tó kẹ́yìn lára ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí máa dé, kò sì ní sídìí pé à ń retí rẹ̀ mọ́. Lára ìbùkún tá a máa gbádùn nígbà yẹn ni pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde, àá sì rí wọn. Bákan náà, Jèhófà máa san Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ lẹ́san torí sùúrù àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nígbà tó bá jí wọn dìde. Ṣé wàá wà níbẹ̀ láti kí wọn káàbọ̀? Wàá wà níbẹ̀ tó o bá ń yááfì àwọn nǹkan torí Ìjọba Ọlọ́run bíi ti Ábúráhámù, tó ò ń fìtara sin Jèhófà nìṣó láìka àwọn ìṣòro tó ò ń kojú sí, tó o sì ń fi sùúrù dúró de Jèhófà.—Ka Míkà 7:7.
ORIN 74 Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà
^ ìpínrọ̀ 5 Ó lè má rọrùn fún wa láti mú sùúrù bá a ṣe ń dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn sì lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Kí la rí kọ́ lára Ábúráhámù táá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a máa ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ láìka àwọn ìṣòro tá à ń kojú sí? Àpẹẹrẹ tó dáa wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní sì fi lélẹ̀?
^ ìpínrọ̀ 13 Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Walden wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2013, ojú ìwé 8 sí 10.
^ ìpínrọ̀ 14 Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Apostolidis wà nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2002, ojú ìwé 24 sí 28.
^ ìpínrọ̀ 16 Ìtàn ìgbésí ayé Arábìnrin Hyde wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2004, ojú ìwé 23 sí 29.
^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Tọkọtaya àgbàlagbà kan ń fìtara sin Jèhófà láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú sí. Ohun tó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé wọ́n ń ronú nípa àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú.