ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 51
Jèhófà Ń Tu Àwọn Tó Rẹ̀wẹ̀sì Nínú
“Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”—SM. 34:18.
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
GBOGBO wa ló máa ń wù pé ká pẹ́ láyé, kí ọkàn wa sì balẹ̀. Àmọ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ, ọjọ́ wa kúrú “wàhálà rẹ̀ sì máa ń pọ̀ gan-an.” (Jóòbù 14:1) Ìyẹn sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. Irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́. Kódà, wọ́n gbàdúrà pé káwọn kú. (1 Ọba 19:2-4; Jóòbù 3:1-3, 11; 7:15, 16) Ṣùgbọ́n léraléra ni Jèhófà Ọlọ́run wọn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì fún wọn lókun. Ìrírí wọn wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kó sì tù wá nínú.—Róòmù 15:4.
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó kojú àwọn ìṣòro tó mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Lára wọn ni Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù, Náómì tó jẹ́ opó àti Rúùtù ìyàwó ọmọ rẹ̀, ọmọ Léfì tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin (73) àti àpọ́sítélì Pétérù. Báwo ni Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Ẹ̀kọ́ wo sì lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè rí kọ́ lára wọn? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” àti pé ‘ó ń gba àwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì là.’—Sm. 34:18, àlàyé ìsàlẹ̀.
JÓSẸ́FÙ FARA DA ÌWÀ ÌKÀ TÍ WỌ́N HÙ SÍ I
3-4. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù nígbà tó jẹ́ ọ̀dọ́?
3 Nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni Jósẹ́fù nígbà tí Ọlọ́run mú kó lá àlá méjì. Àwọn àlá yẹn fi hàn pé lọ́jọ́ kan, Jósẹ́fù máa di èèyàn pàtàkì táwọn tó kù nínú ìdílé ẹ̀ á máa bọlá fún. (Jẹ́n. 37:5-10) Kò pẹ́ tó lá àwọn àlá náà ni nǹkan yí pa dà bìrí fún un. Dípò káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bọlá fún un, ṣe ni wọ́n tà á, ó sì di ẹrú Pọ́tífárì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò. (Jẹ́n. 37:21-28) Àbẹ́ ò rí nǹkan, Jósẹ́fù tó jẹ́ ààyò bàbá ẹ̀ wá di ẹrú lásán-làsàn nílé ọkùnrin kan tó jẹ́ abọ̀rìṣà nílẹ̀ Íjíbítì.—Jẹ́n. 39:1
4 Àmọ́ kékeré nìyẹn nínú ìṣòro tí Jósẹ́fù ní. Ìyàwó Pọ́tífárì parọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀. Láìdúró gbẹ́jọ́, Pọ́tífárì ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n, wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é. (Jẹ́n. 39:14-20; Sm. 105:17, 18) Ẹ wo bó ṣe máa dun Jósẹ́fù tó pé wọ́n parọ́ mọ́ òun pé òun fẹ́ fipá bá ìyàwó oníyàwó lò pọ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí lè mú káwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ burúkú nípa Jèhófà Ọlọ́run Jósẹ́fù. Ó dájú pé ìyẹn máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Jósẹ́fù gan-an!
5. Kí ni Jósẹ́fù ṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì yẹn ò fi bò ó mọ́lẹ̀?
5 Ìwọ̀nba lohun tí Jósẹ́fù lè ṣe nígbà tó jẹ́ ẹrú àti nígbà tó wà lẹ́wọ̀n. Àmọ́ kí ló ṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì yẹn ò fi bò ó mọ́lẹ̀? Dípò táá fi máa ronú lórí àwọn nǹkan tí ò lè ṣe mọ́, ṣe ló gbájú mọ́ iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, bí Jósẹ́fù ṣe máa mú inú Jèhófà dùn ló gbà á lọ́kàn. Jèhófà náà sì bù kún gbogbo ohun tí Jósẹ́fù dáwọ́ lé.—Jẹ́n. 39:21-23.
6. Báwo ni àwọn àlá tí Jósẹ́fù lá sẹ́yìn ṣe tù ú nínú?
6 Ó ṣeé ṣe kí àwọn àlá tí Jósẹ́fù lá sẹ́yìn tù ú nínú. Àwọn àlá náà jẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì máa rí ìdílé òun lẹ́ẹ̀kan sí i àti pé nǹkan ṣì máa sàn fóun. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Nígbà tí Jósẹ́fù tó nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì (37), àwọn àlá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lọ́nà àgbàyanu.—Jẹ́n. 37:7, 9, 10; 42:6, 9.
