Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rẹ Rìn

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rẹ Rìn

“Mọ̀wọ̀n ara rẹ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!”​—MÍKÀ 6:8.

ORIN 31 Bá Ọlọ́run Rìn!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Dáfídì sọ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

ṢÉ LÓÒÓTỌ́ ni Jèhófà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Dáfídì sọ pé: “O fún mi ní apata rẹ láti gbà mí là, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá.” (2 Sám. 22:36; Sm. 18:35) Nígbà tí Dáfídì kọrin yìí, ó ṣeé ṣe kó máa rántí ọjọ́ tí wòlíì Sámúẹ́lì wá sílé wọn, tó sì fi òróró yàn án pé òun ló máa di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Dáfídì ló kéré jù nínú àwọn ọmọkùnrin mẹ́jọ tí bàbá wọn bí, síbẹ̀ òun ni Jèhófà yàn láti rọ́pò Ọba Sọ́ọ̀lù.​—1 Sám. 16:​1, 10-13.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Kò sí àní-àní pé Dáfídì máa gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà pé: “Ó tẹ̀ ba láti wo ọ̀run àti ayé, ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku. Ó ń gbé tálákà dìde . . . kí ó lè mú un jókòó pẹ̀lú àwọn èèyàn pàtàkì.” (Sm. 113:​6-8) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn àti ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́. A tún máa jíròrò ohun tá a lè kọ́ lára Ọba Sọ́ọ̀lù, wòlíì Dáníẹ́lì àti Jésù tó bá kan kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹni.

KÍ LA LÈ RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ JÈHÓFÀ?

3. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe sáwa èèyàn, kí nìyẹn sì fi hàn?

3 Jèhófà fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nínú bó ṣe ń bá àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ aláìpé lò. Kì í ṣe pé ó tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa nìkan, ó tún mú wa lọ́rẹ̀ẹ́. (Sm. 25:14) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà pèsè Ọmọ rẹ̀ pé kó wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run ń ṣàánú wa gan-an, ó sì ń gba tiwa rò!

4. Báwo ni Jèhófà ṣe dá wa, kí sì nìdí?

4 Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Torí pé Jèhófà ló dá wa, ó lè pinnu pé òun á dá wa bí ẹ̀rọ tí kò lè pinnu ohun tó fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá wa lọ́nà tó jẹ́ pé a lè ronú ká sì pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe fúnra wa. Ó fẹ́ káwa èèyàn aláìpé máa jọ́sìn òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ òun, a sì mọ̀ pé a máa jàǹfààní tá a bá ń ṣègbọràn sí òun. (Diu. 10:12; Àìsá. 48:​17, 18) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bá wa lò!

Àwòrán Jésù bó ṣe wà lọ́run. Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jọ máa ṣàkóso wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n jọ ń wo ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì. Àwọn áńgẹ́lì kan ń fò lọ sílẹ̀ ayé kí wọ́n lè jíṣẹ́ tí Jèhófà rán wọn. Gbogbo àwọn tó wà nínú àwòrán yìí ni Jèhófà gbéṣẹ́ fún (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wa lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

5 Jèhófà ń tipasẹ̀ àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ wa lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Jèhófà ló gbọ́n jù láyé àti lọ́run. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò nílò ìmọ̀ràn ẹnikẹ́ni, ó gbà káwọn míì fún òun nímọ̀ràn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà gbà kí Jésù ran òun lọ́wọ́ nígbà tó ń dá àwọn nǹkan. (Òwe 8:​27-30; Kól. 1:​15, 16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni alágbára gbogbo, kò sì sóhun tí kò lè ṣe, síbẹ̀ ó fáwọn míì lágbára láti ṣe àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ó yan Jésù láti jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì tún fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) èèyàn lágbára láti bá Jésù ṣàkóso. (Lúùkù 12:32) Jèhófà tún dá Jésù lẹ́kọ̀ọ́ láti di Ọba àti Àlùfáà Àgbà. (Héb. 5:​8, 9) Bákan náà, ó dá àwọn tó máa bá Jésù jọba lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ kò gbéṣẹ́ fún wọn tán kó tún wá máa tojú bọ iṣẹ́ tó gbé fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fọkàn tán wọn pé ohun tí òun fẹ́ ni wọ́n á ṣe.​—Ìfi. 5:10.

