Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7

‘Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n’

‘Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n’

“Fetí sílẹ̀ kí o sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n.”​—ÒWE 22:17.

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń gbà wá nímọ̀ràn, kí sì nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa máa gba ìmọ̀ràn?

 GBOGBO wa la máa ń nílò ìmọ̀ràn látìgbàdégbà. Nígbà míì, ó lè jẹ́ àwa la máa sọ pé kí ẹnì kan tá a fọkàn tán gbà wá nímọ̀ràn. Ó sì lè jẹ́ arákùnrin kan ló máa sọ fún wa pé a ti fẹ́ “ṣi ẹsẹ̀ gbé” tíyẹn sì máa jẹ́ ká kábàámọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Gál. 6:1) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè jẹ́ pé ẹ̀yìn tá a ṣàṣìṣe lẹnì kan máa bá wa wí. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi gbà wá nímọ̀ràn, ó yẹ ká fetí sí ìmọ̀ràn náà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe wá láǹfààní, ó sì lè jẹ́ ohun tó máa gba ẹ̀mí wa là nìyẹn!​—Òwe 6:23.

2. Bó ṣe wà nínú Òwe 12:15 àti àlàyé ìsàlẹ̀, kí nìdí tó fi yẹ ká máa gba ìmọ̀ràn?

2 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa ‘fetí sílẹ̀, ká sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n.’ (Òwe 22:17) Kò sí èèyàn tó mọ gbogbo nǹkan tán, kò sí ká má rí ẹnì kan tó máa ní ìmọ̀ tàbí ìrírí jù wá lọ. (Ka Òwe 12:15 àti àlàyé ìsàlẹ̀.) Torí náà, tá a bá ń gba ìmọ̀ràn, ìyẹn á fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a máa fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa, a sì gbà pé àfi káwọn èèyàn ràn wá lọ́wọ́ ká tó lè ṣe àwọn nǹkan kan. Ọlọ́run mí sí Ọba Sólómọ́nì láti sọ pé: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà [tàbí “olùdámọ̀ràn,” àlàyé ìsàlẹ̀].”​—Òwe 15:22.

Èwo nínú àwọn ìmọ̀ràn méjì yìí ló máa ń ṣòro fún ẹ láti gbà? (Wo ìpínrọ̀ 3-4)

3. Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà fún wa nímọ̀ràn?

3 Ẹnì kan lè fún wa nímọ̀ràn tó ṣe tààràtà, àmọ́ nígbà míì, ìmọ̀ràn náà lè má ṣe tààràtà. Báwo la ṣe lè gba ìmọ̀ràn tí kò ṣe tààràtà? A lè ka ohun kan nínú Bíbélì tàbí nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ètò Ọlọ́run táá mú ká tún èrò wa ṣe, ká sì ṣàtúnṣe. (Héb. 4:12) Irú ìmọ̀ràn yẹn kì í ṣe tààràtà. Ìmọ̀ràn tó ṣe tààràtà ńkọ́? Alàgbà tàbí arákùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè pe àfiyèsí wa sí ohun kan tó yẹ ká ṣàtúnṣe lé lórí. Ìyẹn ni ìmọ̀ràn tó ṣe tààràtà. Tẹ́nì kan bá fi Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn, ìyẹn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, ṣe ló yẹ ká gba ìmọ̀ràn náà, àá sì fi hàn pé a mọrírì ẹ̀ tá a bá ṣàtúnṣe.

4. Bó ṣe wà nínú Oníwàásù 7:9, kí ni kò yẹ ká ṣe tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn?

4 Ká sòótọ́, tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tó ṣe tààràtà, kì í rọrùn fún wa láti gbà á. Kódà, ó lè bí wa nínú. Kí nìdí? Ó máa ń rọrùn fún wa láti gbà pé aláìpé ni wá, àmọ́ kì í rọrùn láti gbà tẹ́nì kan bá sọ ibi tá a kù sí fún wa. (Ka Oníwàásù 7:9.) A lè má fẹ́ gbà pé òótọ́ lohun tẹ́ni náà sọ. A lè máa ronú pé kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ká bínú torí bó ṣe bá wa sọ̀rọ̀. Kódà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí ẹni náà, ká wá máa sọ pé: ‘Ṣé irú ẹ̀ ló yẹ kó wá gbà mí nímọ̀ràn? Òun náà ṣá máa ń ṣàṣìṣe!’ Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a lè má gba ìmọ̀ràn náà, ká sì fọ̀rọ̀ lọ ẹni tó máa sọ ohun táá bá wa lára mu.

5. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn tó gba ìmọ̀ràn àtàwọn tí kò gba ìmọ̀ràn nínú Bíbélì. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ohun táá jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa gba ìmọ̀ràn àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.

ÀWỌN TÍ KÒ GBA ÌMỌ̀RÀN

6. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Ọba Rèhóbóámù ṣe nígbà tí wọ́n gbà á nímọ̀ràn?

6 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Rèhóbóámù. Nígbà tó di ọba Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn ẹ̀ sọ pé kó ṣe ohun kan fún àwọn. Wọ́n ní kó dín iṣẹ́ tí Sólómọ́nì bàbá ẹ̀ ní káwọn máa ṣe kù. Ni Rèhóbóámù bá lọ bá àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn nípa ohun tí òun máa sọ fáwọn èèyàn náà, ohun tó ṣe yẹn sì bọ́gbọ́n mu. Àwọn àgbààgbà yẹn sọ fún un pé tó bá ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́, wọ́n máa tì í lẹ́yìn. (1 Ọba 12:3-7) Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ràn táwọn àgbààgbà yẹn gba Rèhóbóámù má tẹ́ ẹ lọ́rùn. Torí náà, ó lọ fọ̀rọ̀ lọ àwọn ojúgbà ẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn ọkùnrin tó lọ fọ̀rọ̀ lọ̀ yẹn ti lé lógójì (40) ọdún, torí náà wọ́n á ti nírìírí díẹ̀. (2 Kíró. 12:13) Àmọ́ ìmọ̀ràn burúkú ni wọ́n gba Rèhóbóámù. Wọ́n ní ṣe ni kó fi kún iṣẹ́ táwọn èèyàn náà ń ṣe. (1 Ọba 12:8-11) Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ṣe ló yẹ kí Rèhóbóámù gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, kóun lè ṣèpinnu tó tọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn táwọn ojúgbà ẹ̀ gbà á ló fara mọ́, ohun tó sì ṣe nìyẹn. Ibi tọ́rọ̀ náà já sí fún Rèhóbóámù àtàwọn èèyàn Ísírẹ́lì ò dáa rárá. Bíi ti Rèhóbóámù, ìmọ̀ràn tí wọ́n máa fún wa lè má bá wa lára mu. Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé Bíbélì ni wọ́n fi gbà wá nímọ̀ràn, ó yẹ ká gba ìmọ̀ràn náà.

7. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Ùsáyà?

7 Ọba Ùsáyà ò gba ìmọ̀ràn. Ó wọ ibì kan nínú tẹ́ńpìlì tó jẹ́ pé àwọn àlùfáà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti wọ ibẹ̀, ó sì fẹ́ sun tùràrí níbẹ̀. Àwọn àlùfáà Jèhófà sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà! Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí.” Kí ni Ùsáyà wá ṣe? Ká ní ó gba ìmọ̀ràn yẹn tó sì kúrò nínú tẹ́ńpìlì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bóyá Jèhófà ò bá dárí jì í. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni “inú bí Ùsáyà.” Kí nìdí tí kò fi gba ìmọ̀ràn táwọn àlùfáà yẹn fún un? Ó gbà pé torí pé ọba ni òun, òun lè ṣe ohunkóhun tí òun bá fẹ́. Àmọ́ Jèhófà ò fara mọ́ irú èrò yẹn. Torí pé Ùsáyà ṣe ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe, Jèhófà fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú, ó sì “ya adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.” (2 Kíró. 26:16-21) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ùsáyà kọ́ wa pé ẹni yòówù ká jẹ́, tá a bá kọ ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa látinú Bíbélì, a ò ní rí ojúure Jèhófà.

