ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7
ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!
Àǹfààní Tá À Ń Rí Tí Jèhófà Bá Dárí Jì Wá
“Ìdáríjì tòótọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ.”—SM. 130:4.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ìdáríjì tòótọ́. Ìyẹn sì máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.
1. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro láti mọ̀ pé ẹnì kan ti dárí jì wá?
“MO DÁRÍ JÌ Ẹ́.” Ó dájú pé ara máa tù ẹ́ gan-an tó bá jẹ́ pé ẹni tó o ṣẹ̀ ló sọ bẹ́ẹ̀ fún ẹ. Àmọ́ kí ni gbólóhùn náà, “mo dárí jì ẹ́” túmọ̀ sí? Ṣé ohun tẹ́ni yẹn ń sọ ni pé kẹ́ ẹ ṣì máa ṣọ̀rẹ́ nìṣó? Àbí ohun tó ń sọ ni pé kẹ́ ẹ gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ ọ̀rẹ́ yín ò ní fi bẹ́ẹ̀ gún régé mọ́? Torí náà, ohun tó máa ń wà lọ́kàn àwọn èèyàn máa ń yàtọ̀ síra tí wọ́n bá sọ pé àwọn dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wọ́n.
2. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
2 Bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá yàtọ̀ gan-an sí báwa èèyàn ṣe máa ń dárí ji ara wa. Kò sẹ́ni tó lè dárí jini bíi Jèhófà. Onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà pé: “Ìdáríjì tòótọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bọ̀wọ̀ fún ọ.” a (Sm. 130:4) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn torí ọ̀dọ̀ Jèhófà lèèyàn ti lè rí “ìdáríjì tòótọ́.” Òun ló mọ ohun tí ìdáríjì tòótọ́ jẹ́. Láwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n lo ọ̀rọ̀ kan láti ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá, wọn kì í sì í lò ó tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa báwa èèyàn ṣe ń dárí ji ara wa.
3. Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà dárí jì wá ṣe yàtọ̀ sí tàwa èèyàn? (Àìsáyà 55:6, 7)
3 Tí Jèhófà bá dárí jì wá, ó ti mú ẹ̀ṣẹ̀ náà kúrò pátápátá nìyẹn. Àá tún pa dà di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà máa ń dárí jì wá fàlàlà ní gbogbo ìgbà!—Ka Àìsáyà 55:6, 7.
4. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ ìdáríjì tòótọ́?
4 Ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà dárí jì wá yàtọ̀ sí tàwa èèyàn, torí náà báwo làwa èèyàn aláìpé ṣe lè mọ ohun tí ìdáríjì tòótọ́ jẹ́? Àwọn àpèjúwe tó dáa gan-an ni Jèhófà lò ká lè mọ bó ṣe ń dárí jì wá. A máa gbé àwọn kan lára wọn yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Wọ́n máa jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, ó sì máa jẹ́ ká pa dà di ọ̀rẹ́ òun. Bá a ṣe ń gbé àwọn àpèjúwe náà yẹ̀ wò, a máa mọyì bí Jèhófà Bàbá wa aláàánú ṣe ń dárí jì wá lónírúurú ọ̀nà.
JÈHÓFÀ Ń MÚ Ẹ̀ṢẸ̀ KÚRÒ
5. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?
5 Bíbélì sábà máa ń fi ẹ̀ṣẹ̀ wé ẹrù tó wúwo. Ohun tí Ọba Dáfídì fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wé nìyẹn, ó sọ pé: “Àwọn àṣìṣe mi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí mi; bí ẹrù tó wúwo, wọ́n ti wúwo ju ohun tí mo lè gbé.” (Sm. 38:4) Àmọ́ Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Sm. 25:18; 32:5) Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “dárí jì” túmọ̀ sí “gbé sókè” tàbí “gbé.” Èyí jẹ́ ká rí i pé alágbára ni Jèhófà, ó sì máa ń gbé àwọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò léjìká wa, á sì gbé wọn lọ.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa tó?
6 Àpèjúwe míì nínú Bíbélì sọ bí Jèhófà ṣe máa ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Sáàmù 103:12 sọ pé: “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.” Ìlà oòrùn jìnnà gan-an sí ìwọ̀ oòrùn, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì wà. Ohun tá à ń sọ ni pé Jèhófà máa ń mú kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà gan-an sí wa. Ẹ ò rí i pé àpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an!
7. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ohun tí Jèhófà máa ń ṣe sáwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa? (Míkà 7:18, 19)
7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń mú káwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà gan-an sí wa, ṣé ó máa ń fìyà ẹ̀ jẹ wá? Rárá o. Ọba Hẹsikáyà sọ nípa Jèhófà pé: “O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.” Tàbí bí àlàyé ìsàlẹ̀ ṣe sọ, o ti “mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi kúrò níwájú rẹ.” (Àìsá. 38:9, 17; àlàyé ìsàlẹ̀) Àpèjúwe yìí fi hàn pé Jèhófà máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ronú pìwà dà kúrò níwájú ẹ̀. Ọ̀nà míì tá a lè gbà sọ ọ̀rọ̀ yìí ni pé: “O ti jẹ́ kí [ẹ̀ṣẹ̀ mi] dà bí èyí tí ò wáyé rí.” Bíbélì tún ọ̀rọ̀ yìí sọ nínú àpèjúwe míì tó wà ní Míkà 7:18, 19. (Kà á.) Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé Jèhófà ju àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sísàlẹ̀ òkun. Ẹ má sì gbàgbé pé láyé àtijọ́, tí wọ́n bá ju nǹkan kan sísàlẹ̀ òkun, wọn ò lè rí i mọ́.
