ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 51
Ẹ Máa ‘Fetí sí Jésù’
“Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.”—MÁT. 17:5.
ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. (a) Àṣẹ wo ni Jèhófà pa fáwọn àpọ́sítélì Jésù mẹ́ta, kí ni wọ́n sì ṣe lẹ́yìn náà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
LẸ́YÌN Ìrékọjá ọdún 32 S.K., àpọ́sítélì Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù rí ìran kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nígbà tí wọ́n wà ní apá kan Òkè Hámónì tó ga fíofío, Jèhófà yí Jésù pa dà di ológo níwájú wọn. “Ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” (Mát. 17:1-4) Nígbà tó kù díẹ̀ kí ìran náà parí, àwọn àpọ́sítélì gbọ́ tí Jèhófà sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.” (Mát. 17:5) Ohun táwọn àpọ́sítélì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ìgbésí ayé wọn ṣe fi hàn pé wọ́n tẹ́tí sí Jésù lóòótọ́. Ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.
2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé tá a bá fẹ́ fetí sí ohùn Jésù, àwọn nǹkan kan wà tí kò yẹ ká ṣe mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan méjì tí Jésù sọ pé ó yẹ ká máa ṣe.
“Ẹ GBA ẸNUBODÈ TÓÓRÓ WỌLÉ”
3. Bí Mátíù 7:13, 14 ṣe sọ, kí ló yẹ ká ṣe?
3 Ka Mátíù 7:13, 14. Ẹ kíyè sí i pé ẹnubodè méjì ni Jésù sọ pé ó wà, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹnubodè méjèèjì sì já sí. Ọ̀nà àkọ́kọ́ “fẹ̀,” ọ̀nà kejì sì rí “tóóró,” àmọ́ kò sí ọ̀nà kẹta. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ọ̀nà tóun máa gbà. Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa nìyẹn torí òun ló máa sọ bóyá a máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
4. Ṣàlàyé bí ọ̀nà tó “fẹ̀” yẹn ṣe rí.
4 Ó yẹ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀nà méjèèjì yẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba ọ̀nà tó “fẹ̀” yẹn kọjá torí pé ó rọrùn gbà. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà lójú ọ̀nà náà, wọ́n sì ń ṣe ohun táwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà yẹn ń ṣe. Wọn ò mọ̀ pé Sátánì ló ń fa àwọn èèyàn sójú ọ̀nà yẹn àti pé ikú ló máa gbẹ̀yìn gbogbo àwọn tó ń rin ojú ọ̀nà náà.—1 Kọ́r. 6:9, 10; 1 Jòh. 5:19.
5. Kí làwọn kan ti ṣe kí wọ́n lè máa rìn lójú ọ̀nà “tóóró” náà?
5 Jésù sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀nà tó “fẹ̀” àti èyí tó rí “tóóró.” Ó ní díẹ̀ làwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà tóóró yẹn. Kí nìdí? Nínú ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, Jésù sọ ohun tó fà á, ó ní ká yẹra fáwọn wòlíì èké. (Mát. 7:15) Tá a bá ní ká máa kà á léní èjì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀sìn ló wà, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló sì ń sọ pé òótọ́ làwọn fi ń kọ́ni. Torí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló wà, nǹkan ti tojú sú àwọn èèyàn, wọn ò sì mọ ohun tí wọ́n máa ṣe, ìdí nìyẹn tí wọn ò fi gbìyànjú láti wá ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Àmọ́ ọ̀nà yẹn ò ṣòro láti rí. Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.” (Jòh. 8:31, 32) Inú wa dùn pé o ò tẹ̀ lé ohun tí ọ̀pọ̀ ń ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe lo wá bó o ṣe máa rí òtítọ́. O bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe, o sì ń fetí sáwọn ẹ̀kọ́ Jésù. O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fẹ́ ká pa àwọn ẹ̀kọ́ tó wá látinú ẹ̀sìn èké tì, ká sì jáwọ́ nínú àwọn àjọ̀dún tí kò bá Bíbélì mu. O tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó lè má rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà àti àṣà tí inú Jèhófà ò dùn sí. (Mát. 10:34-36) Ó sì lè ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Síbẹ̀, o ṣe ohun tó tọ́ torí o nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ ọ̀run, o sì fẹ́ rí ojúure ẹ̀. O ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ gan-an!—Òwe 27:11.
