ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
“Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa lóye.”—DÁN. 12:10.
ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, kí ló máa jẹ́ kó o gbádùn ẹ̀?
Ọ̀DỌ́KÙNRIN Ben tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Mo fẹ́ràn kí n máa kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.” Ṣé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Àbí o rò pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì le gan-an, kì í sì í tètè yéni? Kódà, o lè rò pé téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó máa ń súni. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o yí èrò ẹ pa dà tó o bá túbọ̀ mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kí wọ́n kọ wọ́n sínú Bíbélì.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti bá a ṣe lè ṣe é. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ méjì nínú ìwé Dáníẹ́lì, àá sì rí àǹfààní tó máa ṣe wá tá a bá lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ KẸ́KỌ̀Ọ́ ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ?
3. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
3 Ká tó lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àfi kí ẹnì kan ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé o fẹ́ lọ síbì kan tó ò mọ̀, àmọ́ ọ̀rẹ́ ẹ kan tó mọ ibẹ̀ dáadáa tẹ̀ lé ẹ lọ. Bẹ́ ẹ ṣe ń lọ, ó mọ ibi tẹ́ ẹ dé, ó sì mọ ibi tí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan já sí. Ó dájú pé inú ẹ á dùn pé ọ̀rẹ́ ẹ bá ẹ lọ. Jèhófà ló dà bí ọ̀rẹ́ yẹn torí ó mọ ibi tí ọ̀rọ̀ ayé yìí dé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ká lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó yẹ ká fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́.—Dán. 2:28; 2 Pét. 1:19, 20.
4. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kí wọ́n kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ sínú Bíbélì? (Jeremáyà 29:11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 Bíi ti òbí rere kan, Jèhófà fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ òun dáa. (Ka Jeremáyà 29:11.) Àmọ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn òbí wa torí pé òun lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, táá sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó ní kí wọ́n kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ sínú Bíbélì ká lè mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. (Àìsá. 46:10) Torí náà, ẹ̀bùn iyebíye làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí Baba wa ọ̀run fún wa yìí. Àmọ́ kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ṣẹ?
5. Kí làwọn ọ̀dọ́ lè kọ́ lára Max?
5 Nílé ìwé, àwọn ọ̀dọ́ wa máa ń wà pẹ̀lú àwọn tí ò bọ̀wọ̀ fún Bíbélì rárá tàbí àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Ohun tí wọ́n ń sọ àtohun tí wọ́n ń ṣe nígbà míì lè mú káwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣiyèméjì nípa Bíbélì àtohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Max. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ìsìn tòótọ́ kọ́ làwọn òbí mi fi ń kọ́ mi àti pé Bíbélì kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Kí làwọn òbí ẹ̀ ṣe? Ó sọ pé: “Wọn ò kanra mọ́ mi, àmọ́ mo mọ̀ pé ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.” Àwọn òbí Max fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀, àmọ́ Max náà ṣe nǹkan kan. Ó sọ pé: “Èmi fúnra mi kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, mo sì sọ ohun tí mo kọ́ fáwọn ọ̀dọ́ míì nínú ìjọ.” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Max sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yẹn, ó wá dá mi lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá.”
6. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ń ṣiyèméjì, kí sì nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Tó o bá ń ṣiyèméjì bíi ti Max pé ohun tó wà nínú Bíbélì kì í ṣe òótọ́, má jẹ́ kíyẹn kó ìtìjú bá ẹ. Àmọ́, ó yẹ kó o tètè ṣe nǹkan sọ́rọ̀ náà. Ńṣe ni iyèméjì dà bí ohun èlò kan tó lè dóògún. Tá ò bá tètè tọ́jú ẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ló máa bà jẹ́ pátápátá. Torí náà, tó ò bá fẹ́ kí iyèméjì ba ìgbàgbọ́ ẹ jẹ́, ó yẹ kó o bi ara ẹ ní ìbéèrè yìí. ‘Ṣé mo gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?’ Tí kò bá dá ẹ lójú, ó yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ. Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.
