Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹlẹ́dàá Yín Fẹ́ Kẹ́ Ẹ Láyọ̀
‘Ọlọ́run ń fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ.’—SM. 103:5.
1, 2. Tó bá di pé kó o ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, kí nìdí tó fi yẹ kó o tẹ́tí sí Ẹlẹ́dàá wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
TÓ O bá jẹ́ ọ̀dọ́, ó ṣeé ṣe kí onírúurú èèyàn ti fún ẹ nímọ̀ràn nípa ohun tó o lè fayé rẹ ṣe. Àwọn olùkọ́ rẹ, àwọn agbani-nímọ̀ràn àtàwọn míì lè máa rọ̀ ẹ́ pé kó o lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, kó o lè níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Àmọ́, nǹkan ọ̀tọ̀ ni Jèhófà gbà ẹ́ níyànjú pé kó o fayé ẹ ṣe. Jèhófà fẹ́ kó o fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ dáadáa nígbà tó o ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o lè bójú tó ara rẹ lẹ́yìn tó o bá jáde. (Kól. 3:23) Àmọ́ tó bá di pé kó o ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, Jèhófà rọ̀ ẹ́ pé kó o fi ìlànà òun sílò, kó o sì máa rántí ohun tó fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Mát. 24:14.
2 Fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ló rí ohun gbogbo, ó mọ ibi tí ayé yìí ń forí lé, ó sì mọ̀gbà tó máa wá sópin. (Aísá. 46:10; Mát. 24:3, 36) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà mọ̀ wá ju bá a ṣe mọra wa lọ, òun nìkan ló mọ ohun tó máa jẹ́ káyé wa ládùn kó lóyin, àtohun tó lè mú kéèyàn kábàámọ̀. Torí náà, kò sí bí ìmọ̀ràn àwọn èèyàn ṣe lè bọ́gbọ́n mu tó, tí kò bá bá ìlànà Ọlọ́run mu, òtúbáńtẹ́ ni, kò sọ́gbọ́n nínú rẹ̀.—Òwe 19:21.
KÒ SÍ ỌGBỌ́N TÓ LÒDÌ SÍ JÈHÓFÀ TÓ LÈ DÚRÓ
3, 4. Kí ni ìmọ̀ràn burúkú tí Ádámù àti Éfà gbà yọrí sí fún àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn?
3 Ọjọ́ pẹ́ tọ́mọ aráyé ti ń gbàmọ̀ràn tí kò ṣàǹfààní. Sátánì lẹni àkọ́kọ́ tó gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn burúkú, ó sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọ́n á túbọ̀ láyọ̀ tí wọ́n bá fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. (Jẹ́n. 3:1-6) Ẹ gbọ́ ná, ta ló yàn án ní agbani-nímọ̀ràn? Ìwà ọ̀yájú nìyẹn, ìkọjá-àyè sì ni pẹ̀lú. Kì í ṣe pé Sátánì nífẹ̀ẹ́ tọkọtaya yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ bó ṣe máa fi wọ́n sábẹ́ ara rẹ̀ ló ń wá. Ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà, títí kan àwọn àtọmọdọ́mọ wọn máa jọ́sìn òun dípò Jèhófà. Àmọ́, oore wo ni Sátánì ṣe wọ́n tí wọ́n á fi jọ́sìn rẹ̀? Ó ṣe tán, Jèhófà ló fún tọkọtaya yẹn ní gbogbo ohun tí wọ́n ní, òun ló so wọ́n pọ̀, òun ló fi ọgbà Édẹ́nì jíǹkí wọn, ó dá wọn pẹ̀lú ara tí kò lábùkù, wọ́n á sì lè wà láàyè títí láé.
