ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 48
“Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”
“Kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.”—1 PÉT. 1:15.
ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni, kí sì nìdí tí ò fi rọrùn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀?
BÓYÁ a nírètí láti gbé ní ọ̀run tàbí ayé, a lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Pétérù sọ pé: “Bíi ti Ẹni Mímọ́ tó pè yín, kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.’ ” (1 Pét. 1:15, 16) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ẹni tó fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìjẹ́mímọ́. Torí náà, a lè jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa, ohun tó sì yẹ ká ṣe nìyẹn. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé kò ṣeé ṣe torí aláìpé ni wá. Àmọ́, Pétérù náà ṣe àwọn àṣìṣe kan, síbẹ̀ àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fi hàn pé a lè jẹ́ “mímọ́.”
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Àkọ́kọ́, kí ni ìjẹ́mímọ́? Ìkejì, kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́? Ìkẹta, báwo la ṣe lè jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa? Àti ìkẹrin, báwo ni ìjẹ́mímọ́ ṣe kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà?
KÍ NI ÌJẸ́MÍMỌ́?
3. Kí lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ mímọ́, àmọ́ kí ni Bíbélì sọ?
3 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó jẹ́ mímọ́, ohun táwọn èèyàn máa ń rò ni ẹnì kan tí inú ẹ̀ kì í dùn, tó wọ aṣọ ẹ̀sìn, tí ìrísí ẹ̀ sì jọ ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run. Àmọ́, èrò yìí ò tọ̀nà torí pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, “Ọlọ́run aláyọ̀” sì ni. (1 Tím. 1:11) Bíbélì tún pe àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ní “aláyọ̀.” (Sm. 144:15) Kódà, Jésù ò fara mọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó ń wọ aṣọ ńlá, tí wọ́n sì ń ṣe òdodo wọn níwájú àwọn èèyàn. (Mát. 6:1; Máàkù 12:38) Àmọ́ ní ti àwa Kristẹni tòótọ́, ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwa náà jẹ́ mímọ́. A sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ tó jẹ́ mímọ́ ò ní fún wa lófin tá ò ní lè pa mọ́. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ fún wa pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́,” a ò ṣiyèméjì pé a lè jẹ́ mímọ́. Àmọ́ ṣá o, ká tó lè jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ìjẹ́mímọ́ jẹ́.
4. Kí ni “ìjẹ́mímọ́”?
4 Kí ni ìjẹ́mímọ́? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìjẹ́mímọ́” sábà máa ń tọ́ka sí ìwà mímọ́ àti ohun mímọ́. Ó tún máa ń tọ́ka sí yíya ohun kan sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Lédè míì, a lè sọ pé ẹni mímọ́ ni wá tí ìwà wa bá mọ́, tá à ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, tá a sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, tí Jèhófà sì jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà, síbẹ̀, ó ń wù ú pé ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.
“MÍMỌ́, MÍMỌ́, MÍMỌ́ NI JÈHÓFÀ”
5. Ẹ̀kọ́ wo ni báwọn áńgẹ́lì ṣe jẹ́ olóòótọ́ kọ́ wa nípa Jèhófà?
5 Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Ohun táwọn séráfù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì tó sún mọ́ ìtẹ́ Jèhófà sọ nípa rẹ̀ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lára wọn sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.” (Àìsá. 6:3) Èyí fi hàn pé káwọn áńgẹ́lì tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́, àwọn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Ẹni mímọ́ sì ni wọ́n, kódà ibi tí áńgẹ́lì kan bá dúró sí ní ayé máa di mímọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tí Mósè wà níbi igi ẹlẹ́gùn-ún kan tó ń jó.—Ẹ́kís. 3:2-5; Jóṣ. 5:15.
6-7. (a) Bí Ẹ́kísódù 15:1, 11 ṣe sọ, báwo ni Mósè ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́? (b) Kí ló máa ń mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rántí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
6 Lẹ́yìn tí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa já, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wọn jẹ́ mímọ́. (Ka Ẹ́kísódù 15:1, 11.) Ìwà àwọn tó ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run Íjíbítì ò mọ́ rárá. Bí ìwà àwọn tó ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run Kénáánì ṣe rí náà nìyẹn. Wọ́n máa ń fi àwọn ọmọ wọn rúbọ níbi ìjọsìn wọn, wọ́n sì máa ń ṣe ìṣekúṣe tó burú jáì. (Léf. 18:3, 4, 21-24; Diu. 18:9, 10) Àmọ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn ọlọ́run àwọn abọ̀rìṣà yẹn. Kò ní sọ pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa hùwà àìmọ́ torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa rántí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, wọ́n kọ àkọlé kan sára wúrà pẹlẹbẹ tó wà lára láwàní àlùfáà àgbà. Àkọlé náà sọ pé: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.”—Ẹ́kís. 28:36-38.