8. Kí la ti kọ́?
8 Àwọn àpèjúwe yìí ti jẹ́ ká rí i pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, ó ti mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò nìyẹn, kò sì yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi mọ́. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ pé, “aláyọ̀ ni àwọn tí a dárí ìwà wọn tí kò bófin mu jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀; aláyọ̀ ni ẹni tí Jèhófà kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí lọ́rùn lọ́nàkọnà.” (Róòmù 4:6-8) Ẹ ò rí i pé ìyẹn gan-an ni ìdáríjì tòótọ́!
JÈHÓFÀ Ń PA ÀWỌN Ẹ̀ṢẸ̀ WA RẸ́
9. Àwọn àpèjúwe wo ni Jèhófà lò tó jẹ́ ká mọ̀ pé òun lè dárí jì wá pátápátá?
9 Jèhófà lo àwọn àpèjúwe míì tó jẹ́ ká mọyì bó ṣe ń fi ẹbọ ìràpadà pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó bá ronú pìwà dà rẹ́. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà máa ń fọ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ìyẹn sì máa sọ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà di mímọ́. (Sm. 51:7; Àìsá. 4:4; Jer. 33:8) Ohun tí Jèhófà sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà nìyẹn, ó ní: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín; bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò, wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.” (Àìsá. 1:18) Ká sòótọ́, ó máa ń ṣòro gan-an kéèyàn tó lè fọ aṣọ tó pọ́n, kó sì di funfun. Síbẹ̀, àpèjúwe tí Jèhófà lò yìí mú kó dá wa lójú pé òun lè fọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá.
10. Àpèjúwe míì wo ni Jèhófà fi ṣàlàyé bó ṣe máa ń dárí jì wá fàlàlà?
10 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a tún lè fi ẹ̀ṣẹ̀ wé “gbèsè.” (Mát. 6:12; Lúùkù 11:4) Torí náà, gbogbo ìgbà tá a bá ṣẹ Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé à ń jẹ gbèsè kún gbèsè. Gbèsè náà á wá pọ̀ rẹpẹtẹ! Àmọ́ nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ńṣe ló dà bíi pé ó fagi lé gbogbo gbèsè náà. Jèhófà kì í sọ pé ká san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dárí ẹ̀ jì wá. Ẹ ò rí i pé àpèjúwe yìí mára tù wá gan-an torí ó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá!
11. Tí Bíbélì bá sọ pé wọ́n ‘pa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan rẹ́,’ kí ló ń sọ? (Ìṣe 3:19)
11 Jèhófà kì í fagi lé gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa nìkan, ó tún máa ń pa wọ́n rẹ́. (Ka Ìṣe 3:19.) Wo àpèjúwe yìí: Tá a bá fagi lé gbèsè kan lórí bébà, àá ṣì máa rí nọ́ńbà tá a fagi lé náà. Àmọ́ tá a bá pa á rẹ́, a ò ní rí nǹkan kan níbẹ̀ mọ́. Kí àpèjúwe yìí lè yé wa dáadáa, ẹ má gbàgbé pé láyé àtijọ́, tí wọ́n bá fi yíǹkì kọ nǹkan sórí pátákó, ó máa ń rọrùn láti fi kànrìnkàn tó lómi pa nǹkan náà rẹ́. Torí náà, tí wọ́n bá ‘pa gbèsè rẹ́,’ ó ti pa rẹ́ nìyẹn. A ò lè rí ohun tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ mọ́. Á wá dà bíi pé ẹni náà ò jẹ gbèsè rárá. Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà kì í fagi lé ẹ̀ṣẹ̀ wa nìkan, ó tún máa ń pa á rẹ́ pátápátá!—Sm. 51:9.
12. Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀?
12 Jèhófà lo àpèjúwe míì láti fi ṣàlàyé bóun ṣe máa ń pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ó sọ pé: “Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu nù ún, màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi [ìkùukùu] tó ṣú bolẹ̀ nù ún.” (Àìsá. 44:22) Tí Jèhófà bá dárí jì wá, ńṣe ló dà bí ìgbà tó fi ìkùukùu tó ṣú bolẹ̀ bo ẹ̀ṣẹ̀ wa, ká má bàa rí i mọ́.
13. Tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí ni ò yẹ ká ṣe?
13 Kí la rí kọ́ nínú àwọn àpèjúwe yẹn? Ohun tá a kọ́ ni pé tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò yẹ ká máa dára wa lẹ́bi mọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ìdí ni pé ó ti fi ẹ̀jẹ̀ Jésù pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́ pátápátá. Kódà tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ńṣe ló dà bíi pé a ò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan rí. Torí náà, ohun tí Jèhófà máa ṣe fún wa nìyẹn tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.