ÀWỌN TÓ GBA ÌMỌ̀RÀN

8. Kí ni Jóòbù ṣe nígbà tí wọ́n bá a wí?

8 Yàtọ̀ sáwọn tí kò gba ìbáwí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tán yìí, Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó gba ìbùkún nítorí pé wọ́n gba ìbáwí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni, síbẹ̀ ó bẹ̀rù Ọlọ́run. Nígbà tí ìdààmú bá a, ó sọ nǹkan tí kò yẹ kó sọ. Ìyẹn ló jẹ́ kí Jèhófà àti Élíhù bá a wí. Ṣé Jóòbù gba ìbáwí náà? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: ‘Mo sọ̀rọ̀, àmọ́ mi ò lóye, mo kó ọ̀rọ̀ mi jẹ, mo sì ronú pìwà dà nínú iyẹ̀pẹ̀ àti eérú.’ Jèhófà bù kún Jóòbù torí pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.​—Jóòbù 42:3-6, 12-17.

9. Kí ni Mósè ṣe nígbà tí wọ́n bá a wí, kí la sì lè kọ́ lára ẹ̀?

9 Mósè gba ìbáwí tí Jèhófà fún un lẹ́yìn tó ṣàṣìṣe, àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn sì jẹ́ fún wa. Ìgbà kan wà tó bínú gan-an tí kò sì bọlá fún Jèhófà. Ohun tí Mósè ṣe yìí ni ò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 20:1-13) Nígbà tí Mósè ń bẹ Jèhófà torí ìpinnu tí Jèhófà ṣe, Jèhófà sọ fún un pé: “O ò gbọ́dọ̀ bá mi sọ̀rọ̀ yìí mọ́.” (Diu. 3:23-27) Síbẹ̀, Mósè ò torí ìyẹn bínú. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gba ìbáwí tí Jèhófà fún un, Jèhófà sì jẹ́ kó máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìṣó. (Diu. 4:1) Àpẹẹrẹ rere ni Jóòbù àti Mósè jẹ́ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ ká máa gba ìbáwí. Jóòbù tún èrò ẹ̀ ṣe, kò sì wá bó ṣe máa dá ara ẹ̀ láre. Nígbà tí Jèhófà bá Mósè náà wí, ó gba ìbáwí, ó sì ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun ò ní wọ Ilẹ̀ Ìlérí.

10. (a) Àǹfààní wo ni Òwe 4:10-13 sọ pé a máa rí tá a bá ń gba ìbáwí? (b) Àpẹẹrẹ tó dáa wo làwọn kan fi lélẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn wí?

10 A máa jàǹfààní gan-an tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ bíi Jóòbù àti Mósè. (Ka Òwe 4:10-13.) Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn tí wọ́n sì ń gba ìbáwí. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Arákùnrin Emmanuel tó ń gbé ní Kóńgò sọ lẹ́yìn tí wọ́n kìlọ̀ fún un. Ó ní: “Àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn rí i pé mo fẹ́ ṣe ohun tó máa ba àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́. Mo gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún mi, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí n kó síṣòro.” * Nígbà tí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Megan lórílẹ̀-èdè Kánádà ń sọ nípa ojú tó fi máa ń wo ìbáwí, ó ní: “Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìbáwí máa ń bá mi lára mu, àmọ́ ohun tó yẹ kí n ṣe gan-an ni wọ́n ń sọ fún mi.” Arákùnrin Marko tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Croatia náà sọ pé: “Mi ò láǹfààní iṣẹ́ ìsìn mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá mi wí. Àmọ́ tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn, mo gbà pé ìbáwí yẹn ló jẹ́ kí n pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.”