7. Kí ni 1 Pétérù 5:10 sọ tó máa jẹ́ ká lè fara da àdánwò?
7 Ohun tá a rí kọ́. Ìtàn Jósẹ́fù kọ́ wa pé ìwà ìkà ló kúnnú ayé yìí. Torí náà, àwọn èèyàn lè hùwà àìdáa sí wa, kódà ẹnì kan Sm. 62:6, 7; ka 1 Pétérù 5:10.) Ẹ má sì gbàgbé pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni Jósẹ́fù nígbà tí Jèhófà jẹ́ kó lá àwọn àlá méjì tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà fọkàn tán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lónìí ló dà bíi Jósẹ́fù torí pé àwọn náà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Kódà, wọ́n ti ju àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò torí wọ́n pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà làwọn máa ṣe.—Sm. 110:3.
tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe ohun tó dùn wá. Àmọ́ tá a bá fi Jèhófà ṣe Àpáta tàbí Ibi Ààbò wa, a ò ní rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. (ÀWỌN OBÌNRIN MÉJÌ TÍ Ọ̀FỌ̀ ṢẸ̀
8. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Náómì àti Rúùtù?
8 Torí ìyàn tó mú, Náómì àti ìdílé rẹ̀ fi ilé wọn sílẹ̀ ní Júdà, wọ́n sì kó lọ sí Móábù tó jẹ́ ilẹ̀ àjèjì. Níbẹ̀, Élímélékì ọkọ Náómì kú, ó sì fi ọmọ méjì sílẹ̀ fún un. Nígbà tó yá, àwọn ọmọkùnrin náà fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Móábù, ìyẹn Rúùtù àti Ọ́pà. Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, àwọn ọmọkùnrin Náómì méjèèjì kú láìbímọ. (Rúùtù 1:1-5) Ẹ wo ìbànújẹ́ ńlá tó máa bá àwọn obìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yìí! Òótọ́ ni pé Rúùtù àti Ọ́pà lè ní ọkọ míì, àmọ́ ta ló máa tọ́jú Náómì tó ti dàgbà? Ẹ̀dùn ọkàn tó bá Náómì le débi tó fi sọ pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì mọ́. Márà ni kí ẹ máa pè mí, torí Olódùmarè ti mú kí ayé mi korò gan-an.” Àdánù ńlá gbáà ló bá Náómì yìí, abájọ tó fi pinnu láti pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù náà sì tẹ̀ lé e.—Rúùtù 1:7, 18-20.
9. Bó ṣe wà nínú Rúùtù 1:16, 17, 22, kí ni Rúùtù ṣe tó mú kára tu Náómì?
9 Kí ló mú kí ara tu Náómì? Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Rúùtù fi hàn sí i ni. Bí àpẹẹrẹ, Rúùtù sọ fún Náómì pé òun ò ní fi í sílẹ̀ rárá. (Ka Rúùtù 1:16, 17, 22.) Nígbà tí wọ́n dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù ṣiṣẹ́ kára níbi tó ti ń pèéṣẹ́ ọkà bálì kóun àti Náómì lè rí nǹkan jẹ. Ohun tó ṣe yìí mú káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n, kí wọ́n sì máa sọ ohun tó dáa nípa ẹ̀.—Rúùtù 3:11; 4:15.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn aláìní bíi Náómì àti Rúùtù?
10 Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin kan tó jẹ́ kí wọ́n lè ṣojú àánú sáwọn aláìní bíi Náómì àti Rúùtù. Ó sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé tí wọ́n bá ń kórè oko wọn, kí wọ́n fi àwọn irè oko tó wà ní eteetí sílẹ̀ fún àwọn aláìní. (Léf. 19:9, 10) Torí náà, kò ní sídìí pé Náómì àti Rúùtù ń tọrọ jẹ.
11-12. Kí ni Bóásì ṣe tó mú kí inú Náómì àti Rúùtù dùn?
11 Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Bóásì ló ni oko tí Rúùtù ti lọ pèéṣẹ́. Bí Rúùtù ṣe dúró ti ìyá ọkọ rẹ̀, tó sì ń fìfẹ́ tọ́jú ẹ̀ wú Bóásì lórí gan-an. Ìyẹn mú kó ra gbogbo ohun tó jẹ́ ti ìdílé wọn, ó sì fi Rúùtù ṣaya. (Rúùtù 4:9-13) Tọkọtaya náà bí ọmọ kan tí wọ́n pè ní Óbédì, òun ló sì di bàbá bàbá Ọba Dáfídì.—Rúùtù 4:17.
