Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Gbádùn Ìgbésí Ayé Yín

Bí Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ Ṣe Lè Gbádùn Ìgbésí Ayé Yín

“Ìwọ yóò jẹ́ kí n mọ ipa ọ̀nà ìyè.”​SM. 16:11.

ORIN: 133, 89

1, 2. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tony ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kéèyàn yí pa dà?

Ọ̀DỌ́KÙNRIN kan wà tó ń jẹ́ Tony, àtikékeré ni bàbá rẹ̀ ti kú. Ọmọ ilé ìwé ni, àmọ́ kì í fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ kódà ó ń ronú àtifi ilé ìwé sílẹ̀. Ilé sinimá ló máa ń lọ ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ tàbí kó wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Kì í hùwà jàgídíjàgan, kì í sì í lo oògùn olóró. Ìṣòro rẹ̀ kàn ni pé kò mọ ohun tó fẹ́ fayé rẹ̀ ṣe, kò sì dá a lójú pé Ọlọ́run wà. Lọ́jọ́ kan, ó pàdé tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bi wọ́n láwọn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Wọ́n wá fún un ní ìwé The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking àti Was Life Created?

2 Nígbà tí tọkọtaya náà fi máa pa dà sọ́dọ̀ Tony, ojú tó fi ń wo nǹkan ti yàtọ̀. Ó ti ka àwọn ìwé náà débi pé gbogbo etí rẹ̀ ló ti ká kò. Ó wá sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run wà.” Ó gbà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bọ́jọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́, ìgbésí ayé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Kódà, Tony tó ti ń gba òdo ní ilé ìwé tẹ́lẹ̀ wá di ọ̀kan lára àwọn tó mọ̀wé jù. Ó ya ọ̀gá ilé ìwé Tony lẹ́nu nígbà tó rí àwọn àyípadà tó ṣe, ó sì mọ̀ pé ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá sọ pé: “Ìwà ẹ ti yàtọ̀ gan-an o, o sì ń ṣe dáadáa nílé ìwé. Ṣé torí àwọn Ajẹ́rìí tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ yìí náà ni?” Tony sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sì tún wàásù fún un. Tony parí ilé ìwé rẹ̀, ó sì ti di aṣáájú-ọ̀nà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí. Ó tún ń láyọ̀ pé òun ní Jèhófà, Baba tó ju Baba lọ.​—Sm. 68:5.

ṢÈGBỌRÀN SÍ JÈHÓFÀ, WÀÁ SÌ ṢÀṢEYỌRÍ

3. Ìmọ̀ràn wo ni Jèhófà fún ẹ̀yin ọ̀dọ́?

3 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tony jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ wà láàárín wa gan-an, ọ̀rọ̀ yín sì jẹ ẹ́ lógún. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ayé yín, kí ayé yín sì nítumọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi gbà yín níyànjú pé: ‘Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ.’ (Oníw. 12:1) Kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ayé yìí, àmọ́ ó ṣeé ṣe. Tẹ́ ẹ bá gbára lé Jèhófà, ẹ máa ṣàṣeyọrí nísinsìnyí àti jálẹ̀ ìgbésí ayé yín. Kí ọ̀rọ̀ náà lè yé yín dáadáa, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gba Ilẹ̀ Ìlérí àti bí Dáfídì ṣe ṣẹ́gun Gòláyátì.

4, 5. Kí la rí kọ́ látinú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gba Ilẹ̀ Ìlérí àti bí Dáfídì ṣe ṣẹ́gun Gòláyátì? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ àtiwọ Ilẹ̀ Ìlérí, Ọlọ́run ò sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń jagun. (Diu. 28:​1, 2) Dípò bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pa àṣẹ òun mọ́ kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Jóṣ. 1:​7-9) Lójú èèyàn, ó lè dà bíi pé ìmọ̀ràn yẹn ò mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ nìyẹn torí pé léraléra ni Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì. (Jóṣ. 24:​11-13) Ó ṣe kedere pé kéèyàn tó lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run, èèyàn gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́. Téèyàn bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, kò ní rí ìjákulẹ̀ láé. Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí, kò sì yí pa dà títí dòní olónìí.

5 Akin lójú ogun ni Gòláyátì, ó rí fìrìgbọ̀n kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ilé, ó sì di ìhámọ́ra. (1 Sám. 17:​4-7) Àmọ́ gbogbo ohun tí Dáfídì ní ò ju nǹkan méjì péré, ó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì ní kànnàkànnà. Lójú àwọn tí kò nígbàgbọ́, òmùgọ̀ ni Dáfídì. Àmọ́, èrò wọn ò tọ́ torí pé Gòláyátì gan-an ni òmùgọ̀.​—1 Sám. 17:​48-51.