A máa fara wé Jèhófà tá a bá ń dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ tá a sì ń gbéṣẹ́ fún wọn (Wo ìpínrọ̀ 6-7) *

6-7. Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe ń gbéṣẹ́ fáwọn míì?

6 Tí Jèhófà Baba wa ọ̀run tí kò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni bá lè gbéṣẹ́ fún àwọn míì tó sì fọkàn tán wọn, mélòómélòó àwa èèyàn! Bí àpẹẹrẹ, ṣé olórí ìdílé ni ẹ́ àbí alàgbà ìjọ? Fara wé Jèhófà, máa gbéṣẹ́ fáwọn míì, má sì máa tojú bọ iṣẹ́ náà tàbí kó o máa ṣọ́ wọn lọ́wọ́ ṣọ́ wọn lẹ́sẹ̀. Tó o bá ń fara wé Jèhófà, iṣẹ́ náà á di ṣíṣe, wàá tipa bẹ́ẹ̀ dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, ọkàn àwọn ẹni náà á sì balẹ̀ pé àwọn lè ṣe iṣẹ́ náà. (Àìsá. 41:10) Kí ni nǹkan míì táwọn tó wà nípò àṣẹ lè kọ́ lára Jèhófà?

7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń fetí sí èrò àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (1 Ọba 22:​19-22) Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè fara wé Jèhófà? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín sọ èrò wọn nípa bí ẹ ṣe lè ṣe àwọn nǹkan nínú ilé. Tó bá sì bọ́gbọ́n mu, ẹ ṣe ohun tí wọ́n sọ.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe mú sùúrù fún Ábúráhámù àti Sérà?

8 Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni bó ṣe ń mú sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, kì í bínú táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ bá fìrẹ̀lẹ̀ béèrè pé kí nìdí tó fi ṣe ìpinnu tó ṣe. Ìgbà kan wà tó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Ábúráhámù nígbà tó ń béèrè pé kí nìdí tó fi fẹ́ pa Sódómù àti Gòmórà run. (Jẹ́n. 18:​22-33) Ṣé ẹ rántí ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tí Sérà rẹ́rìn-ín lẹ́yìn tó gbọ́ pé òun máa lóyún ní ọjọ́ ogbó òun? Jèhófà ò bínú sí i, kò sì kàn án lábùkù. (Jẹ́n. 18:​10-14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló pọ́n Sérà lé.

9. Kí ni ẹ̀yin òbí àtẹ̀yin alàgbà rí kọ́ lára Jèhófà?

9 Ẹ̀yin òbí àtẹ̀yin alàgbà, kí lẹ rí kọ́ lára Jèhófà? Báwo ló ṣe máa ń rí lára yín tí àwọn ọmọ yín tàbí àwọn akéde inú ìjọ bá béèrè ìdí tẹ́ ẹ fi ṣe ohun tẹ́ ẹ ṣe? Ṣé kì í ṣe pé ẹ máa ń jájú mọ́ wọn? Àbí ṣe lẹ máa ń fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu wọn? Inú àwọn tó wà nínú ìdílé àtàwọn tó wà nínú ìjọ máa dùn tí àwọn tó wà nípò àṣẹ bá ń fara wé Jèhófà. Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, a ti jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.

OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN MÍÌ

10. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àpẹẹrẹ àwọn míì láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́?

10 Torí pé Jèhófà ni ‘Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá,’ ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́. (Àìsá. 30:​20, 21) À ń kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ń kà, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa àwọn tó fìwà jọ Jèhófà tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn. Bákan náà, à ń kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ń ronú nípa àwọn tí kò fìwà jọ Jèhófà tí wọn ò sì mọ̀wọ̀n ara wọn.​—Sm. 37:37; 1 Kọ́r. 10:11.