4 Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn di àjèjì sí i. Bẹ́yin náà ṣe mọ̀, àbájáde rẹ̀ burú gan-an. Ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bí òdòdó téèyàn já kúrò lára igi òdòdó, díẹ̀díẹ̀, á rọ, á sì gbẹ dànù. Kì í ṣe àwọn nìkan ló jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn náà jẹ ńbẹ̀. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù nínú ọmọ aráyé ló kọ̀ láti fara wọn sábẹ́ Ọlọ́run, torí pé tinú wọn ni wọ́n ń ṣe. (Éfé. 2:1-3) Àbájáde ìpinnu wọn yìí ti mú kó ṣe kedere pé kò sí ọgbọ́n tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró.—Òwe 21:30.
5. Kí ló dá Ọlọ́run lójú pé àwọn kan máa ṣe, ṣé bó sì ṣe rí nìyẹn?
5 Síbẹ̀, Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan máa nífẹ̀ẹ́ òun, wọ́n sì máa jọ́sìn òun, títí kan àwọn ọ̀dọ́. (Sm. 103:17, 18; 110:3) Ká sòótọ́, Jèhófà mọyì irú wọn! Ṣó o wà lára wọn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ti ń gbádùn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “ohun rere” tí Ọlọ́run ń pèsè kó o lè láyọ̀ nìyẹn. (Ka Sáàmù 103:5; Òwe 10:22) Lára àwọn ìpèsè yìí ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí, àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, àwọn àfojúsùn tó ń múnú Ọlọ́run dùn àti òmìnira tòótọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn “ohun rere” yìí.
JÈHÓFÀ Ń PÈSÈ OHUN TÓ O NÍLÒ NÍPA TẸ̀MÍ
6. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń tọ́ni sọ́nà?
6 Àwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko torí pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa. (Mát. 4:4) Tó o bá ń tẹ́tí sí i, wàá ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye, wàá sì tún láyọ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,” ìyẹn àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Mát. 5:3) Ọlọ́run ń tọ́ ẹ sọ́nà nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mát. 24:45) A mà dúpẹ́ o pé à ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí yìí lónírúurú!—Aísá. 65:13, 14.
7. Sọ díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó o máa rí tó o bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.
7 Oúnjẹ tẹ̀mí tàbí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa máa ń jẹ́ ká ní ọgbọ́n àti làákàyè, ìyẹn sì máa ń dáàbò boni lónírúurú ọ̀nà. (Ka Òwe 2:10-14.) Bí àpẹẹrẹ, ọgbọ́n àti làákàyè á jẹ́ ká dá àwọn ẹ̀kọ́ èké mọ̀, irú èyí tó sọ pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Wọ́n á jẹ́ kó o rí i pé irọ́ gbuu ni pé kéèyàn tó lè láyọ̀, àfi kéèyàn lówó àtàwọn ohun ìní tara. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò ní jẹ́ kó o máa ro èròkerò tàbí kó o lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. Torí náà, túbọ̀ máa wá ọgbọ́n Ọlọ́run, kó o sì máa lo làákàyè. Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ ṣe kedere sí ìwọ fúnra rẹ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, ó sì fẹ́ kí ayé rẹ dùn.—Sm. 34:8; Aísá. 48:17, 18.
8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìsinsìnyí ló yẹ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àǹfààní wo nìyẹn sì máa ṣe ẹ́ lọ́jọ́ iwájú?
Háb. 3:2, 12-19) Torí náà, ìsinsìnyí ló yẹ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, kó o sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. (2 Pét. 2:9) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ máa balẹ̀ bíi ti Dáfídì tó sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”—Sm. 16:8.
8 Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, ayé èṣù yìí máa rún wómúwómú. Nígbà yẹn, Jèhófà nìkan ló máa lè dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀. Ìgbà kan ń bọ̀ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ojú Jèhófà làá máa wò ká tó rí oúnjẹ jẹ! (ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÓ DÁA JÙ NI JÈHÓFÀ FÚN Ẹ
9. (a) Kí ni Jèhófà máa ń ṣe bó ṣe wà nínú Jòhánù 6:44? (b) Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú kéèyàn pàdé Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí fúngbà àkọ́kọ́?