JÈHÓFÀ MÁA Ń JẸ́ KÁ PA DÀ DI Ọ̀RẸ́ ÒUN
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jèhófà pé ó máa dárí jì wá pátápátá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó máa ń jẹ́ ká pa dà di ọ̀rẹ́ òun. Ìyẹn kì í jẹ́ ká máa dára wa lẹ́bi ṣáá. Torí náà, kò yẹ ká máa bẹ̀rù pé Jèhófà ò tíì dárí jì wá àti pé ó máa fìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ wá, torí pé Jèhófà ò ní ṣe irú ẹ̀ láé. Tí Jèhófà bá sọ pé òun ti dárí jì wá, kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán an? Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Jer. 31:34) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ ọ̀rọ̀ tó jọ ọ́, ó ní: “Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Héb. 8:12) Àmọ́, kí ni Jèhófà ń sọ gan-an?
15. Kí ni Jèhófà ń sọ nígbà tó sọ pé òun ò ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́?
15 Kì í ṣe gbogbo ìgbà tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “rántí” ló máa ń túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ro nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Ó tún kan kéèyàn ṣe nǹkan kan nípa ohun tó ń rò. Ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́ òpó igi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù bẹ̀ ẹ́ pé: “Jésù, rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” (Lúùkù 23:42, 43) Ọkùnrin náà ò sọ pé kí Jésù kàn rántí òun, àmọ́ ó fẹ́ kó ṣe nǹkan kan fóun ni. Ohun tí Jésù sọ fún un fi hàn pé ó máa jí i dìde. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ pé òun ò ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́, ohun tó ń sọ ni pé òun ti dárí jì wá pátápátá, òun ò sì ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá lọ́jọ́ iwájú.
16. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe òmìnira tá a máa gbádùn tí Jèhófà bá dárí jì wá?
16 Bíbélì tún lo àpèjúwe kan tó fi ṣàlàyé òmìnira tá a máa gbádùn tí Jèhófà bá dárí jì wá. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún, Bíbélì fi wá wé “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” Àmọ́, tí Jèhófà bá dárí jì wá, a máa dà bí ẹrú “tí a ti dá . . . sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:17, 18; Ìfi. 1:5) Torí náà, tá a bá mọ̀ pé Jèhófà ti dárí jì wá, ọkàn wa máa balẹ̀ bíi ti ẹrú tó gbòmìnira.
17. Báwo la ṣe ń rí ìwòsàn tí Jèhófà bá dárí jì wá? (Àìsáyà 53:5)
17 Ka Àìsáyà 53:5. Àpèjúwe tó kẹ́yìn fi wá wé àwọn èèyàn tó ní àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí. Nítorí pé Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ rà wá pa dà, ó jẹ́ ká rí ìwòsàn. (1 Pét. 2:24) Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a ti ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́ nìyẹn, àmọ́ ìràpadà jẹ́ kó lè dárí jì wá, ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti pa dà di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Tẹ́nì kan bá ní aìsàn tó le gan-an tó sì rí ìwòsàn, inú ẹ̀ máa dùn. Bẹ́ẹ̀ náà ni inú wa máa ń dùn tí Jèhófà bá dárí jì wá, tá a sì pa dà rí ojú rere rẹ̀.
ÀǸFÀÀNÍ TÁ À Ń RÍ TÍ JÈHÓFÀ BÁ DÁRÍ JÌ WÁ
18. Kí la rí kọ́ nínú àwọn àpèjúwe Bíbélì tó sọ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá? (Tún wo àpótí náà, “Bí Jèhófà Ṣe Ń Dárí Jì Wá.”)
18 Kí la rí kọ́ nínú àwọn àpèjúwe Bíbélì tó sọ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá? Ohun tá a kọ́ ni pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, ó ti dárí jì wá pátápátá nìyẹn, kò sì ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn máa jẹ́ ká pa dà di ọ̀rẹ́ Jèhófà Bàbá wa ọ̀run. Bákan náà, a tún mọ̀ pé ìdáríjì jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ìfẹ́ àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà ń fi hàn sáwa ẹlẹ́ṣẹ̀ ló ń mú kó dárí jì wá, kì í ṣe pé a lẹ́tọ̀ọ́ sí i.—Róòmù 3:24.
19. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà? (Róòmù 4:8) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Ka Róòmù 4:8. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá pé ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan la ti lè rí “ìdáríjì tòótọ́”! (Sm. 130:4) Àmọ́, kí Jèhófà tó lè dárí jì wá, ohun pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Jésù sọ pé: “Tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.” (Mát. 6:14, 15) Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká fìwà jọ Jèhófà, ká sì máa dárí jini. Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe é? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé ẹ̀ fún wa.
ORIN 46 A Dúpẹ́, Jèhófà
a Bí ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣe lo ìdáríjì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ìdáríjì tòótọ́ ti ń wá, ó sì yàtọ̀ pátápátá sí báwa èèyàn ṣe máa ń dárí ji ara wa.