BÓ O ṢE LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ
7. Àpẹẹrẹ rere wo ni Dáníẹ́lì fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? (Dáníẹ́lì 12:10) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Dáníẹ́lì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún gbogbo wa nípa bó ṣe yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ohun tó tọ́ ló mú kí Dáníẹ́lì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó fẹ́ mọ òtítọ́. Dáníẹ́lì tún nírẹ̀lẹ̀, ó mọ̀ pé Jèhófà máa jẹ́ káwọn tí wọ́n mọ òun, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀. (Dán. 2:27, 28; ka Dáníẹ́lì 12:10.) Dáníẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ìyẹn sì fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀. (Dán. 2:18) Dáníẹ́lì tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Ó ṣèwádìí nínú Ìwé Mímọ́ tó wà nígbà ayé rẹ̀. (Jer. 25:11, 12; Dán. 9:2) Báwo lo ṣe lè fara wé Dáníẹ́lì?
8. Kí nìdí táwọn kan fi ń kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àmọ́ kí ló yẹ káwa ṣe?
8 Ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ṣé torí pé o fẹ́ mọ òtítọ́ ló mú kó o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jòh. 4:23, 24; 14:16, 17) Ohun míì wo ló lè mú kẹ́nì kan fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? Àwọn kan máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n ń wá ẹ̀rí tó máa fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ ni Bíbélì. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n rò pé táwọn bá rí àwọn ẹ̀rí yẹn, àwọn máa lè pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, àwọn á sì máa gbé ìgbé ayé àwọn báwọn ṣe fẹ́. Àmọ́, ìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ni pé ká lè mọ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ànímọ́ pàtàkì kan wà tó yẹ ká ní tá a bá fẹ́ lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.
9. Ìwà wo ló yẹ ká ní tá a bá fẹ́ lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? Ṣàlàyé.
9 Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ran àwọn tó bá nírẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́. (Jém. 4:6) Torí náà, ó yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ó tún yẹ ká gbà kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ àti olóye tó ń lò láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa lásìkò tó yẹ. (Lúùkù 12:42) Torí pé Ọlọ́run tó wà létòlétò ni Jèhófà, ó bọ́gbọ́n mu pé ẹrú olóòótọ́ nìkan ló ń lò láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—1 Kọ́r. 14:33; Éfé. 4:4-6.
10. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Arábìnrin Esther ṣe?
10 Máa ṣèwádìí. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tó o fẹ́ràn ni kó o fi bẹ̀rẹ̀, kó o sì ṣèwádìí nípa ẹ̀. Ohun tí Arábìnrin Esther tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe nìyẹn. Ó fẹ́ mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa ìgbà tí Mèsáyà máa dé. Ó ní: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí kí n lè rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa Mèsáyà ti wà lákọsílẹ̀ kí Jésù tó wá sáyé.” Nígbà tó kà nípa Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, ó dá a lójú pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Ó ní: “Wọ́n ti kọ àwọn kan lára àwọn àkájọ ìwé yẹn kí Kristi tó wá sáyé. Torí náà, Ọlọ́run ló sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé náà. Kódà, léraléra ni mo ka àwọn ìwé tó dá lórí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kí wọ́n tó yé mi.” Àmọ́ inú ẹ̀ dùn torí pé ó kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan dáadáa, ó sọ pé: “Ó ti wá dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.”
11. Àǹfààní wo la máa rí tó bá dá wa lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?
11 Tá a bá rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe ṣẹ, ó máa jẹ́ ká fọkàn tán Jèhófà pátápátá, ó sì máa ń jẹ́ ká tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa bó tiẹ̀ jẹ́ pé a láwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àsọtẹ́lẹ̀ méjì tí Dáníẹ́lì sọ tó ti ń ṣẹ báyìí. Táwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá yé wa, á rọrùn fún wa láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O MỌ̀ NÍPA ẸSẸ̀ IRIN ÀTI AMỌ̀?
