Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ṣé ìgbà gbogbo ni ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti wá máa ń gba ọ̀dọ̀ àkọ́bí ọkùnrin kọjá?
Àwọn ìgbà kan wà tá a ti sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ó sì jọ pé èrò yẹn bá ohun tó wà nínú ìwé Hébérù 12:16 mu. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé Ísọ̀ “kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀” ó sì “fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tọrẹ [fún Jékọ́bù] ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.” Ẹsẹ yìí mú kó dà bíi pé nígbà tí Ísọ̀ ta “ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí” fún Jékọ́bù, Jékọ́bù tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn baba ńlá Mèsáyà.—Mát. 1:2, 16; Lúùkù 3:23, 34.
mọ́ nígbà tá a tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn inú Ìwé Mímọ́, a rí i pé kò pọn dandan kí ẹnì kan jẹ́ àkọ́bí kó tó lè wà lára àwọn baba ńlá Mèsáyà. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí mélòó kan yẹ̀ wò:
Rúbẹ́nì ni àkọ́bí Jékọ́bù (ìyẹn Ísírẹ́lì), èyí tí Léà bí fún un. Nígbà tó yá, Rákélì tó jẹ́ aya Jékọ́bù, tó sì tún jẹ́ ààyò rẹ̀ bí àkọ́bí ọmọkùnrin tiẹ̀ náà, ìyẹn Jósẹ́fù. Nígbà tí Rúbẹ́nì ṣe àṣemáṣe, ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó sì di ti Jósẹ́fù. (Jẹ́n. 29:31-35; 30:22-25; 35:22-26; 49:22-26; 1 Kíró. 5:1, 2) Síbẹ̀, ìlà ìdílé Mèsáyà kò gba ọ̀dọ̀ Rúbẹ́nì àti Jósẹ́fù kọjá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ ọmọ kẹrin tí Léà bí fún Jékọ́bù ìyẹn Júdà ni ìlà ìdílé Mèsáyà gbà kọjá.—Jẹ́n. 49:10.
Ìwé Lúùkù 3:32 mẹ́nu kan àwọn márùn-ún míì tí Mèsáyà ti ìlà ìdílé wọn wá, àkọ́bí sì ni gbogbo wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bóásì bí Óbédì, Óbédì náà sì bí Jésè.—Rúùtù 4:17, 20-22; 1 Kíró. 2:10-12.
Àmọ́ Dáfídì ọmọ Jésè kì í ṣe àkọ́bí. Òun ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọ mẹ́jọ tí bàbá wọn bí. Síbẹ̀ ìlà ìdílé Dáfídì ni Mèsáyà gbà wá. (1 Sám. 16:10, 11; 17:12; Mát. 1:5, 6) Bákan náà, ọ̀dọ̀ Sólómọ́nì ni ìlà ìdílé Mèsáyà gbà bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kọ́ ni àkọ́bí Dáfídì.—2 Sám. 3:2-5.
Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé jíjẹ́ àkọ́bí ò já mọ́ nǹkan kan. Ipò pàtàkì ni àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin dì mú nínú ìdílé òun ló sì máa ń di olórí ìdílé lẹ́yìn tí bàbá wọn ò bá sí mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, òun ló máa gba ìlọ́po méjì nínú ogún bàbá wọn.—Jẹ́n. 43:33; Diu. 21:17; Jóṣ. 17:1.
Nígbà míì wọ́n máa ń gbé ẹ̀tọ́ àkọ́bí ọmọ fún ọmọ míì. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù lé Íṣímáẹ́lì lọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ Ísákì di àkọ́bí. (Jẹ́n. 21:14-21; 22:2) Bá a sì ṣe sọ ṣáájú, wọ́n gbé ẹ̀tọ́ àkọ́bí tó jẹ́ ti Rúbẹ́nì fún Jósẹ́fù.
Ẹ jẹ́ ká wá pa dà sínú Hébérù 12:16 tó sọ pé kí ó má ṣe “sí àgbèrè kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀, bí Ísọ̀, ẹni tí ó fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tọrẹ ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.” Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ gan-an?
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ìlà ìdílé Mèsáyà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń jíròrò nínú ẹsẹ yìí. Nínú àwọn ẹsẹ tó ṣáájú, ó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ‘ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ wọn,’ kí wọ́n sì sá fún àgbèrè kí wọ́n má bàa di ẹni “tí a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run dù.” (Héb. 12:12-16) Tí wọ́n bá ṣe àgbèrè, ọ̀rọ̀ wọn ò ní yàtọ̀ sí ti Ísọ̀ tí kò “mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀,” tó jẹ́ pé àwọn nǹkan tara ló jẹ ẹ́ lógún.
Ísọ̀ gbé ayé lásìkò àwọn baba ńlá tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, torí náà ó ṣeé ṣe kóun náà láǹfààní láti rú àwọn ẹbọ kan. (Jẹ́n. 8:20, 21; 12:7, 8; Jóòbù 1:4, 5) Àmọ́ torí pé Ísọ̀ kì í ṣe ẹni tẹ̀mí, ó sọ ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí nù torí abọ́ ọbẹ̀ kan ṣoṣo. Bóyá ohun tó sì mú kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kò fẹ́ ní ìpín nínú ìyà tí Ọlọ́run sọ pé àwọn ọmọ Ábúráhámù máa jẹ. (Jẹ́n. 15:13) Yàtọ̀ síyẹn, Ísọ̀ tún fi hàn pé òun ò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀ bó ṣe lọ fẹ́ àwọn obìnrin méjì tí kì í ṣe olùjọ́sìn Ọlọ́run, èyí sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn òbí rẹ̀ gan-an. (Jẹ́n. 26:34, 35) Ti Jékọ́bù ò rí bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀, torí pé olùjọ́sìn Jèhófà ló fẹ́.—Jẹ́n. 28:6, 7; 29:10-12, 18.
Ní báyìí, kí wá ni ìparí èrò wa nípa ìlà ìdílé tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà ti wá? Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà kan wà tí ìlà ìdílé yẹn gba ọ̀dọ̀ àwọn àkọ́bí kọjá, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ló rí bẹ́ẹ̀. Àwọn Júù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀ wọn ò sì jiyàn, torí wọ́n gbà pé Kristi jẹ́ ọmọ Dáfídì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn Jésè.—Mát. 22:42.