OHUN TÍ Ò NÍ JẸ́ KÁ KÚRÒ LÓJÚ Ọ̀NÀ TÓÓRÓ
6. Bí Sáàmù 119:9, 10, 45 àti 133 ṣe sọ, kí ni ò ní jẹ́ ká kúrò lójú ọ̀nà tóóró?
6 Ní báyìí tá a ti wà lójú ọ̀nà tóóró yẹn, kí ni ò ní jẹ́ ká kúrò níbẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Wọ́n máa ń ṣe irin sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tóóró tó wà lórí àwọn òkè kí àwọn mọ́tò tó ń gbabẹ̀ má bàa já bọ́. Irin yìí máa ń dáàbò bo àwọn awakọ̀ torí kò ní jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ etí ọ̀nà náà jù tàbí kí wọ́n wa mọ́tò gorí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ọ̀nà náà. Ó dájú pé kò sí awakọ̀ tó máa sọ pé irin náà ń dí òun lọ́wọ́, kò sì jẹ́ kóun wakọ̀ bóun ṣe fẹ́. Bí àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà tó wà nínú Bíbélì náà ṣe rí nìyẹn. Àwọn ìlànà yẹn máa ń jẹ́ ká dúró sójú ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Sáàmù 119:9, 10, 45, 133.
7. Ojú wo ló yẹ kẹ́yin ọ̀dọ́ máa fi wo ojú ọ̀nà tóóró náà?
7 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ó máa ń ṣe yín nígbà míì bíi pé àwọn ìlànà Jèhófà ti le jù? Ohun tí Sátánì fẹ́ kẹ́ ẹ máa rò gan-an nìyẹn. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ máa ronú ṣáá nípa ohun táwọn tó wà lójú ọ̀nà tó fẹ̀ ń ṣe tó sì dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ara wọn. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ máa ronú pé ẹ ò gbádùn ara yín bí àwọn ọmọ iléèwé yín tàbí àwọn tẹ́ ẹ̀ ń rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó tún fẹ́ kẹ́ ẹ gbà pé àwọn ìlànà Jèhófà ò jẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ara yín dọ́ba. * Àmọ́ ẹ rántí pé Sátánì ò fẹ́ káwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ẹ̀ mọ ibi tí ọ̀nà náà máa já sí. Àmọ́ ní ti Jèhófà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé a máa láyọ̀ tá a bá dúró sójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Sm. 37:29; Àìsá. 35:5, 6; 65:21-23.
8. Kí lẹ̀yin ọ̀dọ́ lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Olaf?
8 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Olaf yẹ̀ wò, ká sì wo ohun tẹ́yin ọ̀dọ́ lè rí kọ́ lára ẹ̀. * Àwọn ọmọ iléèwé ẹ̀ ń fúngun mọ́ ọn pé kó ṣèṣekúṣe. Nígbà tó ṣàlàyé pé ìlànà Bíbélì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, a kì í sì í ṣèṣekúṣe, ṣe làwọn ọ̀dọ́bìnrin kan ní kíláàsì rẹ̀ ń sọ fún un ṣáá pé kó bá àwọn lò pọ̀. Àmọ́ Olaf ò gbà fún wọn. Yàtọ̀ síyẹn, Olaf dojú kọ ìṣòro míì. Ó sọ pé: “Àwọn olùkọ́ mi ń rọ̀ mí pé kí n lọ sílé ìwé gíga kí n lè dẹni ńlá. Wọ́n sọ pé tí mi ò bá lọ, mi ò lè ríṣẹ́ gidi, mi ò sì ní láyọ̀.” Kí ló jẹ́ kí Olaf borí àwọn nǹkan tí wọ́n ní kó ṣe yìí? Ó sọ pé: “Mo túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará tá a jọ wà nínú ìjọ. Gbogbo wa wá dà bíi ìdílé kan. Yàtọ̀ síyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń dá mi lójú pé inú òtítọ́ ni mo wà. Ìyẹn jẹ́ kí n pinnu pé màá ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, màá sì ṣèrìbọmi.”
9. Kí làwọn tó fẹ́ dúró sójú ọ̀nà tóóró gbọ́dọ̀ máa ṣe?
9 Sátánì fẹ́ kó o kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó fẹ́ kó o dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà tó fẹ̀ “tó lọ sí ìparun.” (Mát. 7:13) Àmọ́, tá a bá ń fetí sí Jésù tá a sì gbà pé ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè la wà, a ò ní kúrò lójú ọ̀nà tóóró náà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan míì tí Jésù sọ pé ó yẹ ká máa ṣe.
MÁA WÁ ÀLÀÁFÍÀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ARÁ
10. Bí Mátíù 5:23, 24 ṣe sọ, kí ni Jésù sọ pé ó yẹ ká máa ṣe?
10 Ka Mátíù 5:23, 24. Jésù sọ̀rọ̀ nípa nǹkan pàtàkì kan táwọn Júù máa ń ṣe. Ẹ jẹ́ ká ronú nípa ẹnì kan tó mú ẹran tó fẹ́ fi rúbọ wá fún àlùfáà nínú tẹ́ńpìlì. Ká sọ pé ìgbà tó fẹ́ fún àlùfáà ní ẹran yẹn gan-an ló rántí pé òun ṣẹ ẹnì kan, Jésù sọ pé kó fi ẹran náà sílẹ̀ níbẹ̀ ‘kí ó sì lọ.’ Kí nìdí? Ìdí ni pé nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì ju ẹbọ tó fẹ́ rú sí Jèhófà lọ. Jésù sọ nǹkan náà, ó ní: “Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ.”
11. Kí ni Jékọ́bù ṣe kó lè wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísọ̀?
11 Tá a bá wo ohun tí Jékọ́bù ṣe nígbà tó fẹ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísọ̀, àá mọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ láàárín àwa àti ẹnì kan. Lẹ́yìn ogún (20) ọdún tí Jékọ́bù ti kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, Jèhófà lo áńgẹ́lì kan láti sọ fún un pé kó pa dà síbẹ̀. (Jẹ́n. 31:11, 13, 38) Àmọ́, ìṣòro kan wà. Ìṣòro náà ni pé Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fẹ́ pa á. (Jẹ́n. 27:41) “Ẹ̀rù wá ba Jékọ́bù gan-an, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀” torí ó rò pé ẹ̀gbọ́n òun ṣì ń bínú sí òun. (Jẹ́n. 32:7) Kí ni Jékọ́bù ṣe kó lè wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó fi ẹ̀bùn rẹpẹtẹ ránṣẹ́ sí Ísọ̀. (Jẹ́n. 32:9-15) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, nígbà tí Jékọ́bù àti Ísọ̀ ríra lójúkojú, ó ṣe ohun tó fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ẹ̀gbọ́n ẹ̀. Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló tẹrí ba fún Ísọ̀! Torí pé Jékọ́bù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀gbọ́n ẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀.—Jẹ́n. 33:3, 4.
12. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jékọ́bù?
12 A kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nínú ohun tí Jékọ́bù ṣe nígbà tó lọ bá Ísọ̀. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jékọ́bù ní mú kó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe ohun tó bá àdúrà ẹ̀ mu, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ísọ̀. Nígbà tí wọ́n pàdé, Jékọ́bù ò bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn pẹ̀lú Ísọ̀ nípa ẹni tó jẹ̀bi tàbí ẹni tó jàre. Ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ ni bó ṣe máa wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin ẹ̀. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jékọ́bù?
BÁ A ṢE LÈ YANJÚ Ọ̀RỌ̀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ÈÈYÀN
13-14. Tá a bá ṣẹ ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà, kí ló yẹ ká ṣe?
13 Tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, ó yẹ ká máa wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa. (Róòmù 12:18) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti ṣẹ ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà? Bíi ti Jékọ́bù, ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. A lè ní kó jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin wa ní ìtùnbí-ìnùbí.
14 Ó yẹ káwa náà yẹ ara wa wò. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo ṣe tán láti gbà pé mo jẹ̀bi lóòótọ́, kí n sì lọ bẹ ẹni náà kí àlàáfíà lè wà láàárín àwa méjèèjì? Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà àti Jésù tí wọ́n bá rí i pé mo lọ yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin mi?’ Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa mú ká fetí sí Jésù, ká sì lọ yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tá a ṣẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jékọ́bù.
15. Báwo la ṣe lè lo ìmọ̀ràn tó wà nínú Éfésù 4:2, 3 tá a bá fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
15 Ẹ wo ohun tí ò bá ṣẹlẹ̀ ká sọ pé Jékọ́bù ò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó lọ bá Ísọ̀! Ọ̀rọ̀ yẹn ò bá má yanjú rárá. Tá a bá lọ bá arákùnrin tàbí arábìnrin wa láti yanjú ọ̀rọ̀ kan, ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. (Ka Éfésù 4:2, 3.) Òwe 18:19 sọ pé: “Ọmọ ìyá tí a ṣẹ̀, ó le ju ìlú olódi lọ, àwọn ìjà kan sì wà tó dà bí ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè ilé gogoro tó láàbò.” Torí náà, tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì lọ bẹ ẹni náà, ṣe ló máa dà bí ìgbà tá a rí ọ̀nà wọ “ilé gogoro tó láàbò” kan.