12 Ẹ wo bí inú Náómì ṣe máa dùn tó nígbà tó gbé Óbédì máyà, tó sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà! Àmọ́ ayọ̀ wọn máa légbá kan nígbà tí wọ́n bá jíǹde nínú ayé tuntun, tí wọ́n sì rí i pé Óbédì ló wá di baba ńlá Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, ìyẹn Jésù Kristi!
13. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Náómì àti Rúùtù?
13 Ohun tá a rí kọ́. Tí àdánwò bá dé bá Òwe 17:17.
wa, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká ní ọgbẹ́ ọkàn. Nígbà míì, ó tiẹ̀ lè ṣe wá bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ. Irú àsìkò yẹn gan-an ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ká sì túbọ̀ sún mọ́ àwọn Kristẹni bíi tiwa. Òótọ́ kan ni pé Jèhófà lè má mú àwọn àdánwò yẹn kúrò, ó ṣe tán, kò jí ọkọ Náómì àti àwọn ọmọ rẹ̀ dìde nígbà yẹn. Àmọ́, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, ó lè lo àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa láti tù wá nínú.—ỌMỌ LÉFÌ KAN TÓ FẸ́RẸ̀Ẹ́ KỌSẸ̀
14. Kí ló kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọmọ Léfì kan?
14 Ọmọ Léfì lẹni tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin (73). Torí náà, ó láǹfààní láti máa sìn níbi ìjọsìn Jèhófà. Síbẹ̀, ìgbà kan wà tí òun alára rẹ̀wẹ̀sì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ń jowú àwọn agbéraga àti àwọn ẹni burúkú torí pé lójú ẹ̀, wọ́n ń gbádùn ìgbésí ayé wọn. (Sm. 73:2-9, 11-14) Lérò tiẹ̀, gbogbo nǹkan ni wọ́n ní, wọ́n lọ́lá, wọ́n lọ́là, ayé yẹ wọ́n, ọkàn wọn sì balẹ̀. Ohun tí onísáàmù náà rí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a débi tó fi sọ pé: “Ó dájú pé lásán ni mo pa ọkàn mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi mọ́ pé mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.” Kò sí àní-àní pé tí ò bá yí èrò ẹ̀ pa dà, ó lè fi Jèhófà sílẹ̀.
15. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 73:16-19, 22-25, báwo ni ọmọ Léfì tó kọ Sáàmù yìí ṣe borí ìrẹ̀wẹ̀sì?
15 Ka Sáàmù 73:16-19, 22-25. Ọmọ Léfì náà “wọ ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run” tó ṣeé ṣe káwọn olùjọsìn bíi tiẹ̀ wà. Ìyẹn mú kó lè ronú jinlẹ̀, kó sì fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà. Ó wá rí i pé èrò òun kò tọ́ àti pé tóun ò bá ṣàtúnṣe òun lè fi Jèhófà sílẹ̀. Ó tún lóye pé “orí ilẹ̀ tó ń yọ̀” làwọn ẹni burúkú wà, wọ́n á sì “pa run.” Tí ọmọ Léfì náà bá máa borí ìlara àti ìrẹ̀wẹ̀sì, ó ṣe pàtàkì kó máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Torí pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, inú ẹ̀ sì dùn. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn [Jèhófà], kò sí ohun míì tó wù mí ní ayé.”
16. Kí la rí kọ́ lára ọmọ Léfì náà?
16 Ohun tá a rí kọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ ká jowú Oníw. 8:12, 13) Tá a bá ń jowú wọn, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, tá ò bá sì ṣọ́ra a lè fi Jèhófà sílẹ̀. Tó bá jọ pé o ti ń jowú àwọn ẹni burúkú, tètè ṣe ohun tí ọmọ Léfì yẹn ṣe. Fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò, kó o sì bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kẹ́gbẹ́. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ohunkóhun míì lọ, wàá ní ojúlówó ayọ̀, o ò sì ní kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí “ìyè tòótọ́.”—1 Tím. 6:19.