12. Kí ni ẹsẹ̀ “irin” tó “dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀” ṣàpẹẹrẹ? (Dáníẹ́lì 2:41-43)
12 Ka Dáníẹ́lì 2:41-43. Nígbà tí Dáníẹ́lì ń túmọ̀ àlá tí Ọba Nebukadinésárì lá, ó sọ pé ẹsẹ̀ ère tí ọba rí jẹ́ “irin” tó “dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀.” Tá a bá fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí wé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú ìwé Dáníẹ́lì àti Ìfihàn, a máa rí i pé ẹsẹ̀ ère yẹn ṣàpẹẹrẹ ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé báyìí, ìyẹn ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Dáníẹ́lì sọ pé ìjọba yẹn “máa lágbára lápá kan,” “kò sì ní lágbára lápá kan.” Kí nìdí tí ò fi ní lágbára lápá kan? Ìdí ni pé àwọn mẹ̀kúnnù tó ṣàpẹẹrẹ amọ̀ rírọ̀ ò jẹ́ kí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso wọn lo agbára ẹ̀ tó dà bí irin bó ṣe fẹ́. b
13. Nígbà tá a lóye àsọtẹ́lẹ̀ yìí, àwọn òótọ́ pọ́ńbélé wo la mọ̀?
13 Àlàyé tí Dáníẹ́lì ṣe nípa ère inú àlá yẹn, pàápàá ẹsẹ̀ ère yẹn jẹ́ ká mọ àwọn òótọ́ pọ́ńbélé kan. Àkọ́kọ́, ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ti ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé òun lágbára. Bí àpẹẹrẹ, àwọn orílẹ̀-èdè méjì yìí ló gbawájú lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́gun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ogun Àgbáyé Kejì. Àmọ́, ìjọba alágbára yìí ò lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ torí pé àwọn ará ìlú máa ń bá ara wọn àti ìjọba jà. Ìkejì, ìjọba alágbára yìí ló máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn kí Ìjọba Ọlọ́run tó fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń dojú ìjà kọ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, wọn ò ní lè gba ipò ẹ̀. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé “òkúta” tó ṣàpẹẹrẹ Ìjọba Ọlọ́run máa fọ́ ẹsẹ̀ ère yẹn, ìyẹn ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà.—Dán. 2:34, 35, 44, 45.
14. Tí àsọtẹ́lẹ̀ ẹsẹ̀ irin àti amọ̀ bá yé wa, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́?
14 Ṣé ó dá ẹ lójú pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ nípa ẹsẹ̀ irin àti amọ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kò ní jẹ́ kó o máa lépa owó torí ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run. (Lúùkù 12:16-21; 1 Jòh. 2:15-17) Tó o bá gbà pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí, á jẹ́ kó o tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Mát. 6:33; 28:18-20) Ní báyìí tá a ti sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, o ò ṣe bi ara ẹ ní ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé ó dá mi lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó pa gbogbo ìjọba èèyàn run?’
BÁWO NI ÌJÀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN “ỌBA ÀRÍWÁ” ÀTI “ỌBA GÚÚSÙ” ṢE KÀN Ẹ́?
15. Ta ni “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” lónìí? (Dáníẹ́lì 11:40)
15 Ka Dáníẹ́lì 11:40. Dáníẹ́lì orí 11 sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba méjì kan tí wọ́n ń bá ara wọn jìjàkadì, kí wọ́n lè mọ ẹni tó máa ṣàkóso ayé. Tá a bá fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí wé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì, a máa rí i pé ìjọba Rọ́ṣíà àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn ni “ọba àríwá,” ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà sì ni “ọba gúúsù.” c
16. Kí ni “ọba àríwá” ń ṣe sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láwọn ìlú tó ti ń ṣàkóso?
16 Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń gbé láwọn ìlú tí “ọba àríwá” ti ń ṣàkóso ń fara da inúnibíni tí ọba yìí ń ṣe sí wọn. Ọba yìí ti fìyà jẹ àwọn ará wa kan, ó sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Dípò kí ohun tí “ọba àríwá” ṣe yìí dẹ́rù ba àwọn ará wa, ṣe ló túbọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Kí nìdí tí wọn ò fi bẹ̀rù? Ìdí ni pé àwọn ará wa mọ̀ pé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ń jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣẹ. d (Dán. 11:41) Ohun tá a mọ̀ yìí mú kó dá àwa náà lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, á sì mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.