11. Kí ni Arákùnrin Karl Klein sọ pé ó yẹ ká ṣe tí wọ́n bá bá wa wí?

11 Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tó jàǹfààní lẹ́yìn tó gba ìbáwí ni Arákùnrin Karl Klein tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbà kan tí Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ bá a wí. Arákùnrin Klein sọ pé ìbáwí tí wọ́n fún òun ò kọ́kọ́ bá òun lára mu. Ó sọ pé: “Nígbà tí èmi àti [Arákùnrin Rutherford] ríra, ó ní, ‘Pẹ̀lẹ́ o Karl!’ Àmọ́ torí pé inú ṣì ń bí mi, imú ni mo fi dá a lóhùn. Nígbà tí Arákùnrin Rutherford rí bí mo ṣe dá òun lóhùn, ó sọ pé, ‘Karl, ṣọ́ra o! Èṣù ń dọdẹ ẹ o!’ Ojú tì mí, mo wá sọ pé ‘Kò sí nǹkan kan Arákùnrin Rutherford.’ Àmọ́ ó mọ̀ pé inú ṣì ń bí mi. Torí náà, ó tún kìlọ̀ fún mi pé ‘Ó dáa, àmọ́ ṣọ́ra o, Èṣù ń dọdẹ ẹ.’ Òótọ́ lọ̀rọ̀ tó sọ! Tá a bá di arákùnrin wa sínú torí ó sọ ohun tó yẹ kó sọ fún wa . . . , ńṣe là ń ti ara wa sẹ́nu pàkúté Èṣù.” * (Éfé. 4:25-27) Arákùnrin Klein gba ìmọ̀ràn tí Arákùnrin Rutherford fún un, ọ̀rẹ́ wọn ò sì bà jẹ́.

KÍ LÓ MÁA JẸ́ KÁ GBA ÌBÁWÍ?

12. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè jẹ́ ká gba ìbáwí? (Sáàmù 141:5)

12 Kí ló máa jẹ́ ká gba ìbáwí? Ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì máa rántí pé aláìpé ni wá àti pé a máa ń hùwà òmùgọ̀ nígbà míì. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Jóòbù ní èrò tí kò tọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ó yí èrò ẹ̀ pa dà, Jèhófà sì bù kún un. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jóòbù nírẹ̀lẹ̀. Ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó gba ìbáwí tí Élíhù fún un, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Élíhù kéré sí i lọ́jọ́ orí. (Jóòbù 32:6, 7) Ìrẹ̀lẹ̀ tún máa jẹ́ ká ṣiṣẹ́ lórí ìbáwí tí wọ́n fún wa kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé kò yẹ kí wọ́n fún wa nírú ìbáwí yẹn tàbí tí ẹni tó sọ fún wa bá kéré sí wa lọ́jọ́ orí. Alàgbà kan ní Kánádà sọ pé, “Kò sí bá a ṣe lè tẹ̀ síwájú táwọn míì ò bá gbà wá nímọ̀ràn torí pé àwọn ló máa ń rí ibi tá a kù sí.” Gbogbo wa ló yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè túbọ̀ ní èso tẹ̀mí, ká sì túbọ̀ já fáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni.​—Ka Sáàmù 141:5.

13. Tí wọ́n bá bá wa wí, ojú wo ló yẹ ká fi wò ó?

13 Gbà pé torí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń bá ẹ wí. Ohun tó dáa jù ni Jèhófà fẹ́ fún wa. (Òwe 4:20-22) Ó máa ń bá wa wí nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tàbí àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ìyẹn ló sì ń fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Hébérù 12:9, 10 sọ pé: ‘Torí ire wa ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.’

14. Kí ló yẹ ká máa wò tí wọ́n bá bá wa wí?

14 Ohun tí wọ́n bá ẹ sọ ni kó o wò, má wo bí wọ́n ṣe sọ ọ́. Nígbà míì, tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn, ó lè máa ṣe wá bíi pé ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà sọ ọ́ kọ́ nìyẹn. Ká sòótọ́, ó yẹ kẹ́ni tó fẹ́ gba èèyàn nímọ̀ràn sapá láti sọ ọ́ lọ́nà tó máa rọrùn fún ẹni náà láti gbà á. * (Gál. 6:1) Tó bá jẹ́ àwa ni wọ́n gbà nímọ̀ràn, ohun tí wọ́n sọ fún wa ló yẹ ká wò, kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ yẹn ò dáa tó. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Tí inú mi ò bá tiẹ̀ dùn sí ohun tẹ́ni náà sọ fún mi, ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ wà níbẹ̀? Ṣé mo lè gbójú fo àìpé ẹni tó fún mi nímọ̀ràn kí n lè jàǹfààní látinú ohun tó sọ?’ A máa fi hàn pé a gbọ́n tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa.​—Òwe 15:31.