7 Ọ̀rọ̀ tó wà lára wúrà pẹlẹbẹ yẹn ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà jẹ́ mímọ́. Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan ò lè rí àkọlé náà ńkọ́ torí pé kò lè dé ibi tí àlùfáà àgbà wà? Ṣé ẹni náà á ṣì mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé ló gbọ́ nígbà tí wọ́n ń ka Òfin yẹn. (Diu. 31:9-12) Tó o bá wà níbẹ̀, ìwọ náà máa gbọ́ gbólóhùn yìí: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, . . . ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.” “Kí ẹ jẹ́ mímọ́ fún mi, torí èmi Jèhófà jẹ́ mímọ́.”—Léf. 11:44, 45; 20:7, 26.
8. Kí la rí kọ́ nínú Léfítíkù 19:2 àti 1 Pétérù 1:14-16?
8 Ẹ jẹ́ ká wo gbólóhùn kan nínú Léfítíkù 19:2 tí Mósè kà fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹ jẹ́ mímọ́, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.’ ” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ẹsẹ Bíbélì yìí ni Pétérù ti fa ọ̀rọ̀ yọ nígbà tó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ “mímọ́.” (Ka 1 Pétérù 1:14-16.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́, síbẹ̀ ohun tí Pétérù sọ jẹ́ ká rí ẹ̀kọ́ tó wà nínú Léfítíkù 19:2. Ẹ̀kọ́ náà ni pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ mímọ́. Ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé nínú Párádísè.—1 Pét. 1:4; 2 Pét. 3:13.
‘Ẹ JẸ́ MÍMỌ́ NÍNÚ GBOGBO ÌWÀ YÍN’
9. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá gbé Léfítíkù orí 19 yẹ̀ wò?
9 Torí pé a fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run wa tó jẹ́ mímọ́, ó ń wu àwa náà ká mọ ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ mímọ́. Jèhófà ti fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ mímọ́. Àwọn ìmọ̀ràn yẹn wà nínú ìwé Léfítíkù orí 19. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Marcus Kalisch tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Hébérù sọ pé: “Orí Bíbélì yìí ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan. Kódà, ó lè jẹ́ pé orí yìí ló ṣe pàtàkì jù nínú ìwé Léfítíkù àti àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì.” Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹsẹ mélòó kan yẹ̀ wò nínú orí yìí, ká lè rí bí àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa. Bá a ṣe ń gbé wọn yẹ̀ wò, ẹ fi sọ́kàn pé àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ bá gbólóhùn tá a fi bẹ̀rẹ̀ Léfítíkù orí kọkàndínlógún (19) mu tó ní: “Kí ẹ jẹ́ mímọ́.”
10-11. Kí ni Léfítíkù orí 19:3 sọ pé ká ṣe, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?
10 Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jẹ́ mímọ́, Jèhófà fi kún un pé: “Kí kálukú yín máa bọ̀wọ̀ fún ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀ . . . Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.”—Léf. 19:2, 3.
11 Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run tó ní ká máa bọlá fáwọn òbí wa. Ṣé ẹ rántí ìgbà tí ọkùnrin kan bi Jésù pé: “Ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?” Ọ̀kan lára ìdáhùn tí Jésù fún ọkùnrin náà ni pé kó máa bọ̀wọ̀ fún bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀. (Mát. 19:16-19) Kódà, Jésù bá àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin wí torí pé wọn ò fẹ́ bójú tó àwọn òbí wọn. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” (Mát. 15:3-6) Lára “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” náà ni òfin karùn-ún nínú Òfin Mẹ́wàá àti ohun tá a kà nínú Léfítíkù 19:3. (Ẹ́kís. 20:12) Ẹ tún jẹ́ ká fi sọ́kàn pé lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Kí ẹ jẹ́ mímọ́, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́,” ló ṣẹ̀ wá sọ fún wọn ní Léfítíkù 19:3 pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá wọn.