6. Kí la máa jíròrò báyìí?

6 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin tó lè mú ká láyọ̀ kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀. Nǹkan mẹ́rin náà ni oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè, àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, àwọn àfojúsùn tó ń múnú Ọlọ́run dùn àti òmìnira tòótọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá yàn-nà-ná àwọn kókó mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ká sì wo bí àwọn ìlànà tó wà nínú Sáàmù 16 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.

MÁA JẸ OÚNJẸ TẸ̀MÍ DÉÉDÉÉ

7. (a) Kí lo lè sọ nípa ẹni tẹ̀mí? (b) Kí ni “ìpín” Dáfídì, báwo nìyẹn sì ṣe rí lára rẹ̀?

7 Ẹni tẹ̀mí máa ń nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó sì máa ń fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Ó máa ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, ó sì máa ń ṣègbọràn sí i. (1 Kọ́r. 2:​12, 13) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Dáfídì. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà ni ìpín tí ó kàn mí àti ti ife mi.” (Sm. 16:5) Dáfídì mọyì “ìpín” rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà, ìyẹn àjọṣe tó dáa tó ní pẹ̀lú rẹ̀, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sm. 16:1) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ó sọ pé inú òun dùn gan-an. Ó ṣe kedere pé kò sóhun míì tó ń múnú Dáfídì dùn bí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.​—Ka Sáàmù 16:​9, 11.

8. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀?

8 Àwọn tó ń wá bí wọ́n á ṣe gbádùn ayé wọn kí wọ́n sì lówó ò lè ní irú ayọ̀ tí Dáfídì ní. (1 Tím. 6:​9, 10) Arákùnrin kan ní Kánádà sọ pé: “Kì í ṣe ohun tí ayé yìí lè fúnni ló ń jẹ́ kọ́kàn èèyàn balẹ̀, bí kò ṣe ohun tá a lè fún Jèhófà tó fún wa ní gbogbo ẹ̀bùn rere.” (Ják. 1:17) Ó dájú pé tó o bá nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, tó o sì fayé rẹ sìn ín, ìgbésí ayé rẹ á nítumọ̀, ọkàn rẹ á sì balẹ̀. Àmọ́, báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń wá àkókò láti túbọ̀ mọ Jèhófà. Ìyẹn gba pé kó o máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó o máa kíyè sí àwọn ohun tó dá, kó o sì máa ronú nípa àwọn ànímọ́ tó ní, títí kan bó ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ẹ.​—Róòmù 1:20; 5:8.

9. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí ẹ bíi ti Dáfídì?

9 Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa máa ń jẹ́ kó bá wa wí nígbà míì. Dáfídì mọyì ìbáwí tí Jèhófà fún un, ó sọ pé: “Èmi yóò fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹni tí ó ti fún mi ní ìmọ̀ràn. Ní ti tòótọ́, kíndìnrín mi ti tọ́ mi sọ́nà ní òru.” (Sm. 16:7) Dáfídì máa ń ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń jẹ́ kó máa darí òun. Tíwọ náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì máa wù ẹ́ pé kó o máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo. Ìyẹn á mú kó o di ẹni tẹ̀mí, kí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú rẹ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christin sọ pé: “Tí mo bá ń ṣèwádìí, tí mo sì ń ronú lórí ohun tí mo kà, ó máa ń ṣe mí bíi pé èmi gangan ni Jèhófà kọ ọ̀rọ̀ yìí fún!”

10. Bó ṣe wà nínú Aísáyà 26:​3, àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn jẹ́ ẹni tẹ̀mí?

10 Tó o bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, wàá rí i pé kò sí nǹkan kan mọ́ nínú ayé yìí, wàá sì tún mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáyé yìí láìpẹ́. Jèhófà ló dìídì fún ẹ ní ìmọ̀ àti òye yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó fẹ́ kó o gbájú mọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, kó o ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kọ́kàn ẹ sì balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Ka Aísáyà 26:3.) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Joshua láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Tó o bá sún mọ́ Jèhófà, wàá mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì àtàwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì.” Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí, ohun tó o sì mọ̀ yẹn á jẹ́ kó o ṣèpinnu táá fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀.

