Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni Bíbélì sọ nípa agbára tí Jèhófà ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Àìsá. 45:21) Àmọ́ Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ fún wa nípa bí Jèhófà ṣe ń mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àti ìgbà tó máa ń sọ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ bó ṣe máa ń wù ú tó láti mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká da ara wa láàmú torí Jèhófà nìkan ló mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tá a mọ̀.
Jèhófà máa ń ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́, àfi èyí tó bá sọ pé òun ò ní ṣe. Torí pé ọgbọ́n Jèhófà pọ̀ gan-an tí ò sì láàlà, òun nìkan ló lè sọ ohun tó bá fẹ́ kó ṣẹlẹ̀. (Róòmù 11:33) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé ó lè kó ara ẹ̀ níjàánu, ó lè sọ pé òun ò fẹ́ mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀.—Fi wé Àìsáyà 42:14.
Jèhófà máa ń jẹ́ kí ohun tó bá sọ ṣẹ. Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe kan bí Jèhófà ṣe lágbára láti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Àìsáyà 46:10 sọ pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀, mò ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, tipẹ́tipẹ́ ni mo sì ti ń sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀. Mo sọ pé, ‘ìpinnu mi máa dúró, màá sì ṣe ohunkóhun tó bá wù mí.’”
Torí náà, ohun tó jẹ́ ká gbà pé Jèhófà lágbára láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni pé ó lágbára láti jẹ́ káwọn nǹkan náà ṣẹlẹ̀. Táwọn èèyàn bá fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nínú eré kan, àfi kí wọ́n wò ó parí. Àmọ́ ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kí Jèhófà wo ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kó tó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, Jèhófà lè pinnu pé kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ lásìkò pàtó kan, tí àsìkò yẹn bá sì tó, nǹkan náà máa ṣẹlẹ̀.—Ẹ́kís. 9:5, 6; Mát. 24:36; Ìṣe 17:31.
Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ṣètò,” “mọ ọ́n” àti “ní in lọ́kàn” tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú. (2 Ọba 19:25; àlàyé ìsàlẹ̀; Àìsá. 46:11) Inú ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan tó túmọ̀ sí “amọ̀kòkò” la ti tú àwọn ọ̀rọ̀ yìí. (Jer. 18:4) Bí amọ̀kòkò kan tó mọṣẹ́ ṣe lè fi amọ̀ mọ ìkòkò tó rẹwà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe lè mú káwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ kí ìfẹ́ ẹ̀ lè ṣẹ.—Éfé. 1:11.
Jèhófà máa ń fẹ́ káwọn èèyàn fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Jèhófà kì í kádàrá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé òun kọ́ ló ń mú káwọn olóòótọ́ ọkàn ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n pa run. Torí náà, ó máa ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, ó sì máa ń gbà wá níyànjú pé ká ṣe ohun tó tọ́.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì. Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ ni àwọn ará ìlú Nínéfè. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa ìlú yẹn run torí ìwà burúkú táwọn èèyàn ibẹ̀ ń hù. Àmọ́ nígbà táwọn èèyàn yẹn yí pa dà, Jèhófà “pèrò dà nípa àjálù tó sọ pé òun máa mú kó dé bá wọn, kò sì jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wọn.” (Jónà 3:1-10) Ìdí tí Jèhófà fi pèrò dà nípa àjálù tó sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn ni pé àwọn ará ìlú Nínéfè fúnra wọn ló pinnu pé àwọn máa yí pa dà torí ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún wọn.
Àpẹẹrẹ kejì ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀gágun kan tó ń jẹ́ Kírúsì. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé ó máa dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn, ó sì máa pàṣẹ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. (Àìsá. 44:26–45:4) Ọba Kírúsì ti ilẹ̀ Páṣíà mú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ. (Ẹ́sírà 1:1-4) Àmọ́ Kírúsì kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà. Síbẹ̀, Jèhófà lo Kírúsì láti mú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ láìfi dandan mú un pé kó wá jọ́sìn òun.—Òwe 21:1.
Díẹ̀ rèé lára àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ń ṣe tó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ká sòótọ́, kò sẹ́nì kankan tó lè lóye bí Jèhófà ṣe ń ronú àti kúlẹ̀kúlẹ̀ nǹkan tó ń ṣe. (Àìsá. 55:8, 9) Àmọ́ àwọn nǹkan tá a mọ̀ nípa Jèhófà ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára gan-an pé gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tó tọ́, títí kan àwọn nǹkan tó sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.