Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Báwo ni àpilẹ̀kọ náà “Kí Orúkọ Rẹ Di Mímọ́” nínú Ilé Ìṣọ́ June 2020 ṣe ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ nípa orúkọ Jèhófà àti bó ṣe jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run?
Nínú àpilẹ̀kọ yẹn, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun pàtàkì kan wà tó kan gbogbo àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì, ìyẹn ni bí orúkọ ńlá Jèhófà ṣe máa di mímọ́. Àmọ́, ohun méjì kan wà tó dá lórí bí orúkọ ẹ̀ ṣe máa di mímọ́. Ohun àkọ́kọ́ ni bóyá ìṣàkóso Jèhófà ló dáa jù lọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìkejì ni báwa èèyàn ṣe lè fi hàn pé Jèhófà la máa sìn.
Kí nìdí tá a fi sọ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni orúkọ Jèhófà àti bí orúkọ náà ṣe máa di mímọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé ìdí mẹ́ta tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.
Àkọ́kọ́, Sátánì ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ ní ọgbà Édẹ́nì. Nígbà tí Sátánì béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ Éfà, ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé Jèhófà kì í bójú tó àwa èèyàn, àwọn òfin tó fún wa sì ti le jù. Ohun tí Sátánì ṣe yìí fi hàn pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ta ko Jèhófà, ó sì pe Jèhófà ní òpùrọ́. Torí náà, ó ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pè é ní “Èṣù,” tó túmọ̀ sí “Abanijẹ́.” (Jòh. 8:44) Torí pé Éfà gba irọ́ Sátánì gbọ́, ìyẹn jẹ́ kó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, kò sì gbà kí Ọlọ́run máa ṣàkóso òun. (Jẹ́n. 3:1-6) Àtìgbà yẹn ni Sátánì ti ń ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tó sì ń pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ ọn. Àwọn tó bá gba irọ́ rẹ̀ gbọ́ ló sábà máa ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Torí náà, lójú àwa èèyàn Ọlọ́run, kò tọ́ bí wọ́n ṣe ba orúkọ mímọ́ Jèhófà jẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jù lọ sì ni. Èyí ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé àti gbogbo ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.
Ìkejì, Jèhófà pinnu pé òun máa dá orúkọ òun láre, òun á sì mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ náà nítorí àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lójú Jèhófà nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ó dájú pé màá sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́.” (Ìsík. 36:23) Jésù náà jẹ́ ká mọ ohun táwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ fi ṣáájú tá a bá ń gbàdúrà. Ó sọ pé: “Kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa yin orúkọ Ọlọ́run lógo. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.” (1 Kíró. 16:29; Sm. 96:8) “Ẹ fi orin yin orúkọ rẹ̀ ológo.” (Sm. 66:2) ‘Màá yin orúkọ rẹ lógo títí láé.’ (Sm. 86:12) Ọ̀kan lára ìgbà tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run ni ìgbà tí Jésù wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, tó sọ pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Jèhófà náà sì dá a lóhùn pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”—Jòh. 12:28. a
Ìkẹta, ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé kan orúkọ ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan: Lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí, tí àdánwò ìkẹyìn sì ti wáyé, kí ló kàn? Ṣé bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ á ṣì jẹ́ àríyànjiyàn fún àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká rántí ohun méjì tá a sọ pé ó dá lórí bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di
mímọ́, ìyẹn bóyá Jèhófà la máa sìn àti bó ṣe jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ṣé ó máa nira fáwọn èèyàn tó ti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láti máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó? Rárá. Ìdí ni pé wọ́n á ti di pípé, wọ́n á sì ti yege àdánwò. Wọ́n á ti gba ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣé ẹni tó yẹ kó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run ṣì máa jẹ́ àríyànjiyàn fún àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn? Rárá. Nítorí pé nígbà yẹn, á ti hàn kedere láyé àtọ̀run pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, àkóso ẹ̀ ló sì dáa jù lọ. Àmọ́ nígbà yẹn, ṣé ẹ̀gàn ṣì máa wà lórí orúkọ Jèhófà?Lásìkò yẹn, orúkọ Jèhófà á ti di mímọ́ pátápátá, wọn ò sì ní lè bà á jẹ́ mọ́. Torí náà, orúkọ Jèhófà ló máa ṣe pàtàkì jù lójú gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ láyé àtọ̀run. Kí nìdí? Ìdí ni pé àá máa rí bí Jèhófà ṣe ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu. Bí àpẹẹrẹ: Lẹ́yìn tí Jésù bá dá àkóso pa dà fún Jèhófà Ọlọ́run, Jèhófà máa “jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.” (1 Kọ́r. 15:28) Lẹ́yìn náà, gbogbo èèyàn máa gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ohun tí Jèhófà fẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ máa wá ṣẹ pé kí àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì di ìdílé kan, ká sì wà níṣọ̀kan.—Éfé. 1:10.
Báwo ló ṣe máa rí lára wa àtàwọn áńgẹ́lì lẹ́yìn tí gbogbo nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀? Ó dájú pé a ò ní yéé yin Jèhófà lógo nítorí orúkọ rere rẹ̀, ìgbà gbogbo lá sì máa wù wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Ọba Dáfídì láti sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run . . . Kí á yin orúkọ rẹ̀ ológo títí láé.” (Sm. 72:18, 19) Torí náà, títí láé làá máa rí àwọn nǹkan táá jẹ́ ká máa yin orúkọ Jèhófà nìṣó.
Orúkọ Jèhófà jẹ́ ká mọ ìwà àti ìṣe rẹ̀, ìyẹn sì ń fara hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, orúkọ rẹ̀ rán wa létí pé ìfẹ́ ló fi ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. (1 Jòh. 4:8) Gbogbo ìgbà làá máa rántí pé torí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe dá wa, ó nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà àti pé ìfẹ́ ló fi ń ṣàkóso wa lọ́nà tó tọ́. Gbogbo ìgbà làá sì máa rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, títí láé làá máa sún mọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, tí àá sì máa yin orúkọ rẹ̀ lógo.—Sm. 73:28.
a Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń ṣe àwọn nǹkan kan “nítorí orúkọ rẹ̀.” Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń darí àwọn èèyàn ẹ̀, ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó máa ń gbà wọ́n sílẹ̀, ó máa ń dárí jì wọ́n, ó sì máa ń dáàbò bò wọ́n. Jèhófà máa ń ṣe gbogbo nǹkan yìí nítorí orúkọ rẹ̀.—Sm. 23:3; 31:3; 79:9; 106:8; 143:11.