Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde.” Ṣé ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ ni pé èèyàn lè máa dẹ́ṣẹ̀ léraléra kí Ọlọ́run sì máa dárí jì í?
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì náà ń sọ nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé èèyàn lè ṣubú ní ti pé ó ń tinú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíì. Láìka tàwọn ìṣòro tó ní sí, ó ń dìde tó túmọ̀ sí pé ó ń fara dà á.
Ká lè lóye ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kà á láti ẹsẹ tó ṣáájú sí èyí tó tẹ̀ lé e: “Má ṣe lúgọ sí tòsí ilé olódodo láti ṣe é níbi; má ṣe ba ibi ìsinmi rẹ̀ jẹ́. Nítorí olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde, àmọ́ àjálù yóò mú kí ẹni burúkú ṣubú pátápátá. Tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má ṣe dunnú, tó bá sì kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ yọ̀.”—Òwe 24:15-17.
Àwọn kan sọ pé ẹsẹ 16 yẹn ń sọ nípa ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ àmọ́ tí Ọlọ́run dárí jì. Àwọn aṣáájú ìsìn méjì kan lórílẹ̀-èdè England sọ pé “bí àwọn oníwàásù láyé àtijọ́ àti lóde òní ṣe máa ń túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí nìyẹn.” Wọ́n fi kún un pé, irú èrò yìí túmọ̀ sí pé “ẹni rere lè ṣubú . . . sínú ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, síbẹ̀ kó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé ó lè dìde ní ti pé Ọlọ́run máa dárí jì í ní gbogbo ìgbà tó bá ronú pìwà dà.” Ẹnì kan tó fẹ́ràn àtimáa dẹ́sẹ̀ lè fi àlàyé yìí kẹ́wọ́. Ó lè máa ronú pé tóun bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, Ọlọ́run ṣì máa dárí ji òun.
Àmọ́ o, kì í ṣe ohun tí ẹsẹ 16 yẹn ń sọ nìyẹn.
Onírúurú ọ̀nà la lè gbà lo ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ṣubú” ní ẹsẹ 16 àti 17. Ó lè túmọ̀ sí pé kéèyàn kan ṣubú ní ti gidi. Bí àpẹẹrẹ, màlúù kan lè ṣubú lójú ọ̀nà, ẹnì kan lè já bọ́ látorí òrùlé tàbí kí òkúta kan bọ́ sílẹ̀. (Diu. 22:4, 8; Émọ́sì 9:9) A tún lè lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà máa ń darí ẹsẹ̀ ẹni nígbà tí inú Rẹ̀ bá dùn sí ọ̀nà ẹni náà. Bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ ṣubú, kò ní balẹ̀ pátápátá, nítorí pé Jèhófà dì í lọ́wọ́ mú.”—Sm. 37:23, 24; Òwe 11:5; 13:17; 17:20.
Àmọ́ ẹ kíyè sí kókó kan tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Edward H. Plumptre sọ, ó ní: “Kò sígbà kankan tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí [“ṣubú”] ń sọ nípa ẹnì kan tó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀.” Abájọ tí ọ̀mọ̀wé míì fi ṣàlàyé ẹsẹ 16 yẹn lọ́nà yìí, ó ní: “Ṣe lẹni tó ń fìyà jẹ àwọn èèyàn Ọlọ́run kàn ń ṣàṣedànù. Ìdí ni pé bópẹ́bóyá, àwọn èèyàn Ọlọ́rùn máa ṣàṣeyọrí. Àmọ́ ní tàwọn ẹni burúkú, wọn ò ní ṣàṣeyọrí!”
Torí náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ni Òwe 24:16 ń sọ nípa ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó ṣubú sínú ìṣòro tàbí tó ń tinú ìṣòro kan bọ́ sí òmíì ló ń sọ. Nínú ayé burúkú tá à ń gbé yìí, olódodo lè ṣàìsàn tàbí kó láwọn ìṣòro míì. Kódà, ìjọba lè ṣenúnibíni sí i nítorí ohun tó gbà gbọ́. Bó ti wù kó rí, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé Ọlọ́run máa ti òun lẹ́yìn, á sì fún òun lókun láti fara dà á. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé Ọlọ́run máa ń dúró ti àwọn èèyàn ẹ̀, wọn kì í sì í bọ́hùn. Kí nìdí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé, “Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.”—Sm. 41:1-3; 145:14-19.
Inú “olódodo” kì í dùn pé àwọn míì níṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ torí ó mọ̀ pé “ó máa dára fún àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.”—Oníw. 8:11-13; Jóòbù 31:3-6; Sm. 27:5, 6.