12. Tá a bá wo ìmọ̀ràn tó wà nínú Léfítíkù 19:3, ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
12 Tá a bá wo ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún wa pé ká máa bọlá fáwọn òbí wa, ó yẹ ká bi ara wa pé ‘Ṣé mò ń bọlá fáwọn òbí mi?’ Tó o bá rí i pé o ò ṣe tó bó ṣe yẹ fáwọn òbí ẹ, sapá kó o lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ti kọjá, àmọ́ ní báyìí, rí i pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa wà pẹ̀lú wọn, kó o lè túbọ̀ máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, máa pèsè nǹkan tara tí wọ́n nílò fún wọn. Máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, kó o sì máa tù wọ́n nínú. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yẹn, ṣe lò ń pa àṣẹ tó wà nínú Léfítíkù 19:3 mọ́.
13. (a) Àṣẹ míì wo la tún rí nínú Léfítíkù 19:3? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó wà nínú Lúùkù 4:16-18 lónìí?
13 Léfítíkù 19:3 tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ míì nípa bá a ṣe lè jẹ́ mímọ́. Ó sọ pé kí ẹ máa pa Sábáàtì mọ́. Àwa Kristẹni ò tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́, torí náà a kì í pa Sábáàtì mọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pa Sábáàtì mọ́, àá sì tún rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àǹfààní tó ṣe wọ́n. Ọjọ́ Sábáàtì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sinmi kí wọ́n lè ráyè jọ́sìn Ọlọ́run. * Ìdí nìyẹn tí Jésù fi máa ń lọ sínú sínágọ́gù ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ Sábáàtì kó lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 31:12-15; ka Lúùkù 4:16-18.) Òfin Ọlọ́run tó wà nínú Léfítíkù 19:3 tó sọ pé ká máa ‘pa sábáàtì rẹ̀ mọ́’ yẹ kó mú ká máa wáyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa pa àṣẹ náà mọ́? Tó o bá ń wáyè fún ìjọsìn Ọlọ́run, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ gún régé, ìyẹn á sì jẹ́ kó o jẹ́ mímọ́.
TÚBỌ̀ JẸ́ KÍ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ LÁGBÁRA
14. Òtítọ́ pàtàkì wo la tẹnu mọ́ nínú Léfítíkù orí 19?
14 Léfítíkù 19 tẹnu mọ́ òtítọ́ pàtàkì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ mímọ́. Ọ̀rọ̀ pàtàkì tó parí ẹsẹ kẹrin ni: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.” Gbólóhùn yẹn àtèyí tó jọ ọ́ fara hàn nígbà mẹ́rìndínlógún (16) nínú orí kọkàndínlógún (19) ìwé Léfítíkù. Èyí rán wa létí òfin kìíní tó sọ pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ . . . O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.” (Ẹ́kís. 20:2, 3) Kristẹni kọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ jẹ́ mímọ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ò jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run jẹ́. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a ti pinnu pé àá máa yẹra fún ìwà èyíkéyìí tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Ọlọ́run.—Léf. 19:12; Àìsá. 57:15.
15. Tá a bá gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ẹbọ rírú yẹ̀ wò nínú Léfítíkù orí 19, kí nìyẹn máa mú ká ṣe?
15 Ọ̀nà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ń fi hàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run àwọn ni pé wọ́n ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Léfítíkù 18:4 sọ pé: “Kí ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa rìn nínú wọn. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.” Léfítíkù orí 19 sọ lára “àwọn àṣẹ” náà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, ẹsẹ 5-8, 21 àti 22 sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń fi ẹran rúbọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ rú ẹbọ náà lọ́nà tí ò ní “sọ ohun mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́.” Tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ yìí, wọ́n á mú kó wù wá láti máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ká sì máa rú ẹbọ ìyìn sí i lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà bí Hébérù 13:15 ṣe gbà wá nímọ̀ràn.
16. Ìlànà wo ló wà nínú Léfítíkù 19 tó jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín?
16 Tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́, ìwà wa gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí tàwọn tí kò sin Ọlọ́run, èyí sì lè má rọrùn. Ìdí ni pé nígbà míì, àwọn ọmọléèwé wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì máa ń fẹ́ ká ṣe ohun tó ta ko ìjọsìn wa. Nírú ipò yìí, ó gba pé ká ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́? Ẹ jẹ́ ká wo ìlànà pàtàkì kan nínú Léfítíkù 19:19, ó sọ pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tó ní oríṣi òwú méjì tí wọ́n hun pọ̀.’ Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí ló jẹ́ kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Òfin yẹn ò kan àwa Kristẹni lónìí torí pé a lè wọ aṣọ tó ní oríṣiríṣi òwú. Àmọ́, a kì í hùwà bí àwọn èèyàn tí ìwà wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ ta ko ohun tí Bíbélì sọ, kódà tí wọ́n bá jẹ́ àwọn ọmọléèwé wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa. Ṣùgbọ́n a ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Síbẹ̀, àwọn ìpinnu tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa ń mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn tí kò sin Jèhófà. Èyí ṣe pàtàkì gan-an torí pé tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́, a gbọ́dọ̀ ya ara wa sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run.—2 Kọ́r. 6:14-16; 1 Pét. 4:3, 4.