11. Kí la rí kọ́ látinú ìwà burúkú tí Sọ́ọ̀lù hù?

11 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Sọ́ọ̀lù. Níbẹ̀rẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Kò gbéra ga, kódà ṣe ló sá pa mọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ fi jọba. (1 Sám. 9:21; 10:​20-22) Àmọ́ nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù di agbéraga, ó sì jọ ara ẹ̀ lójú. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó di ọba ló fi irú ẹni tó jẹ́ hàn. Nígbà kan, ó fi ìkánjú rú ẹbọ tó yẹ kí wòlíì Sámúẹ́lì rú, dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa gba àwọn èèyàn ẹ̀ là, èyí sì fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn mú kó pàdánù ojúure Jèhófà, Jèhófà sì kọ̀ ọ́ ní ọba. (1 Sám. 13:​8-14) Ìkìlọ̀ gidi lèyí jẹ́ fún wa pé ká má ṣe máa kọjá àyè ara wa.

12. Kí ni Dáníẹ́lì ṣe tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀?

12 Ohun tí wòlíì Dáníẹ́lì ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ìwà burúkú tí Sọ́ọ̀lù hù. Àtìgbà ọ̀dọ́ ni Dáníẹ́lì ti fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun, òun sì nírẹ̀lẹ̀, kódà ìgbà gbogbo ló máa ń wojú Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà mú kó túmọ̀ àlá Nebukadinésárì, kò gbé ògo fún ara ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ló gbé ògo fún, tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. (Dán. 2:​26-28) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Táwọn ará bá ń gbádùn àsọyé wa tàbí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń méso rere jáde, Jèhófà ló yẹ ká gbógo fún. Ó yẹ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé Jèhófà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe, kì í ṣe agbára wa. (Fílí. 4:13) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù là ń fara wé. Lọ́nà wo?

13. Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 5:​19, 30 kọ́ wa tó bá di pé kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹ̀?

13 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, Ọmọ Ọlọ́run sì ni, ó gbára lé Jèhófà. (Ka Jòhánù 5:​19, 30.) Jésù ò gbìyànjú ẹ̀ láé láti gbapò mọ́ Bàbá ẹ̀ lọ́wọ́. Fílípì 2:6 sọ fún wa pé Jésù “kò ronú rárá láti já nǹkan gbà, ìyẹn, pé kó bá Ọlọ́run dọ́gba.” Jésù fi ara ẹ̀ sábẹ́ Jèhófà, ó mọ̀ pé ó níbi tí agbára òun mọ, torí náà ó bọ̀wọ̀ fún Bàbá ẹ̀.

Jésù mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kì í sì í kọjá àyè ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn kan sọ pé kó ṣe ohun tó ju agbára ẹ̀ lọ?

14 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù ṣe nígbà tí Jémíìsì àti Jòhánù pẹ̀lú ìyá wọn sọ pé kí Jésù ṣe ohun tó ju agbára ẹ̀ lọ. Jésù ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Bàbá òun nìkan ló lè pinnu ẹni tó máa jókòó sápá ọ̀tún tàbí apá òsì òun nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 20:​20-23) Ó hàn pé Jésù mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kò sì kọjá àyè ẹ̀. Kò ṣe kọjá ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. (Jòh. 12:49) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

Báwo la ṣe lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù? (Wo ìpínrọ̀ 15-16) *

15-16. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 4:6 sílò?

15 A lè fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa bíi ti Jésù tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 4:6 sílò. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ fún wa pé: “Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.” Torí náà, táwọn èèyàn bá ní ká fún àwọn ní ìmọ̀ràn, kò yẹ kó jẹ́ pé ohun tó kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn tàbí èrò tiwa la máa sọ fún wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, ìlànà Bíbélì tàbí àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run ló yẹ ká ní kí wọ́n tẹ̀ lé. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa àti pé “àwọn àṣẹ òdodo” Jèhófà ló dáa jù.​—Ìfi. 15:​3, 4.