MÁA WÁ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÒÓTỌ́

11. Kí ni Dáfídì sọ nípa bá a ṣe lè ní ọ̀rẹ́ tòótọ́?

11 Ka Sáàmù 16:3. Dáfídì mọ béèyàn ṣe lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ó sọ pé inú òun máa ń dùn láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn tí Dáfídì pè ní àwọn “ẹni mímọ́” yìí máa ń hùwà rere, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin. Onísáàmù míì náà sọ ohun kan náà nípa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó ní: “Alájọṣe ni mo jẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, àti pẹ̀lú àwọn tí ń pa àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́.” (Sm. 119:63) Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìwọ náà lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè dàgbà jù ẹ́ lọ tàbí kí wọ́n kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí.

12. Kí ló mú kí àárín Jónátánì àti Dáfídì wọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

12 Kì í ṣe àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ́ Dáfídì nìkan ló bá ṣọ̀rẹ́. Ṣé o rántí orúkọ “ọlọ́lá” kan tó di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn Dáfídì? Jónátánì lorúkọ rẹ̀. Kódà, àjọṣe tó wà láàárín àwọn méjèèjì wà lára àwọn tí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì gbà lọ́wọ́ Dáfídì? Kí ló wá mú kí àárín wọn wọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn méjèèjì mọyì báwọn ṣe fìgboyà kojú àwọn ọ̀tá Jèhófà.​—1 Sám. 13:3; 14:13; 17:​48-50; 18:1.

13. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ ní àwọn ọ̀rẹ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

13 Tá a bá yan ọ̀rẹ́ láàárín àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, inú tiwa náà máa dùn bíi ti Dáfídì àti Jónátánì. Arábìnrin Kiera tó ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní kárí ayé pọ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ wọn ló wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àṣà wọn sì yàtọ̀ síra.” Tíwọ náà bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń mú ká wà níṣọ̀kan kárí ayé.

MÁA LÉ ÀWỌN ÀFOJÚSÙN TÓ Ń MÚNÚ ỌLỌ́RUN DÙN

14. (a) Kí ló máa jẹ́ kó o ní àwọn àfojúsùn tó ń múnú Jèhófà dùn? (b) Kí làwọn ọ̀dọ́ kan sọ nípa àfojúsùn tẹ̀mí tí wọ́n ní?

14 Ka Sáàmù 16:8. Ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé Dáfídì. Ìwọ náà máa láyọ̀ tó o bá fi ìjọsìn Jèhófà ṣe ohun àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ tó o sì ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé: “Tí mo bá ń rántí gbogbo ìsapá tí mo ṣe kọ́wọ́ mi lè tẹ àwọn àfojúsùn kan, tọ́wọ́ mi sì tẹ̀ ẹ́, inú mi máa ń dùn.” Arákùnrin kan láti Jámánì, tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó sì ń sìn nílẹ̀ míì sọ pé: “Tí mo bá dàgbà, mi ò ní fẹ́ bojú wẹ̀yìn kí n wá rí i pé mi ò ṣe nǹkan kan fún Jèhófà.” Ó dá wa lójú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, lo àwọn ẹ̀bùn tó o ní láti bọlá fún Ọlọ́run, kó o sì fi ran àwọn míì náà lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Torí náà, ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ̀ wọ́n. Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn gan-an láti dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀.​—1 Jòh. 3:22; 5:​14, 15.

15. Àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn rẹ? (Wo àpótí náà “ Àwọn Nǹkan Tó O Lè Fi Ṣe Àfojúsùn.”)

15 Àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn rẹ? O lè pinnu pé o fẹ́ máa dáhùn lọ́rọ̀ ara rẹ nípàdé tàbí kó o di aṣáájú-ọ̀nà. O sì lè pinnu pé wàá lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. O lè kọ́ èdè míì kó o lè lọ sìn níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè yẹn. Barak, arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sọ pé: “Ṣe ni inú mi máa ń dùn bí mo ṣe ń jí láràárọ̀, tí mo sì ń rí i pé Jèhófà ni mò ń lo gbogbo okun mi fún. Kò sóhun míì tó lè fúnni nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀.”

MỌYÌ ÒMÌNIRA TÍ ỌLỌ́RUN FÚN Ẹ

16. Ọwọ́ wo ni Dáfídì fi mú àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà, kí sì nìdí?