17-18. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú Léfítíkù 19:23-25?
17 Gbólóhùn náà “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín” yẹ kó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé kí wọ́n fi àjọṣe wọn àti Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Ọ̀nà wo ni wọ́n máa gbà ṣe é? Léfítíkù 19:23-25 sọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é. (Kà á.) Ẹ jẹ́ ká wo báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣe ohun tí Jèhófà sọ yìí lẹ́yìn tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Tí ọkùnrin kan bá gbin igi eléso fún oúnjẹ, kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. Tó bá di ọdún kẹrin, ó máa kó àwọn èso rẹ̀ lọ síbi mímọ́ níwájú Jèhófà. Àmọ́, tó bá di ọdún karùn-ún, ó lè jẹ nínú àwọn èso náà. Òfin yẹn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ti Jèhófà ló yẹ kí wọ́n fi ṣáájú, kì í ṣe tara wọn. Ó yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè fáwọn, kí wọ́n sì fi hàn pé ìjọsìn ẹ̀ ló ṣe pàtàkì jù sí wọn, ó sì dájú pé Jèhófà máa pèsè ohun tí wọ́n máa jẹ. Jèhófà tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa mú ọrẹ wá sí ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń jọ́sìn rẹ̀.
18 Òfin tó wà nínú Léfítíkù 19:23-25 rán wa létí ọ̀rọ̀ Jésù nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè. Jésù sọ pé: “Ẹ yéé ṣàníyàn nípa . . . ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu.” Ó wá fi kún un pé: “Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí.” Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run máa pèsè fún wa bó ṣe ń pèsè fáwọn ẹyẹ. (Mát. 6:25, 26, 32) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tá a nílò fún wa. Àwa náà máa ń ṣe “ìtọrẹ àánú” fáwọn tó nílò ìrànwọ́ lọ́nà tó máa buyì kún wọn. Inú wa sì máa ń dùn láti tètè fowó ṣètìlẹyìn nígbà tí ìjọ bá nílò rẹ̀. Gbogbo ọrẹ àtinúwá tá à ń ṣe yìí ni Jèhófà ń kíyè sí, ó sì máa san wá lẹ́san. (Mát. 6:2-4) Bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan yìí fi hàn pé a lóye ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 19:23-25, a sì ń tẹ̀ lé e.
19. Kí lo rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a gbé yẹ̀ wò nínú Léfítíkù?
19 A ti gbé àwọn ẹsẹ mélòó kan yẹ̀ wò nínú Léfítíkù orí 19, a sì ti rí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà jẹ́ mímọ́ tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run wa mímọ́. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ “mímọ́ nínú gbogbo ìwà” wa. (1 Pét. 1:15) Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò sin Jèhófà ti fojú ara wọn rí ìwà rere wa. Ká sòótọ́, ó ti mú káwọn kan yin Jèhófà lógo. (1 Pét. 2:12) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la ṣì lè rí kọ́ nínú Léfítíkù orí 19. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àwọn ẹsẹ Bíbélì míì nínú orí yìí tó máa jẹ́ ká mọ àwọn ibòmíì nígbèésí ayé wa tó yẹ ká ti jẹ́ “mímọ́” bí Pétérù ṣe rọ̀ wá.
ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’
^ A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, a sì ń fẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, ó ń fẹ́ káwa tá à ń jọ́sìn ẹ̀ náà jẹ́ mímọ́. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe káwa èèyàn aláìpé jẹ́ mímọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe. Ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni àti ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Àwọn nǹkan yẹn máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa.
^ Kó o lè mọ̀ nípa Sábáàtì àtàwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú ẹ̀, wo àpilẹ̀kọ náà, “Ó Yẹ Ká Ní Àkókò fún Iṣẹ́ àti Ìsinmi” nínú Ilé Ìṣọ́ December 2019.