16 Yàtọ̀ sí pé à ń fògo fún Jèhófà, àwọn ìdí míì tún wà tó fi yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká láyọ̀, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì? Kókó yìí la máa jíròrò báyìí.

ÀǸFÀÀNÍ WO LA MÁA RÍ TÁ A BÁ LẸ́MÌÍ ÌRẸ̀LẸ̀ TÁ A SÌ MỌ̀WỌ̀N ARA WA?

17. Kí nìdí táwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn fi máa ń láyọ̀?

17 Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, a máa láyọ̀. Kí nìdí? Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, inú wa máa dùn, a sì máa mọyì ohun táwọn míì bá ṣe fún wa. Àpẹẹrẹ kan nìgbà tí Jésù wo àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn. Ẹ rántí pé ẹnì kan péré ló pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù torí ó mọ̀ pé òun ò lè wo ara òun sàn láé. Ó ṣe kedere pé ọkùnrin yìí lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún òun, ó sì yin Ọlọ́run lógo.​—Lúùkù 17:​11-19.

18. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n ara ẹni ṣe máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì? (Róòmù 12:10)

18 Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Kí nìdí? Wọ́n gbà pé àwọn míì láwọn ànímọ́ tó dáa, wọ́n sì máa ń fọkàn tán wọn. Inú àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn máa ń dùn táwọn míì bá ṣàṣeyọrí, wọ́n sì máa ń yìn wọ́n tinútinú.​—Ka Róòmù 12:10.

19. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbéra ga?

19 Lọ́wọ́ kejì, kì í rọrùn fáwọn tó ń gbéra ga láti yin àwọn míì torí wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa yin àwọn. Wọ́n máa ń fi ara wọn wé àwọn míì, wọ́n sì gbà pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ. Wọn kì í dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, wọn kì í sì í gbéṣẹ́ fún wọn. Nǹkan tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń sọ ni pé, “Tó o bá fẹ́ kíṣẹ́ ẹ di ṣíṣe”​—ìyẹn báwọn ṣe fẹ́​—“àfi kó o ṣe é fúnra ẹ.” Agbéraga èèyàn máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé òun lòun gbayì jù, ó sì máa ń jowú táwọn míì bá ṣe dáadáa jù ú lọ. (Gál. 5:26) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í lọ́rẹ̀ẹ́ gidi. Tá a bá rí i pé a ti fẹ́ máa gbéra ga, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà taratara pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ‘yí èrò inú wa pa dà’ kí ìwà burúkú yìí má bàa gbilẹ̀ nínú ọkàn wa.​—Róòmù 12:2.

20. Kí nìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì mọ̀wọ̀n ara wa?

20 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa! A rí bó ṣe ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bá àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lò, a sì fẹ́ fara wé e. Yàtọ̀ síyẹn, a tún fẹ́ fara wé àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ bá Ọlọ́run rìn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fún Jèhófà ní gbogbo ògo àti ọlá tó tọ́ sí i. (Ìfi. 4:11) Nípa bẹ́ẹ̀, àwa náà á lè máa bá Baba wa ọ̀run rìn torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn.

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹni tó nírẹ̀lẹ̀ máa ń ṣàánú àwọn èèyàn ó sì máa ń gba tiwọn rò. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan la máa kọ́ látinú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní. A tún máa jíròrò ohun tá a lè kọ́ lára Ọba Sọ́ọ̀lù, wòlíì Dáníẹ́lì àti Jésù tó bá kan kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹni.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Alàgbà kan ń dá arákùnrin ọ̀dọ́ kan lẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe lè bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn. Lẹ́yìn náà, alàgbà yẹn jẹ́ kí arákùnrin ọ̀dọ́ náà ṣe iṣẹ́ yẹn fúnra ẹ̀ láìsí pé ó tún ń tojú bọ̀ ọ́.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń bi alàgbà kan bóyá òun lè lọ síbi ìgbéyàwó tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ìlànà Bíbélì ni alàgbà náà fi tọ́ arábìnrin náà sọ́nà, kì í ṣe èrò ara ẹ̀.