17. Kí ni “ọba gúúsù” ṣe sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láwọn ìlú tó ti ń ṣàkóso?
17 Láwọn ìgbà kan, “ọba gúúsù” náà ti ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò lọ́wọ́ sógun, wọ́n sì tún lé àwọn ọmọ wọn kúrò nílé ìwé nítorí ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó dán àwọn èèyàn Jèhófà wò láwọn ìlú tí “ọba gúúsù” ti ń ṣàkóso. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ìpolongo ìbò, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè fẹ́ gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí olóṣèlú kan. Ó lè má dìbò, àmọ́ lọ́kàn ẹ̀, ó lè fẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú kan wọlé. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká má dá sọ́rọ̀ òṣèlú rárá, kódà kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́kàn wa.—Jòh. 15:18, 19; 18:36.
18. Báwo ni ìjà tó wà láàárín “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Ó ṣeé ṣe kí ìdààmú bá àwọn tí ò gba àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì gbọ́ tí wọ́n bá rí “ọba gúúsù” tó ń ‘fi ìwo kan’ “ọba àríwá.” (Dán. 11:40, àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn ọba méjèèjì yìí ní ohun ìjà alágbára tó lè pa gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí tó wà láyé run. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà ò ní jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀. (Àìsá. 45:18) Dípò kí ìjà tó wà láàárín “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” máa kó wa lọ́kàn sókè, ṣe ló yẹ kó jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ó tún jẹ́ ká rí i pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run.
MÁA KÍYÈ SÍ ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ
19. Kí la ò mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
19 A ò mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe máa ṣẹ. Kódà, kì í ṣe gbogbo ohun tí wòlíì Dáníẹ́lì kọ sílẹ̀ ló mọ ìtumọ̀ ẹ̀. (Dán. 12:8, 9) Àmọ́, tá ò bá tiẹ̀ mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣe máa ṣẹ, ìyẹn ò sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ò ní ṣẹ. Ó dá wa lójú pé ní àkókò tó yẹ, Jèhófà máa jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, bó ti ṣe nígbà àtijọ́.—Émọ́sì 3:7.
20. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo là ń retí pé kó ṣẹ láìpẹ́, kí ló sì yẹ ká máa ṣe?
20 Àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” (1 Tẹs. 5:3) Lẹ́yìn náà, àwọn ìjọba ayé máa gbéjà ko ìsìn èké, wọ́n sì máa pa á run. (Ìfi. 17:16, 17) Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:18, 19) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16) Ó dá wa lójú pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ká sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló máa fi hàn pé a mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ń ṣe fún wa.
ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
a Kò sí bí nǹkan ṣe burú tó nínú ayé yìí, ọkàn wa balẹ̀ pé láìpẹ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ohun tá a kọ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló mú kíyẹn dá wa lójú. Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. A tún máa gbé àsọtẹ́lẹ̀ méjì tí Dáníẹ́lì kọ yẹ̀ wò ní ṣókí. A sì tún máa rí bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè jàǹfààní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà tá a bá lóye wọn.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó ‘Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́’ Payá” nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2012, ìpínrọ̀ 7-9.
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ta Ni ‘Ọba Àríwá’ Lónìí?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2020, ìpínrọ̀ 3-4.
d Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ta Ni ‘Ọba Àríwá’ Lónìí?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2020, ìpínrọ̀ 7-9.