16 Ka Sáàmù 16:​2, 4Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà máa ń jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ohun tó dáa ká sì kórìíra ohun tó burú. (Ámósì 5:15) Dáfídì náà sọ pé Jèhófà ló ṣe òun lóore. Onínúure èèyàn lẹni tó ń hùwà ọmọlúwàbí, Dáfídì sì sapá láti jẹ́ onínúure bíi ti Jèhófà. Dáfídì náà kórìíra àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra, bí ìbọ̀rìṣà. Ìdí ni pé ìbọ̀rìṣà máa ń rẹ àwọn èèyàn wálẹ̀, ó sì máa ń gbé ògo tó jẹ́ ti Jèhófà fún nǹkan míì.​—Aísá. 2:​8, 9; Ìṣí. 4:11.

17, 18. (a) Kí ni Dáfídì sọ pé ó máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó ń ṣe ìsìn èké? (b) Kí ló máa ń mú káwọn èèyàn lónìí “sọ ìbànújẹ́ wọn di púpọ̀”?

17 Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, ìṣekúṣe wà lára ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìsìn èké. (Hós. 4:​13, 14) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ ìsìn èké torí pé wọ́n gbádùn ìṣekúṣe. Àmọ́ ṣé ìyẹn fún wọn láyọ̀ tó wà pẹ́ títí? Kò sóhun tó jọ ọ́! Dáfídì sọ pé, àwọn tó bá ń sin ọlọ́run míì máa ní ìbànújẹ́ tó pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń fìyà jẹ àwọn ọmọdé. (Aísá. 57:5) Kò sí àní-àní pé Jèhófà kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀! (Jer. 7:31) Ká sọ pé àsìkò yẹn lo gbáyé, ó dájú pé inú rẹ máa dùn gan-an pé àwọn òbí rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.

18 Bákan náà lónìí, ìsìn èké fàyè gba ìṣekúṣe, kódà wọ́n fọwọ́ sí kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin, kí obìnrin sì máa fẹ́ obìnrin. Àmọ́ bíi ti ayé ìgbà yẹn, ìbànújẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. (1 Kọ́r. 6:​18, 19) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ́wọ́ sí irú ìwà bẹ́ẹ̀ ṣe ń ní ìbànújẹ́ púpọ̀. Torí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹ́tí sí Jèhófà Baba yín ọ̀run. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé ire yín ló máa jẹ́ tẹ́ ẹ bá ń ṣègbọràn sí i. Ẹ fi sọ́kàn pé ìgbádùn téèyàn máa ń rí nídìí ìwà burúkú ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìbànújẹ́ tó máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀. (Gál. 6:8) Joshua tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “A lè lo òmìnira wa bá a ṣe fẹ́, àmọ́ tá a bá ṣì í lò, a máa kan ìdin nínú iyọ̀.”

19, 20. Ìbùkún wo làwọn ọ̀dọ́ tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i máa rí?

19 Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòh. 8:​31, 32) Òmìnira yẹn máa gbà wá lọ́wọ́ ìsìn èké, àìmọ̀kan àti ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán. Kò tán síbẹ̀ o, lọ́jọ́ iwájú a tún máa ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ìwọ náà máa ní òmìnira yẹn báyìí tó o bá ‘dúró nínú ọ̀rọ̀ Kristi’ tó o sì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá “mọ òtítọ́,” kì í ṣe torí pé o kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìkan, àmọ́ torí pé ò ń fi sílò nígbèésí ayé rẹ.

20 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ mọyì òmìnira tí Ọlọ́run fún yín. Ẹ fi ọgbọ́n lo òmìnira yín, kẹ́ ẹ lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn ìpinnu tí ẹ ò ní kábàámọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Tó o bá ń fi ọgbọ́n lo òmìnira rẹ ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, á rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì lọ́jọ́ iwájú, irú bí iṣẹ́ tó o máa ṣe àti bóyá kó o ṣègbéyàwó tàbí kó o ṣì ní sùúrù fúngbà díẹ̀.”

21. Kí lá mú kó o máa rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí “ìyè tòótọ́”?

21 Téèyàn bá tiẹ̀ rí towó ṣe nínú ayé tó ń lọ sópin yìí, ìgbádùn náà kì í tọ́jọ́, torí pé òní la rí, kò sẹ́ni mọ̀la. (Ják. 4:​13, 14) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o máa rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Tím. 6:19) Ohun kan ni pé Jèhófà kì í fipá múni rìn lójú ọ̀nà yẹn, ọwọ́ wa nìyẹn kù sí. Torí náà fi Jèhófà ṣe “ìpín” rẹ, kó o sì mọyì ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “ohun rere” tó fún ẹ. (Sm. 103:5) Ní paríparí ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé òun nìkan ló lè fún ẹ ní ayọ̀, táá sì jẹ́ kí ayé rẹ dùn títí láé.​—Sm. 16:11.