9 Jèhófà ló máa ń fa àwọn èèyàn wá sínú òtítọ́, á sì mú kí wọ́n di ara ìdílé rẹ̀. (Ka Jòhánù 6:44.) Tó o bá pàdé ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fúngbà àkọ́kọ́, nǹkan mélòó ni wàá lè sọ pó o mọ̀ nípa ẹ̀? Ṣàṣà ni nǹkan tí wàá lè sọ nípa onítọ̀hún, yàtọ̀ sí orúkọ rẹ̀ àti bó ṣe rí. Àmọ́ tó bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo pàdé fúngbà àkọ́kọ́, ohun tó o mọ̀ nípa ẹ̀ pọ̀ gan-an. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ ti wá tàbí pé orílẹ̀-èdè yín, èdè yín tàbí àṣà yín yàtọ̀ síra, ohun tẹ́ ẹ mọ̀ nípa ara yín pọ̀ gan-an!
10, 11. Kí ni gbogbo àwa èèyàn Jèhófà fi jọra, àǹfààní wo nìyẹn sì ṣe ẹ́?
10 Bí àpẹẹrẹ, gbàrà tẹ́ ẹ bá ti ríra lẹ ti máa mọ̀ pé èdè kan náà lẹ̀ ń sọ, ìyẹn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní “èdè mímọ́.” (Sef. 3:9) Ẹ mọ̀ pé ohun kan náà lẹ gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run, ìlànà kan náà lẹ̀ ń tẹ̀ lé, ìrètí kan náà lẹ ní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ká sòótọ́, àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa ẹnì kan nìyí torí pé àwọn nǹkan yẹn ló ń jẹ́ ká fọkàn tán ara wa, kí okùn ọ̀rẹ́ wa sì lágbára.
11 Kì í ṣe àsọdùn tá a bá sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa jù lo ní torí pé o jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ibi gbogbo láyé ni wọ́n wà, ó kàn
jẹ́ pé o ò tíì bá púpọ̀ nínú wọn pàdé ni! Ibo lo tún ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀? Kò sírú ẹ̀ níbòmíì yàtọ̀ sí àárín àwa èèyàn Jèhófà.JÈHÓFÀ JẸ́ KÓ O MỌ ÀWỌN ÀFOJÚSÙN TÓ Ń MÚNÚ RẸ̀ DÙN
12. Àwọn àfojúsùn wo lo lè ní nínú ìjọsìn Jèhófà?
12 Ka Oníwàásù 11:9–12:1. Ǹjẹ́ o ní àwọn àfojúsùn èyíkéyìí nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Bóyá ò ń sapá láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó sì lè jẹ́ pé ṣe lò ń gbìyànjú láti sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti bó o ṣe ń dáhùn nípàdé. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá kíyè sí i pé ò ń tẹ̀ síwájú tàbí tí ẹnì kan bá gbóríyìn fún ẹ torí pé ò ń tẹ̀ síwájú? Ó dájú pé inú rẹ máa dùn, wàá sì láyọ̀ pé ọwọ́ rẹ ti ń tẹ àfojúsùn rẹ. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o fi sípò àkọ́kọ́ láyé ẹ lò ń ṣe yẹn bíi ti Jésù.—Sm. 40:8; Òwe 27:11.
13. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kéèyàn gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sàn ju kéèyàn máa wá bí á ṣe rọ́wọ́ mú nínú ayé?
13 Téèyàn bá gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó dájú pé á láyọ̀, ìgbésí ayé rẹ̀ á sì nítumọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé béèyàn ṣe máa rọ́wọ́ mú nínú ayé ló ń lé, kódà tó bá tiẹ̀ rí towó ṣe, asán ni gbogbo ẹ̀ máa já sí, òfo ọjọ́ kejì ọjà. (Lúùkù 9:25) Ohun tí Ọba Sólómọ́nì sọ jẹ́ ká gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí.—Róòmù 15:4.
14. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Sólómọ́nì ṣe?
14 Sólómọ́nì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sì lágbára. Ó wá pinnu pé òun fẹ́ dán ìgbádùn wò, kóun lè rí ohun rere tó máa tibẹ̀ wá. (Oníw. 2:1-10) Ó kọ́ àwọn ilé ńláńlá, ó sì ṣe àwọn ọgbà ìtura àti ọgbà eléso tó rẹwà, kódà kò sóhun tó fẹ́ tọ́wọ́ rẹ̀ ò tẹ̀. Síbẹ̀, ṣé ó láyọ̀ lẹ́yìn tó kó gbogbo nǹkan yẹn jọ? Ṣé àwọn nǹkan yẹn sì tẹ́ ẹ lọ́rùn? Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi, àní èmi, sì yíjú sí gbogbo iṣẹ́ mi tí ọwọ́ mi ti ṣe . . . , sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀ . . . kò sì sí nǹkan kan tí ó ní àǹfààní.” (Oníw. 2:11) Ó dájú pé ẹ̀kọ́ pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn lọ̀rọ̀ Sólómọ́nì jẹ́ fún wa.
15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o nígbàgbọ́, àǹfààní wo nìyẹn sì máa ṣe ẹ́, bó ṣe wà nínú Sáàmù 32:8?
15 Jèhófà ò fẹ́ kó o jìyà kó o tó gbọ́n. Ó fẹ́ kó o máa ṣègbọràn sí òun, kí ìfẹ́ òun sì gbawájú láyé rẹ. Ká sòótọ́, ó gba ìgbàgbọ́ kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó o ṣe. Sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé ‘ìfẹ́ tó o fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’ (Héb. 6:10) Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára. Wàá rí i pé ohun tó dáa jù lọ ni Baba rẹ ọ̀run fẹ́ fún ẹ.—Ka Sáàmù 32:8.
ÒMÌNIRA TÒÓTỌ́ NI ỌLỌ́RUN FÚN Ẹ
16. Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọyì òmìnira rẹ, báwo lo ò ṣe ní ṣì í lò?
16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ibi tí ẹ̀mí Jèhófà bá wà, òmìnira máa wà níbẹ̀.’ (2 Kọ́r. 3:17) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òmìnira, òun náà ló sì mú kó máa wù ẹ́ láti ní òmìnira. Bó ti wù kó rí, kò fẹ́ kó o ṣi òmìnira náà lò, kó o má bàa kó sínú ìṣòro. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń wo àwòrán oníhòòhò, tí wọ́n ń ṣe ìṣekúṣe, tí wọ́n ń ṣeré géle, tí wọ́n jẹ́ ọ̀mùtí tàbí tí wọ́n ń lo oògùn olóró. Ó lè jọ pé wọ́n ń gbádùn ara wọn lóòótọ́, àmọ́ ìgbádùn náà kì í pẹ́. Ohun tó máa ń tẹ̀yìn àwọn nǹkan yìí yọ kì í dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń kó àìsàn, ohun tí wọ́n ń ṣe máa ń di bárakú, ó sì lè yọrí sí ikú. (Gál. 6:7, 8) Ó ṣe kedere pé ìtànjẹ lásán ni òmìnira tí wọ́n rò pé àwọn ní.—Títù 3:3.
17, 18. (a) Báwo ni ṣíṣègbọràn sí Jèhófà ṣe ń mú ká gbádùn òmìnira? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé òmìnira tí Ádámù àti Éfà gbádùn nínú ọgbà Édẹ́nì pọ̀ ju èyí tí aráyé ní lónìí?