TÓ O BÁ JẸ́ KÁWỌN MÍÌ GBÀ Ẹ́ NÍMỌ̀RÀN, WÀÁ JÀǸFÀÀNÍ

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì?

15 Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Òwe 13:10 sọ pé: “Ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.” Ẹ ò rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí! Àwọn tó máa ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì sábà máa ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, tá a bá fi wọ́n wé àwọn tí kì í gbàmọ̀ràn. Torí náà, rí i pé ò ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì.

Kí nìdí tí arábìnrin ọ̀dọ́ kan ṣe ní kí arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ gba òun nímọ̀ràn? (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa mú ká gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì?

16 Ìgbà wo la lè ní kí àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà gbà wá nímọ̀ràn? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan. (1) Arábìnrin kan ní kí akéde kan tó nírìírí tẹ̀ lé òun lọ sọ́dọ̀ ẹni tóun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbẹ̀, ó ní kí akéde náà gba òun nímọ̀ràn ohun tóun lè ṣe kóun lè túbọ̀ di olùkọ́ tó já fáfá. (2) Nígbà tí arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ fẹ́ ra aṣọ, ó ní kí arábìnrin míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ bá òun wò ó bóyá aṣọ tóun fẹ́ rà bójú mu. (3) Nígbà tí arákùnrin kan fẹ́ sọ àsọyé nígbà àkọ́kọ́, ó sọ fún arákùnrin kan tó ti ń sọ àsọyé tipẹ́ pé kó máa fọkàn bá òun lọ bóun ṣe ń sọ àsọyé náà. Ó sì ní kó sọ àwọn ibi tó yẹ kóun ti ṣàtúnṣe kóun lè tẹ̀ síwájú. Kódà, arákùnrin kan tó ti ń sọ àsọyé fún ọ̀pọ̀ ọdún lè lọ bá arákùnrin míì tóun náà ti ń sọ àsọyé tipẹ́ pé kó sọ àwọn ibi tó yẹ kóun ti ṣàtúnṣe nínú àsọyé tóun sọ, kó sì rí i pé òun ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn tí arákùnrin náà bá fún òun.

17. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàmọ̀ràn?

17 Láwọn ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù mélòó kan sígbà tá a wà yìí, gbogbo wa ni wọ́n máa gbà nímọ̀ràn. Ìmọ̀ràn náà lè ṣe tààràtà, ó sì lè má ṣe tààràtà. Tó bá ti ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ rántí àwọn nǹkan tá a jíròrò yìí. Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ohun tí wọ́n bá ẹ sọ ni kó o wò, kì í ṣe bí wọ́n ṣe sọ ọ́, kó o sì rí i pé o ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn náà. Ó ṣe tán, kò sẹ́nì kankan tó gbọ́n tán nínú wa. Torí náà, tá a bá ń ‘fetí sí ìmọ̀ràn tá a sì ń gba ìbáwí,’ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé a máa “di ọlọ́gbọ́n.”​—Òwe 19:20.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

^ ìpínrọ̀ 5 Àwa èèyàn Jèhófà mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti gba ìmọ̀ràn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Kí ló sì máa jẹ́ ká jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wa?

^ ìpínrọ̀ 10 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 11 Wo Ilé Ìṣọ́ April, 15 1985, ojú ìwé 21-28.

^ ìpínrọ̀ 14 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn tó ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn ṣe lè sọ ọ́ lọ́nà tó máa rọrùn fún wọn láti gbà á.