16. Nǹkan míì wo ló yẹ ká ronú lé, kí sì nìdí?
16 Ó tún yẹ ká ronú nípa nǹkan tá a máa sọ tá a bá débẹ̀ àti bá a ṣe máa sọ ọ́. Tá a bá ti ṣe tán láti lọ, ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bí ẹni náà ṣe máa yọ́nú sí wa. Ó lè kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan tí ò bá wa lára mu. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ṣe la gbaná jẹ, tá a sì ń dá ara wa láre, ṣéyẹn máa yanjú ọ̀rọ̀ náà? Rárá! Fi sọ́kàn pé bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni náà ṣe pàtàkì ju kó o máa wá ẹni tó jẹ̀bi tàbí ẹni tó jàre.—1 Kọ́r. 6:7.
17. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Gilbert?
17 Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Gilbert sapá gan-an láti wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹnì kan. Ó sọ pé: “Èdèkòyédè wà láàárín èmi àti ọmọbìnrin mi. Ó lé lọ́dún méjì tí mo fi ń gbìyànjú láti bá a sọ̀rọ̀ ká sì yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí, àmọ́ pàbó ló já sí.” Kí ni Gilbert tún ṣe? Ó sọ pé: “Kí n tó bá ọmọ mi sọ̀rọ̀, mo máa ń gbàdúrà, mo sì máa ń múra ọkàn mi sílẹ̀ pé ó lè sọ nǹkan tí ò ní bá mi lára mu. Mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ dárí jì í, kì í ṣe kí n máa jà fún ẹ̀tọ́ mi. Ohun tó yẹ kí n wá ni bí àlàáfíà ṣe máa jọba láàárín àwa méjèèjì.” Kí ló wá yọrí sí? Gilbert sọ pé: “Lónìí, ọkàn mi balẹ̀ torí pé àjọṣe àárín èmi àti àwọn ará ilé mi dára gan-an.”
18-19. Tá a bá ti ṣẹ ẹnì kan, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe, kí sì nìdí?
18 Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rí i pé o ti ṣẹ arákùnrin tàbí arábìnrin kan? Ṣe ohun tí Jésù sọ kí àlàáfíà lè wà láàárín ẹ̀yin méjèèjì. Gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀, kó o sì jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀, wàá sì fi hàn pé ò ń fetí sí Jésù.—Mát. 5:9.
19 A dúpẹ́ pé Jèhófà ń fìfẹ́ darí wa nípasẹ̀ Jésù Kristi tó jẹ́ “orí ìjọ.” (Éfé. 5:23) Bíi ti àpọ́sítélì Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa “fetí sí” Jésù. (Mát. 17:5) A ti rí bá a ṣe lè ṣe é nígbà tá a bá lọ yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin tá a ṣẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní kúrò lójú ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè, a ó sì gba ọ̀pọ̀ ìbùkún nísinsìnyí àti ayọ̀ tí kò lópin lọ́jọ́ iwájú.
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
^ Jésù gbà wá níyànjú pé ká gba ẹnu ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó tún sọ fún wa pé ká máa wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe ká kojú tá a bá fẹ́ fi ìmọ̀ràn Jésù sílò, báwo la sì ṣe lè borí ẹ̀?
^ Wo Ìbéèrè 6 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, “Kí Ni Mo Lè Ṣe Káwọn Ojúgbà Mi Má Ba Ìwà Mi Jẹ́?” àti eré ojú pátákó náà Má Ṣe Jẹ́ Kí Àwọn Ẹgbẹ́ Ẹ Ba Ìwà Ẹ Jẹ́! lórí ìkànnì www.dan124.com. (Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > Ọ̀DỌ́.)
^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
^ ÀWÒRÁN: Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà bá a ṣe wà lójú ọ̀nà “tóóró” tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, a ò ní máa wo àwòrán ìṣekúṣe, a ò ní máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó máa jẹ́ ká ṣèṣekúṣe, a ò sì ní gbà fáwọn tó ní dandan ká lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga.
^ ÀWÒRÁN: Kí àlàáfíà lè wà láàárín Jékọ́bù àti Ísọ̀, Jékọ́bù tẹrí ba fún un léraléra.