17 Ní ìfiwéra, àwọn èèyàn mélòó lo mọ̀ tó ṣàìsàn torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì? Ó ṣe kedere pé tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, àá ní ìlera tó dáa, àá sì ní òmìnira tòótọ́. (Sm. 19:7-11) Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń lo òmìnira rẹ bó ṣe tọ́, tó ò ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, àwọn òbí rẹ á rí i pé o ṣe é fọkàn tán, inú Jèhófà náà á sì dùn sí ẹ. Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní òmìnira tó kún rẹ́rẹ́, tí Bíbélì pè ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
18 Ádámù àti Éfà gbádùn òmìnira yẹn fúngbà díẹ̀. Ẹ rántí ìgbà tí wọ́n wà nínú ọgbà Édẹ́nì, òfin mélòó ni Jèhófà fún wọn? Kò ju ẹyọ kan lọ. Ọlọ́run sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso igi kan ṣoṣo. (Jẹ́n. 2:9, 17) Ṣé a lè sọ pé òfin kan ṣoṣo yẹn ti nira jù tàbí pé ó ká wọn lọ́wọ́ kò? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ṣé a lè fi wé àwọn òfin jáǹtìrẹrẹ táwọn èèyàn ṣe tí wọ́n sì ń fipá mú àwọn èèyàn láti tẹ̀ lé?
19. Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe ń kọ́ wa ká lè ní òmìnira?
19 Ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni Jèhófà ń gbà bá wa lò. Dípò kó fún wa láwọn òfin jáǹtìrẹrẹ, ṣe ló ń fi sùúrù kọ́ wa ká lè máa tẹ̀ lé òfin ìfẹ́. Ó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun, ká sì kórìíra ohun tó burú. (Róòmù 12:9) Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù kọ́ wa pé téèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, kò ní kó sínú ẹ̀ṣẹ̀. (Mát. 5:27, 28) Kódà títí wọnú ayé tuntun ni Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run á máa kọ́ wa ká lè máa ṣe ohun tó tọ́, ká sì kórìíra ohun búburú bíi tiẹ̀. (Héb. 1:9) Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká ní ara àti ọpọlọ pípé. Wo bó ṣe máa rí ná, o ò ní máa bá àìpé ẹ̀dá wọ̀yá ìjà mọ́, bẹ́ẹ̀ lo ò sì ní jìyà ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ti fà mọ́. Níkẹyìn, wàá gbádùn “òmìnira ológo” tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ẹ.
20. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo òmìnira tó ní? (b) Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà?
20 Ohun kan ni pé ó níbi tí òmìnira wa mọ, bẹ́ẹ̀ lá sì máa rí títí ayé. Ìdí sì ni pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì wa lá máa darí àwọn ohun tá à ń ṣe. Ohun tí Jèhófà ń rọ̀ wá pé ká ṣe ni pé ká fara wé òun. Òmìnira Jèhófà kò láàlà, síbẹ̀ ó jẹ́ kí ìfẹ́ máa darí bí òun ṣe ń bá àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn lò. (1 Jòh. 4:7, 8) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé tá a bá jẹ́ kí ìfẹ́ máa darí wa nìkan la máa gbádùn òmìnira tòótọ́.
21. (a) Báwo làwọn ohun tí Jèhófà fún Dáfídì ṣe rí lára rẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
21 Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ “ohun rere” ni Jèhófà ti fún ẹ, bí oúnjẹ tẹ̀mí tó pọ̀ jaburata, àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, àfojúsùn tó ń múnú Ọlọ́run dùn àti òmìnira tòótọ́. Ìbéèrè náà ni pé ṣé o mọrírì àwọn ìpèsè yìí? (Sm. 103:5) Tó o bá mọyì ẹ̀, ọ̀rọ̀ tìẹ náà á dà bíi ti Dáfídì tó sọ nínú àdúrà tó gbà nínú Sáàmù 16:11 pé: “Ìwọ yóò jẹ́ kí n mọ ipa ọ̀nà ìyè. Ayọ̀ yíyọ̀ tẹ́rùn ń bẹ ní ojú rẹ; adùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.” Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ míì tó wà nínú Sáàmù 16. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí máa jẹ́ ká tún mọ ohun tá a lè ṣe káyé wa lè dùn bí oyin.