àwọn ẹni burúkú tó jọ pé wọ́n ń gbádùn ayé wọn. Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ara wọn, ojú ayé lásán ni, kò sì lè tọ́jọ́. (ÀÌPÉ PÉTÉRÙ KÓ ÌRẸ̀WẸ̀SÌ BÁ A
17. Kí ló mú kí Pétérù rẹ̀wẹ̀sì?
17 Onítara èèyàn ni àpọ́sítélì Pétérù, àmọ́ nígbà míì, ó máa ń fi ìwàǹwára ṣe nǹkan, ó sì máa ń tètè sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń sọ̀rọ̀ tàbí ṣe àwọn nǹkan tóun fúnra ẹ̀ máa ń pa dà kábàámọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ jìyà, kóun sì kú, Pétérù bá a wí, ó sọ fún un pé: “Èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.” (Mát. 16:21-23) Àmọ́ Jésù tún èrò Pétérù ṣe. Nígbà táwọn jàǹdùkú wá mú Jésù, Pétérù ò tiẹ̀ rò ó lẹ́ẹ̀mejì, ṣe ló gé etí ẹrú àlùfáà àgbà. (Jòh. 18:10, 11) Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún èrò Pétérù ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, Pétérù tún fọ́nnu pé tí àwọn àpọ́sítélì tó kù bá tiẹ̀ fi Jésù sílẹ̀, òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. (Mát. 26:33) Nígbà tọ́rọ̀ dójú ẹ̀, ẹ̀rù ba Pétérù tó dára ẹ̀ lójú, ó sì sẹ́ Ọ̀gá ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá Pétérù, torí náà, ó “bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.” (Mát. 26:69-75) Ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé bóyá ni Jésù máa dárí ji òun.
18. Kí ni Jésù ṣe tó mú kí Pétérù borí ìrẹ̀wẹ̀sì?
18 Àmọ́ Pétérù ò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì yẹn bo òun mọ́lẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Lẹ́yìn tó ṣàṣìṣe, ó kọ́fẹ pa dà, ó sì tún dara pọ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì yòókù. (Jòh. 21:1-3; Ìṣe ) Kí ló jẹ́ kó kọ́fẹ pa dà? Ohun kan ni pé ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti gbàdúrà fún Pétérù kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ má bàa yẹ̀, ó sì rọ Pétérù pé gbàrà tí ó bá pa dà, kí ó fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun. Jèhófà dáhùn àdúrà àtọkànwá yẹn. Nígbà tó yá, Jésù fara han Pétérù lóun nìkan kó lè fún un lókun. ( 1:15, 16Lúùkù 22:32; 24:33, 34; 1 Kọ́r. 15:5) Lóru ọjọ́ kan táwọn àpọ́sítélì ń wá ẹja títí àmọ́ tí wọn ò rẹ́ja pa, Jésù fara hàn wọ́n. Nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn, Jésù fún Pétérù láǹfààní láti fi hàn bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun. Ó ṣe kedere pé Jésù ti dárí ji ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí, ó sì fún un ní iṣẹ́ míì láti ṣe.—Jòh. 21:15-17.
19. Báwo ni Sáàmù 103:13, 14 ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa?
19 Ohun tá a rí kọ́. Ohun tí Jésù ṣe fún Pétérù fi hàn pé aláàánú ni Jésù, Jèhófà ló sì fìyẹn jọ. Torí náà tá a bá ṣàṣìṣe, ká má ṣe ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá láé. Ká rántí pé ohun tí Sátánì fẹ́ ká máa rò gan-an nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò wá, ká rántí pé aláàánú ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Irú ojú yìí kan náà ló yẹ ká fi máa wo àwọn tó bá ṣẹ̀ wá.—Ka Sáàmù 103:13, 14.
20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, Náómì àti Rúùtù, ọmọ Léfì náà àti Pétérù jẹ́ kó dá wa lójú pé “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn.” (Sm. 34:18) Nígbà míì, Jèhófà máa ń fàyè gba pé ká kojú àwọn ìṣòro kan tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́ tá a bá gbára lé e, tá a sì fara da àwọn ìṣòro náà láìbọ́hùn, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára. (1 Pét. 1:6, 7) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, àá rí àwọn ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń ṣèrànwọ́ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí àìpé tàbí àwọn ìṣòro míì mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì.
ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa
^ ìpínrọ̀ 5 Jósẹ́fù, Náómì àti Rúùtù, ọmọ Léfì kan àti àpọ́sítélì Pétérù kojú àwọn ìṣòro tó mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Jèhófà ṣe tù wọ́n nínú, tó sì fún wọn lókun. A tún máa jíròrò ohun tá a lè rí kọ́ lára wọn, àá sì rí bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.
^ ìpínrọ̀ 56 ÀWÒRÁN: Ìbànújẹ́ bá Náómì, Rúùtù àti Ọ́pà wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ọkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kú. Nígbà tó yá, inú Rúùtù, Náómì àti Bóásì dùn nígbà tí wọ́n bí Óbédì.